Ojú Ìwòye Bíbélì
“Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé” Kí Ló Túmọ̀ Sí?
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kẹrin Sànmánì Tiwa, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni fi àwọn ohun ìní, àwọn ẹbí, àti ọ̀nà ìgbésí ayé wọn sílẹ̀ láti lọ gbé ibi àdádó ní àwọn aṣálẹ̀ Íjíbítì. A wá mọ̀ wọ́n sí anchorite [ayara-ẹni-láṣo], láti inú ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà, a·na·kho·reʹo, tí ó túmọ̀ sí “mo yẹra.” Òpìtàn kan ṣàpèjúwe wọn bí ẹni tí kì í bẹ́gbẹ́ wọn ṣe. Àwọn ayara-ẹni-láṣo rò pé nípa yíyẹra kúrò láwùjọ ẹ̀dá ènìyàn, àwọn ń ṣègbọràn sí ohun tí a béèrè lọ́wọ́ Kristẹni láti ‘má ṣe jẹ́ apá kan ayé.’—Jòhánù 15:19.
Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú láti wà “láìní èérí kúrò nínú ayé.” (Jákọ́bù 1:27) Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ ní kedere pé: “Ẹ̀yin panṣágà obìnrin, ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run? Nítorí náà, ẹni yòó wù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:4) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èyí ha túmọ̀ sí pé, a retí kí àwọn Kristẹni di ayara-ẹni-láṣo, tí ń yẹra fún àwọn ẹlòmíràn ní èrò ìtúmọ̀ olówuuru bí? Wọ́n kò ha gbọ́dọ̀ bá àwọn tí kò ṣàjọpín àwọn èrò ìgbàgbọ́ ìsìn wọn ṣe bí?
Àwọn Kristẹni Kì Í Ṣe Aláìbẹ́gbẹ́ṣe
A jíròrò èròǹgbà ṣíṣàìjẹ́ apá kan ayé nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àkọsílẹ̀ Bíbélì tí ó tẹnu mọ́ àìní náà pé kí àwọn Kristẹni ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ògìdìgbó àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí a sọ di àjèjì sí Ọlọ́run. (Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 6:14-17; Éfésù 4:18; Pétérù Kejì 2:20.) Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń fi ọgbọ́n yẹra fún àwọn ìṣesí, ọ̀rọ̀, àti ìwà tí ó forí gbárí pẹ̀lú àwọn ọ̀nà òdodo ti Jèhófà, irú bí ọ̀nà ìkíyànyán tí ayé ń gbà lépa ọrọ̀, òkìkí, àti ṣíṣe fàájì láṣejù. (Jòhánù Kíní 2:15-17) Wọ́n tún yẹra fún ayé nípa wíwà ní àìdásítọ̀tún-tòsì nínú àwọn ọ̀ràn ogun àti ti ìṣèlú.
Jésù Kristi sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ‘kì yóò jẹ́ apá kan ayé.’ Ṣùgbọ́n ó tún gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ, kì í ṣe láti mú wọn kúrò ní ayé, bíkòṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà.” (Jòhánù 17:14-16) Ó ṣe kedere pé Jésù kò fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ di aláìbẹ́gbẹ́ṣe, tí ń kọ gbogbo ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe Kristẹni. Ní gidi, wíwà ní ibi àdádó kò ní jẹ́ kí Kristẹni kan mú iṣẹ́ tí a gbé fún un láti wàásù, kí ó sì kọ́ni “ní gbangba àti láti ilé dé ilé” ṣẹ.—Ìṣe 20:20; Mátíù 5:16; Kọ́ríńtì Kíní 5:9, 10.
Ìmọ̀ràn náà pé kí a wà láìsí àbààwọ́n nínú ayé kò fún àwọn Kristẹni ní ìdí kankan láti ronú pé àwọn yọrí ọlá ju àwọn ẹlòmíràn lọ. Àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Jèhófà kórìíra “ìgbéra-ẹni-ga.” (Òwe 8:13, NW) Gálátíà 6:3 sọ pé, “bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ ohun kan nígbà tí òun kò jẹ́ nǹkan kan, òun ń tan èrò inú ara rẹ̀ jẹ.” Àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀lára jíjẹ́ ayọrí-ọlá ń tan ara wọn jẹ nítorí pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀ wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.”—Róòmù 3:23.
“Má Ṣe Sọ̀rọ̀ Ẹnì Kankan Lọ́nà Ìbàjẹ́”
Ní ìgbà ayé Jésù, àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n ń ṣáátá gbogbo àwọn tí kì í ṣe ara àwùjọ ìsìn wọn nìkan. Àwọn Farisí wà lára wọn. Wọ́n mọ Òfin Mósè dunjú, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n mọ apá kíkéré jù lọ lára òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù dunjú. (Mátíù 15:1, 2; 23:2) Wọ́n ń fi títẹ̀lé ọ̀pọ̀ àwọn ààtò onísìn kínníkínní yangàn. Àwọn Farisí máa ń hùwà bíi pé wọ́n yọrí ọlá ju àwọn mìíràn lọ kìkì nítorí àwọn àṣeyọrí wọn ní ti ìmọ̀ àti ipò nínú ìsìn. Wọ́n máa ń fi ìṣesí onítara àti ìtẹ́ńbẹ́lú ènìyàn tí wọ́n ní hàn nípa sísọ pé: “Ogunlọ́gọ̀ yí tí kò mọ Òfin jẹ́ àwọn ẹni ègún.”—Jòhánù 7:49.
Àwọn Farisí tilẹ̀ ní ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n fi ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn tí kì í ṣe Farisí. Látètèkọ́ṣe, a ń lo ọ̀rọ̀ èdè Hébérù náà ʽam ha·ʼaʹrets lọ́nà rere láti fi tọ́ka sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ara àwùjọ àwọn ènìyàn gbáàtúù. Ṣùgbọ́n bí àkókò ti ń lọ, àwọn alákọ aṣáájú ìsìn ilẹ̀ Júdà yí èrò ìtumọ̀ ʽam ha·ʼaʹrets pa dà sí ti ìṣáátá. Àwọn àwùjọ mìíràn, tí àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni wà lára wọn, ti lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “kèfèrí” àti “abọgibọ̀pẹ̀” lọ́nà ìtàbùkù láti tọ́ka sí àwọn ènìyàn tí èrò ìgbàgbọ́ ìsìn wọn yàtọ̀ sí tiwọn.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ojú wo ni àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi wo àwọn tí wọn kò tí ì gba ìsìn Kristẹni? A ṣí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù létí láti hùwà sí àwọn aláìgbàgbọ́ “pẹ̀lú ìwà tútù” àti “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (Tímótì Kejì 2:25; Pétérù Kíní 3:15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú èyí. Ó jẹ́ ẹni tí ó ṣeé sún mọ́, kì í ṣakọ. Dípò gbígbé ara rẹ̀ ga ju àwọn ẹlòmíràn lọ, ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń gbéni ró. (Kọ́ríńtì Kíní 9:22, 23) Nínú lẹ́tà onímìísí rẹ̀ sí Títù, Pọ́ọ̀lù fúnni ní ìṣítí “láti má ṣe sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́, láti má ṣe jẹ́ aríjàgbá, láti jẹ́ afòyebánilò, kí [a] máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sójútáyé sí ènìyàn gbogbo.”—Títù 3:2.
Nínú Bíbélì, a máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “aláìgbàgbọ́” lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti tọ́ka sí àwọn tí kì í ṣe Kristẹni. Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ẹ̀rí pé a lo ọ̀rọ̀ náà “aláìgbàgbọ́” gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ka àfàṣẹsí tàbí ìpenilórúkọ tí a kò jẹ́. Dájúdájú, a kò lò ó láti fi bẹnu àtẹ́ luni tàbí fi tẹ́ńbẹ́lú àwọn tí kì í ṣe Kristẹni, nítorí pé èyí yóò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì. (Òwe 24:9) Lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń yẹra fún lílekoko jù tàbí ṣíṣakọ sí àwọn aláìgbàgbọ́. Wọ́n kà á sí ìwà àìlọ́wọ̀ láti fún àwọn ẹbí tàbí àwọn aládùúgbò wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ní orúkọ ìtàbùkù. Wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì, tí ó wí pé: “Ẹrú Olúwa . . . yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.”—Tímótì Kejì 2:24.
“Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn”
Ó ṣe pàtàkì láti dá àwọn ewu tí ó wà nínú bíbá ayé ṣe wọléwọ̀de mọ̀, ní pàtàkì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ń fi ìwà àìlọ́wọ̀ púpọ̀ jọjọ hàn sí àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run. (Fi wé Kọ́ríńtì Kíní 15:33.) Síbẹ̀, nígbà tí Bíbélì gbani nímọ̀ràn láti “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn,” ọ̀rọ̀ náà “gbogbo” ní àwọn tí wọn kò ṣàjọpín àwọn èrò ìgbàgbọ́ Kristẹni nínú. (Gálátíà 6:10) Dájúdájú, lábẹ́ àwọn ipò kan, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní bá àwọn aláìgbàgbọ́ jẹun. (Kọ́ríńtì Kíní 10:27) Nítorí náà, àwọn Kristẹni lóde òní ń fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì hùwà sí àwọn aláìgbàgbọ́, wọ́n sì ń wò wọ́n bí ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn.—Mátíù 22:39.
Kì yóò tọ̀nà láti rò pé ẹnì kan kò ní ìwà yíyẹ tàbí pé ó jẹ́ oníwà pálapàla kìkì nítorí pé kò mọ àwọn òtítọ́ Bíbélì. Àwọn àyíká ipò àti àwọn ènìyàn yàtọ̀. Nítorí náà, olúkúlùkù Kristẹni gbọ́dọ̀ pinnu bí ìwọ̀n tí òun yóò pààlà ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́ yóò ti mọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì yóò pọn dandan, bẹ́ẹ̀ sì ni kì yóò bá ìwé mímọ́ mu kí Kristẹni kan ya ara rẹ̀ láṣo bí àwọn ayara-ẹni-láṣo ti ṣe tàbí kí ó nímọ̀lára jíjẹ́ ayọrí-ọlá bí àwọn Farisí ti ṣe.