ORÍ 25
Jésù Fàánú Hàn sí Adẹ́tẹ̀ Kan, Ó sì Wò Ó Sàn
MÁTÍÙ 8:1-4 MÁÀKÙ 1:40-45 LÚÙKÙ 5:12-16
JÉSÙ WO ADẸ́TẸ̀ KAN SÀN
Bí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mẹ́rin ṣe ń wàásù nínú “àwọn sínágọ́gù wọn káàkiri gbogbo Gálílì,” àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. (Máàkù 1:39) Kódà wọ́n ròyìn rẹ̀ dé ìlú tí ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan wà. Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn sọ pé ‘ẹ̀tẹ̀ bo’ ọkùnrin náà. (Lúùkù 5:12) Àrùn burúkú yìí le débi pé tó bá ti pẹ́ lára, ṣe lá máa ba àwọn ẹ̀yà ara jẹ́ díẹ̀díẹ̀.
Torí náà, ipò tí adẹ́tẹ̀ náà wà le gan-an, Òfin sì sọ pé ó gbọ́dọ̀ kúrò láàárín àwọn èèyàn. Yàtọ̀ síyẹn tó bá wà nítòsí àwọn èèyàn, ó gbọ́dọ̀ máa kígbe pé “Aláìmọ́, aláìmọ́!” kí wọ́n má bàa sún mọ́ ọn débi tí wọ́n á fi kó àrùn náà. (Léfítíkù 13:45, 46) Àmọ́ kí ni adẹ́tẹ̀ yìí ṣe? Ṣe ló lọ bá Jésù, ó sì forí balẹ̀ fún un, ó sọ pé: “Olúwa, tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”—Mátíù 8:2.
Ẹ ò rí i pé ọkùnrin yẹn ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù! Ó dájú pé àánú rẹ̀ máa ṣe Jésù gan an! Kí ni Jésù máa wá ṣe báyìí? Ká sọ pé o wà níbẹ̀, kí ni wàá ṣe? Àánú ọkùnrin náà ṣe Jésù, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án. Jésù wá sọ fún un pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.” (Mátíù 8:3) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ẹ̀tẹ̀ náà kúrò lára ọkùnrin náà, ara rẹ̀ sì yá bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún àwọn kan láti gba ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn gbọ́.
Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ ká sọ pé ẹnì kan bíi Jésù tó jẹ́ aláàánú àti alágbára ló ń ṣàkóso? Bí Jésù ṣe fàánú hàn sí adẹ́tẹ̀ yẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tí Jésù Ọba wa bá ń ṣàkóso ayé, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí á nímùúṣẹ pé: “Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà, yóò sì gba ẹ̀mí àwọn tálákà là.” (Sáàmù 72:13) Ó dá wa lójú pé tó bá dìgbà yẹn, Jésù máa ran gbogbo àwọn tó níṣòro lọ́wọ́.
Ẹ rántí pé kí Jésù tiẹ̀ tó wo adẹ́tẹ̀ yìí sàn ni àwọn èèyàn ti ń kan sárá sí i torí àwọn nǹkan tó ń ṣe. Ní báyìí, àwọn èèyàn máa tún gbọ́ nípa iṣẹ́ àgbàyanu tó ṣe yìí. Àmọ́ Jésù ò fẹ́ kí àwọn èèyàn gba òun gbọ́ kìkì nítorí ohun tí wọ́n gbọ́ nípa òun. Ó mọ àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé kò “ní jẹ́ ká gbọ́ ohùn rẹ̀ lójú ọ̀nà” ìyẹn ni pé kò fẹ́ káwọn èèyàn kàn máa sọ ohun tí wọ́n rò nípa òun. (Àìsáyà 42:1, 2) Ìdí nìyẹn tó fi sọ fún adẹ́tẹ̀ tó wò sàn pé: “Rí i pé o ò sọ fún ẹnì kankan, àmọ́ lọ, kí o fi ara rẹ han àlùfáà, kí o sì mú ẹ̀bùn tí Mósè sọ lọ.”—Mátíù 8:4.
Ẹ̀yin náà kúkú mọ bí inú ọkùnrin náà ṣe máa dùn tó pé ara òun ti yá, kò sì lè pa á mọ́ra. Torí náà, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í tan ìròyìn náà kiri. Èyí wá mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ mọ̀ sí i nípa Jésù. Kódà, ó le débi pé Jésù ò lè lọ sáàárín ìlú mọ́, ibi àdádó ló lọ ń gbé fúngbà díẹ̀. Síbẹ̀, àwọn èèyàn níbi gbogbo ṣì ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè kọ́ wọn, kó sì wò wọ́n sàn.