Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
25 Nítorí náà, lẹ́yìn tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì+ dé ìpínlẹ̀ náà, tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ó kúrò ní Kesaríà lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, ó sì lọ sí Jerúsálẹ́mù. 2 Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn èèyàn sàràkí-sàràkí lára àwọn Júù wá sọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù láìdáa lójú rẹ̀.+ Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Fẹ́sítọ́ọ̀sì 3 pé kó ṣojú rere sáwọn,* kó ránṣẹ́ pe Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ ṣe ni wọ́n ń gbèrò láti lúgọ de Pọ́ọ̀lù kí wọ́n sì pa á lójú ọ̀nà.+ 4 Ṣùgbọ́n, Fẹ́sítọ́ọ̀sì fèsì pé kí wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ nínú àhámọ́ ní Kesaríà pé òun náà máa pa dà síbẹ̀ láìpẹ́. 5 Ó sọ pé: “Torí náà, kí àwọn tó wà nípò àṣẹ láàárín yín bá mi lọ, kí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án, tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ọkùnrin náà ti ṣe ohun tí kò tọ́.”+
6 Nígbà tó ti lo nǹkan bí ọjọ́ mẹ́jọ sí mẹ́wàá láàárín wọn, ó lọ sí Kesaríà, ó jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́ lọ́jọ́ kejì, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù wọlé. 7 Nígbà tó wọlé, àwọn Júù tó wá láti Jerúsálẹ́mù dúró yí i ká, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn tó lágbára kàn án, àwọn ẹ̀sùn tí wọn kò lè fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn.+
8 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù gbèjà ara rẹ̀, ó ní: “Mi ò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan sí Òfin àwọn Júù tàbí sí tẹ́ńpìlì tàbí sí Késárì.”+ 9 Fẹ́sítọ́ọ̀sì, tó ń wá ojú rere àwọn Júù,+ dá Pọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Ṣé o fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí a lè dá ẹjọ́ rẹ níbẹ̀ níwájú mi lórí àwọn nǹkan yìí?” 10 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Késárì, níbi tó yẹ kí a ti dá ẹjọ́ mi. Mi ò ṣe àìdáa kankan sí àwọn Júù, bí ìwọ náà ṣe ń rí i kedere báyìí. 11 Tó bá jẹ́ pé oníwà àìtọ́ ni mí lóòótọ́, tí mo sì ti ṣe ohun tó yẹ fún ikú,+ mi ò bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ má pa mí; àmọ́ tí kò bá sí òótọ́ nínú gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn ọkùnrin yìí fi kàn mí, kò sẹ́ni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi mí lé wọn lọ́wọ́ kó lè fi wá ojú rere. Mo ké gbàjarè sí Késárì!”+ 12 Lẹ́yìn tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì ti bá àwùjọ àwọn agbani-nímọ̀ràn sọ̀rọ̀, ó fèsì pé: “Késárì lo ké gbàjarè sí; ọ̀dọ̀ Késárì ni wàá sì lọ.”
13 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Ọba Ágírípà àti Bẹ̀níìsì dé sí Kesaríà láti ṣe ìbẹ̀wò àyẹ́sí sọ́dọ̀ Fẹ́sítọ́ọ̀sì. 14 Nítorí pé wọ́n máa pẹ́ díẹ̀ níbẹ̀, Fẹ́sítọ́ọ̀sì gbé ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù wá síwájú ọba, ó ní:
“Ọkùnrin kan wà tí Fẹ́líìsì fi sílẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n, 15 nígbà tí mo wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi,+ wọ́n ní kí a dá a lẹ́bi. 16 Àmọ́ mo fún wọn lésì pé kò bá ìlànà àwọn ara Róòmù mu pé kí a fi ẹnì kan léni lọ́wọ́ láti fi wá ojú rere, kí ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà tó fojú kojú pẹ̀lú àwọn tó fẹ̀sùn kàn án, kí ó sì láǹfààní láti gbèjà ara rẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà.+ 17 Torí náà, nígbà tí wọ́n débí, mi ò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀, lọ́jọ́ kejì mo jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú ọkùnrin náà wọlé. 18 Àwọn tó mú ẹ̀sùn wá dìde dúró, àmọ́ wọn ò fi ìkankan nínú ẹ̀sùn ohun burúkú tí mo rò pé ó ṣe kàn án.+ 19 Wọ́n kàn ń ṣe awuyewuye pẹ̀lú rẹ̀ nípa ìjọsìn ọlọ́run àjúbàfún*+ wọn àti nípa ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jésù, tó ti kú ṣùgbọ́n tí Pọ́ọ̀lù ń tẹnu mọ́ pé ó wà láàyè.+ 20 Nítorí mi ò mọ bí mo ṣe lè yanjú awuyewuye yìí, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí a sì dá ẹjọ́ rẹ̀ níbẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí.+ 21 Àmọ́ nígbà tí Pọ́ọ̀lù ké gbàjarè pé kí a fi òun sílẹ̀ nínú àhámọ́ títí di ìgbà tí Ẹni Ọlọ́lá* máa ṣèpinnu,+ mo pàṣẹ pé kí a fi í síbẹ̀ títí màá fi rán an lọ sọ́dọ̀ Késárì.”
22 Ágírípà wá sọ fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: “Mo fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkùnrin náà fúnra mi.”+ Ó fèsì pé: “Ní ọ̀la, wàá gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀.” 23 Torí náà, lọ́jọ́ kejì, Ágírípà àti Bẹ̀níìsì dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ afẹfẹyẹ̀yẹ̀, wọ́n sì wọnú gbọ̀ngàn àwùjọ pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọkùnrin jàǹkàn-jàǹkàn ní ìlú náà; nígbà tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì pàṣẹ, wọ́n mú Pọ́ọ̀lù wọlé. 24 Fẹ́sítọ́ọ̀sì wá sọ pé: “Ọba Ágírípà àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà pẹ̀lú wa, ọkùnrin tí ẹ̀ ń wò yìí ni gbogbo àwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti níbí yìí fi ẹjọ́ rẹ̀ sùn mí, tí wọ́n ń kígbe pé kò yẹ kó wà láàyè mọ́.+ 25 Àmọ́ mo rí i pé kò ṣe nǹkan kan tó yẹ fún ikú.+ Torí náà, nígbà tí ọkùnrin yìí fúnra rẹ̀ ké gbàjarè sí Ẹni Ọlọ́lá, mo pinnu pé màá rán an lọ. 26 Ṣùgbọ́n mi ò ní ohun pàtó tí mo lè kọ nípa rẹ̀ sí Olúwa mi. Nítorí náà, mo mú un wá síwájú gbogbo yín, ní pàtàkì síwájú rẹ, Ọba Ágírípà, kí n lè rí nǹkan kọ, lẹ́yìn tí àyẹ̀wò ẹjọ́ rẹ̀ bá ti wáyé. 27 Lójú tèmi, ó dà bíi pé kò bọ́gbọ́n mu láti fi ẹlẹ́wọ̀n kan ránṣẹ́, kí n má sì tọ́ka sí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.”