Sin Jèhófà Láìsí Ìpínyà Ọkàn
“Màríà . . . ń fetí sí ọ̀rọ̀ [Jésù]. Màtá . . . ní ìpínyà-ọkàn nítorí bíbójútó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe.”—LÚÙKÙ 10:39, 40.
1, 2. Kí nìdí tí Jésù fi nífẹ̀ẹ́ Màtá, àmọ́ àṣìṣe wo ni Màtá ṣe tó fi hàn pé kì í ṣe ẹni pípé?
KÍ LÓ máa ń wá sọ́kàn rẹ tó o bá rántí Màtá, arábìnrin Lásárù? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun nìkan ni Bíbélì dárúkọ rẹ̀ ní tààràtà pé Jésù fẹ́ràn, Jésù tún ní ìfẹ́ àtọkànwá fún àwọn obìnrin míì bíi Màríà ìyá rẹ̀ ọ̀wọ́n àti arábìnrin Màtá tó ń jẹ́ Màríà. (Jòh. 11:5; 19:25-27) Kí wá nìdí tí ìwé Ìhìn Rere fi sọ̀rọ̀ Màtá lọ́nà yìí?
2 Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àlejò ó sì máa ń ṣiṣẹ́ kára. Ṣùgbọ́n ohun tó mú kó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an ni pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára. Màtá gba àwọn ẹ̀kọ́ Jésù gbọ́ tọkàntọkàn, kò sì ṣiyè méjì pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Jòh. 11:21-27) Síbẹ̀, Màtá kì í ṣe ẹni pípé torí pé òun náà máa ń ṣàṣìṣe bíi ti gbogbo èèyàn. Nígbà kan tí Màtá gba Jésù lálejò, ó sọ fún Jésù pé ó yẹ kó bá Màríà wí torí pé kò bá òun ṣiṣẹ́. Màtá sọ pé: “Olúwa, kò ha jámọ́ nǹkan kan fún ọ pé arábìnrin mi ti fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan? Sọ fún un . . . kí ó dara pọ̀ ní ríràn mí lọ́wọ́.” (Ka Lúùkù 10:38-42.) Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí?
MÀTÁ NÍ ÌPÍNYÀ ỌKÀN
3, 4. Ọ̀nà wo ni Màríà gbà yan “ìpín rere,” kí ló sì dájú pé Màtá rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ náà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
3 Jésù mọrírì bí Màtá àti Màríà ṣe gbà á lálejò, torí náà ó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Màríà lo àǹfààní yẹn láti gba ìmọ̀ látọ̀dọ̀ Olùkọ́ Ńlá náà, ó jókòó “lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa . . . ó sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.” Ohun tó yẹ kí Màtá náà ṣe nìyẹn. Ó sì dájú pé tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù á gbóríyìn fún un pé kì í ṣe oúnjẹ tó ń gbọ́ nìkan ló gbájú mọ́.
4 Àmọ́ ọkàn Màtá ò pa pọ̀, ńṣe ló ń sè tó ń sọ̀ kí ara lè tu Jésù. Gbogbo bó sì ṣe ń dá mú tibí tó ń dá mú tọ̀hún múnú bí i torí pé Màríà ò bá a dá sí i. Jésù rí i pé oúnjẹ tí Màtá ń sè ti pọ̀ jù, torí náà ó fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ fún un pé: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀.” Ó wá sọ́ fún un pé oúnjẹ kan ṣoṣo ti tó. Àmọ́, Jésù gbóríyìn fún Màríà, ó sọ pé: “Ní tirẹ̀, Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Màríà lè tètè gbàgbé ohun tó jẹ lọ́jọ́ yẹn, kò jẹ́ gbàgbé bí Jésù ṣe gbóríyìn fún un àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó gbọ́ látẹnu rẹ̀ torí pé ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Lẹ́yìn ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún, àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀.” (Jòh. 11:5) Gbólóhùn yìí fi hàn pé Màtá gba ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Jésù fún un, ó sì sapá láti sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.
5. Kí nìdí tó fi túbọ̀ ṣòro láti pọkàn pọ̀ lóde òní? Ìbéèrè wo lèyí lè mú ká bi ara wa?
5 Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà lónìí tí kì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn, wọ́n sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé: “Kò tíì sígbà kankan nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn tí ẹ̀rọ ìgbàlódé pọ̀ tó báyìí rí.” Ìdí tọ́rọ̀ sì fi rí bẹ́ẹ̀ nígbà yẹn ni pé ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ṣe àwọn ohun tí kì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀ jáde. Àwọn nǹkan bí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ayára bí àṣá, ìwé ìròyìn tó ní àwòrán aláràbarà, rédíò, sinimá, tẹlifíṣọ̀n àti onírúurú ọ̀nà téèyàn lè gbà báni sọ̀rọ̀ di ohun tó wọ́pọ̀. Ìyẹn mú káwọn èèyàn máa sọ nígbà yẹn pé “Ayé Ọ̀làjú” la wà yìí. Àmọ́ bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, wọ́n wá rí i pé ayé ti ń di “Ayé Ìpínyà Ọkàn.” Bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí ní ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn, mélòómélòó wá ni lóde òní! Abájọ tí ìwé ìròyìn Ile-Iṣọ Na ti September 15, ọdún 1958 fi sọ pé: “Bí òpin ayé yìí ṣe ń sún mọ́lé, ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan tí kì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀ máa pọ̀ sí i.” Bọ́rọ̀ sì ṣe rí gan-an nìyẹn. Ńṣe ni ọ̀pọ̀ ohun tí kì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀ ń pọ̀ sí i ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Torí náà, ìbéèrè pàtàkì kan wà tó yẹ ká bi ara wa. Ìbéèrè náà sì ni pé: Kí la lè ṣe ká má bàa gba ìpínyà ọkàn láyè, ká lè máa pọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn wa bíi ti Màríà?
MÁ ṢE LO AYÉ DÉ Ẹ̀KÚNRẸ́RẸ́
6. Ọ̀nà tó dáa wo làwa èèyàn Jèhófà ń gbà lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé?
6 Apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé láti gbé ìsìn tòótọ́ lárugẹ. Àpẹẹrẹ kan ni ti àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá [“Photo-Drama of Creation”], ìyẹn sinimá tó ní àwòrán oríṣiríṣi tí ọ̀kan ń ṣí tẹ̀ lé òmíràn, tó ní àwọn àwòrán aláwọ̀ mèremère, tó sì máa ń gbóhùn jáde. Kí Ogun Àgbáyé Kìíní tó bẹ̀rẹ̀ àti nígbà tó ń jà lọ́wọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ni sinimá yìí tù nínú. Apá tó kẹ́yìn nínú sinimá náà ṣàlàyé àlàáfíà tó máa wà nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù Kristi. Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere náà lórí rédíò, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ló sì gbọ́ ọ. Lónìí, ètò Ọlọ́run ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé bíi kọ̀ǹpútà àti Íńtánẹ́ẹ̀tì láti wàásù ìhìn rere náà dé àwọn erékùṣù tó jìnnà réré àti jákèjádò ayé.
7. (a) Kí nìdí tó fi léwu láti lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́? (b) Kí ló yẹ kó jẹ wá lógún? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
7 Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ewu wà nínú kéèyàn máa lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:29-31.) Ó rọrùn fún Kristẹni kan láti máa lo àkókò tó pọ̀ jù lórí àwọn nǹkan bíi ṣíṣe eré ìgbà ọwọ́ dilẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ sí, kó máa kàwé najú, kó máa wo tẹlifíṣọ̀n, kó máa gbafẹ́ kiri kó lè mọ ìlú ká, kó máa lọ sí àwọn ibi ìtajà ńláńlá láti fójú lóúnjẹ, kó máa fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé àtàwọn nǹkan míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan yìí ò burú, tí Kristẹni kan ò bá fura, wọ́n lè gba àkókò rẹ̀ pátápátá. Tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tá à ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà, tá à ń ka àwọn ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ àti ìròyìn eré ìdárayá ní ìṣẹ́jú ìṣẹ́jú, ìyẹn náà tún lè fi àkókò wa ṣòfò, ó sì lè gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ.a (Oníw. 3:1, 6) Tá a bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù lórí àwọn nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé, ìyẹn ìjọsìn Jèhófà.—Ka Éfésù 5:15-17.
8. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tó wà nínú ayé?
8 Sátánì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe káwọn ohun tó wà nínú ayé lè fà wá mọ́ra kí wọ́n sì fa ìpínyà ọkàn fún wa. Ohun tó ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìyẹn, ó sì túbọ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí. (2 Tím. 4:10) Torí náà, ó yẹ ká fi ìmọ̀ràn yìí sílò pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ . . . àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé.” Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò lójoojúmọ́, àá pọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn wa, ‘ìfẹ́ tá a ní fún Baba’ á sì máa pọ̀ sí i. Èyí á mú kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, àá sì máa rí ojú rere rẹ̀ títí láé.—1 Jòh. 2:15-17.
JẸ́ KÍ OJÚ RẸ MÚ Ọ̀NÀ KAN
9. Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé ká jẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan, àpẹẹrẹ wo ló sì fi lélẹ̀?
9 Àwọn ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Jésù fún Màtá bá ìwà àti ẹ̀kọ tí Jésù fi ń kọ́ni mu. Ó gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ kí ojú wọ́n “mú ọ̀nà kan,” kí wọ́n lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Ka Mátíù 6:22, 33.) Jésù ò kó àwọn ohun ìní tara jọ, kò kọ́lé bẹ́ẹ̀ sì ni kò ralẹ̀.—Lúùkù 9:58; 19:33-35.
10. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
10 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣẹlẹ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù tó lè mú kó má pọkàn pọ̀, àmọ́ kò gba ìpínyà ọkàn láyè. Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àwọn ará ìlú Kápánáúmù bẹ̀ ẹ́ pé kó má ṣe kúrò nílùú àwọn lẹ́yìn tó ti kọ́ wọn tó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Àmọ́, kí ni Jésù ṣe? Ó sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:42-44) Ohun tí Jésù sì ṣe gan-an nìyẹn, ó rìn jákèjádò ilẹ̀ Palẹ́sìnì, ó ń wàásù ó sì ń kọ́ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe káàkiri máa ń mú kó rẹ̀ ẹ́ nígbà míì, ó sì máa ń nílò ìsinmi.—Lúùkù 8:23; Jòh. 4:6.
11. Kí ni Jésù sọ fún ọkùnrin kan tó wá fọ̀rọ̀ lọ̀ ọ́, ìkìlọ̀ wo ló sì fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀?
11 Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè fara da àtakò, ọkùnrin kan já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín ogún pẹ̀lú mi.” Àmọ́ Jésù kọ̀ láti bá wọn dá sí i. Ó wá sọ pé: “Ọkùnrin yìí, ta ní yàn mí ṣe onídàájọ́ tàbí olùpín nǹkan fún yín?” Jésù wá ń kọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ nìṣó, ó kìlọ̀ fún wọn nípa ewu tó wà nínú jíjẹ́ kí àwọn nǹkan tara gbà wọ́n lọ́kàn débi tí wọn ò fi ní lè pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—Lúùkù 12:13-15.
12, 13. (a) Ṣáájú ikú Jésù, kí ló wú àwọn Gíríìkì aláwọ̀ṣe kan lórí? (b) Kí ni Jésù ṣe nípa ohun tó fẹ́ fa ìpínyà ọkàn fún un yìí?
12 Nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún Jésù lọ́sẹ̀ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 26:38; Jòh. 12:27) Ó ní iṣẹ́ tó pọ̀ láti ṣe, ó fara da àdánwò lílekoko àti ikú oró. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Sunday, ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Bí Bíbélì ṣe sọ, Jésù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù, àwọn èrò sì ń kan sáárá sí “ẹni tí ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní orúkọ Jèhófà.” (Lúùkù 19:38) Lọ́jọ́ kejì, Jésù wọ tẹ́ńpìlì, ó sì lé àwọn tó ń fi ìwọra ṣòwò jáde torí pé wọ́n sọ ilé Ọlọ́run di ibi tí wọ́n ti ń ja àwọn Júù bíi tiwọn lólè.—Lúùkù 19:45, 46.
13 Àwọn Gíríìkì aláwọ̀ṣe wà lára àwọn èrò tó wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn ohun tí Jésù ṣe wú wọn lórí débi pé wọ́n sọ fún àpọ́sítélì Fílípì pé kó bá àwọn ṣètò báwọn ṣe máa rí Jésù bá sọ̀rọ̀. Àmọ́, Jésù ò jẹ́ kíyẹn fa ìpínyà ọkàn fóun, ó pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì tó wà níwájú rẹ̀. Kò gbìyànjú láti di gbajúmọ̀ kó lè sá fún ikú ìrúbọ látọwọ́ àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Torí náà, lẹ́yìn tó ṣàlàyé fún Áńdérù àti Fílípì pé wọ́n máa tó pa òun, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ni fún ọkàn rẹ̀ ń pa á run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kórìíra ọkàn rẹ̀ nínú ayé yìí, yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” Kàkà kó máa wá bó ṣe máa tẹ́ àwọn Gíríìkì yẹn lọ́rùn, ó gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n múra tán láti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ torí àwọn míì, ó wá ṣèlérí fún wọn pé: “Bí ẹnikẹ́ni yóò bá ṣèránṣẹ́ fún mi, Baba yóò bọlá fún un.” Láìsí àní-àní, ọ̀rọ̀ yìí gbé Fílípì ró, ó sì lọ jábọ̀ fún àwọn tó rán an sí Jésù.—Jòh. 12:20-26.
14. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù ni Jésù fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, kí ló fi hàn pé ó máa ń wáyè fáwọn nǹkan míì?
14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù pọkàn sórí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere, kì í ṣe aláṣekúdórógbó. Ó kéré tán, ó lọ síbi ìgbéyàwó kan, ó sì pa kún ayọ̀ ọjọ́ ìgbéyàwó náà nípa sísọ omi di ọtí wáìnì. (Jòh. 2:2, 6-10) Ó tún lọ sílé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ àtàwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere nígbà tí wọ́n pè é síbi àsè oúnjẹ alẹ́. (Lúùkù 5:29; Jòh. 12:2) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń wáyè láti gbàdúrà, láti ṣàṣàrò àti láti sinmi.—Mát. 14:23; Máàkù 1:35; 6:31, 32.
“MÚ GBOGBO ẸRÙ WÍWÚWO KÚRÒ”
15. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa, àpẹẹrẹ rere wo ló sì fi lélẹ̀?
15 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìgbésí ayé Kristẹni kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ wé eré ìje tó gba ìfaradà, torí náà ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò.” (Ka Hébérù 12:1.) Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù fi àwọn ohun tó fi ń kọ́ni ṣèwà hù, ó fi iṣẹ́ tó lè sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀ àti olókìkí nínú ìsìn àwọn Júù sílẹ̀. Ó pọkàn pọ̀ sórí “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” Ó ṣiṣẹ́ kára láti wàásù ìhìn rere, ó rìnrìn-àjò jákèjádò ìlú Síríà, Éṣíà Kékeré, Makedóníà àti Jùdíà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tó ní láti máa gbé títí láé ní ọ̀run, ó sọ pé: “Ní gbígbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn àti nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú, mo ń lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje.” (Fílí. 1:10; 3:8, 13, 14) Pọ́ọ̀lù lo àǹfààní jíjẹ́ tó jẹ́ àpọ́n láti túbọ̀ ṣiṣẹ́ sin “Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà-ọkàn.”—1 Kọ́r. 7:32-35.
16, 17. Yálà a ti ṣègbéyàwó tàbí a ò tíì ṣègbéyàwó, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù? Sọ ìrírí kan.
16 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ti yàn láti wà láì lọ́kọ tàbí aya kí bùkátà wọn lè ṣẹ́ pẹ́rẹ́ kí wọ́n sì lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. (Mát. 19:11, 12) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti ṣègbéyàwó sábà máa ń ní bùkátà tó pọ̀ láti gbọ́ nínú ìdílé. Àmọ́, yálà a ti ṣègbéyàwó tàbí a ò tíì ṣègbéyàwó, gbogbo wa lè “mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò,” ká lè sin Ọlọ́run láìsí ìpínyà ọkàn. Ó lè gba pé ká dín àkókò tá à ń lò lórí àwọn ohun tí ò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan kù, ká sì pinnu láti lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
17 Bí àpẹẹrẹ, Mark àti Claire tó wá láti orílẹ̀-èdè Wales bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà tí wọ́n parí iléèwé wọn, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ náà lọ lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó. Mark sọ pé: “A ta fúláàtì wa tó ní yàrá mẹ́ta, a sì fi iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ tá à ń ṣe sílẹ̀ ká lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé kárí ayé.” Láti ogún ọdún sẹ́yìn ni Mark àti Claire ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba jákèjádò ilẹ̀ Áfíríkà. Nígbà kan, owó tó wà lọ́wọ́ wọn ku dọ́là mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] péré, àmọ́ Jèhófà ò fi wọ́n sílẹ̀. Claire sọ pé: “Inú wa máa ń dùn, a sì ń láyọ̀ pé ojoojúmọ́ ayé wa la fi ń sin Jèhófà. A ti ní àwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ láti ọdún yìí wá, a ò sì ṣaláìní àwọn ohun tá a nílò. Ohun díẹ̀ tá a yááfì ò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ayọ̀ tá à ń rí nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.” Ọ̀pọ̀ àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún náà ti rí i pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn.b
18. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ káwọn kan bi ara wọn?
18 Ìwọ ńkọ́? Kí lo máa ṣe tó o bá rí i pé ìtara tó o ní fún ìjọsìn Jèhófà ti dín kù torí pé ò ń gba àwọn ohun tí kò pọn dandan láyè láti gbà ẹ́ lọ́kàn? Ohun tó o lè ṣe ni pé kó o máa wá àkókò fún Bíbélì kíkà, kó o máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì túbọ̀ máa fi ohun tó ò ń kọ́ sílò. Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ìyẹn la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Òpè Eniyan A Máa Gba Ohun Gbogbo Gbọ́.”
b Tún ka ìtàn ìgbésí ayé Hadyn àti Melody Sanderson nínú àpilẹ̀kọ náà, “A Mọ Ohun Tó Tọ́, A Sì Ṣe É.” (Ilé Ìṣọ́, March 1, 2006) Wọ́n fi iṣẹ́ olówó gọbọi sílẹ̀ ní ilẹ̀ Ọsirélíà, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ka ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbà tí owó tán lọ́wọ́ wọn lákòókò tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Íńdíà.