Ìwé Kìíní sí Tímótì
6 Kí àwọn tó jẹ́ ẹrú* máa ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún àwọn olúwa wọn,+ kí àwọn èèyàn má bàa sọ̀rọ̀ àbùkù nípa orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.+ 2 Bákan náà, kí àwọn tí olúwa wọn jẹ́ onígbàgbọ́ má ṣe hùwà àìlọ́wọ̀ sí wọn torí wọ́n jẹ́ ará. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n túbọ̀ máa ṣe ìránṣẹ́, torí àwọn tó ń jàǹfààní iṣẹ́ ìsìn rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti àyànfẹ́.
Túbọ̀ máa fi nǹkan wọ̀nyí kọ́ni, kí o sì máa gbani níyànjú. 3 Tí ẹnikẹ́ni bá fi ẹ̀kọ́ míì kọ́ni, tí kò sì fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní,*+ tó wá látọ̀dọ̀ Olúwa wa Jésù Kristi àti ẹ̀kọ́ tó bá ìfọkànsin Ọlọ́run mu,+ 4 ó ń gbéra ga, kò sì lóye ohunkóhun.+ Ìjiyàn àti fífa ọ̀rọ̀ ló gbà á lọ́kàn.*+ Àwọn nǹkan yìí máa ń fa owú, wàhálà, bíbanijẹ́,* ìfura burúkú, 5 ṣíṣe awuyewuye lemọ́lemọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan láàárín àwọn èèyàn tí ìrònú wọn ti dìbàjẹ́,+ tí wọn ò mọ òtítọ́, tí wọ́n sì ń ronú pé èrè ni ìfọkànsin Ọlọ́run wà fún.+ 6 Lóòótọ́, èrè ńlá wà nínú ìfọkànsin Ọlọ́run+ téèyàn bá ní ìtẹ́lọ́rùn.* 7 Torí a ò mú nǹkan kan wá sí ayé, a ò sì lè mú ohunkóhun jáde.+ 8 Torí náà, tí a bá ti ní oúnjẹ* àti aṣọ,* àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.+
9 Àmọ́ àwọn tó pinnu pé àwọn fẹ́ di ọlọ́rọ̀ máa ń kó sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn+ àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́ ọkàn tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì lè pani lára, èyí tó ń mú kí àwọn èèyàn pa run kí wọ́n sì ṣègbé.+ 10 Torí ìfẹ́ owó ni ọ̀kan lára ohun tó ń fa onírúurú jàǹbá, àwọn kan tí wọ́n sì ní irú ìfẹ́ yìí ti ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ìrora tó pọ̀ gún gbogbo ara wọn.+
11 Àmọ́, ìwọ tí o jẹ́ èèyàn Ọlọ́run, sá fún àwọn nǹkan yìí. Ṣùgbọ́n máa wá òdodo, ìfọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà àti ìwà tútù.+ 12 Ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́; di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí, èyí tí a torí rẹ̀ pè ọ́, tí o sì wàásù rẹ̀ dáadáa ní gbangba lójú ọ̀pọ̀ ẹlẹ́rìí.
13 Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, ẹni tó pa ohun gbogbo mọ́ láàyè àti Kristi Jésù, ẹlẹ́rìí tó wàásù dáadáa ní gbangba níwájú Pọ́ńtíù Pílátù,+ 14 pé kí o pa àṣẹ náà mọ́ láìní àbààwọ́n àti láìlẹ́gàn títí di ìgbà tí Olúwa wa Jésù Kristi máa fara hàn,+ 15 èyí tí ẹni tó jẹ́ aláyọ̀ àti Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo máa fi hàn nígbà tí àwọn àkókò rẹ̀ bá tó. Òun ni Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa,+ 16 ẹnì kan ṣoṣo tó ní àìkú,+ ẹni tó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́,+ tí èèyàn kankan kò rí rí, tí wọn ò sì lè rí.+ Òun ni kí ọlá àti agbára ayérayé jẹ́ tirẹ̀. Àmín.
17 Sọ* fún àwọn ọlọ́rọ̀ inú ètò àwọn nǹkan yìí* pé kí wọ́n má ṣe gbéra ga,* kí wọ́n má sì gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ tí kò dáni lójú,+ àmọ́ lé Ọlọ́run, ẹni tó ń pèsè gbogbo ohun tí à ń gbádùn fún wa lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ.+ 18 Sọ fún wọn pé kí wọ́n máa ṣe rere, àní kí wọ́n máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere, kí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́,* kí wọ́n ṣe tán láti máa fúnni,+ 19 kí wọ́n máa to ìṣúra tí kò lè díbàjẹ́ jọ láti fi ṣe ìpìlẹ̀ tó dáa fún ọjọ́ iwájú,+ kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.+
20 Tímótì, máa ṣọ́ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ,+ yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán tó ń ba ohun mímọ́ jẹ́ àti àwọn ohun tí wọ́n ń fi ẹ̀tàn pè ní “ìmọ̀” èyí tó ń ta ko òtítọ́.+ 21 Àwọn kan sì ti kúrò nínú ìgbàgbọ́ torí wọ́n ń fi irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ hàn.
Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú rẹ.