ORÍ 91
Jésù Jí Lásárù Dìde
ÀJÍǸDE LÁSÁRÙ
ÌGBÌMỌ̀ SÀHẸ́NDÌRÌN Ń WÁ BÍ WỌ́N ṢE MÁA PA JÉSÙ
Jésù pàdé Màtá àti Màríà nítòsí ìlú Bẹ́tánì, wọ́n wá mú un lọ sí ibojì tí wọ́n sin Lásárù sí. Inú ihò kan ni, wọ́n sì fi òkúta kan dí ẹnu ihò náà. Jésù wá sọ pé: “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Torí pé Màtá ò mọ ohun tí Jésù ní lọ́kàn tó fi ní kí wọ́n gbé òkúta yẹn, ó sọ fún Jésù pé: “Olúwa, á ti máa rùn báyìí, torí ó ti pé ọjọ́ mẹ́rin.” Àmọ́ Jésù dá a lóhùn pé: “Ṣebí mo sọ fún ọ pé tí o bá gbà gbọ́, o máa rí ògo Ọlọ́run?”—Jòhánù 11:39, 40.
Ni wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jésù wá gbójú sókè wo ọ̀run, ó sì gbàdúrà pé: “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi. Lóòótọ́, mo mọ̀ pé o máa ń gbọ́ tèmi; àmọ́ torí èrò tó dúró yí ká ni mo fi sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.” Bí Jésù ṣe gbàdúrà lójú gbogbo èèyàn yẹn jẹ́ kí wọ́n rí i pé Ọlọ́run ló fún un lágbára tó máa fi ṣe iṣẹ́ ìyanu yẹn. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Lásárù, jáde wá!” Ni Lásárù bá jáde pẹ̀lú aṣọ tí wọ́n fi dì í tọwọ́tẹsẹ̀ àtèyí tí wọ́n fi di ojú rẹ̀. Jésù wá sọ pé: “Ẹ tú u, kí ẹ jẹ́ kó máa lọ.”—Jòhánù 11:41-44.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tó wá tu Màríà àti Màtá nínú, tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu yìí ló gba Jésù gbọ́. Àmọ́ ṣe làwọn kan lọ ròyìn ohun tí Jésù ṣe fáwọn Farisí. Àwọn Farisí àtàwọn olórí àlùfáà máa ń pàdé pọ̀ láti gbọ́ ẹjọ́ ní Sàhẹ́ndìrìn tó jẹ́ ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù. Lára àwọn tó wà nílé ẹjọ́ yẹn ni àlùfáà àgbà tó ń jẹ́ Káyáfà. Ọ̀pọ̀ lára wọn wá sọ pé: “Kí ni ká ṣe, torí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì? Tí a bá jẹ́ kó máa bá a lọ báyìí, gbogbo wọn ló máa gbà á gbọ́, àwọn ará Róòmù á sì wá gba àyè wa àti orílẹ̀-èdè wa.” (Jòhánù 11:47, 48) Lóòótọ́, ìròyìn táwọn ọkùnrin yẹn gbọ́ fi hàn pé Jésù ń “ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì,” àmọ́ inú wọn ò dùn bí Ọlọ́run ṣe ń lo Jésù láti ṣe àwọn iṣẹ́ náà. Ohun tó ṣe pàtàkì sí wọn ni bí ipò tí wọ́n wà àti agbára tí wọ́n ní láti darí àwọn èèyàn ò ṣe ní bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.
Bí Jésù ṣe jí Lásárù dìde jẹ́ ohun ìtìjú ńlá fáwọn Sadusí tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde. Torí náà, Káyáfà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Sadusí sọ pé: “Ẹ ò mọ nǹkan kan rárá, ẹ ò sì rò ó pé ó máa ṣe yín láǹfààní pé kí ọkùnrin kan kú torí àwọn èèyàn dípò kí gbogbo orílẹ̀-èdè pa run.”—Jòhánù 11:49, 50; Ìṣe 5:17; 23:8.
Torí ipò àlùfáà àgbà tí Káyáfà wà ni Ọlọ́run fi mí sí i láti sọ ọ̀rọ̀ yẹn, “èrò ara rẹ̀ kọ́ ni ohun tó sọ yìí.” Ohun tó ń sọ ni pé Jésù gbọ́dọ̀ kú kó má bàa di pé àwọn èèyàn á máa fojú kéré àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù, ìyẹn ló sì máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lágbára láti darí àwọn èèyàn. Síbẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ lohun tí Káyáfà sọ yìí, ó jẹ́ ká rí i pé ikú Jésù ló máa ra àwọn èèyàn pa dà. Kì í sì í ṣe àwọn Júù nìkan ló wà fún, ó tún máa kan gbogbo “àwọn ọmọ Ọlọ́run tó ti fọ́n káàkiri.”—Jòhánù 11:51, 52.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ohun tí Káyáfà sọ yẹn mú káwọn èèyàn yìí ronú pé ó yẹ káwọn wá bí àwọn ṣe máa pa Jésù. Ṣé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Nikodémù ọ̀rẹ́ Jésù tó wà lára ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ló dọ́gbọ́n sọ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yẹn fún Jésù? A ò lè sọ, àmọ́ ohun tá a mọ̀ ni pé Jésù kúrò ní Jerúsálẹ́mù àti agbègbè rẹ̀, ìyẹn ni ò jẹ́ kó kú ṣáájú àsìkò tí Ọlọ́run yàn pé ó máa kú.