ORÍ 21
“Ọrùn Mi Mọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀jẹ̀ Gbogbo Èèyàn”
Pọ́ọ̀lù fìtara wàásù, ó sì ń fún àwọn alàgbà nímọ̀ràn
Ó dá lórí Ìṣe 20:1-38
1-3. (a) Ṣàlàyé ohun tó fa ikú Yútíkọ́sì. (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe, kí lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sì jẹ́ ká mọ̀ nípa Pọ́ọ̀lù?
PỌ́Ọ̀LÙ ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ará tó wà ní ìjọ Tíróásì lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan. Torí pé alẹ́ tó máa lò kẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn ará náà nìyẹn, ó bá wọn sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, títí di ọ̀gànjọ́ òru. Wọ́n tan àtùpà bíi mélòó kan sínú yàrá tí wọ́n wà. Torí náà, ooru mú, ó sì ṣeé ṣe kí èéfín àtùpà tó ń jó yẹn ti bo inú yàrá náà. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì jókòó sí ojú ọ̀kan lára àwọn fèrèsé tó wà lókè ilé náà. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, oorun gbé Yútíkọ́sì lọ, ó sì ṣubú láti àjà kẹta!
2 Torí pé oníṣègùn ni Lúùkù, ó ṣeé ṣe kó wà lára àwọn tó kọ́kọ́ sáré jáde lọ wo ọ̀dọ́kùnrin náà. Nígbà tí wọ́n fi máa débẹ̀, ẹ̀pa ò bóró mọ́, “òkú” Yútíkọ́sì ni wọ́n bá. (Ìṣe 20:9) Àmọ́, ohun ìyanu kan ṣẹlẹ̀. Pọ́ọ̀lù dùbúlẹ̀ lé ọ̀dọ́kùnrin náà, ó sì sọ fáwọn ará náà pé: “Ẹ dákẹ́ ariwo, torí ó ti jí.” Pọ́ọ̀lù ti jí Yútíkọ́sì dìde!—Ìṣe 20:10.
3 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe lágbára tó. Àmọ́, ṣé Pọ́ọ̀lù ló fà á tí Yútíkọ́sì fi kú? Rárá o! Síbẹ̀, kò fẹ́ kí ikú ọ̀dọ́kùnrin yìí ba àkókò pàtàkì yẹn jẹ́ tàbí kó mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀. Torí náà bó ṣe jí Yútíkọ́sì dìde tu ìjọ yẹn nínú, ó sì fún wọn níṣìírí láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ. Ó ṣe kedere pé ẹ̀mí èèyàn jọ Pọ́ọ̀lù lójú. Ohun tó sọ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ gbogbo èèyàn.” (Ìṣe 20:26) Ẹ jẹ́ ká wo bí àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ṣe lè ran àwa náà lọ́wọ́, tó bá dọ̀rọ̀ kí ẹ̀mí àwọn èèyàn jọ wá lójú.
“Ó Bẹ̀rẹ̀ Ìrìn Àjò Rẹ̀ Lọ sí Makedóníà” (Ìṣe 20:1, 2)
4. Ìṣòro ńlá wo ni Pọ́ọ̀lù ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ nínú ẹ̀?
4 Bá a ṣe sọ ní orí tó ṣáájú, Pọ́ọ̀lù ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ nínú ìṣòro ńlá kan ni. Wàhálà kékeré kọ́ ni iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ dá sílẹ̀ nílùú Éfésù. Àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà tí wọ́n ń gbẹ́ ère, tí wọ́n sì ń tà á fáwọn tó ń jọ́sìn òrìṣà Átẹ́mísì náà lọ́wọ́ nínú wàhálà tó ṣẹlẹ̀ yìí. Ìṣe 20:1 sọ pé: “Nígbà tí rúkèrúdò náà rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn, lẹ́yìn tó fún wọn ní ìṣírí, tó sì dágbére fún wọn, ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Makedóníà.”
5, 6. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe pẹ́ tó nílùú Makedóníà, kí ló sì ṣe fáwọn ará tó wà níbẹ̀? (b) Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi ń wo àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀?
5 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń lọ sí Makedóníà, ó dúró ní etíkun ìlú Tíróásì, ó sì lo ọjọ́ mélòó kan níbẹ̀. Ó ń dúró de Títù tó lọ sí Kọ́ríńtì kó wá bá òun níbẹ̀. (2 Kọ́r. 2:12, 13) Àmọ́, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ò rí Títù, ó lọ sí Makedóníà, ó sì ṣeé ṣe kó lò tó ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ níbẹ̀ kó lè fún àwọn ará “ní ọ̀pọ̀ ìṣírí.”a (Ìṣe 20:2) Nígbà tó yá, Títù wá bá Pọ́ọ̀lù ní Makedóníà, ó sì mú ìròyìn rere wá nípa ohun táwọn ará Kọ́ríńtì ṣe nígbà tí wọ́n gba lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí wọn. (2 Kọ́r. 7:5-7) Ìyẹn ló mú kí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà míì sí wọn. Lẹ́tà náà la wá mọ̀ sí Kọ́ríńtì Kejì.
6 Ó bá a mu wẹ́kú pé Lúùkù lo ọ̀rọ̀ náà “ìṣírí” láti fi ṣàlàyé ìbẹ̀wò tí Pọ́ọ̀lù ṣe sáwọn ará tó wà nílùú Éfésù àti Makedóníà. Ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni gan-an! Pọ́ọ̀lù ò dà bí àwọn Farisí tí wọ́n ń wo àwọn èèyàn bí ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan, alábàáṣiṣẹ́ ló ka àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni sí. (Jòh 7:47-49; 1 Kọ́r. 3:9) Kódà, nígbà tó fẹ́ fún wọn ní ìmọ̀ràn tó lágbára, kò bá wọn sọ̀rọ̀ bíi pé òun sàn jù wọ́n lọ.—2 Kọ́r. 2:4.
7. Báwo làwọn alábòójútó ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lónìí?
7 Lónìí, àwọn alàgbà àtàwọn alábòójútó àyíká máa ń sapá gan-an kí wọ́n lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù. Kódà nígbà tí wọ́n bá ń báni wí, ohun tó máa ń wà lọ́kàn wọn ni pé kí wọ́n fún àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ níṣìírí. Àwọn alábòójútó kì í dá àwọn èèyàn lẹ́bi, ṣe ni wọ́n máa ń ronú nípa bí nǹkan ṣe rí lára àwọn èèyàn, tí wọ́n á sì fún wọn níṣìírí. Alábòójútó àyíká kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ló máa ń fẹ́ ṣe ohun tó dáa, àmọ́ àwọn ìṣòro tí wọ́n ń bá yí kì í jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n lè ṣe.” Àwọn alábòójútó lè fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin bẹ́ẹ̀ lókun.—Héb. 12:12, 13.
Wọ́n “Gbìmọ̀ Pọ̀ Láti Pa Á” (Ìṣe 20:3, 4)
8, 9. (a) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù ò fi lọ sí Síríà mọ́? (b) Kí ló ṣeé ṣe kó mú káwọn Júù di Pọ́ọ̀lù sínú?
8 Láti Makedóníà, Pọ́ọ̀lù lọ sí ìlú Kọ́ríńtì.b Lẹ́yìn tó ti lo oṣù mẹ́ta níbẹ̀, ó wù ú láti máa bá ìrìn àjò ẹ̀ lọ sí Kẹnkíríà, níbi tó ti fẹ́ wọkọ̀ ojú omi lọ sí Síríà. Ibẹ̀ ló máa gbà lọ sí Jerúsálẹ́mù, á sì kó àwọn ẹ̀bùn tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ fún àwọn ará tó jẹ́ aláìní níbẹ̀.c (Ìṣe 24:17; Róòmù 15:25, 26) Àmọ́, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí Pọ́ọ̀lù yí ibi tó fẹ́ gbà pa dà. Ìṣe 20:3 sọ pé: “Àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á”!
9 Kò yani lẹ́nu pé àwọn Júù di Pọ́ọ̀lù sínú torí pé apẹ̀yìndà ni wọ́n kà á sí. Ṣáájú ìgbà yẹn, ìwàásù Pọ́ọ̀lù ti jẹ́ kí Kírípọ́sì, tó jẹ́ alága sínágọ́gù tó wà ní Kọ́ríńtì di Kristẹni. (Ìṣe 18:7, 8; 1 Kọ́r. 1:14) Nígbà kan, àwọn Júù tó wà ní Kọ́ríńtì fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù níwájú Gálíò tó jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀ Ákáyà. Àmọ́, ṣe ni Gálíò sọ pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ohun tó sì ṣe yìí múnú bí àwọn ọ̀tá Pọ́ọ̀lù gan-an ni. (Ìṣe 18:12-17) Ó ṣeé ṣe káwọn Júù tó wà ní Kọ́ríńtì mọ̀ tàbí kí wọ́n rò pé Pọ́ọ̀lù máa tó wọkọ̀ òkun ní Kẹnkíríà tó wà nítòsí wọn. Torí náà, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti lọ dènà dè é níbẹ̀. Kí ni Pọ́ọ̀lù máa wá ṣe báyìí?
10. Ṣé bí Pọ́ọ̀lù ò ṣe gba Kẹnkíríà fi hàn pé ojo ni? Ṣàlàyé.
10 Kí Pọ́ọ̀lù má bàa kó sí àwọn Júù yẹn lọ́wọ́, kí nǹkan kan má sì ṣe ọrẹ tí wọ́n fi rán an, kò lọ sí Kẹnkíríà mọ́, ṣe ló pa dà sí Makedóníà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìrìn àjò orí ilẹ̀ léwu nígbà yẹn, torí pé àwọn olè sábà máa ń dá àwọn èèyàn lọ́nà. Kódà, àwọn ilé táwọn arìnrìn àjò máa ń sùn sí náà léwu. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù yàn láti gba orí ilẹ̀ dípò táá fi lọ kó sọ́wọ́ àwọn tó ń dènà dè é ní Kẹnkíríà. Ohun míì tún ni pé òun nìkan kọ́ ló ń rìnrìn àjò náà. Àwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò míṣọ́nnárì lọ́tẹ̀ yìí ni Àrísítákọ́sì, Gáyọ́sì, Síkúńdọ́sì, Sópátérì, Tímótì, Tírófímù àti Tíkíkù.—Ìṣe 20:3, 4.
11. Kí làwa Kristẹni máa ń ṣe lónìí ká má bàa kó sínú ewu, àpẹẹrẹ wo sì ni Jésù fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí?
11 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, táwa Kristẹni bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lónìí, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa kó sínú ewu. Láwọn agbègbè kan, ṣe ni gbogbo wa jọ máa ń lọ síbi tá a ti máa ṣíṣẹ, tàbí ó kéré tán, ká lọ ní méjìméjì dípò tẹ́nì kan á fi máa dá lọ. Tó bá wá dọ̀rọ̀ inúnibíni ńkọ́? Àwa Kristẹni mọ̀ pé a ò ríbi yẹ̀ ẹ́ sí. (Jòh. 15:20; 2 Tím. 3:12) Síbẹ̀, a kì í mọ̀ọ́mọ̀ fi ara wa sínú ewu. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Jésù yẹ̀ wò. Nígbà kan táwọn alátakò ṣa òkúta tí wọ́n sì fẹ́ máa sọ ọ́ lu Jésù ní Jerúsálẹ́mù, ó “fara pa mọ́, ó sì kúrò nínú tẹ́ńpìlì.” (Jòh. 8:59) Nígbà tó tún yá, táwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á, “Jésù ò rìn káàkiri ní gbangba mọ́ láàárín àwọn Júù, àmọ́ ó kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè tó wà nítòsí aginjù.” (Jòh. 11:54) Jésù máa ń ṣe ohun tó bá yẹ láti dáàbò bo ara ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, tó bá rí i pé kò ta ko ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Lóde òní, ohun táwa Kristẹni náà máa ń ṣe nìyẹn.—Mát. 10:16.
‘Ìtùnú Tí Wọ́n Rí Gbà Kọjá Sísọ’ (Ìṣe 20:5-12)
12, 13. (a) Báwo ni àjíǹde Yútíkọ́sì ṣe rí lára àwọn ará ìjọ náà? (b) Ìrètí wo ló wà nínú Bíbélì tó ń tu àwọn téèyàn wọn ti kú nínú?
12 Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n bá a rìnrìn àjò gba Makedóníà kọjá, nígbà tó sì yá ó jọ pé wọ́n gba ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé gbogbo wọn tún pàdé ní Tíróásì.d Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Láàárín ọjọ́ márùn-ún, a dé ọ̀dọ̀ wọn ní Tíróásì.”e (Ìṣe 20:6) Ìlú yìí ni Pọ́ọ̀lù ti jí Yútíkọ́sì tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan dìde. Fojú inú wo bó ṣe máa rí lára àwọn ará náà nígbà tí Pọ́ọ̀lù jí Yútíkọ́sì dìde! Bí àkọsílẹ̀ náà ṣe sọ, ‘ìtùnú tí wọ́n rí gbà kọjá sísọ.’—Ìṣe 20:12.
13 Òótọ́ ni pé irú iṣẹ́ ìyanu yìí kì í ṣẹlẹ̀ lóde òní. Síbẹ̀, àwọn téèyàn wọn kú máa ń rí ‘ìtùnú tó kọjá sísọ gbà’ nípasẹ̀ ìrètí àjíǹde tó wà nínú Bíbélì. (Jòh. 5:28, 29) Torí pé aláìpé ni Yútíkọ́sì, ó tún pa dà kú. (Róòmù 6:23) Àmọ́, àwọn tó bá jíǹde nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí máa láǹfààní láti máa wà láàyè títí láé! Bákan náà, àwọn tó máa bá Jésù jọba lọ́run máa gba àìkú. (1 Kọ́r. 15:51-53) Torí náà, yálà a jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí “àgùntàn mìíràn,” àwa Kristẹni òde òní kì í banú jẹ́ jù, torí pé ìrètí tá a ní máa ń mú ká rí ‘ìtùnú tó kọjá sísọ.’—Jòh. 10:16.
“Ní Gbangba àti Láti Ilé dé Ilé” (Ìṣe 20:13-24)
14. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn alàgbà ìjọ tó wà ní Éfésù nígbà tí wọ́n lọ pàdé ẹ̀ ní Mílétù?
14 Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò kúrò ní Tíróásì lọ sí Ásósì, lẹ́yìn náà ni wọ́n lọ sí Mítílénè, Kíósì, Sámósì àti Mílétù. Ó wu Pọ́ọ̀lù pé kó dé Jerúsálẹ́mù kí Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì tó bẹ̀rẹ̀. Bó ṣe ń kánjú lọ sí Jerúsálẹ́mù nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì yẹn jẹ́ ká rí ohun tó fà á tí kò fi dúró ní Éfésù nígbà tó ń pa dà bọ̀. Àmọ́, torí pé ó fẹ́ bá àwọn alàgbà ìjọ tó wà ní Éfésù sọ̀rọ̀, ló ṣe sọ pé kí wọ́n wá pàdé òun ní Mílétù. (Ìṣe 20:13-17) Nígbà tí wọ́n dé, Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ̀ dáadáa bí mo ṣe ń ṣe láàárín yín láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo ti dé sí ìpínlẹ̀ Éṣíà, tí mò ń sìn bí ẹrú fún Olúwa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti omijé àti àwọn àdánwò tó ṣẹlẹ̀ sí mi nítorí ọ̀tẹ̀ àwọn Júù, bí mi ò ṣe fà sẹ́yìn nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tó lérè fún yín tàbí nínú kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé. Àmọ́ mo jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì nípa ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.”—Ìṣe 20:18-21.
15. Kí nìdí tá a fí ń wàásù láti ilé dé ilé?
15 Onírúurú ọ̀nà la gbà ń wàásù fáwọn èèyàn lónìí. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a máa ń sapá láti lọ síbi tá a ti lè ráwọn èèyàn, bóyá láwọn ibi tí wọ́n ti ń wọkọ̀, ibi táwọn èrò pọ̀ sí tàbí ibi tí wọ́n ti ń tajà. Bó ti wù kó rí, iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé lọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń wàásù. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé, bá a ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé ń mú kí gbogbo èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Èyí sì ń fi hàn pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. Ìdí míì ni pé, bá a ṣe ń lọ sílè àwọn èèyàn ń mú ká lè ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, bá a ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, ká sì lè fara da ìṣòro. Láìsí àní-àní, ohun táwọn èèyàn fi ń dá àwa Kristẹni tòótọ́ mọ̀ lónìí ni bá a ṣe ń fìtara wàásù “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.”
16, 17. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun ò bẹ̀rù, báwo sì làwa Kristẹni ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lónìí?
16 Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn alàgbà ìjọ tó wà ní Éfésù pé òun ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun ní Jerúsálẹ́mù. Ó wá fi kún un pé: “Síbẹ̀, mi ò ka ẹ̀mí mi sí ohun tó ṣe pàtàkì sí mi, tí mo bá ṣáà ti lè parí eré ìje mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:24) Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù ò bẹ̀rù rárá, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ láti parí iṣẹ́ ìwàásù ẹ̀. Kódà, kò jẹ́ kí àìlera ẹ̀ tàbí inúnibíni tó gbóná janjan tí wọ́n ṣe sí i dí òun lọ́wọ́.
17 Lónìí, àwa Kristẹni náà ń fara da onírúurú ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará wa kan ń fara da inúnibíni, àìsàn ń bá àwọn kan fínra, àwọn míì ní ìdààmú ọkàn, kódà ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa láwọn ibì kan. Àwọn ọmọ ilé ìwé náà máa ń fúngun mọ́ àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni pé kí wọ́n ṣe ohun tí ò dáa. Láìka àwọn ìṣòro táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kojú sí, bíi ti Pọ́ọ̀lù a máa ń fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin. A ti pinnu láti máa “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.”
“Ẹ Kíyè sí Ara Yín àti sí Gbogbo Agbo” (Ìṣe 20:25-38)
18. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi lè sọ pé ọrùn òun mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn, báwo làwọn alàgbà ìjọ Éfésù náà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
18 Nígbà táwọn alàgbà ìjọ Éfésù wá bá Pọ́ọ̀lù, ó sọ bóun ṣe bójú tó àwọn ìjọ fún wọn, ó sì gbà wọ́n nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun. Ó jẹ́ kí wọ́n kọ́kọ́ mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà tí wọ́n máa rí òun kẹ́yìn nìyẹn. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ gbogbo èèyàn, nítorí mi ò fà sẹ́yìn nínú sísọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún yín.” Báwo làwọn alàgbà ìjọ Éfésù ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tí ọrùn wọn á fi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ gbogbo èèyàn? Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ kíyè sí ara yín àti sí gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ ti yàn yín ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:26-28) Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wọn pé “àwọn aninilára ìkookò” máa yọ́ wọnú agbo, wọ́n á sì “sọ àwọn ọ̀rọ̀ békebèke láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn sẹ́yìn ara wọn.” Kí ló yẹ káwọn alàgbà yìí ṣe? Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ máa wà lójúfò, kí ẹ sì fi sọ́kàn pé fún ọdún mẹ́ta, mi ò ṣíwọ́ gbígba ẹnì kọ̀ọ̀kan yín níyànjú pẹ̀lú omijé tọ̀sántòru.”—Ìṣe 20:29-31.
19. Kí làwọn apẹ̀yìndà ṣe nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ń parí lọ, kí nìyẹn sì yọrí sí nígbà tó yá?
19 “Àwọn aninilára ìkookò” wọnú ìjọ níparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ní nǹkan bí ọdún 98 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi ló ti fara hàn báyìí . . . Wọ́n kúrò lọ́dọ̀ wa, àmọ́ wọn kì í ṣe ara wa; torí ká ní wọ́n jẹ́ ara wa ni, wọn ò ní fi wá sílẹ̀.” (1 Jòh. 2:18, 19) Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta, àwọn apẹ̀yìndà ti kóra jọ, wọ́n sì gbà pé àwọn dáa ju àwọn míì nínú ìjọ. Nígbà tó sì di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin, Olú Ọba Kọnsitatáìnì fọwọ́ sí ayédèrú ẹ̀sìn Kristẹni. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí sọ “àwọn ọ̀rọ̀ békebèke.” Wọ́n da ẹ̀kọ́ Kristẹni pọ̀ mọ́ àṣà àti ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu kó lè dà bíi pé Kristẹni ni wọ́n. Títí dòní, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣì ń tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà yìí.
20, 21. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe tó fi hàn pé ó múra tán láti yááfì àwọn nǹkan torí àwọn ará, báwo làwọn alàgbà náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí?
20 Pọ́ọ̀lù ò dà bí àwọn tó máa yọ́ wọnú ìjọ kí wọ́n lè kó àwọn èèyàn nífà. Ó ń ṣiṣẹ́ kó lè gbọ́ bùkátà ara ẹ̀ kó má bàa di ẹrù lé ìjọ lórí. Kì í ṣe torí kí Pọ́ọ̀lù lè kó ọrọ̀ jọ ló ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe fún wọn. Ó gba àwọn alàgbà ìjọ Éfésù nímọ̀ràn pé kí wọ́n ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan nítorí àwọn ará. Ó sọ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ aláìlera, ẹ sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ sọ pé: ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.’ ”—Ìṣe 20:35.
21 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn alàgbà lónìí máa ń múra tán láti yááfì àwọn nǹkan torí àwọn arákùnrin wọn. Àwọn tí Jèhófà yàn láti máa “ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run” máa ń ṣe é tọkàntọkàn, wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́. Wọn ò dà bí àwọn aṣáájú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń sanra táwọn ọmọ ìjọ wọn sì ń rù. Kò sí àyè fún ìgbéraga tàbí kéèyàn máa wá ipò ọlá nínú ìjọ Kristẹni, torí ẹ̀tẹ́ ló máa ń gbẹ̀yìn àwọn tó bá ń wá “ògo ara wọn.” (Òwe 25:27) Téèyàn bá sì kọjá àyè ẹ̀, dandan ni kó kàbùkù.—Òwe 11:2.
22. Kí ló mú káwọn alàgbà ìjọ Éfésù nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù gan-an?
22 Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, ìyẹn sì mú káwọn náà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Kódà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ máa lọ, “gbogbo wọn bú sẹ́kún, wọ́n gbá Pọ́ọ̀lù mọ́ra, wọ́n sì fẹnu kò ó lẹ́nu tìfẹ́tìfẹ́.” (Ìṣe 20:37, 38) Bákan náà lónìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọyì àwọn tó dà bíi Pọ́ọ̀lù wọ́n sì máa ń nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, torí pé ṣe nirú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń lo àkókò, okun àtàwọn ohun ìní wọn nítorí àwọn ará. Ní báyìí tá a ti gbé àpẹẹrẹ rere Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò, ó hàn kedere pé kò sọ àsọdùn, kò sì gbéra ga nígbà tó sọ pé: “Ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ gbogbo èèyàn.”—Ìṣe 20:26.
a Wo àpótí náà, “Àwọn Lẹ́tà Tí Pọ́ọ̀lù Kọ Nígbà Tó Wà ní Makedóníà.”
b Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ṣèbẹ̀wò sílùú Kọ́ríńtì ló kọ lẹ́tà sáwọn ará Róòmù.
c Wo àpótí náà, “Pọ́ọ̀lù Fi Ọrẹ Táwọn Ará Fi Ṣèrànwọ́ Jíṣẹ́.”
d Bí Lúùkù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “a” nínú Ìṣe 20:5, 6 fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù lọ bá Lúùkù nílùú Fílípì lẹ́yìn tó ti fi í sílẹ̀ síbẹ̀ nígbà kan, táwọn méjèèjì wá jọ lọ sí Tíróásì.—Ìṣe 16:10-17, 40.