A Yà Wọ́n Sọ́tọ̀ Láti Jẹ́ Onídùnnú Olùyìn Jákèjádò Ayé
“Ẹ máa yin Olúwa! Ẹ máa yìn, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa, ẹ máa yin orúkọ Olúwa.”—ORIN DÁFÍDÌ 113:1.
1, 2. (a) Ní ìbámu pẹ̀lú Orin Dáfídì 113:1-3, ta ni ó yẹ kí ó gba ìyìn àfìtaraṣe wa? (b) Ìbéèrè wo ni ó yẹ kí a béèrè?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ni Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé, Ọba Aláṣẹ Àgbáyé wa títí ayérayé. Ó yẹ gidigidi fún ìyìn wa àfìtaraṣe. Ìdí nìyí tí Orin Dáfídì 113:1-3 fi pàṣẹ fún wa pé: “Ẹ máa yin Olúwa! Ẹ máa yìn, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa, ẹ máa yin orúkọ Olúwa. Ìbùkún ni orúkọ Olúwa láti ìsinsìnyí lọ àti sí i láéláé. Láti ìlà oòrùn títí ó fi dé ìwọ̀ rẹ̀, orúkọ Olúwa ni kí a yìn.”
2 Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Ọlọ́run, inú wa dùn láti ṣe èyí. Ẹ wo bí ó ṣe mú ọkàn wa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tó pé láìpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run yóò mú kí orin ìyìn ìdùnnú tí a ń kọ lónìí gba gbogbo ilẹ̀ ayé kan! (Orin Dáfídì 22:27) A ha ń gbọ́ ohùn rẹ nínú gbajúgbajà ẹgbẹ́ akọrin jákèjádò ayé yìí bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, wo bí yóò ṣe mú ọ láyọ̀ tó láti jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, tí kò sì sí ìdùnnú yìí!
3. (a) Kí ni ó mú kí àwọn ènìyàn Jèhófà yàtọ̀ gédégbé, kí wọ́n sì jẹ́ aláìláfiwé? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni a fi yà wá sọ́tọ̀?
3 Dájúdájú, yíyìn tí a ń yin Jèhófà níṣọ̀kan ń mú kí a yàtọ̀ gédégbé, ó sì mú kí a jẹ́ aláìláfiwé. A ń sọ̀rọ̀, a sì ń kọ́ni ní ìṣọ̀kan, a sì ń lo àwọn ọ̀nà kan náà láti polongo ‘oore Jèhófà púpọ̀púpọ̀.’ (Orin Dáfídì 145:7) Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí a ti yà sí mímọ́ fún Jèhófà, a yà wá sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run wa, Jèhófà. Ọlọ́run sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ìgbàanì tí a yà sí mímọ́, Ísírẹ́lì, láti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká, kí wọ́n má sì jẹ́ kí àṣà àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì kó àbààwọ́n bá wọn. (Ẹ́kísódù 34:12-16) Ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní òfin tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe èyí. Bákan náà lónìí, Jèhófà ti fún wa ní Ọ̀rọ̀ Mímọ́ rẹ̀, Bíbélì. Ìtọ́ni rẹ̀ ń fi hàn wá bí a ṣe lè ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé yìí. (Kọ́ríńtì Kejì 6:17; Tímótì Kejì 3:16, 17) A kò yà wá sọ́tọ̀ nípa yíya ara wa láṣo ní gbígbé ilé àwọn ọkùnrin àti obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti Bábílónì Ńlá ti ń ṣe. Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi, a jẹ́ olùyin Jèhófà ní gbangba.
Fara Wé Olórí Olùyin Jèhófà
4. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti yíyin Jèhófà?
4 Jésù kò fìgbà kan rí yà bàrá kúrò nínú ète rẹ̀ láti yin Jèhófà. Èyí sì mú kí ó yàtọ̀ pátápátá sí ayé. Nínú sínágọ́gù àti ní tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, ó yin orúkọ mímọ́ Ọlọ́run. Yálà lórí òkè tàbí ní etíkun, ibikíbi tí àwọn ènìyàn bá ti pé jọ, Jésù wàásù òtítọ́ Jèhófà ní gbangba. Ó polongo pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Bàbá, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 11:25) Àní nígbà tí ó ń jẹ́jọ́ níwájú Pọ́ńtíù Pílátù, Jésù fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Jésù mọrírì ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ rẹ̀. Ibikíbi tí ó bá wà, Jésù jẹ́rìí sí Jèhófà, ó sì yìn ín ní gbangba.
5. Àwọn wo ni Orin Dáfídì 22:22 ní ìmúṣẹ sí lára, kí sì ni ó yẹ kí ó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa?
5 Nínú Orin Dáfídì 22:22, a rí gbólóhùn àsọtẹ́lẹ̀ yìí nípa Olórí Olùyin Jèhófà: “Èmi óò sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi: ní àwùjọ ìjọ ni èmi óò máa yìn ọ́.” Nínú Hébérù 2:11, 12, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àwọn ẹsẹ wọ̀nyí fún Jésù Olúwa àti fún àwọn tí Jèhófà Ọlọ́run ti yà sí mímọ́ fún ògo ti ọ̀run. Bíi tirẹ̀, ojú kò tì wọ́n láti yin orúkọ Jèhófà láàárín ìjọ. Àwa pẹ̀lú ha ní irú ẹ̀mí ìrònú kan náà yí nígbà tí a bá wà ní àwọn ìpàdé ìjọ bí? Fífi tí a ń fi ìtara kópa nínú ìpàdé, ní ti ìrònú àti ohùn wa, ń fi ìyìn fún Jèhófà. Ṣùgbọ́n ìyìn onídùnnú wa ha mọ síbẹ̀ yẹn bí?
6. Iṣẹ́ wo ni Jésù fàṣẹ yàn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, báwo sì ni àwọn olùfẹ́ ìmọ́lẹ̀ ṣe ń fi ògo fún Ọlọ́run?
6 Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 5:14-16 ti sọ, Jésù Olúwa tún fàṣẹ yanṣẹ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn tàn kí àwọn ẹlòmíràn baà lè yin Jèhófà. Ó wí pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. . . . Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín kí wọ́n sì lè fi ògo fún Bàbá yín tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run.” Àwọn olùfẹ́ ìmọ́lẹ̀ ń mú ògo wá fún Ọlọ́run. Wọ́n ha ń ṣe èyí kìkì nípa sísọ àti ṣíṣe iṣẹ́ rere, tí ó jẹ mọ́ ti ìfẹ́dàáfẹ́re bí? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń ṣe é nípa fífi ìṣọ̀kan fi ògo fún Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn olùfẹ́ ìmọ́lẹ̀ ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì ń di onídùnnú olùyìn rẹ̀. Ìwọ ha ti gbé ìgbésẹ̀ aláyọ̀ yí bí?
Ìdùnnú Tí Ń Wá Láti Inú Yíyin Jèhófà
7. Èé ṣe tí àwọn olùyìn Jèhófà fi kún fún ìdùnnú tó bẹ́ẹ̀, irú ìdùnnú wo sì ni ó jẹ́ tiwọn, ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
7 Èé ṣe tí àwọn olùyin Jèhófà fi jẹ́ onídùnnú tó bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ìdùnnú jẹ́ èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Nínú Gálátíà 5:22, ohun ni a kọ tẹ̀ lé ìfẹ́. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní fi èso ẹ̀mí Jèhófà yí hàn. Họ́wù, ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí rẹ̀ dà sórí nǹkan bí 120 ọmọ ẹ̀yìn Jésù, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n yin Jèhófà. ‘Ìdàrúdàpọ̀ ọkàn bá’ àwọn Júù onítara ìsìn tí wọ́n ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wá sí Jerúsálẹ́mù, ‘ìyanu sì bá wọn.’ Wọ́n kígbe pé: “Àwa gbọ́ wọn tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n wa nípa àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run”! (Ìṣe 2:1-11) Kí ni ìyọrísí yíyin Jèhófà ní onírúurú èdè lọ́nà àgbàyanu yìí? Nǹkan bí 3,000 Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba náà nípa Mèsáyà. Wọ́n ṣe batisí, wọ́n gba ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì fi ìháragàgà pa ohùn wọn pọ̀ gẹ́gẹ́ bí onídùnnú olùyin Jèhófà. (Ìṣe 2:37-42) Ẹ wo irú ìbùkún tí èyí jẹ́!
8. Lẹ́yìn ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, kí ni àwọn Kristẹni ṣe láti mú ìdùnnú wọn pọ̀ sí i?
8 Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Láti ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n sì ń pésẹ̀ nígbà gbogbo sí tẹ́ńpìlì pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n sì ń jẹ oúnjẹ wọn nínú àwọn ilé àdáni, wọ́n sì ń ṣalábàápín oúnjẹ pẹ̀lú ayọ̀ inú dídùn ńláǹlà àti òtítọ́ inú ọkàn àyà, wọ́n ń yin Ọlọ́run wọ́n sì ń rí ojú rere lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn. Lẹ́sẹ̀ kan náà Jèhófà ń bá a lọ láti mú àwọn wọnnì tí a ń gbà là dara pọ̀ mọ́ wọn lójoojúmọ́.” (Ìṣe 2:46, 47) Ṣé kìkì wíwà papọ̀ wọn àti ṣíṣalábàápín oúnjẹ ni ó mú ayọ̀ ńláǹlà wá fún wọn? Rárá o, olórí ìdùnnú wọn wá láti inú yíyin Jèhófà Ọlọ́run láti ọjọ́ dé ọjọ́. Ìdùnnú wọn sì pọ̀ sí i nígbà tí wọ́n rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún tí ń dáhùn pa dà sí ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn tiwa ṣe rí lónìí.
Àwọn Onídùnnú Olùyìn ní Gbogbo Orílẹ̀-Èdè
9. (a) Nígbà wo ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè ní àǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere náà, báwo sì ni ó ṣe ṣe èyí? (b) Èé ṣe tí a fi tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí Kọ̀nílíù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣáájú batisí wọn?
9 Jèhófà kò fẹ́ kí ìgbòkègbodò ìtànmọ́lẹ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń ṣe mọ sí orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo. Nítorí náà, bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa, ó fún àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè ní àǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere rẹ̀. Lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run, Pétérù lọ sí ilé Kèfèrí kan tí ó jẹ́ ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Kesaréà. Níbẹ̀, ó bá Kọ̀nílíù tí ó pé jọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Bí wọ́n ti tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù, wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù nínú ọkàn àyà wọn. Báwo ni a ṣe mọ̀? Nítorí pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bà lé àwọn Kèfèrí onígbàgbọ́ yẹn lórí. Bí ó ṣe sábà máa ń rí, kìkì lẹ́yìn batisí ní ẹ̀bùn ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń bà léni lórí, ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yí, Jèhófà fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba àwọn tí kì í ṣe Júù wọ̀nyí ṣáájú ìrìbọmi wọn. Kání Jèhófà kò ṣe ìyẹn ni, Pétérù ì bá máà ní ìdálójú pé Ọlọ́run ti ń tẹ́wọ́ gba àwọn Kèfèrí nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Rẹ̀, ì bá má sì ní ìdálójú pé wọ́n tóótun fún batisí nínú omi.—Ìṣe 10:34, 35, 47, 48.
10. Báwo ni a ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ìgbà láéláé pé àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè yóò yin Jèhófà?
10 Láti ìgbà láéláé ni Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè yóò yin òun. Òun yóò ní àwọn onídùnnú olùyìn ní ilẹ̀ gbogbo. Láti jẹ́rìí sí èyí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàyọlò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó sọ fún ìjọ àwọn Kristẹni kárí ayé ní Róòmù pé: “Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara yín lẹ́nì kíní kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wá, pẹ̀lú ògo fún Ọlọ́run ní iwájú. Nítorí mo wí pé Kristi ní ti gàsíkíá di òjíṣẹ́ àwọn wọnnì tí a kọ nílà nítorí jíjólóòótọ́ Ọlọ́run, kí ó baà lè fìdí ẹ̀rí ìlérí tí Òun ṣe fún àwọn baba ńlá wọn múlẹ̀, àti kí àwọn orílẹ̀-èdè baà lè yin Ọlọ́run lógo fún àánú rẹ̀. Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ [nínú Orin Dáfídì 18:49] pé: ‘Dájúdájú ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi jẹ́wọ́ mímọ̀ ọ́ ní gbangba wálíà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè èmi yóò sì kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ dájúdájú.’ Ó sì tún wí [nínú Diutarónómì 32:43] pé: ‘Ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ Àti pẹ̀lú [nínú Orin Dáfídì 117:1 pé]: ‘Ẹ yin Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ sì jẹ́ kí gbogbo àwọn ènìyàn yìn ín.’”—Róòmù 15:7-11.
11. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ran àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ láti kọ́ nípa òtítọ́ rẹ̀, kí sì ni ó ti jẹ́ àbájáde rẹ̀?
11 Àwọn ènìyàn kò lè yin Jèhófà níṣọ̀kan láìjẹ́ pé wọ́n gbé ìrètí wọn ka Jésù Kristi, ẹni tí Ọlọ́run ti yàn sípò láti ṣàkóso lórí àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè. Láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ Rẹ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè ayérayé, Ọlọ́run ti gbé ètò ẹ̀kọ́ kan ti ó kárí ayé kalẹ̀. Ó ń pèsè ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ ọlọ́gbọ́n inú ẹrú rẹ̀. (Mátíù 24:45-47) Ki ni àbájáde rẹ̀? Àwọn onídùnnú tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ń kọrin ìyìn sí Jèhófà ní ilẹ̀ tí ó lé ní 230. Ọ̀pọ̀ mílíọ́nù míràn sì ń fi ìfẹ́ hàn sí ṣíṣe ohun kan náà. Ṣàkíyèsí iye tí ó wá sí Ìṣe Ìrántí ní 1996: 12,921,933. Èyí mà ga o!
A Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Ogunlọ́gọ̀ Ńlá ti Àwọn Onídùnnú Olùyìn
12. Ìran arùmọ̀lára-sókè wo ni àpọ́sítélì Jòhánù rí, kí sì ni ìmúṣẹ tí ìran yìí ní gan-an?
12 Nínú ìran, àpọ́sítélì Jòhánù rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ó ti inú gbogbo orílẹ̀-èdè jáde wá. (Ìṣípayá 7:9) Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ orin ìyìn tí ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ń kọ pa pọ̀ pẹ̀lú àṣẹ́kù ẹni àmì òróró Ọlọ́run? Jòhánù sọ fún wa pé: “Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni àwa jẹ ní gbèsè fún ìgbàlà.” (Ìṣípayá 7:10) A ń polongo èyí láìṣojo ní apá ibi gbogbo ní ayé. Ní jíju imọ̀ ọ̀pẹ, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀, a ń fi ìṣọ̀kan yin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, a sì ń fi ìdùnnú jẹ́wọ́ níwájú ọ̀run òun ayé pé “àwa jẹ” òun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi, “ní gbèsè” fún ìgbàlà wa. Ẹ wo bí àpọ́sítélì Jòhánù ti yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tó ní rírí ìran arùmọ̀lára sókè ti ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí! Ẹ sì wo bí a ti ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tó lónìí ní rírí àwọn tí Jòhánù rí àti ní jíjẹ́ apá kan wọn!
13. Kí ni ó mú kí àwọn ènìyàn Jèhófà yàtọ̀ sí ayé?
13 Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, a ń fi jíjẹ́ orúkọ rẹ̀ yangàn. (Aísáyà 43:10, 12) Jíjẹ́ tí a jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà mú kí a yàtọ̀ sí ayé yìí. Ẹ wo irú ìdùnnú tí ó jẹ́ láti máa jẹ́ orúkọ Ọlọ́run tí ó yàtọ̀ gédégbé àti láti ní ṣíṣe iṣẹ́ àtọ̀runwá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ète wa nínú ìgbésí ayé! Ète kíkọyọyọ ti Jèhófà láti ya orúkọ mímọ́ rẹ̀ sí mímọ́ àti láti dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre nípasẹ̀ Ìjọba náà ti mú kí ìgbésí ayé wa ní ìtumọ̀. Ó sì ti ràn wá lọ́wọ́ láti ní àyè kan nínú ète rẹ̀ àtọ̀runwá nípa orúkọ rẹ̀ àti Ìjọba rẹ̀. Ó ti ṣe èyí ní ọ̀nà mẹ́ta.
A fi Òtítọ́ Síkàáwọ́ Wa
14, 15. (a) Kí ni ọ̀nà kan tí Ọlọ́run gbà ràn wá lọ́wọ́ láti ní àyè kan nínú ète rẹ̀ àtọ̀runwá ní ti orúkọ rẹ̀ àti Ìjọba rẹ̀? (b) Báwo ni Ìjọba tí a gbé kalẹ̀ ní ọdún 1914 Sànmánì Tiwa ṣe yàtọ̀ si èyí tí a dojú rẹ̀ bolẹ̀ ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa?
14 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà ti fi òtítọ́ síkàáwọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀. Ìṣípayá tí ó ru ìmọ̀lára ẹni sókè jù lọ ni pé Ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọdún 1914. (Ìṣípayá 12:10) Ìṣàkóso ti ọ̀run yìí yàtọ̀ sí ìjọba tí ó ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, níbi tí àwọn ọba tí ó wà ní ìlà Dáfídì ti máa ń gorí ìtẹ́. A dojú ìjọba yẹn délẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, a fi Jerúsálẹ́mù sábẹ́ ìṣàkóso àwọn agbára ayé Kèfèrí. Ìjọba tuntun tí Jèhófà gbé kalẹ̀ ní ọdún 1914 jẹ́ ìjọba ti ọ̀run tí a kì yóò fi sábẹ́ ẹnikẹ́ni bí kò ṣe Jèhófà, bẹ́ẹ̀ sì ni a kì yóò lè pa á run. (Dáníẹ́lì 2:44) Bákan náà, ìṣàkóso rẹ̀ yàtọ̀. Lọ́nà wo? Ìṣípayá 11:15 dáhùn pé: “Ohùn rara sì dún ní ọ̀run, pé: ‘Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀, òun yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.’”
15 “Ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀” ń lo ọlá àṣẹ lórí ayé aráyé látòkè délẹ̀. Ọ̀nà tuntun tí Jèhófà gbà fi ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ hàn yí, tí ó ní nínú Mèsáyà Ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn 144,000 arákùnrin Jésù, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí a ti jí dìde nísinsìnyí sí ògo ti ọ̀run, kì í ṣe ọ̀ràn ìmọ̀ ẹ̀kọ́ lásán—ohun kan tí ó jẹ́ àbá èrò orí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè fẹ́ láti jíròrò. Rárá o, Ìjọba ọ̀run yìí jẹ́ ìṣàkóso gidi. Ìrètí aláyọ̀ tí a ní, ti wíwà láàyè títí láé ní ìjẹ́pípé, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìṣàkóso rẹ̀, fún wa ní ìdí púpọ̀ láti túbọ̀ máa kún fún ayọ̀. Irú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà bẹ́ẹ̀ tí a fi síkàáwọ́ wa ń sún wa nígbà gbogbo láti sọ̀rọ̀ rere nípa rẹ̀. (Orin Dáfídì 56:10) Ìwọ ha ń ṣe èyí déédéé nípa sísọ fún ẹni gbogbo pé Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run ti ń ṣàkóso nísinsìnyí ní ọ̀run?
Ẹ̀mí Mímọ́ àti Ẹgbẹ́ Ará Jákèjádò Ayé Ń Ràn Wá Lọ́wọ́
16, 17. Kí ni ọ̀nà kejì àti ìkẹta tí Ọlọ́run gbà ràn wá lọ́wọ́ láti ní àyè kan nínú ète rẹ̀ àtọ̀runwá?
16 Ọ̀nà kejì tí Ọlọ́run gbà ràn wá lọ́wọ́ láti ní àyè kan nínú ète rẹ̀ àtọ̀runwá ni nípa fífún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tí ń mú kí a lè mú èso rere rẹ̀ jáde nínú ìgbésí ayé wa kí a sì ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. (Gálátíà 5:22, 23) Ní àfikún sí i, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Àwa gba, . . . ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kí àwa baà lè mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti fi fún wa pẹ̀lú inú rere.” (Kọ́ríńtì Kíní 2:12) Nípa dídáhùn pa dà sí ẹ̀mí Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún gbogbo wa nísinsìnyí láti mọ àti láti lóye àwọn ohun rere tí ó fi inú rere fún wa ní lọ́ọ́lọ́ọ́—àwọn ìlérí rẹ̀, òfin rẹ̀, ìlànà rẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.—Fi wé Mátíù 13:11.
17 Ní ti ọ̀nà kẹta tí Ọlọ́run gbà ń ràn wá lọ́wọ́, a ní ẹgbẹ́ ara wa kárí ayé àti ìṣètò gbígbádùn mọ́ni ti ètò àjọ Jèhófà fún ìjọsìn. Àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ó rọ̀ wá láti “ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” (Pétérù Kíní 2:17) Ìdílé wa kárí ayé ti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìdùnnú ńláǹlà àtọkànwá ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí Orin Dáfídì 100:2 ti pàṣẹ pé: “Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa: ẹ wá tí ẹ̀yin ti orin sí iwájú rẹ̀.” Ẹsẹ 4 sọ síwájú sí i pé: “Ẹ lọ sí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ọpẹ́, àti sí àgbàlá rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ìyìn: ẹ máa dúpẹ́ fún un, kí ẹ sì máa fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀.” Nítorí náà, yálà a ń wàásù ní gbangba tàbí a wà ní àwọn ìpàdé wa, a lè ní ìdùnnú. Ẹ wo irú àlàáfíà àti ààbò tí a ti rí nínú àwọn àgbàlá ẹlẹ́wà ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Jèhófà!
Fífi Ìdùnnú Yin Jèhófà!
18. Èé ṣe tí a fi lè kún fún ayọ̀ nínú yíyin Jèhófà láìka inúnibíni tàbí ìṣòro mìíràn tí ó lè dé bá wa sí?
18 Láìka ipò ìṣòro, inúnibíni, tàbí àwọn ìṣòro mìíràn tí ó lè dé bá wa sí, ẹ jẹ́ kí a kún fún ayọ̀ pé a wà nínú ilé ìjọsìn Jèhófà. (Aísáyà 2:2, 3) Ẹ jẹ́ kí a rántí pé ìdùnnú jẹ́ ànímọ́ ọkàn àyà. Àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa ìjímìjí jẹ́ onídùnnú olùyin Jèhófà láìka ọ̀pọ̀ ìṣòro àti àdánù tí ó dé bá wọn sí. (Hébérù 10:34) Ọ̀ràn àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa lónìí rí bíi tiwọn gẹ́lẹ́.—Mátíù 5:10-12.
19. (a) Àṣẹ tí a pa léraléra wo ni ó ru wá sókè láti yin Jèhófà? (b) Ìwàláàyè wa ayérayé sinmi lórí kí ni, kí sì ni ìpinnu wa?
19 Gbogbo wa tí ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà ni inú wa ń dùn láti ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì láti yìn ín. Léraléra ni ìwé Ìṣípayá fi gbólóhùn náà “Ẹ yin Jáà!” há ìyìn Ọlọ́run láàárín. (Ìṣípayá 19:1-6) Nínú ẹsẹ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ti Orin Dáfídì 150, a sọ fún wa nígbà 13 pé kí a yin Jèhófà. Èyí jẹ́ àrọwà tí ń lọ́ jákèjádò ayé sọ́dọ̀ gbogbo ẹ̀dá láti dara pọ̀ nínú fífi ìdùnnú kọrin ìyìn sí Jèhófà. Ìwàláàyè wa ayérayé sinmi lórí dídara pọ̀ nínú kíkọrin Halelújà ńlá yìí! Bẹ́ẹ̀ ni, kìkì àwọn tí ń yin Jèhófà láìdábọ̀ ni àwọn ènìyàn tí yóò wà láàyè títí láé. Nítorí náà, a pinnu láti rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ìjọ àgbáyé adúróṣinṣin rẹ̀ bí òpin ti ń sún mọ́lé. Nígbà náà, a lè retí láti rí ìparí ọ̀rọ̀ Orin Dáfídì 150 tí yóò ní ìmúṣẹ pátápátá pé: “Jẹ́ kí ohun gbogbo tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.”
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni ó mú kí àwọn ènìyàn Jèhófà yàtọ̀ gédégbé, kí wọ́n sì jẹ́ aláìláfiwé?
◻ Èé ṣe tí àwọn ènìyàn Jèhófà fi kún fún ìdùnnú tó bẹ́ẹ̀?
◻ Kí ni ó mú wa yàtọ̀ sí ayé?
◻ Ọ̀nà mẹ́ta wo ni Ọlọ́run gbà ràn wá lọ́wọ́ láti ní àyè kan nínú ète rẹ̀ àtọ̀runwá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ibikíbi tí ó bá wà, Jésù máa ń jẹ́rìí nípa Jèhófà, ó sì máa ń yìn ín ní gbangba