ORÍ 28
Kí Nìdí Tí Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Kò Fi Gbààwẹ̀?
MÁTÍÙ 9:14-17 MÁÀKÙ 2:18-22 LÚÙKÙ 5:33-39
ÀWỌN ỌMỌLẸ́YÌN JÒHÁNÙ TỌ JÉSÙ LỌ, WỌ́N SÌ BÉÈRÈ ÌDÍ TÍ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN TIẸ̀ KÒ FI GBÀÀWẸ̀
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù lọ sí Ìrékọjá tí wọ́n ṣe lọ́dún 30 S. K. ni wọ́n ju Jòhánù Arinibọmi sẹ́wọ̀n. Jòhánù fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa tẹ̀ lé Jésù, àmọ́ kì í ṣe gbogbo wọn ló ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ju Jòhánù sẹ́wọ̀n.
Bí Ìrékọjá ọdún 31 S.K. ṣe ń sún mọ́lé, àwọn ọmọlẹ́yìn Jòhánù kan wá bá Jésù, wọ́n bi í pé: “Kí ló dé tí àwa àti àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀ àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?” (Mátíù 9:14) Ìdí sì ni pé àwọn Farisí ti sọ ààwẹ̀ di apá pàtàkì nínú ìjọsìn wọn. Nígbà tó yá, Jésù sọ àpèjúwe nípa Farisí kan tó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀, tó wá ń gbàdúrà pé: “Ọlọ́run, mo dúpẹ́ pé mi ò dà bíi gbogbo àwọn èèyàn yòókù . . . Ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ni mò ń gbààwẹ̀.” (Lúùkù 18:11, 12) Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jòhánù náà ti sọ ààwẹ̀ gbígbà dàṣà tàbí kí wọ́n máa gbààwẹ̀ láti fi ṣọ̀fọ̀ Jòhánù tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n. Àwọn kan tiẹ̀ lè máa ronú pé kí nìdí tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kò fi gbààwẹ̀ torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jòhánù.
Jésù fi àpèjúwe kan dá wọn lóhùn, ó ní: “Kò sí ohun tó máa mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó ṣọ̀fọ̀ tí ọkọ ìyàwó bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, àbí ó wà? Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọ́n máa wá gbààwẹ̀.”—Mátíù 9:15.
Jòhánù fúnra rẹ̀ tiẹ̀ pe Jésù ní ọkọ ìyàwó. (Jòhánù 3:28, 29) Ìdí nìyẹn tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò fi gbààwẹ̀ nígbà tí Jésù wà pẹ̀lú wọn. Tí Jésù bá wá kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ á ṣọ̀fọ̀, wọn ò sì ní lè jẹun. Àmọ́ tó bá jíǹde, kò ní sídìí fún wọn láti máa gbààwẹ̀ tàbí ṣọ̀fọ̀ mọ́.
Lẹ́yìn ìyẹn Jésù sọ àpèjúwe méjì yìí: “Kò sí ẹni tó máa rán ègé aṣọ tí kò tíì sún kì mọ́ ara aṣọ àwọ̀lékè tó ti gbó, torí aṣọ tuntun náà máa ya kúrò lára aṣọ àwọ̀lékè náà, ó sì máa ya ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àwọn èèyàn kì í sì í rọ wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti gbó. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àpò náà máa bẹ́, wáìnì á dà nù, àpò náà á sì bà jẹ́. Àmọ́ inú àpò awọ tuntun ni àwọn èèyàn máa ń rọ wáìnì tuntun sí.” (Mátíù 9:16, 17) Kí ni Jésù ní lọ́kàn?
Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù mọ̀ pé kò sídìí táwọn ọmọ ẹ̀yìn òun á fi máa gbààwè bíi tàwọn Júù. Jésù ò fọwọ́ sí ìjọsìn wọn torí ó mọ̀ pé oríṣiríṣi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ni wọ́n ti mú wọnú ẹ̀. Kò sì wá láti ṣàtúnṣe sí i, torí ó mọ̀ pé kò ní pẹ́ kógbá sílé. Jésù ò fẹ́ rán aṣọ tuntun mọ́ aṣọ tó ti gbó, kò sì fẹ́ da wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti bà jẹ́.