Jèhófà Ń Mú Ọ̀pọ̀ Ọmọ Wá Sínú Ògo
“Nítorí ó yẹ fún [Ọlọ́run], ní mímú ọ̀pọ̀ ọmọ wá sínú ògo, láti sọ Olórí Aṣojú ìgbàlà wọn di pípé nípasẹ̀ àwọn ìjìyà.”—HÉBÉRÙ 2:10.
1. Èé ṣe tí a fi lè ní ìdánilójú pé ète Jèhófà fún aráyé yóò ní ìmúṣẹ?
JÈHÓFÀ dá ilẹ̀ ayé láti jẹ́ ilé ayérayé ti ìdílé ẹ̀dá ènìyàn pípé tí ń gbádùn ìyè tí kò lópin. (Oníwàásù 1:4; Aísáyà 45:12, 18) Ní tòótọ́, baba ńlá wa Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ó sì tipa báyìí tàtaré ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú sí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ète Ọlọ́run fún aráyé yóò ní ìmúṣẹ nípasẹ̀ Irú Ọmọ tí òun Ṣèlérí, Jésù Kristi. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 22:18; Róòmù 5:12-21; Gálátíà 3:16) Ìfẹ́ fún ayé aráyé sún Jèhófà láti fi “Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ìfẹ́ sì sún Jésù láti “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) “Ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí” yìí ra ẹ̀tọ́ àti ìfojúsọ́nà tí Ádámù pàdánù padà, ó sì mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe.—1 Tímótì 2:5, 6; Jòhánù 17:3.
2. Báwo ni a ṣe ṣàpẹẹrẹ àmúlò ẹbọ ìràpadà Jésù ní Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún ti Ísírẹ́lì?
2 A ń ṣàpẹẹrẹ àmúlò ẹbọ ìràpadà Jésù ní Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún. Ní ọjọ́ yẹn, àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì yóò kọ́kọ́ fi akọ màlúù kan rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yóò sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ síbi Àpótí Ẹ̀rí ọlọ́wọ̀ nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ti àgọ́ àjọ náà, lẹ́yìn náà yóò sì gbé e lọ sí inú tẹ́ńpìlì. Ó ṣe èyí nítorí ara rẹ̀, ìdílé rẹ̀, àti ẹ̀yà Léfì. Lọ́nà tí ó jọra, Jésù Kristi gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́ lákọ̀ọ́kọ́ láti bo ẹ̀ṣẹ̀ “àwọn arákùnrin” rẹ̀ nípa tẹ̀mí mọ́lẹ̀. (Hébérù 2:12; 10:19-22; Léfítíkù 16:6, 11-14) Ní Ọjọ́ Ètùtù, àlùfáà àgbà tún máa ń fi ewúrẹ́ kan rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa ń gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ó ń tipa báyìí ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀yà 12 ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kì í ṣe àlùfáà. Bákan náà, Àlùfáà Àgbà Jésù Kristi yóò lo ẹ̀jẹ̀ ìwàláàyè rẹ̀ nítorí àwọn wọnnì lára aráyé tí wọ́n ń lo ìgbàgbọ́, ní fífagi lé ẹ̀ṣẹ̀ wọn.—Léfítíkù 16:15.
Ó Mú Wọn Wá Sínú Ògo
3. Ní ìbámu pẹ̀lú Hébérù 2:9, 10, kí ni Ọlọ́run ti ń ṣe fún 1,900 ọdún?
3 Fún 1,900 ọdún, Ọlọ́run ti ń ṣe ohun tí ó pabanbarì tí ó ní í ṣe pẹ̀lú “àwọn arákùnrin” Jésù. Ní ti èyí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A rí Jésù, tí a ti ṣe ní ẹni rírẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì, tí a fi ògo àti ọlá dé ládé nítorí tí ó ti kú, kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. Nítorí ó yẹ fún ẹni [Jèhófà Ọlọ́run] tí ohun gbogbo torí rẹ̀ wà àti nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo fi wà, ní mímú ọ̀pọ̀ ọmọ wá sínú ògo, láti sọ Olórí Aṣojú ìgbàlà wọn di pípé nípasẹ̀ àwọn ìjìyà.” (Hébérù 2:9, 10) Jésù Kristi ni Olórí Aṣojú ìgbàlà, tí ó kọ́ ìgbọ́ràn pípé nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀ nígbà tí ó fi wà gẹ́gẹ́ bí ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. (Hébérù 5:7-10) Jésù ni ẹni àkọ́kọ́ tí a kọ́kọ́ bí gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí.
4. Nígbà wo ni a bí Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí, báwo sì ni a ṣe bí i bẹ́ẹ̀?
4 Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀, láti bí Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí, láti lè mú un wá sínú ògo ọ̀run. Nígbà tí ó dá wà pẹ̀lú Jòhánù Oníbatisí, Jésù ṣe ìrìbọmi pátápátá láti fàmì ẹ̀rí fífi ara rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́ hàn. Àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere ti Lúùkù sọ pé: “Nígbà tí a batisí gbogbo ènìyàn, a batisí Jésù pẹ̀lú, bí ó sì ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ ní ìrí ti ara bí àdàbà bà lé e, ohùn kan sì jáde wá láti inú ọ̀run pé: ‘Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.’” (Lúùkù 3:21, 22) Jòhánù rí ẹ̀mí mímọ́ tí ó bà lé Jésù lórí, ó sì gbọ́ tí Jèhófà sọ̀rọ̀ ní gbangba pé òun tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Òun olùfẹ́ ọ̀wọ́n. Ní àkókò yẹn àti nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, Jèhófà bí Jésù gẹ́gẹ́ bí àkọ́kọ́ lára ‘ọ̀pọ̀ ọmọ tí a óò mú wá sínú ògo.’
5. Àwọn wo ni wọ́n kọ́kọ́ jàǹfààní nínú ẹbọ Jésù, mélòó sì ni wọ́n?
5 Àwọn “arákùnrin Jésù” ti jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jàǹfààní láti inú ìrúbọ rẹ̀. (Hébérù 2:12-18) Nínú ìran, àpọ́sítélì Jòhánù rí wọn tí wọ́n ti wà nínú ògo lórí Òkè Síónì ti ọ̀run pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi Olúwa tí a jí dìde. Jòhánù tún sọ iye wọn, ó wí pé: “Mo sì rí, sì wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Ńlá Síónì, àti pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n ní orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn. . . . Àwọn wọ̀nyí ni a rà lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, a kò sì rí èké kankan lẹ́nu wọn; wọ́n wà láìní àbààwọ́n.” (Ìṣípayá 14:1-5) Nítorí náà, ‘ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí a mú wá sínú ògo’ ní ọ̀run para pọ̀ jẹ́ kìkì 144,001 péré—Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tẹ̀mí.
‘A Bí I Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run’
6, 7. Àwọn wo ni a “bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” kí sì ni èyí túmọ̀ sí fún wọn?
6 Àwọn tí Jèhófà bí ni a “bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ẹni tí a ti bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í bá a lọ ní dídá ẹ̀ṣẹ̀, nítorí irú-ọmọ Rẹ̀ [ti Jèhófà] ṣì wà nínú irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀, kò sì lè sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti bí i.” (1 Jòhánù 3:9) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni “irú-ọmọ” tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níhìn-ín. Ní ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn 144,000 ní “ìbí tuntun” sí ìrètí ti ọ̀run.—1 Pétérù 1:3-5, 23.
7 Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run láti inú ìbí rẹ̀ ní ti ẹ̀dá ènìyàn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé náà, Ádámù ti jẹ́ “ọmọkùnrin Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:35; 3:38) Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn batisí Jésù, ó ṣe pàtàkì pé kí Jèhófà polongo pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.” (Máàkù 1:11) Nípa ìpolongo yìí tí ó bá ìtújáde ẹ̀mí mímọ́ rìn, ó ṣe kedere pé nígbà náà Ọlọ́run mú Jésù wá gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, a bí Jésù ní “ìbí tuntun” nígbà náà pẹ̀lú àǹfààní láti gba ìyè lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí nínú ọ̀run. Gẹ́gẹ́ bí tirẹ̀, a ‘tún’ àwọn 144,000 arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí ‘bí.’ (Jòhánù 3:1-8; Wo Ilé-Ìṣọ́nà, November 15, 1992, ojú ìwé 3 sí 6.) Pẹ̀lúpẹ̀lù, gẹ́gẹ́ bí Jésù, Ọlọ́run fòróró yàn wọ́n, ó sì yanṣẹ́ pípòkìkí ìhìn rere fún wọn.—Aísáyà 61:1, 2; Lúùkù 4:16-21; 1 Jòhánù 2:20.
Ẹ̀rí Fífi Ẹ̀mí Bíni
8. Ẹ̀rí fífi ẹ̀mí bí wo ni ó wà nínú ọ̀ràn ti (a) Jésù (b) àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí?
8 Ẹ̀rí wà pé a fi ẹ̀mí bí Jésù. Jòhánù Oníbatisí rí ẹ̀mí tí ó bà lé Jésù lórí, ó sì gbọ́ ìpolongo Ọlọ́run nípa jíjẹ́ tí Mèsáyà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fòróró yàn náà jẹ́ ọmọ tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, báwo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yóò ṣe mọ̀ pé a ti fi ẹ̀mí bí wọn? Toò, ní ọjọ́ tí ó gòkè re ọ̀run, Jésù wí pé: “Nítorí Jòhánù, ní tòótọ́, fi omi batisí, ṣùgbọ́n a ó batisí yín nínú ẹ̀mí mímọ́ ní ọjọ́ tí kò ní pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn èyí.” (Ìṣe 1:5) A “batisí” àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù “nínú ẹ̀mí mímọ́” ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. ‘Ariwo kan láti ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ti atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì,’ bá ìtújáde ẹ̀mí mímọ́ yẹn rìn, “àwọn ahọ́n bí ti iná” sì wà lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà. Èyí tí ó tún pabanbarì jù lọ ni agbára tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ní ‘láti fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ti ń yọ̀ǹda fún wọn láti sọ̀rọ̀ jáde.’ Nítorí náà, ẹ̀rí tí ó ṣeé fojú rí, tí ó sì ṣeé fetí gbọ́ wà pé ọ̀nà sí ògo ti ọ̀run gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run ti ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi.—Ìṣe 2:1-4, 14-21; Jóẹ́lì 2:28, 29.
9. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé a fi ẹ̀mí bí àwọn ará Samáríà, Kọ̀nílíù, àti àwọn mìíràn ní ọ̀rúndún kìíní?
9 Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, Fílípì ajíhìnrere wàásù ní Samáríà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Samáríà tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ tí a sì batisí wọn, wọn kò ní ẹ̀rí pé Ọlọ́run ti bí wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù gbàdúrà tí wọ́n sì gbé ọwọ́ wọn lé àwọn onígbàgbọ́ wọ̀nyẹn lórí, “wọ́n . . . bẹ̀rẹ̀ sí rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.” (Ìṣe 8:4-25) Èyí jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ará Samáríà tí wọ́n gbà gbọ́ ni a ti fi ẹ̀mí bí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run. Lọ́nà tí ó jọra, ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa, Kọ̀nílíù àti àwọn Kèfèrí mìíràn tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Ọlọ́run. Pétérù àti àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n jẹ́ Júù tí wọ́n bá a lọ “ṣe kàyéfì, nítorí pé ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ ni a ń tú jáde sórí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú. Nítorí wọ́n gbọ́ tí wọ́n ń fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń gbé Ọlọ́run ga lọ́lá.” (Ìṣe 10:44-48) Ọ̀pọ̀ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gba “àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí,” irú bí fífi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀. (1 Kọ́ríńtì 14:12, 32) Àwọn wọ̀nyí tipa báyìí ní ẹ̀rí ṣíṣe kedere pé a ti fi ẹ̀mí bí wọn. Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn Kristẹni ọjọ́ iwájú yóò ṣe mọ̀ bóyá a fi ẹ̀mí bí wọn tàbí a kò fi bí wọn?
Ẹ̀rí Tí Ẹ̀mí Ń Jẹ́
10, 11. Lórí ìpìlẹ̀ Róòmù 8:15-17, báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé pé ẹ̀mí ń jẹ́rìí pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi?
10 Gbogbo 144,000 Kristẹni ẹni àmì òróró ti ni ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé wọ́n ní ẹ̀mí Ọlọ́run. Nípa èyí, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, ẹ̀mí tí ń mú kí a ké jáde pé: ‘Ábà, Baba!’ Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nígbà náà, bí àwa bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú: àwọn ajogún Ọlọ́run ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, kìkì bí a bá jọ jìyà pa pọ̀, kí a lè ṣe wá lógo pa pọ̀ pẹ̀lú.” (Róòmù 8:15-17) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ìmọ̀lára jíjẹ́ ọmọ Bàbá wọn ọ̀run, èrò ṣíṣe pàtàkì gidi ti jíjẹ́ ọmọ. (Gálátíà 4:6, 7) Wọ́n ní ìdánilójú gbangba gbàǹgbà pé Ọlọ́run ti bí wọn sínú ipò ọmọ nípa tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba ọ̀run. Nínú èyí, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń kó ipa pàtàkì.
11 Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ẹ̀mí náà, tàbí ẹ̀mí ìrònú lílágbára jù lọ, ti àwọn ẹni àmì òróró ń sún wọn láti dáhùn padà lọ́nà rere sí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ìrètí ti ọ̀run. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n bá ka ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn ọmọ Jèhófà nípa tẹ̀mí, wọ́n máa ń gbà látọkànwá pé àwọn ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kàn. (1 Jòhánù 3:2) Wọ́n mọ̀ pé a ti “batisí” àwọn “sínú Kristi Jésù” àti sínú ikú rẹ̀. (Róòmù 6:3) Ìdánilójú wọn tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ni pé wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí, tí wọn yóò kú tí a óò sì jí wọn dìde sínú ògo ti ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe fún Jésù.
12. Kí ni ẹ̀mí Ọlọ́run ti mú kí ó wà nínú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?
12 Dídi ẹni tí a bí sínú ipò ọmọ tẹ̀mí kì í ṣe ohun tí a ń mú ìfẹ́ dàgbà fún. Kì í ṣe nítorí hílàhílo ayé tí kò fara rọ yìí ni àwọn tí a fi ẹ̀mí bí ṣe fẹ́ lọ sí ọ̀run. (Jóòbù 14:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí Jèhófà ti mú kí ìrètí àti ìfẹ́-ọkàn tí kò wọ́pọ̀ nínú àwọn ẹ̀dá ènìyàn ní gbogbogbòò wà nínú ojúlówó àwọn ẹni àmì òróró. Irú àwọn ẹni tí a bí bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé ìwàláàyè àìnípẹ̀kun nínú ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé tí ìdílé aláyọ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ yí ká yóò ga lọ́lá. Ṣùgbọ́n, irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ohun tí ó jọba ní ọkàn-àyà wọn. Ìrètí ti ọ̀run tí àwọn ẹni àmì òróró ni lágbára tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fínnúfíndọ̀ fi gbogbo ìfojúsọ́nà àti àjọṣe ti orí ilẹ̀ ayé rúbọ.—2 Pétérù 1:13, 14.
13. Ní ìbámu pẹ̀lú 2 Kọ́ríńtì 5:1-5, kí ni ‘ìfẹ́-ọkàn taratara’ tí Pọ́ọ̀lù ní, kí sì ni èyí fi hàn ní ti àwọn tí a fi ẹ̀mí bí?
13 Ìrètí ìyè ti ọ̀run tí Ọlọ́run fúnni lágbára nínú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí èrò wọn fi dà bíi ti Pọ́ọ̀lù, tí ó kọ̀wé pé: “Àwa mọ̀ pé bí ilé wa ti ilẹ̀ ayé, àgọ́ yìí, bá di títúpalẹ̀, àwa yóò ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti àìnípẹ̀kun ní ọ̀run. Nítorí nínú ilé gbígbé yìí, àwa ń kérora ní tòótọ́, a ń fi taratara ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé èyí tí ó wà fún wa láti ọ̀run wọ̀, kí ó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn gbígbé e wọ̀ ní ti gidi, a kò ní rí wa ní ìhòòhò. Ní ti tòótọ́, àwa tí a wà nínú àgọ́ yìí ń kérora, níwọ̀n bí a ti dẹrù pa wá; nítorí pé àwa kò fẹ́ láti bọ́ ọ kúrò, bí kò ṣe láti gbé èkejì wọ̀, kí ìyè lè gbé èyí tí ó jẹ́ kíkú mì. Wàyí o, ẹni tí ó mú wa jáde fún ohun yìí gan-an ni Ọlọ́run, ẹni tí ó fún wa ní àmì ìdánilójú ohun tí ń bọ̀, èyíinì ni, ẹ̀mí náà.” (2 Kọ́ríńtì 5:1-5) ‘Ìfẹ́-ọkàn taratara’ tí Pọ́ọ̀lù ní jẹ́ láti jíǹde sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú. Ní títọ́ka sí ara ẹ̀dá ènìyàn, ó lo àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ ti àgọ́ tí ó lè wó, ibùgbé kan tí ó jẹ́ ẹlẹgẹ́, tí ó sì wà fún ìgbà díẹ̀ bí a bá fi wé ilé kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀ ayé nínú ẹran ara kíkú, àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ẹ̀mí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìṣàpẹẹrẹ ìyè ti ọ̀run tí ń bọ̀ ń wo iwájú fún “ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” ara ti ẹ̀mí tí kò lè kú, tí kò sì lè díbàjẹ́. (1 Kọ́ríńtì 15:50-53) Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù, wọ́n lè sọ taratara pé: “Àwa jẹ́ onígboyà gidi gan-an, ó sì dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti kúkú má ṣe wà nínú ara [ẹ̀dá ènìyàn], kí a sì fi ọ̀dọ̀ Olúwa ṣe ilé wa [ní ọ̀run].”—2 Kọ́ríńtì 5:8.
A Mú Wọn Wọnú Májẹ̀mú Àkànṣe
14. Nígbà tí Jésù ń dá ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí sílẹ̀, májẹ̀mú wo ni ó kọ́kọ́ mẹ́nu kàn, ipa wo ni ó sì kó ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí?
14 Àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí ní ìdánilójú pé a ti mú wọn wọnú májẹ̀mú àkànṣe méjì. Jésù mẹ́nu kan ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí nígbà tí ó lo àkàrà aláìwú àti wáìnì láti dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ tí ń bọ̀ sílẹ̀, ó sì sọ ní ti ife wáìnì náà pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.” (Lúùkù 22:20; 1 Kọ́ríńtì 11:25) Àwọn wo ni wọ́n wà nínú májẹ̀mú tuntun náà? Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn mẹ́ńbà Ísírẹ́lì tẹ̀mí—àwọn tí Jèhófà pète láti mú wá sínú ògo ti ọ̀run. (Jeremáyà 31:31-34; Gálátíà 6:15, 16; Hébérù 12:22-24) Bí ẹ̀jẹ̀ Jésù tí a ta sílẹ̀ ti mú un ṣiṣẹ́, májẹ̀mú tuntun náà mú àwọn ènìyàn fún orúkọ Jèhófà jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì sọ àwọn Kristẹni ti a fi ẹ̀mí bí wọ̀nyí di apá kan “irú-ọmọ” Ábúráhámù. (Gálátíà 3:26-29; Ìṣe 15:14) Májẹ̀mú tuntun náà fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí ní àǹfààní láti di ẹni tí a mú wá sínú ògo nípa jíjí wọn dìde sí ìyè àìleèkú nínú ọ̀run. Nítorí pé ó jẹ́ “májẹ̀mú àìnípẹ̀kun,” àǹfààní rẹ̀ yóò wà títí láé. Ẹ jẹ́ kí a ṣì máa wò ó ná bóyá májẹ̀mú yìí yóò tún ṣiṣẹ́ ní àwọn ọ̀nà mìíràn nígbà Ẹgbẹ̀rúndún àti lẹ́yìn ìgbà náà.—Hébérù 13:20.
15. Ní ìbámu pẹ̀lú Lúùkù 22:28-30, inú májẹ̀mú mìíràn wo ni a mú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wọ̀, ìgbà wo sì ni?
15 “Ọ̀pọ̀ ọmọ” tí Jèhófà pète láti ‘mú wá sínú ògo’ ni a ti mú wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú sínú májẹ̀mú fún Ìjọba ọ̀run. Nípa májẹ̀mú yìí láàárín òun alára àti àwọn tí ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ rẹ̀, Jésù wí pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan, kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu nídìí tábìlì mi nínú ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” (Lúùkù 22:28-30) A fìdí májẹ̀mú Ìjọba náà múlẹ̀ nígbà tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Májẹ̀mú yẹn ń bá iṣẹ́ lọ títí láé láàárín Kristi àti àwọn ọba amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ìṣípayá 22:5) Nítorí náà, ó dá àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí lójú hán-ún hán-ún pé wọ́n wà nínú májẹ̀mú tuntun àti nínú májẹ̀mú fún Ìjọba. Nítorí náà, nígbà tí a bá ń ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, kìkì ìwọ̀nba kéréje àwọn ẹni àmì òróró tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé ni ó ń ṣàjọpín nínú àkàrà, tí ń dúró fún ara ẹ̀dá ènìyàn aláìlẹ́ṣẹ̀ ti Jésù, àti wáìnì, tí ń ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ pípé rẹ̀ tí a tú jáde nínú ikú, tí ó sì mú kí májẹ̀mú tuntun náà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 11:23-26; wo Ilé-Ìṣọ́nà, February 1, 1989, ojú ìwé 17 sí 20.
A Pè Wọ́n, A Yàn Wọ́n, Wọ́n sì Jẹ́ Olùṣòtítọ́
16, 17. (a) Láti di ẹni tí a mú wá sínú ògo, kí ni gbogbo 144,000 gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Àwọn wo ni “ọba mẹ́wàá,” báwo ni wọ́n sì ṣe ń bá àṣẹ́kù “àwọn arákùnrin” Kristi lórí ilẹ̀ ayé lò?
16 Àmúlò àkọ́kọ́ ti ẹbọ ìràpadà Jésù mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn 144,000 láti di ẹni tí a pè sí ìyè ti ọ̀run, tí a sì yàn nípa jíjẹ́ ẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí bí. Àmọ́ ṣáá o, láti di ẹni tí a mú wá sínú ògo, wọ́n gbọ́dọ̀ ‘máa sa gbogbo ipá wọn láti mú pípè àti yíyàn wọn dájú,’ wọ́n sì gbọ́dọ̀ jẹ́ olùṣòtítọ́ dé ojú ikú. (2 Pétérù 1:10; Éfésù 1:3-7; Ìṣípayá 2:10) Ìwọ̀nba kéréje àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró tí ó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ń pa ìwà títọ́ wọn mọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “ọba mẹ́wàá” tí ó dúró fún gbogbo agbára ìṣèlú ń ta kò wọ́n. Áńgẹ́lì kan sọ pé: “Àwọn wọ̀nyí yóò bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun, ṣùgbọ́n, nítorí pé òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ṣẹ́gun wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀ yóò ṣe bẹ́ẹ̀.”—Ìṣípayá 17:12-14.
17 Kò sí ohun tí àwọn olùṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn lè fi Jésù, “Ọba àwọn ọba” ṣe, nítorí ọ̀run ni ó wà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń kógun ti àṣẹ́kù “àwọn arákùnrin” rẹ̀ tí ó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:17) Ìyẹn yóò dópin ní Amágẹ́dọ́nì ogun Ọlọ́run, nígbà tí ìṣẹ́gun yóò dájú fún “Ọba àwọn ọba” àti fún “àwọn arákùnrin” rẹ̀—“àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Ní báyìí náà, ọwọ́ àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí dí fọ́fọ́. Kí ni wọ́n ń ṣe nísinsìnyí, kí Jèhófà tó mú wọn wá sínú ògo?
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Àwọn wo ni Ọlọ́run ‘mú wá sínú ògo ti ọ̀run’?
◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti di ẹni tí a “bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run”?
◻ Báwo ni ‘ẹ̀mí ṣe ń jẹ́rìí’ pẹ̀lú àwọn Kristẹni kan?
◻ Inú àwọn májẹ̀mú wo ni a ti mú àwọn tí a fi ẹ̀mí bí wọ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, a pèsè ẹ̀rí pé a ti ṣí ọ̀nà sí ògo ti ọ̀run