Ẹgbẹ́ Awo Ha Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Bí?
JESU KRISTI ni a fẹ̀sùn kàn pé ó jẹ́ ọ̀mùtí, alájẹkì, ẹni tí kò pa Ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹlẹ́rìí èké, asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọrun, àti ìránṣẹ́ Eṣu. A sì tún fi ẹ̀sùn jíjẹ́ adojú-ìjọba-dé kàn án.—Matteu 9:34; 11:19; 12:24; 26:65; Johannu 8:13; 9:16; 19:12.
Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jesu, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bákan náà di àyànsọjú fún àwọn ìfẹ̀sùnkanni mímúná. Àwùjọ àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní kan ni àwọn ènìyàn wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn olùṣàkóso ìlú-ńlá ní kíkígbe pé: ‘Àwọn wọ̀nyí ti yí ayé po.’ (Iṣe 17:6) Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn Paulu àti alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ Sila ni a mú tọ àwọn aláṣẹ lọ tí a sì fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ń yọ ìlú-ńlá Filippi lẹ́nu gidigidi.—Iṣe 16:20.
Paulu ni a fẹ̀sùn kàn lẹ́yìn náà pé ó jẹ́ “aláṣeràn ènìyàn, ẹni tí ó ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàárín gbogbo àwọn Ju tí wọ́n wà ní gbogbo ayé” àti pé ó ń gbìyànjú “láti ba tẹ́ḿpìlì jẹ́.” (Iṣe 24:5, 6) Àwọn ẹni pàtàkì láàárín àwọn Ju ní Romu ṣàpèjúwe ipò-ọ̀ràn àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu lọ́nà pípéye nígbà tí wọ́n jẹ́wọ́ pé: “Nítorí bí ó ṣe ti ìsìn ìyapa yìí ni, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”—Iṣe 28:22.
Lọ́nà tí ó ṣe kedere, àwùjọ titun yìí tí Jesu Kristi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni àwọn kan kà sí àwùjọ ìsìn olójú-ìwòye àti àṣà àṣerégèé tí ó forígbárí pẹ̀lú ohun tí a tẹ́wọ́gbà ní àwọn ọjọ́ wọnnì pé ó jẹ́ ìṣarasíhùwà ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tí ó bójúmu. Láìsí iyèméjì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ lónìí yóò ti ka àwọn Kristian sí ẹgbẹ́ awo aṣèparun. Àwọn afẹ̀sùnkanni náà sábà máa ń jẹ́ sàràkí àti àwọn mẹ́ḿbà tí a bọ̀wọ̀ fún láwùjọ, ó sì jọ pé èyí ti mú kí àwọn ẹ̀sùn náà túbọ̀ lágbára síi. Ọ̀pọ̀ gba ẹ̀sùn tí a fi kan Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣeéṣe kí o mọ̀, gbogbo àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí jẹ́ èké! Òtítọ́ náà pé àwọn ènìyàn sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kò mú kí wọ́n jẹ́ òtítọ́.
Lónìí ńkọ́? Yóò ha jẹ́ ohun tí ó yẹ láti tọ́ka sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ìsìn olójú-ìwòye àti àṣà àṣerégèé tí ó forígbárí pẹ̀lú ohun tí a tẹ́wọ́gbà pé ó jẹ́ ìṣarasíhùwà ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tí ó sì bójúmu bí? Ẹgbẹ́ awo ha ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bí?
Ohun Tí Ẹ̀rí Fihàn
Ìjòyè-òṣìṣẹ́ ìjọba kan ní ìlú-ńlá St. Petersburg, Russia, ṣàlàyé pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a fihàn fún wa bí irú ẹgbẹ́ awo abẹ́lẹ̀ kan tí wọ́n ń jókòó nínú òkùnkùn tí wọ́n ń dúḿbú àwọn ọmọdé tí wọ́n sì ń pa araawọn.” Bí ó ti wù kí ó rí, láìpẹ́ yìí ni àwọn ènìyàn Russia ṣẹ̀ṣẹ̀ di ojúlùmọ̀ dáradára pẹ̀lú ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí jẹ́ níti gidi. Lẹ́yìn ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àpéjọpọ̀ àgbáyé kan, ìjòyè-òṣìṣẹ́ kan-náà ṣàkíyèsí pé: “Nísinsìnyí mo rí àwọn ènìyàn gidi, tí ń rẹ́rìn-ín músẹ́, tí wọ́n tilẹ̀ sàn ju ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí mo mọ̀ lọ. Wọ́n jẹ́ ẹni àlàáfíà àti ẹni píparọ́rọ́, wọ́n sì fẹ́ràn araawọn gidigidi lẹ́nìkínní kejì.” Ó fikún un pé: “Níti gidi èmi kò lóye ìdí tí àwọn ènìyàn fi ń pa irú irọ́ bẹ́ẹ̀ nípa wọn.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kìí ṣe àwọn ìpàdé awo, bẹ́ẹ̀ sì ni ìjọsìn wọn kìí ṣe ní bòókẹ́lẹ́. Julia Mitchell Corbett òǹkọ̀wé kan tí kìí ṣe Ẹlẹ́rìí ṣàlàyé pé: “Nígbà tí wọ́n bá pàdé, tí ó sábà máa ń ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lọ́sẹ̀, nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba (wọn kìí pé ibi ìpàdé wọn ní ṣọ́ọ̀ṣì), ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àkókò wọn ni wọ́n ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìjíròrò Bibeli.” Àwọn ibi ìpàdé wọn ni a fi àkọlé sàmì sí ní kedere. Àwọn ìpàdé wọn kìí ṣe ní bòókẹ́lẹ́, gbogbo ènìyàn pátá ni a sì késí láti wá síbẹ̀. Àwọn àlejò tí wọn kò sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ń bọ̀ ni wọ́n ń kí káàbọ̀ tọ̀yàyà-tọ̀yàyà.
“Àwọn Ẹlẹ́rìí ti jèrè orúkọ rere ti jíjẹ́ aláìlábòsí, olùmẹ̀tọ́-mẹ̀yẹ, àti alákíkanjú,” ni Corbett fikún un nínú ìwé rẹ̀ Religion in America. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kìí ṣe Ẹlẹ́rìí gbà láìjanpata pé kò sí ohun kan tí ó jẹ́ mérìíyìírí tàbí tí ó ṣàjèjì nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ìwà wọn kò forígbárí pẹ̀lú ohun tí a tẹ́wọ́gbà pé ó jẹ́ ìwà bíbójúmu ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ṣàlàyé lọ́nà tí ó jẹ́ òtítọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí “rinkinkin mọ́ àkójọ òfin ìwàrere gíga nínú ìwà ti ara-ẹni.”
Olùdarí ìròyìn àti àwọn àkànṣe ìwéwèédáwọ́lé fún ilé-iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan ní United States kọ̀wé sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìdáhùnpadà sí ìròyìn kan tí a gbékarí ẹ̀tanú nípa àwọn Ẹlẹ́rìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n náà 60 Minutes. Ó sọ pé: “Bí àwọn ènìyàn púpọ̀ síi bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìsìn yín, orílẹ̀-èdè yìí kì yóò rí bí ó ti rí yìí. Èmi jẹ́ oníròyìn kan tí ó mọ̀ pé ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ lílágbára nínú Ẹlẹ́dàá jẹ́ ìpìlẹ̀ ètò-àjọ yín. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé kìí ṣe gbogbo àwọn Oníròyìn ni wọ́n jẹ́ ẹlẹ́tanú bẹ́ẹ̀.”
Ìsìn Tí A Mọ̀ Dáradára
Ó ha tọ́ láti sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ àwùjọ ìsìn kékeré olójú-ìwòye àṣerégèé bí? Ní èrò-ìtumọ̀ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ níwọ̀nba ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ìsìn kan. Bí ó ti wù kí ó rí, rántí ohun tí Jesu sọ pé: ‘Híhá ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti tóóró ni ojú-ọ̀nà náà, tí ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín.’—Matteu 7:13, 14.
Lọ́nàkọ́nà, àwọn Ẹlẹ́rìí kìí ṣe ẹgbẹ́ awo kékeré olójú-ìwòye àṣerégèé kan. Ní ìgbà ìrúwé ọdún 1993, iye tí ó ju million 11 ènìyàn lọ ni ó pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi tí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe. Ṣùgbọ́n èyí tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì ju iye wọn lọ ni àwọn ànímọ́ ìwàrere ẹ̀dá àti ìwà àwòfiṣàpẹẹrẹ wọn, èyí tí ó ti mú kí a gbóríyìn fún wọn kárí-ayé. Kò sí iyèméjì pé èyí ti jẹ́ kókó abájọ kan ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fún wọn ní ìdánimọ̀ lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ìsìn kan, tí a mọ̀.
Ìdájọ́ ẹnu àìpẹ́ yìí tí Kóòtù Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Europe ṣe jẹ́ ọ̀kan tí ó tayọ. Ó polongo pé àwọn Ẹlẹ́rìí níláti gbádùn òmìnira ìrònú, ẹ̀rí-ọkàn, àti ìsìn àti pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ náà láti sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn kí wọ́n sì fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Agbára káká ni èyí yóò fi rí bẹ́ẹ̀ bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọgbọ́n ẹ̀tàn àti èyí tí kò bá ìlànà ìwàhíhù mú ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń lò láti kó mẹ́ḿbà jọ tàbí bí wọ́n bá ń lo àwọn ọgbọ́n àyínìke láti ṣàkóso ọkàn àwọn ọmọlẹ́yìn wọn.
Ogunlọ́gọ̀ káàkiri àgbáyé ti dojúlùmọ̀ dáradára pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Lọ́wọ́ àráádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn tí kìí ṣe Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tàbí tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn ní ìgbà kan tàbí òmíràn, àwa béèrè pé, Àwọn ìgbìdánwò èyíkéyìí ha wà láti lo ẹ̀tàn láti fagbára mú yín gba ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ bí? Àwọn Ẹlẹ́rìí ha lo àwọn ọgbọ́n ẹ̀tàn ti síṣàkóso lórí ọkàn yín bí? Kò sí iyèméjì pé “bẹ́ẹ̀kọ́” ní yóò jẹ́ ìdáhùnpadà yín láìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n. Lọ́nà ṣíṣe kedere, bí a bá ti lo àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ni, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tí ó ti di ẹran-ìjẹ yóò tako ìjiyàn èyíkéyìí láti gbè sẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
‘Ire Ìran Ènìyàn Gbà Wọ́n Lọ́kàn’
Àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ awo tilẹ̀ máa ń sábà ya araawọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìdílé, ọ̀rẹ́, àti ẹgbẹ́ àwùjọ lápapọ̀. Bẹ́ẹ̀ ha ni ọ̀ràn rí pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bí? Oníròyìn kan ní Ìlú Aláààrẹ ti Czechoslovakia kọ̀wé pé, “Èmi kìí ṣe ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.” Síbẹ̀, ó fikún un pé: “Ó ṣe kedere pé wọ́n [àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa] ní okun ìwàrere kíkàmàmà. . . . Wọ́n fìmọrírì hàn fún àwọn aláṣẹ ìjọba ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbọ́ pé Ìjọba Ọlọrun nìkanṣoṣo ni ó lágbára láti yanjú gbogbo àwọn ìṣòro ènìyàn. Ṣùgbọ́n kíyèsi pé—wọn kìí ṣe agbawèrè-mẹ́sìn. Wọ́n jẹ́ ẹni tí ire ìran ènìyàn gbà lọ́kàn.”
Wọn kìí sìí dágbé nínú àwùjọ adánìkanwà, ní yíya araawọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan àti àwọn ẹlòmíràn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbà pé ó jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ wọn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu láti nífẹ̀ẹ́ àti láti bójútó àwọn ìdílé wọn. Wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn láti inú ẹ̀yà àti ìsìn gbogbo wá wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀, wọ́n máa ń yára dáhùnpadà pẹ̀lú àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ àti àwọn ìrànlọ́wọ́ ìfẹ́dàáfẹ́re mìíràn.
Èyí tí ó ṣe pàtàkì jù, wọ́n ń kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kan tí kò ní àfiwé. Ìsìn mélòó ni ó ní ètò kan tí a gbékalẹ̀ láti lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ń gbé láwùjọ wọn? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe èyí ní iye tí ó ju 200 ilẹ̀ àti ní èdè tí ó ju 200 lọ! Ní kedere, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni “ire ìran ènìyàn gbà lọ́kàn.”
Ìtòròpinpin Mọ́ Bibeli Láìgbagbẹ̀rẹ́
A gbà pé, ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń pèsè. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbà pé Jehofa jẹ́ Ọlọrun Olodumare àti pé Jesu ni Ọmọkùnrin rẹ̀, kìí ṣe apákan ọlọrun mẹ́talọ́kan. Ìgbàgbọ́ wọn fìdímúlẹ̀ gbọnyin nínú èrò-ìgbàgbọ́ náà pé Ìjọba Ọlọrun nìkanṣoṣo ni ó lè mú ìtura wá fún ìran ènìyàn tí ń jìyà. Wọ́n ń kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nípa ìparun ètò-ìgbékalẹ̀ oníwà-ìbàjẹ́ yìí tí ó súnmọ́lé. Wọ́n ń wàásù nípa ìlérí Ọlọrun nípa paradise orí ilẹ̀-ayé kan fún aráyé onígbọràn. Wọn kìí júbà fún àgbélébùú. Wọn kìí ṣayẹyẹ Keresimesi. Wọ́n gbàgbọ́ pé ọkàn lè kú àti pé kò sí iná ọ̀run àpáàdì. Wọn kò ní jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò ní gba ẹ̀jẹ̀ sára. Wọ́n takété sí lílọ́wọ́ nínú ìṣèlú àti ìkópa nínú ogun jíjà. Ìwọ ha ti bi araàrẹ léèrè rí nípa ìdí rẹ̀ tí ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi yàtọ̀ tóbẹ́ẹ̀?
Ìwé-ìròyìn Massachusetts kan, Daily Hampshire Gazette, ṣàlàyé pé títú tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa “túmọ̀ Bibeli láìgbagbẹ̀rẹ́ ka ọ̀pọ̀ àwọn ìgbòkègbodò tí àwọn ẹlòmíràn ronú pé ó tọ̀nà léèwọ̀ . . . , gbogbo rẹ̀ nítorí ìsapá náà láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní àti ọ̀rọ̀ inú Bibeli.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion fohùnṣọ̀kan pé “gbogbo ohun tí wọ́n gbàgbọ́ ni a gbékarí Bibeli. Wọ́n ‘ń pèsè ẹ̀rí-ìdánilójú fún ọ̀rọ̀-ẹsẹ-ìwé mímọ́’ (ìyẹn ni pé, wọ́n ń pèsè ọ̀rọ̀ tí a fàyọ láti inú Bibeli láti ṣètìlẹ́yìn) fún èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo gbólóhùn ìgbàgbọ́, ní títẹ́wọ́gba ọlá-àṣẹ Bibeli láìjanpata, èyí tí ìtayọlọ́lá rẹ̀ rékọjá ẹ̀kọ́-àtọwọ́dọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà.” Ìwé náà Religion in America sọ pé: “Àwùjọ náà kò tíì yí ìpọkànpọ̀ rẹ̀ sórí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli síbòmíràn rí, àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni a sì ń ṣètìlẹ́yìn fún nípasẹ̀ ètò tí a fìṣọ́ra wéwèé ti títọ́ka sí ìwé mímọ́.”
Ta Ni Aṣáájú Wọn?
Ní pàtó, nítorí ìtòròpinpin mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli tímọ́tímọ́ yìí ni a kò fi lè rí ìjúbà àwọn aṣáájú tí wọ́n jẹ́ ènìyàn àti sísọ wọ́n di òrìṣà tí ó jẹ́ àmì-ànímọ́ àwọn ẹgbẹ́ awo lónìí láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọ́n kọ èròǹgbà ìyàtọ̀ láàárín ẹgbẹ́ àlùfáà àti ọmọ-ìjọ. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ lọ́nà ṣíṣewẹ́kú nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pé: “Ẹgbẹ́ agbo àwọn àlùfáà àti àwọn orúkọ oyè tí a fi ń mọniyàtọ̀ ni a kàléèwọ̀.”
Wọ́n ń tọ Jesu Kristi lẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú wọn àti gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ Kristian. Jesu ni ó sọ pé: “Kí a máṣe pè yín ní Rabbi, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí gbogbo yín jẹ́ ará. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ máṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀-ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni tí ń bẹ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni kí a máṣe pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.”—Matteu 23:8-12, NW.
Ó ṣe kedere pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jìnnà pátápátá sí jíjẹ́ ẹgbẹ́ awo gẹ́gẹ́ bí Jesu ti jìnnà sí jíjẹ́ alájẹkì àti ọ̀mùtí. A gbà pé, kìí ṣe olúkúlùkù ẹni tí àwọn ìròyìn èké nípa Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lo agbára ìdarí lé lórí ni ó kó sínú pàkúté ti fífọ̀rọ̀ èké bà á jẹ́. O wulẹ̀ lè jẹ́ pé àwọn kan ni a ti fún ní ìsọfúnni òdì. Bí ìwọ bá ní àwọn ìbéèrè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti ìgbàgbọ́ wọn, èéṣe tí ìwọ kò fi wá ọ̀nà láti túbọ̀ mọ̀ wọ́n síi? Ilẹ̀kùn àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn wà ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún gbogbo àwọn tí ń wá òtítọ́.
O tún lè jàǹfààní láti inú ìfìṣọ́ra wá ìmọ̀ pípéye wọn nínú Bibeli kí o sì kọ́ nípa bí o ṣe lè sin Ọlọrun ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu pé: “Wákàtí ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsìnyí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun.”—Johannu 4:23.