Àrísítákọ́sì Alábàákẹ́gbẹ́ Adúróṣinṣin
ÀRÍSÍTÁKỌ́SÌ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí ó gbẹ́kẹ̀ lé. Kí ni ó wá sí ọ lọ́kàn nígbà tí o gbọ́ orúkọ yìí? Ohunkóhun ha wá sí ọ lọ́kàn bí? Ìwọ ha mọ ipa tí ó kó nínú ìkẹ́sẹjárí ìtàn ẹ̀sìn Kristẹni ìjímìjí bí? Bí Àrísítákọ́sì tilẹ̀ lè máà jẹ́ ẹni tí a mọ̀ bí ẹni mowó gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá inú Bíbélì, bí ó ti wù kí ó rí, ó kópa nínú ọ̀pọ̀ ìtàn tí a sọ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.
Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, ta ni Àrísítákọ́sì? Ipò ìbátan wo ni ó ní pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù? Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Àrísítákọ́sì jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ adúróṣinṣin? Ẹ̀kọ́ wo ni a sì lè rí kọ́ láti inú yíyẹ àpẹẹrẹ rẹ̀ wò?
Àrísítákọ́sì wọnú àkọsílẹ̀ ìwé Ìṣe lọ́nà tí ó múni jí gìrì nígbà tí àwùjọ àwọn èèyànkéèyàn kan tí kò ṣeé ṣàkóso ń pariwo gèè, tí wọ́n sì ń dá rúgúdù sílẹ̀ ní ìlú Éfésù. (Ìṣe 19:23-41) Bíbáni fi fàdákà kọ́ ojúbọ fún jíjọ́sìn Átẹ́mísì, ọlọ́run èké, jẹ́ iṣẹ́ tí ń mú èrè gọbọi wọlé fún Dímẹ́tíríù àti àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà míràn ní Éfésù. Nípa báyìí, nígbà tí ìgbétásì ìwàásù Pọ́ọ̀lù nínú ìlú náà mú kí ọ̀pọ̀ pa ìjọsìn àìmọ́ ti abo ọlọ́run yìí tì, Dímẹ́tíríù ru àwọn oníṣẹ́ ọnà yòó kù sókè. Ó sọ fún wọn pé kì í ṣe ọrọ̀ ajé wọn nìkan ni ìwàásù Pọ́ọ̀lù fẹ́ bà jẹ́, ṣùgbọ́n, ó tún lè fa pé kí a pa ìjọsìn Átẹ́mísì tì.
Nígbà tí wọn kò rí Pọ́ọ̀lù, àwùjọ èèyànkéèyàn tí inú wọ́n ń ru gùdù náà fipá wọ́ àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì, lọ sínú gbọ̀ngàn ìwòran. Níwọ̀n bí àwọn méjèèjì ti wà nínú ewu ńlá, àwọn ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù rọ̀ ọ́ pé kí ó “má ṣe fi ara rẹ̀ wewu nínú gbọ̀ngàn ìwòran náà.”
Fojú wo ara rẹ nínú ipò yẹn. Fún nǹkan bíi wákàtí méjì, àwùjọ èèyànkéèyàn tí kò ṣeé ṣàkóso náà ṣáà ń pariwo gèè pé, “Títóbi ni Átẹ́mísì ti àwọn ará Éfésù!” Ní tòótọ́, rírí i pé ẹ̀mí àwọn wà lọ́wọ́ ẹgbàágbèje àwọn agbawèrèmẹ́sìn yẹn láìlè sọ̀rọ̀ láti gbèjà ara wọn rárá gbọ́dọ̀ jẹ́ ìrírí agbonijìgì tí ó pá Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì láyà gidigidi. Wọ́n ti gbọ́dọ̀ máa ṣiyè méjì nípa pé wọn yóò lè jáde kúrò níbẹ̀ láàyè. Ó dùn mọ́ni pé, wọ́n jáde kúrò níbẹ̀ láàyè. Ní tòótọ́, ìṣekedere àkọsílẹ̀ Lúùkù ti mú kí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí ọ̀ràn náà ṣojú wọn ni ó lò, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ti Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì fúnra wọn.
Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, akọ̀wé ìlú náà paná ìrọ́kẹ̀kẹ̀ náà. Ó ti ní láti mú ìtura ńláǹlà wá fún Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì láti gbọ́ bí ó ṣe fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ nípa àìmọwọ́mẹsẹ̀ wọn, tí wọ́n sì rí i lẹ́yìn náà tí a bomi paná rògbòdìyàn tí ó yí wọn ká.
Báwo ni ìmọ̀lára rẹ ì bá ti rí lẹ́yìn irú ìrírí bẹ́ẹ̀? Ìwọ yóò ha ti parí èrò sí pé jíjẹ́ míṣọ́nnárì alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù kò yẹ fún ọ, pé ó ti léwu jù, pé yóò sàn jù fún ọ láti lépa ìgbésí ayé tí kò ní wàhálà nínú? Àrísítákọ́sì kò ronú lọ́nà yẹn rárá! Nítorí tí ó jẹ́ ará Tẹsalóníkà, ó ṣeé ṣe kí ó ti mọ ewu tí ó wà nínú pípolongo ìhìn rere náà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wàásù ní ìlú Àrísítákọ́sì ní nǹkan bí ọdún díẹ̀ ṣáájú, rúkèrúdò ńlá kan bẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú. (Ìṣe 17:1-9; 20:4) Àrísítákọ́sì fi ìdúróṣinṣin dúró ti Pọ́ọ̀lù.
Láti Gíríìsì sí Jerúsálẹ́mù
Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn rúkèrúdò àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà, Pọ́ọ̀lù wà ní Gíríìsì, ó sì kù díẹ̀ kí ó rìnrìn àjò lórí òkun lọ sí Síríà nínú ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, nígbà tí “àwọn Júù pilẹ̀ wéwèé ìdìmọ̀lù kan lòdì sí i.” (Ìṣe 20:2, 3) Ta ni a rí pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù nínú ipò eléwu yìí? Àrísítákọ́sì ni!
Ewu tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dìde yìí mú kí Pọ́ọ̀lù, Àrísítákọ́sì, àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn yí ìwéwèé wọn pa dà, wọ́n kọ́kọ́ rìnrìn àjò gba Makedóníà, lẹ́yìn náà, wọ́n ń dúró lọ́nà bí wọ́n ṣe ń gba etíkun Éṣíà Kékeré lọ kí wọ́n tó wọkọ̀ lọ sí Fòníṣíà láti Pátárà. (Ìṣe 20:4, 5, 13-15; 21:1-3) Ète ìrìn àjò yí ní kedere jẹ́ láti kó ọrẹ àwọn Kristẹni ní Makedóníà àti Ákáyà lọ fún àwọn ará wọn tí wọ́n ṣaláìní ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 24:17; Róòmù 15:25, 26) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ rìnrìn àjò pọ̀, bóyá nítorí onírúurú ìjọ ti gbé ẹrù iṣẹ́ yìí lé wọn lọ́wọ́. Kò sí àní-àní pé, jíjùmọ̀ rìn bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ ààbò fún wọn.
Àrísítákọ́sì ní àǹfààní ńláǹlà láti bá Pọ́ọ̀lù lọ sí Jerúsálẹ́mù láti Gíríìsì. Ṣùgbọ́n, ìrìn àjò wọn kejì yóò mú kí wọ́n lọ láti Jùdíà títí dé Róòmù.
Ìrìn Àjò Lọ sí Róòmù
Lákòókò yí, àyíká ipò náà yàtọ̀ pátápátá. Pọ́ọ̀lù ti wà ní àhámọ́ ní Kesaréà fún ọdún méjì, ó ti ké gbàjarè sí Késárì, a óò sì rán an lọ sí Róòmù pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́. (Ìṣe 24:27; 25:11, 12) Gbìyànjú láti finú wòye bí ìmọ̀lára àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù yóò ti rí. Ìrìn àjò láti Kesaréà sí Róòmù yóò pẹ́, yóò sì tánni lókun, a kò sì mọ ibi tí yóò jálẹ̀ sí. Ta ni yóò bá a lọ láti fún un ní ìtìlẹ́yìn àti ìrànlọ́wọ́? A yan àwọn ọkùnrin méjì tàbí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn. Àwọn ni Àrísítákọ́sì àti Lúùkù, tí ó kọ ìwé Ìṣe.—Ìṣe 27:1, 2.
Báwo ni ó ṣe ṣeé ṣe fún Lúùkù àti Àrísítákọ́sì láti wọ ọkọ̀ òkun kan náà ní apá àkọ́kọ́ ìrìn àjò wọn sí Róòmù? Èrò òpìtàn Giuseppe Ricciotti ni pé: “Ìṣètò ti ara ẹni ni àwọn méjì wọ̀nyí bá wọnú ọkọ̀ . . . tàbí, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, balógun ọ̀rún náà fi inú rere gbà wọ́n sínú ọkọ̀ nípa dídọ́gbọ́n kà wọ́n sí ẹrú Pọ́ọ̀lù, níwọ̀n bí òfin ti gbà kí ọlọ̀tọ̀ Róòmù kan ní àwọn ẹrú bíi mélòó kan tí ń ṣèrànwọ́ fún un.” Ẹ wo bí wíwà tí wọ́n wà nítòsí Pọ́ọ̀lù yóò ti mú un lọ́kàn le tó, ẹ sì wo irú ìṣírí tí wọn yóò jẹ́ fún un!
Lójú àdánù àti ìfẹ̀míwewu Lúùkù àti Àrísítákọ́sì fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Pọ́ọ̀lù hàn. Ní ti gidi, wọ́n dojú kọ ipò tí ó wu ìwàláàyè wọn léwu nígbà tí ọkọ̀ tí àwọn àti òǹdè alábàákẹ́gbẹ́ wọn wà rì ní erékùṣù Málítà.—Ìṣe 27:13–28:1.
“Òǹdè Ẹlẹgbẹ́” Pọ́ọ̀lù
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ àwọn lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará ní Kólósè àti sí Fílémónì ní ọdún 60 sí 61 Sànmánì Tiwa, Àrísítákọ́sì àti Lúùkù ṣì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Róòmù. A tọ́ka sí Àrísítákọ́sì àti Epafírásì gẹ́gẹ́ bí “òǹdè ẹlẹgbẹ́” Pọ́ọ̀lù. (Kólósè 4:10, 14; Fílémónì 23, 24) Nítorí náà, fún àkókò kan, ó hàn kedere pé Àrísítákọ́sì wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Bí Pọ́ọ̀lù tilẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n ní Róòmù fún ó kéré tán ọdún méjì, a gbà kí ẹ̀ṣọ́ máa ṣọ́ ọ nínú ilé tí ó fúnra rẹ̀ gbà, níbi tí ó ti lè polongo ìhìn rere náà fún àwọn àlejò. (Ìṣe 28:16, 30) Nígbà náà, Àrísítákọ́sì, Épáfírásì, Lúùkù, àti àwọn mìíràn ṣèránṣẹ́ fún Pọ́ọ̀lù, ní ríràn án lọ́wọ́ àti gbígbé e ró.
“Àrànṣe Afúnnilókun”
Lẹ́yìn ṣíṣàgbéyẹ̀wò oríṣiríṣi ìran nínú èyí tí Àrísítákọ́sì ti fara hàn nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì tí a mí sí, àwòrán wo ni ó mú wá sí ọ lọ́kàn? Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé náà, W. D. Thomas ti sọ, Àrísítákọ́sì “dúró gédégbé gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan tí ó lè dojú kọ àtakò, kí ó sì là á já láìjẹ́ pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ yingin, tàbí kí ìpinnu rẹ̀ láti sìn dín kù. Ó dúró gédégbé gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan tí kì í ṣe àwọn àkókò tí nǹkan ń lọ geerege, tí ó sì ń dùn yùngbà nìkan ni ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan kò fara rọ pẹ̀lú.”
Pọ́ọ̀lù sọ pé Àrísítákọ́sì àti àwọn yòó kù jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” (Gíríìkì, pa·re·go·riʹa) fún òun, ìyẹn ni pé, wọ́n jẹ́ orísun ìtùnú. (Kólósè 4:10, 11) Nítorí náà nípa títu Pọ́ọ̀lù nínú àti mímú ọkàn rẹ̀ le, Àrísítákọ́sì jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ àtàtà ní àkókò àìní. Bíbá àpọ́sítélì náà kẹ́gbẹ́ àti ṣíṣe wọlé wọ̀de pẹ̀lú rẹ̀ fún ọdún bíi mélòó kan ti gbọ́dọ̀ jẹ́ ìrírí tí ń tẹ́ni lọ́rùn, tí ó sì ń bù kúnni nípa tẹ̀mí.
A lè máà rí ara wa nínú ipò tí ó múni jí gìrì tó ti Àrísítákọ́sì. Síbẹ̀síbẹ̀, irú ìdúróṣinṣin kan náà ni ó yẹ kí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ìjọ Kristẹni òde òní ní sí àwọn arákùnrin Kristi nípa tẹ̀mí àti sí ètò àjọ Jèhófà. (Fi wé Mátíù 25:34-40.) Bó pẹ́ bó yá, ó ṣeé ṣe kí wàhálà dé bá àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa tí a mọ̀ tàbí kí wọ́n sorí kọ́, bóyá nítorí ikú olólùfẹ́ kan, àìsàn, tàbí àwọn àdánwò míràn. Nípa dídúró tì wọ́n gbágbágbá àti pípèsè ìrànlọ́wọ́, ìtùnú, àti ìṣírí, a lè rí ayọ̀, a sì lè fi hàn pé a jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ adúróṣinṣin.—Fi wé Òwe 17:17; Ìṣe 20:35.