Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Inú Iṣẹ́ Ìyanu Jesu
“WÀYÍ o ní ọjọ́ kẹta àsè ìgbéyàwó kan ṣẹlẹ̀ ní Kana ti Galili . . . Jesu ati awọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni a késí síbi àsè ìgbéyàwó naa pẹlu. Nígbà tí ọtí wáìnì kò tó ìyá Jesu wí fún un pé: ‘Wọn kò ní ọtí wáìnì kankan.’” Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìyanu tí Jesu kọ́kọ́ ṣe.—Johannu 2:1-3, NW.
Irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ kò ha ti ṣàìjámọ́ pàtàkì jù, kéré jù, láti mú wá sí àfiyèsí Jesu? Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Bibeli kan ṣàlàyé pé: “Àlejò ṣíṣe ní Ìlà-Oòrùn jẹ́ ojúṣe mímọ́ ọlọ́wọ̀ . . . Àlejò ṣíṣe níti gidi, pàápàá jùlọ níbi àsè ìgbéyàwó, béèrè fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ jíjẹ mímu. Bí ìpèsè bá [tán] níbi àsè ìgbéyàwó, ìtìjú náà kò ní tán lára ìdílé àti àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó náà bọ̀rọ̀.”
Nítorí náà Jesu gbégbèésẹ̀. Ó kíyèsi pé “ìṣà omi mẹ́fà tí a fi òkúta ṣe ni ó fìdíkalẹ̀ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí awọn ìlànà àfilélẹ̀ ìwẹ̀mọ́ gaara awọn Júù ti béèrè.” Wíwẹ ọwọ́ lọ́nà ààtò-àṣà ṣáájú oúnjẹ jẹ́ àṣà láàárín àwọn Júù, wọ́n sì nílò omi rẹpẹtẹ fún ìlò àwọn wọnnì tí wọ́n bá pésẹ̀. Jesu pàṣẹ fún àwọn wọnnì tí ń gbóúnjẹ fún àwọn àlejò pé: “Ẹ fi omi kún awọn ìṣà omi naa.” Kì í ṣe Jesu ni “olùdarí àsè,” ṣùgbọ́n ó sọ̀rọ̀ ní tààràtà àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ní ọlá-àṣẹ. Ìròyìn náà sọ pé: ‘Wàyí o, nígbà tí olùdarí àsè tọ́ omi náà wò, a ti sọ ọ́ di ọtí wáìnì.’—Johannu 2:6-9, NW; Marku 7:3.
Ó lè dàbí ohun àjèjì pé ohun tí ó wọ́pọ̀ bí àsè ìgbéyàwó ní yóò jẹ́ ibi tí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ Jesu yóò ti wáyé, ṣùgbọ́n ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣí ohun púpọ̀ payá nípa Jesu. Òun jẹ́ àpọ́n, àti pé ní àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan lẹ́yìn náà ó jíròrò àwọn àǹfààní jíjẹ́ àpọ́n pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. (Matteu 19:12) Bí ó ti wù kí ó rí, wíwà rẹ̀ ní ibi àsè ìgbéyàwó náà ṣí i payá pé dájúdájú òun kì í ṣe aṣòdì sí ìgbéyàwó. Ó wà déédéé, ó ti ìṣètò ìgbéyàwó náà lẹ́yìn; ó wò ó gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí ó lọ́lá lójú Ọlọrun.—Fiwé Heberu 13:4.
Jesu kì í ṣe arojúkókó olùṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ tí àwọn òṣèré ṣọ́ọ̀ṣì fi hàn lẹ́yìn náà pé ó jẹ́. Ó ṣe kedere pé ó gbádùn níní ìfararora pẹ̀lú àwọn ènìyàn kò sì lòdì sí níní àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. (Fiwé Luku 5:29.) Àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ tipa báyìí fi àpẹẹrẹ ìṣáájú lélẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Jesu funra rẹ̀ fi hàn pé kò pọndandan kí wọ́n parọ́rọ́ bí ẹni tí ọ̀fọ̀ sẹ̀ tàbí kí wọ́n fajúro láìnídìí—bí ẹni pé ìwà òdodo túmọ̀ sí àìláyọ̀. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn Kristian ni a pàṣẹ fún lẹ́yìn náà pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo ninu Oluwa.” (Filippi 4:4, NW) Àwọn Kristian lónìí ń lo ìṣọ́ra láti fi eré ìtura sí àyè tí ó lọ́gbọ́n-nínú pé kí a fi sí. Wọ́n ń rí ayọ̀ wọn nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun, ṣùgbọ́n nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jesu, wọ́n ń wá àkókò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti gbádùn ìfararora pẹ̀lú ara wọn ní àyíká ipò tí ó jẹ́ ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà.
Tún ṣàkíyèsí èrò ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jesu ní pẹ̀lú. Òun kò sí lábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe kankan láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. Kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan tí a níláti múṣẹ nípa èyí. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ti fi hàn, àníyàn ìyá rẹ̀ àti ipò tí àwọn méjèèjì tí wọ́n ń ṣègbéyàwó náà yóò wà ni ó wulẹ̀ ru ìmọ̀lára Jesu sókè. Ó bìkítà nípa ìmọ̀lára wọn ó sì fẹ́ láti gbà wọ́n lọ́wọ́ ojútì. Ìyẹn kò ha gbé ìgbàgbọ́ rẹ ró pé Kristi ní ọkàn-ìfẹ́ tòótọ́ nínú rẹ—àní nínú àwọn ìṣòro rẹ ojoojúmọ́ pẹ̀lú bí?—Fiwé Heberu 4:14-16.
Níwọ̀n bí ìṣà omi kọ̀ọ̀kan ti “lè gba òṣùwọ̀n ohun olómi méjì tabi mẹ́ta” ti omi gidi, iṣẹ́ ìyanu Jesu wémọ́ ọ̀pọ̀ òṣùwọ̀n wáìnì—bóyá lítà 390 (105 gálọ́ọ̀nù)! (Johannu 2:6, NW) Kí ni ìdí fún ìwọ̀n tí ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀? Kì í ṣe pé Jesu ń ṣe ìgbélárugẹ ìmùtípara, ohun kan tí Ọlọrun dẹ́bi fún. (Efesu 5:18) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń fi ìwà ọ̀làwọ́ bíi ti Ọlọrun hàn. Níwọ̀n bí wáìnì ti jẹ́ ohun mímu tí ó wọ́pọ̀, àmukù èyíkéyìí ni a lè lò fún ayẹyẹ mìíràn.—Fiwé Matteu 14:14-20; 15:32-37.
Àwọn Kristian ìjímìjí ṣe àfarawé àpẹẹrẹ ìwà ọ̀làwọ́ Jesu. (Fiwé Iṣe 4:34, 35.) Bákan náà ni a sì fún àwọn ènìyàn Jehofa lónìí ní ìṣírí láti “sọ fífúnni dàṣà.” (Luku 6:38, NW) Bí ó ti wù kí ó rí, iṣẹ́ ìyanu tí Jesu kọ́kọ́ ṣe tún ní ìjẹ́pàtàkì alásọtẹ́lẹ̀. Ó tọ́ka sí ọjọ́ iwájú kan nígbà tí Ọlọrun yóò fi ìwà ọ̀làwọ́ pèsè “ohun àbọ́pa tí ó kún [fún] ọ̀rá, ti ọtí wáìnì tí ó tòrò lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀,” tí yóò sì mú ebi kúrò pátápátá.—Isaiah 25:6.
Ṣùgbọ́n, ti ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe èyí tí ó wémọ́ ìwòsàn ti ara ìyára ńkọ́? Kí ni a lè rí kọ́ nínú wọn?
Ṣíṣe Ohun Tí Ó Dára Ní Ọjọ́ Sábáàtì
“Dìde, gbé àkéte rẹ kí o sì máa rìn.” Jesu bá ọkùnrin kan tí ó ti ń ṣàìsàn fún ọdún 38 sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ìròyìn Ìhìnrere náà ń bá a nìṣó pé: “Pẹlu èyíinì ọkùnrin naa di alára dídá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì gbé àkéte rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn.” Lọ́nà tí ó yanilẹ́nu, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ìyípadà tí ó débá ipò rẹ̀ yìí tẹ́lọ́rùn. Ìròyìn náà sọ pé: “Awọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí Jesu, nitori pé ó ń ṣe nǹkan wọnyi lákòókò Sábáàtì.”—Johannu 5:1-9, 16, NW.
Sábáàtì ni a retí pé kí ó jẹ́ ọjọ́ ìsinmi àti ayọ̀ fún gbogbo ènìyàn. (Eksodu 20:8-11) Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ Jesu ó ti di òfin dídíjú tí ń tẹnilóríba, tí ó jẹ́ àtọwọ́dá. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Alfred Edersheim kọ̀wé pé nínú ẹ̀ka-ìpín gígùn gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ti òfin Sábáàtì nínú ìwé Talmud, “àwọn kókó-ọ̀ràn tí ó jẹ́ pé agbára káká ni aronúmòye ènìyàn kan tí orí rẹ̀ pé yóò fi kà á sí ohun tí ó ṣe bàbàrà ni a ń jíròrò lọ́nà jíjinlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ní ìjẹ́pàtàkì níti ìsìn.” (The Life and Times of Jesus the Messiah) Àwọn ráábì so ìjẹ́pàtàkì ìyè-àti-ikú mọ́ àwọn ìlànà tí kò níláárí, tí wọ́n fi ìkùgbùù ṣe, tí ń dárí gbogbo apá ìgbésí-ayé Júù kan pátá—lọ́pọ̀ ìgbà láìní ìmí-ẹ̀dùn kankan fún ìmọ̀lára ẹ̀dá ènìyàn. Òfin Sábáàtì kan pa á láṣẹ pé: “Bí ilé bá wó lu ọkùnrin kan mọ́lẹ̀ tí a sì ń ṣiyèméjì bóyá ó wà níbẹ̀ tàbí kò sí níbẹ̀, tàbí bóyá ó wàláàyè tàbí ó ti kú, tàbí bóyá kèfèrí ni tàbí ọmọ Israeli, wọ́n lè kó àwókù náà kúrò lórí rẹ̀. Bí wọ́n bá rí i pé ó wàláàyè wọ́n lè túbọ̀ kó o kúrò lórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí [ó bá ti] kú, kí wọ́n fi í sílẹ̀.”—Ìlànà pàtàkì Yoma 8:7, The Mishnah, tí a túmọ̀ láti ọwọ́ Herbert Danby.
Ojú wo ni Jesu fi wo jíjiyàn lórí àwọn ohun tí kò tó gbé pọ́n bẹ́ẹ̀? Nígbà tí a ṣe lámèyítọ́ rẹ̀ fún wíwonisàn ní ọjọ́ Sábáàtì, ó wí pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, emi naa sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” (Johannu 5:17, NW) Jesu kò ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kí ó baà lè sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí a ti yọ̀ọ̀da fún àwọn ọmọ Lefi láti máa bá iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wọn nìṣó ní ọjọ́ Sábáàtì, Jesu lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ṣe iṣẹ́ tí Ọlọrun yàn fún un gẹ́gẹ́ bíi Messia láì rú Òfin Ọlọrun.—Matteu 12:5.
Àwọn ìwòsàn tí Jesu ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì tún tú àwọn akọ̀wé àti Farisi Júù fó pé wọ́n jẹ́ ‘olódodo àṣelékè’—wọn kì í yípadà wọn kò sì wà déédéé nínú ìrònú wọn. (Oniwasu 7:16) Dájúdájú, kì í ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun pé kí a fi iṣẹ́ tí ó dára mọ sí àwọn ọjọ́ kan pàtó nínú ọ̀sẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọrun kò retí pé kí Sábáàtì jẹ́ iṣẹ́ àṣedànù ti pípa ìlànà mọ́. Jesu sọ ní Marku 2:27 (NW) pé: “Sábáàtì wáyé nitori ènìyàn, kì í sì í ṣe ènìyàn nitori sábáàtì.” Àwọn ènìyàn ni Jesu fẹ́ràn, kì í ṣe àwọn òfin tí a fi ìkùgbùù ṣe.
Nítorí èyí àwọn Kristian lónìí yóò ṣe dáradára láti máṣe ṣe àṣerégèé níti àìfẹ́ẹ́yípadà tàbí kí ìrònú wọn darí síhà kìkì ohun tí òfin sọ. Àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ipò ọlá-àṣẹ nínú ìjọ ń fàsẹ́yìn láti máṣe di ẹrù àwọn òfin àti ìlànà àtọwọ́dá tí ó pọ̀ rékọjá ààlà ru àwọn ẹlòmíràn. Àpẹẹrẹ Jesu tún ń fún wa ní ìṣírí láti máa wá ọ̀nà láti ṣe ohun tí ó dára. Fún àpẹẹrẹ, Kristian kan kò gbọdọ̀ ronú láé pé òun yóò ṣàjọpín àwọn òtítọ́ Bibeli kìkì nígbà tí òun bá ń kópa nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé gẹ́gẹ́-bí-àṣà tàbí nígbà tí òun bá wà lórí pèpéle ìbánisọ̀rọ̀. Aposteli Peteru sọ pé Kristian níláti máa “wà ní ìmúratán nígbà gbogbo lati ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ [wọn] ìdí fún ìrètí tí ń bẹ ninu [wọn].” (1 Peteru 3:15, NW) Àkókò kì í pààlà sí ṣíṣe ohun tí ó dára.
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Ìyọ́nú
Iṣẹ́ ìyanu àrà-ọ̀tọ̀ mìíràn ni a kọ sílẹ̀ nínú Luku 7:11-17 (NW). Ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ náà, Jesu “rin ìrìn-àjò lọ sí ìlú-ńlá kan tí a ń pè ní Naini, awọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ogunlọ́gọ̀ ńlá sì ń bá a rin ìrìn-àjò.” Títí di òní olónìí, àwọn ibi ìsìnkú ni a ṣì lè rí ní apá ìhà gúúsù ìlà-oòrùn abúlé Nein ti àwọn ará Arab òde-òní. “Bí ó ti súnmọ́ ibodè ìlú-ńlá naa,” ó bá àwọn tí ń pariwo pàdé. “Họ́wù, wò ó! wọ́n ń gbé ọkùnrin kan tí ó ti kú jáde, ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo ìyá rẹ̀. Yàtọ̀ sí èyí, opó ni oun. Ogunlọ́gọ̀ tí ó tóbi pupọ lati ìlú-ńlá naa tún wà pẹlu rẹ̀.” H. B. Tristram sọ pé “ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sin òkú kò tí ì yípadà” láti ìgbà ìjímìjí wá, ó sì fikún un pé: “Mo ti rí àwọn obìnrin tí wọ́n ń rìn lọ níwájú agà ìgbókùú rí, tí àwọn obìnrin abániṣọ̀fọ̀ sì wà ní iwájú wọn. Wọ́n ń na apá wọn gbalaja, wọ́n ń fa irun wọn, wọ́n ń fi ìmọ̀lára ìkẹ́dùn wíwúwo jùlọ hàn, wọ́n sì ń fi ohùn arò pe orúkọ ẹni tí ó kú náà.”—Eastern Customs in Bible Lands.
Ní àárín irúfẹ́ ipò rúdurùdu aláriwo yìí ni opó kan wà tí ń kẹ́dùn, ẹni tí ojú rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ kún fún ìrora gidigidi. Gẹ́gẹ́ bí òǹṣèwé Herbert Lockyer ti sọ, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọkọ rẹ̀ ti kú, ó ń wo ọmọkùnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, àti ìtùnú ìdánìkanwà rẹ̀—aláfẹ̀yìntì àti òpómúléró. Bí ó ti pàdánù ọmọkùnrin rẹ̀ kanṣoṣo, alátìlẹ́yìn kanṣoṣo tí ó kù fún un ní a ti mú lọ.” (All the Miracles of the Bible) Báwo ni Jesu ṣe hùwàpadà? Gẹ́gẹ́ bí Luku ti sọ ọ́ lọ́nà dídán mọ́rán, “nígbà tí Oluwa sì tajúkán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé: ‘Dẹ́kun sísunkún.’” Gbólóhùn náà “àánú . . . ṣe é” ni a fàyọ láti inú ọ̀rọ̀ Griki kan tí ó túmọ̀ sí “ìwọ́rọ́kù” lóréfèé. Ó túmọ̀ sí “kí a ru ìmọ̀lára ẹni sókè láti inú lọ́hùn-ún wá.” (Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words) Bẹ́ẹ̀ni, Jesu ni a sún láti ní ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ nínú ara rẹ̀.
Ó ti ṣeé ṣe kí ìyá Jesu fúnra rẹ̀ jẹ́ opó ní àkókò yìí, nítorí náà ó ṣeé ṣe kí ó mọ bí ìrora ọ̀fọ̀ ti ń rí nígbà tí ó pàdánù bàbá alágbàtọ́ rẹ̀, Josefu. (Fiwé Johannu 19:25-27.) Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìgbà tí opó náà bá bẹ̀ Jesu. Lójú ẹsẹ̀, “ó súnmọ́ ọn ó sì fọwọ́kan agà ìgbókùú naa,” lójú òtítọ́ náà pé lábẹ́ Òfin Mose fífọwọ́kan òkú a máa sọni di aláìmọ́. (Numeri 19:11) Nípasẹ̀ agbára iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, Jesu lè mú ohun náà gan-an tí ó jẹ́ okùnfà àìmọ́ kúrò! “Ó . . . wí pé: ‘Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!’ Ọkùnrin tí ó ti kú naa sì dìde jókòó ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó sì fi í fún ìyá rẹ̀.”
Ẹ wo ẹ̀kọ́ rírunisókè nípa ìyọ́nú tí èyí jẹ́! Àwọn Kristian kò níláti ṣàfarawé ìṣarasíhùwà àìnífẹ̀ẹ́, àti àìníwà-bí-ọ̀rẹ́ tí a ń fi hàn ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí. (2 Timoteu 3:1-5) Ní ìyàtọ̀ pátápátá, 1 Peteru 3:8 (NW) gbaniníyànjú pé: “Lákòótán, gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan naa, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.” Nígbà tí ojúlùmọ̀ wa kan bá kú tàbí ṣàìsàn lílekoko, a kò lè jíni dìde tàbí kí a wo ẹni tí ń ṣàìsàn náà sàn. Ṣùgbọ́n a lè fúnni ní ìrànlọ́wọ́ gbígbéṣẹ́ àti ìtùnú, bóyá nípa wíwà níbẹ̀ kí a sì bá wọn sọkún.—Romu 12:15.
Àjíǹde tí ń múni jígìrì yìí tí Jesu ṣe tún tọ́ka sí ọjọ́-ọ̀la—àkókò kan nígbà tí “gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n wà ninu awọn ibojì ìrántí yoo gbọ́ ohùn rẹ̀ wọn yoo sì jáde wá”! (Johannu 5:28, 29, NW) Kárí ayé, àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ yóò ní ìrírí ìyọ́nú Jesu nígbà tí àwọn ìyá, bàbá, ọmọ, àti àwọn ọ̀rẹ́ tí ikú ti mú lọ bá tún padà wá láti inú ibojì!
Àwọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Tí Iṣẹ́ Ìyanu Náà Kọ́ni
Nígbà náà, ó ṣe kedere pé àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu rékọjá ìfagbára hàn tí ń múnilóríyá. Wọ́n fi ògo fún Ọlọrun, ní fífi àpẹẹrẹ àwòkọ́ṣe lélẹ̀ fún àwọn Kristian tí a rọ̀ láti ‘yin Ọlọrun lógo.’ (Romu 15:6, NW) Wọ́n pèsè ìṣírí fún ṣíṣe ohun tí ó dára, fífi ìwà ọ̀làwọ́ hàn, fífi ìyọ́nú hàn. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ, wọ́n ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun àkọ́fojúrí nípa iṣẹ́ agbára tí a óò ṣe nígbà Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún ti Kristi.
Nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé, Jesu ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní àárín agbègbè ààlà ilẹ̀ tí ó kéré ní ìfiwéra. (Matteu 15:24) Gẹ́gẹ́ bí Ọba tí a ṣelógo, agbègbè ìṣàkóso rẹ̀ yóò gbòòrò kárí ilẹ̀-ayé! (Orin Dafidi 72:8) Nígbà náà lọ́hùn-ún, àwọn wọnnì tí wọ́n rí ìwòsàn iṣẹ́ ìyanu àti àjíǹde rẹ̀ gbà tún padà kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Lábẹ́ ipò ọba rẹ̀ lókè ọ̀run, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ni a óò mú kúrò pátápátá, tí èyí yóò sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìyè àìnípẹ̀kun. (Romu 6:23; Ìṣípayá 21:3, 4) Bẹ́ẹ̀ni, àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu tọ́ka sí ọjọ́-ọ̀la ológo tí ń bọ̀wá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́wọ́ láti mú ìrètí tòótọ́ dàgbà fún jíjẹ́ apákan rẹ̀. Títí tí àkókò náà yóò fi tó, ẹ wo àgbàyanu ìtọ́wò ṣáájú tí àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu Kristi pèsè nípa àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Jesu sọ omi di ọtí-wáìnì