Ákúílà àti Pírísílà Tọkọtaya Àwòfiṣàpẹẹrẹ
“ẸBÁ mi kí Pírísíkà ati Ákúílà àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kristi Jésù, tí wọ́n fi ọrùn ara wọn wewu nítorí ọkàn mi, àwọn ẹni tí kì í ṣe èmi nìkan ṣùgbọ́n tí gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ń fi ọpẹ́ fún.”—Róòmù 16:3, 4.
Àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wọ̀nyí sí ìjọ Kristẹni tí ń bẹ ní Róòmù ṣàfihàn iyì gíga lọ́lá àti ìkàsí ọlọ́yàyà tí ó ní fún tọkọtaya yìí. Ó rí i dájú pé òun kò gbàgbé wọn nígbà tí ó ń kọ̀wé sí ìjọ wọn. Ṣùgbọ́n, ta ni “àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀” Pọ́ọ̀lù méjì wọ̀nyí, èé sì ti ṣe tí wọ́n fi ṣọ̀wọ́n fún un àti fún ìjọ tó bẹ́ẹ̀?—Tímótì Kejì 4:19.
Ara àwọn àfọ́nká Júù (àwọn Júù tí a tú káàkiri) ni Ákúílà, ó sì jẹ́ ọmọ ìlú Pọ́ńtù, ẹkùn kan ní àríwá Éṣíà Kékeré. Òun àti ìyàwó rẹ̀ Pírísílà (Pírísíkà) ti fìdí kalẹ̀ sí Róòmù. Àwùjọ àwọn Júù tí ó pọ̀ díẹ̀ ti wà ní ìlú yẹn, ó kéré tán, láti ìgbà tí Pompey ti ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 63 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí a kó ọ̀pọ̀ ẹlẹ́wọ̀n lọ sí Róòmù gẹ́gẹ́ bí ẹrú. Ní tòótọ́, àwọn àkọlé Róòmù fi hàn pé nǹkan bíi sínágọ́gù méjìlá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ wà ní ìlú àtijọ́ náà. Àwọn Júù mélòó kan láti Róòmù wà ní Jerúsálẹ́mù ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nígbà tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere. Bóyá àwọn ni wọ́n kọ́kọ́ mú ìhìn iṣẹ́ Kristẹni dé olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Róòmù.—Ìṣe 2:10.
Bí ó ti wù kí ó rí, a ti lé àwọn Júù kúrò ní Róòmù ní ọdún 49 tàbí ní ìbẹ̀rẹ̀ 50 ọdún Sànmánì Tiwa, nípasẹ̀ àṣẹ Olú Ọba Kíláúdíù. Fún ìdí èyí, ní Kọ́ríńtì tí í ṣe ìlú Gíríìsì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti pàdé Ákúílà àti Pírísílà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé sí Kọ́ríńtì, Ákúílà àti Pírísílà fi inú rere fi aájò àlejò hàn sí i, wọ́n sì fún un ní iṣẹ́, nítorí iṣẹ́ kan náà ni wọ́n ń ṣe—pípàgọ́.—Ìṣe 18:2, 3.
Àwọn Olùpàgọ́
Èyí kì í ṣe iṣẹ́ tí ó rọrùn. Pípàgọ́ ní nínú gígé ìrépé ohun èlò tàbí awọ líle, tí ó rí wúruwùru, àti rírán wọn pa pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn náà, Fernando Bea, ṣe sọ, ó jẹ́ “iṣẹ́ kan tí ó ń béèrè òye iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ àti ìfarabalẹ̀” lọ́wọ́ àwọn olùpàgọ́ tí ń lo “àwọn fọ́nrán wúruwùru, tí ó yi, tí wọ́n ń lò fún pípàgọ́ nígbà tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò, tí wọ́n fi ń pèsè ààbò kúrò lọ́wọ́ oòrùn àti òjò, tàbí fún dídi ẹrù nínú ọkọ̀ òkun.”
Èyí gbé ìbéèrè kan dìde. Pọ́ọ̀lù kò ha sọ pé òún ‘gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì,’ ní títipa báyìí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún un láti lépa iṣẹ́ ìgbésí ayé tí ó jọni lójú ní àwọn ọdún tí ń bọ̀? (Ìṣe 22:3) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ ni èyí, àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní kà á sí ohun tí ó ní ọlá láti kọ́ èwe kan ní iṣẹ́ ọwọ́ àní bí yóò bá gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ gíga pàápàá. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Ákúílà àti Pọ́ọ̀lù ti gba òye iṣẹ́ wọn nínú pípàgọ́ nígbà tí wọ́n wà ní ọ̀dọ́. Òye iṣẹ́ yẹn wá wúlò gidigidi lẹ́yìn náà. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, wọn kò ka irú iṣẹ́ àmúṣe bẹ́ẹ̀ sí olórí góńgó wọn. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé iṣẹ́ tí òun àti Ákúílà pẹ̀lú Pírísílà jọ ṣe ní Kọ́ríńtì wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan láti ṣètìlẹyìn fún ìgbòkègbodò òun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ, ti pípolongo ìhìn rere ‘láìgbé ẹrù ìnira tí ń náni lówó ka ẹnikẹ́ni lórí.’—Tẹsalóníkà Kejì 3:8; Kọ́ríńtì Kìíní 9:18; Kọ́ríńtì Kejì 11:7.
Ó hàn gbangba pé, inú Ákúílà àti Pírísílà dùn láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ míṣọ́nnárì Pọ́ọ̀lù rọrùn. Ta ní mọ iye ìgbà tí àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́ta yìí dáwọ́ dúró nígbà iṣẹ́ wọn láti wàásù láìjẹ́ bí àṣà fún àwọn tí ó gbéṣẹ́ fún wọn àti àwọn tí ń kọjá lọ! Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ wọn ti pípàgọ́ kò jọni lójú, tí ó sì ń tánni lókun, wọ́n láyọ̀ láti ṣe é, ní ṣíṣiṣẹ́ àní ní “òru ati ọ̀sán” kí wọ́n baà lè mú kí ire Ọlọ́run tẹ̀ síwájú—gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ Kristẹni lónìí ṣe ń fi ààbọ̀ṣẹ́ tàbí iṣẹ́ tí ń bá ìgbà yí gbọ́ bùkátà ara wọn kí wọ́n baà lè lo ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àkókò tí ó ṣẹ́kù fún ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gbọ́ ìhìn rere.—Tẹsalóníkà Kìíní 2:9; Mátíù 24:14; Tímótì Kìíní 6:6.
Àwọn Àpẹẹrẹ Aájò Àlejò
Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ilé Ákúílà ni Pọ́ọ̀lù lo gẹ́gẹ́ bí ibùdó fún ìgbòkègbodò míṣọ́nnárì rẹ̀ ní oṣù 18 tí ó fi wà ní Kọ́ríńtì. (Ìṣe 18:3, 11) Nígbà náà, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, Ákúílà àti Pírísílà gbádùn gbígba Sílà (Sílífánù) àti Tímótì pẹ̀lú lálejò nígbà tí wọ́n dé láti Makedóníà. (Ìṣe 18:5) Lẹ́tà méjì ti Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Tẹsalóníkà, tí ó wa di apá kan ìwé inú Bíbélì, ni ó ṣeé ṣe pé àpọ́sítélì náà kọ nígbà tí ó fi wà lọ́dọ̀ Ákúílà àti Pírísílà.
Ó rọrùn láti wòye pé ní àkókò yìí, ilé Pírísílà àti Ákúílà jẹ́ ibùdó gidi fún ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ibẹ̀ kún fún ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n—Sítéfánásì àti ìdílé rẹ̀, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́ ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Ákáyà, tí Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ batisí; Títíọ́sì Jọ́sítù, ẹni tí ó gba Pọ́ọ̀lù láyè láti lo ilé rẹ̀ fún sísọ àwíyé; àti Kírípọ́sì, olóyè alábòójútó sínágọ́gù, tí òun pẹ̀lú gbogbo agboolé rẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́. (Ìṣe 18:7, 8; Kọ́ríńtì Kìíní 1:16) Àwọn tí ó tún kù ni, Fọ́túnátù àti Ákáíkọ́sì; Gáyọ́sì, ẹni tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ilé rẹ̀ ni a ti ń ṣe ìpàdé ìjọ; Érásítù, ìríjú ìlú; Tẹ́tíọ́sì, akọ̀wé tí Pọ́ọ̀lù pe lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ara Róòmù fún láti kọ ọ́ sílẹ̀; àti Fébè, arábìnrin tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ ní ìjọ Kẹnkíríà tí ó wà nítòsí, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé òun ni ó mú lẹ́tà lọ láti Kọ́ríńtì sí Róòmù.—Róòmù 16:1, 22, 23; Kọ́ríńtì Kìíní 16:17.
Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí tí wọ́n ti ní àǹfààní láti fi aájò àlejò hàn sí òjíṣẹ́ arìnrìn àjò kan mọ bí ó ti lè fúnni níṣìírí àti bí ó ti jẹ́ mánigbàgbé tó. Àwọn ìrírí tí ń gbéni ró tí a sọ ní irú àkókò yẹn lè jẹ́ orísun ìtura ní ti gidi nípa ti ẹ̀mí fún gbogbogbòò. (Róòmù 1:11, 12) Pẹ̀lúpẹ̀lù, gẹ́gẹ́ bí Ákúílà àti Pírísílà ti ṣe, àwọn tí wọ́n ṣí ilé wọn sílẹ̀ fún ìpàdé, bóyá Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, ní ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn ti ṣíṣètìlẹ́yìn lọ́nà yìí fún ìtẹ̀síwájú ìjọsìn tòótọ́.
Ọ̀rẹ́ àwọn àti Pọ́ọ̀lù wọ̀ débi pé Ákúílà àti Pírísílà bá a lọ nígbà tí ó fi kúrò ní Kọ́ríńtì ní ìgbà ìrúwé ọdún 52 Sànmánì Tiwa, ní bíbá a lọ títí dé Éfésù. (Ìṣe 18:18-21) Wọ́n dúró ní ìlú yẹn, wọ́n sì fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìbẹ̀wò àpọ́sítélì náà tí yóò tẹ̀ lé e. Ibí yìí ni àwọn olùkọ́ dídángájíá ti ìhìn rere wọ̀nyí ti mú Ápólò tí ó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ “wọ ẹgbẹ́ wọn,” inú wọ́n sì dùn ní ríràn án lọ́wọ́ láti lóye “ọ̀nà Ọlọ́run . . . lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.” (Ìṣe 18:24-26) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù padà ṣèbẹ̀wò sí Éfésù nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta, ní nǹkan bí ìgbà òtútù ọdún 52 tàbí ọdún 53 Sànmánì Tiwa, pápá tí àwọn akínkanjú tọkọtaya yìí ti ṣiṣẹ́ ti pọ́n fún ìkórè. Fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta, Pọ́ọ̀lù wàásù, ó sì kọ́ni nípa “Ọ̀nà Náà,” nígbà tí ìjọ àwọn ará Éfésù ń ṣe ìpàdé ní ilé Ákúílà.—Ìṣe 19:1-20, 26; 20:31; Kọ́ríńtì Kìíní 16:8, 19.
Lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n padà sí Róòmù, àwọn ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù méjì wọ̀nyí ń bá a nìṣó láti “máa tẹ̀ lé ìlà ipa ọ̀nà aájò àlejò,” ní mímú kí ilé wọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn ìpàdé Kristẹni.—Róòmù 12:13; 16:3-5.
Wọ́n ‘Fi Ọrùn Wọn Wewu’ Nítorí Pọ́ọ̀lù
Bóyá Pọ́ọ̀lù tún gbé lọ́dọ̀ Ákúílà àti Pírísílà nígbà tí ó fi wà ní Éfésù. Ó ha ń gbé pẹ̀lú wọn nígbà rúkèrúdò àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà? Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Ìṣe 19:23-31 ṣe sọ, nígbà tí àwọn ọkùnrin oníṣẹ́ ọnà tí wọ́n ń ṣe ojúbọ gbé ọ̀tẹ̀ dìde sí wíwàásù ìhìn rere, àwọn ará ní láti dá Pọ́ọ̀lù dúró láti má ṣe fi ara rẹ̀ wewu nípa lílọ síwájú àwọn ènìyànkénìyàn náà. Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan lórí Bíbélì ti sọ pé ó lè jẹ́ pé nínú irú àyíká ipò eléwu bẹ́ẹ̀ gan-an ni Pọ́ọ̀lù ti nímọ̀lára ‘àìdánilójú àní nípa ìwàláàyè rẹ̀ pàápàá,’ tí Ákúílà àti Pírísílà sì dá sí ọ̀rọ̀ ní àwọn ọ̀nà kan, ‘ní fífi ọrùn ara wọn wewu’ nítorí rẹ̀.—Kọ́ríńtì Kejì 1:8; Róòmù 16:3, 4.
Nígbà tí “rògbòdìyàn” naa “ti rọlẹ̀,” Pọ́ọ̀lù fi ọgbọ́n fi ìlú náà sílẹ̀. (Ìṣe 20:1) Dájúdájú, Ákúílà àti Pírísílà pẹ̀lú kojú àtakò àti ìfiniṣẹ̀sín. Ìyẹ́n ha mú kí wọ́n sorí kodò bí? Ní òdì kejì, Ákúílà àti Pírísílà ń bá a nìṣó tìgboyàtìgboyà nínú ìsapá Kristẹni wọn.
Tọkọtaya Tímọ́tímọ́
Lẹ́yìn tí ìṣàkóso Kíláúdíù ti dópin, Ákúílà àti Pírísílà padà sí Róòmù. (Róòmù 16:3-15) Ṣùgbọ́n, nígbà tí a mẹ́nu kàn wọ́n kẹ́yìn nínú Bíbélì, wọ́n ti padà sí Éfésù. (Tímótì Kejì 4:19) Ní àfikún sí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú gbogbo ìtọ́kasí yòó kù nínú Ìwé Mímọ́, a dárúkọ ọkọ àti aya yìí pa pọ̀ ni. Ẹ wo tọkọtaya tímọ́tímọ́ àti oníṣọ̀kan tí wọ́n jẹ́! Pọ́ọ̀lù kò lè ronú nípa arákùnrin ọ̀wọ́n yẹn, Ákúílà, láìrántí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ oníṣòtítọ́ ti aya rẹ̀. Ẹ sì wo àpẹẹrẹ rere tí èyí jẹ́ fún àwọn tọkọtaya Kristẹni lónìí, nítorí pé ìtìlẹ́yìn adúróṣinṣin ti alábàáṣègbéyàwó olùfọkànsìn kan ń jẹ́ kí ẹnì kan lè ṣe púpọ̀ “nínú iṣẹ́ Olúwa” àti, nígbà míràn, ju bí ì bá ti lè ṣe nígbà tí ó jẹ́ àpọ́n.—Kọ́ríńtì Kìíní 15:58.
Ákúílà àti Pírísílà ṣiṣẹ́ sìn nínú àwọn ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bíi mélòó kan. Bíi tiwọn, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni onítara lónìí ti mú ara wọn wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti lọ sí ibi tí àìní gbé pọ̀. Wọ́n tún ń gbádùn ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn tí ń wá láti inú rírí ire Ìjọba tí ń dàgbà, àti èyí tí ń wá láti inú mímú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ọlọ́yàyà ti Kristẹni, tí ó sì ṣeyebíye dàgbà.
Nípasẹ̀ àpẹẹrẹ gíga lọ́lá ti ìfẹ́ Kristẹni wọn, Ákúílà àti Pírísílà jèrè ìmọrírì Pọ́ọ̀lù àti ti àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, wọ́n ní ànímọ́ rere pẹ̀lú Jèhófà fúnra rẹ̀. Ìwé Mímọ́ mú un dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́ ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.”—Hébérù 6:10.
A lè máà ní àǹfààní láti lo ara wa ní àwọn ọ̀nà tí ó jọ èyí tí Ákúílà àti Pírísílà gbà lo ara wọn, síbẹ̀ a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn títa yọ lọ́lá. Ìtẹ́lọ́rùn jíjinlẹ̀ yóò jẹ́ tiwa bí a ti ń fi okun àti ìwàláàyè wa fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀, ní ṣíṣàìgbàgbé “rere ṣíṣe ati ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irúfẹ́ àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.”—Hébérù 13:15, 16.