Máa Gba Ìbáwí Jèhófà
“Má kọ ìbáwí Jèhófà.”—ÒWE 3:11.
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gba ìbáwí tó bá ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá?
SÓLÓMỌ́NÌ ỌBA Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ kí olúkúlùkù wa máa gba ìbáwí tó bá ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Ó ní: “Ìwọ ọmọ mi, má kọ ìbáwí Jèhófà; má sì fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìbáwí àfitọ́nisọ́nà rẹ̀, nítorí pé ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, àní gẹ́gẹ́ bí baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.” (Òwe 3:11, 12) Òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn, nítorí pé Baba rẹ tí ń bẹ lọ́run fẹ́ràn rẹ ló ṣe ń bá ọ wí.
2. Kí ni “ìbáwí” túmọ̀ sí, báwo lẹnì kan sì ṣe lè rí ìbáwí gbà?
2 “Ìbáwí” túmọ̀ sí fífi ẹgba, ojú àti ọ̀rọ̀ nani tàbí fífúnni ní ìtọ́ni àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Hébérù 12:11) Tó o bá ń gba ìbáwí Ọlọ́run tó o sì ń fi í sílò á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa tọ ipa ọ̀nà òdodo á sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run mímọ́. (Sáàmù 99:5) Ìbáwí lè wá nípasẹ̀ àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́, látinú àwọn nǹkan tó ò ń kọ́ láwọn ìpàdé ìjọ àti ohun tó ò ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìwé tí “olóòótọ́ ìríjú náà” ṣe. (Lúùkù 12:42-44) Wo bí wàá ṣe kún fún ọpẹ́ tó bí ẹnì kan bá sọ fún ọ nípa ohun kan tó yẹ kó o ṣe àtúnṣe lé lórí! Àmọ́, irú ìbáwí wo ló lè tọ́ sí ẹnì kan tó bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì?
Ìdí Tí Ìjọ Fi Ń Yọ Àwọn Kan Lẹ́gbẹ́
3. Ìgbà wo ni ìyọlẹ́gbẹ́ máa ń wáyé?
3 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ṣe. Wọ́n máa ń jíròrò àwọn ìlànà Jèhófà láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wọn. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni láti mọ ohun tí Jèhófà ń fẹ́ kí wọ́n máa ṣe. Ìgbà tẹ́nì kan tó jẹ́ ara ìjọ bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí kò sì ronú pìwà dà ni ìyọlẹ́gbẹ́ máa ń wáyé.
4, 5. Àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ nípa yíyọ èèyàn lẹ́gbẹ́ wo la sọ̀rọ̀ rẹ̀ níhìn-ín, kí sì nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi rọ ìjọ láti gba irú ẹni bẹ́ẹ̀ padà?
4 Àpẹẹrẹ ẹnì kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ nínú Ìwé Mímọ́ rèé: Ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì fàyè gba “irúfẹ́ àgbèrè tí kò tilẹ̀ sí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé ọkùnrin kan ní aya kan tí ó jẹ́ ti baba rẹ̀.” Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n “fi irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ lé Sátánì lọ́wọ́ fún ìparun ẹran ara, kí a bàa lè gba ẹ̀mí là.” (1 Kọ́ríńtì 5:1-5) Bí ìjọ bá yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ náà lẹ́gbẹ́, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi í lé Sátánì lọ́wọ́, ó tún padà di apá kan ayé Èṣù nìyẹn. (1 Jòhánù 5:19) Yíyọ tí ìjọ bá yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ á mú ohun tó lè nípa búburú lórí ìjọ kúrò, á sì jẹ́ kí ìjọ lè pa “ẹ̀mí” rere tàbí ìwà rere tó gbilẹ̀ nínú ìjọ mọ́, kí ìjọ lè máa bá a nìṣó láti máa fi ànímọ́ Ọlọ́run tó ní hàn.—2 Tímótì 4:22; 1 Kọ́ríńtì 5:11-13.
5 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n yọ ẹni tó hùwà àìtọ́ náà lẹ́gbẹ́ tí Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé kí wọ́n gbà á padà. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì náà sọ pé kí ‘Sátánì má bàa fi ọgbọ́n àyínìke borí’ wọn ni. Nítorí ó dájú pé ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ti ronú pìwà dà, ó sì ti jáwọ́ nínú ìwàkiwà. (2 Kọ́ríńtì 2:8-11) Báwọn ará Kọ́ríńtì bá kọ̀ láti gba ọkùnrin tó ronú pìwà dà náà padà, Sátánì á fi ọgbọ́n àyínìke borí wọn ní ti pé, wọ́n á dẹni tó le koko jù, wọ́n á sì di aláìlè-dárí-jini bí Èṣù ṣe fẹ́ kí wọ́n rí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kò pẹ́ kò jìnnà tí wọ́n fi ‘dárí ji’ ọkùnrin tó ronú pìwà dà náà, tí wọ́n “sì tù ú nínú.”—2 Kọ́ríńtì 2:5-7.
6. Àǹfààní wo ló wà nínú ìyọlẹ́gbẹ́?
6 Àǹfààní wo ló ń tìdí ìyọlẹ́gbẹ́ wá? Ó ń mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ mímọ́ Jèhófà, ó sì ń dáàbò bo orúkọ rere táwọn èèyàn rẹ̀ ní. (1 Pétérù 1:14-16) Pípa òfin Ọlọ́run mọ́ ló jẹ́ láti yọ oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Ó tún ń jẹ́ kí ìjọsìn Ọlọ́run máa lọ déédéé nínú ìjọ. Ó sì tún lè pe orí ẹni tí kò ronú pìwà dà náà wálé.
Ipa Kékeré Kọ́ Ni Ìrònúpìwàdà Ń Kó
7. Kí ni ojú Dáfídì rí nígbà tó kọ̀ láti jẹ́wọ́ ìrélànàkọjá rẹ̀?
7 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ bíburú jáì ni wọ́n ronú pìwà dà ní tòótọ́, a kì í sì í yọ wọ́n kúrò nínú ìjọ. Àmọ́ ṣá o, kì í rọrùn fáwọn kan láti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Gbé ọ̀ràn Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì, tó kọ Sáàmù 32 yẹ̀ wò. Orin yẹn ṣí i payá pé fáwọn àkókò kan, Dáfídì ò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì kan tó dá. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ti ìṣekúṣe tó wáyé láàárín òun àti Bátí-ṣébà. Ohun tí èyí yọrí sí ni pé wàhálà tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kó bá a mú kí agbára rẹ̀ joro, bí ìgbà tí afẹ́fẹ́ gbígbẹ háúháú ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn bá fa omi gbẹ lára igi. Ṣìbáṣìbo bá Dáfídì, àmọ́ nígbà tó ‘jẹ́wọ́ àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀, Jèhófà dárí jì í.’ (Sáàmù 32:3-5) Lẹ́yìn náà ni Dáfídì kọrin pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí Jèhófà kò ka ìṣìnà sí lọ́rùn.” (Sáàmù 32:1, 2) Ẹ ò wa rí i pé ohun àgbàyanu ni láti rí àánú Ọlọ́run gbà!
8, 9. Báwo lèèyàn ṣe lè fi ìrònúpìwàdà hàn, báwo ló sì ṣe ṣe pàtàkì tó bó bá dọ̀ràn gbígba ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ padà?
8 Ó wá ṣe kedere báyìí pé, ẹlẹ́ṣẹ̀ kan gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà bó bá máa rí àánú Ọlọ́run gbà. Àmọ́ ṣá o, ojútì tàbí ìbẹ̀rù pé kí àṣírí má lọ tú kọ́ ni ìrònúpìwàdà o. “Láti ronú pìwà dà” túmọ̀ sí “láti yí ọkàn ẹni padà” kúrò nínú ìwà tí kò dára, nítorí pé èèyàn kábàámọ̀. Ẹni tó ronú pìwà dà lẹni tó ní “ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀” tó sì ń fẹ́ láti ‘ṣe àtúnṣe àìtọ́,’ débi tó bá lè ṣe é dé.—Sáàmù 51:17; 2 Kọ́ríńtì 7:11.
9 Ká tó lè gba ẹnì kan padà sínú ìjọ Kristẹni, ó ṣe pàtàkì pé kírú ẹni bẹ́ẹ̀ ronú pìwà dà. A kì í wulẹ̀ gba ẹnì kan padà sínú ìjọ kìkì nítorí pé ó ti pẹ́ díẹ̀ tá a ti yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Ká tó lè gbà á padà, ọkàn ẹ̀ ti gbọ́dọ̀ yí padà dáadáa. Ó gbọ́dọ̀ mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ tóun dá ṣe burú tó, àti bí ẹ̀gàn tó kó bá orúkọ Jèhófà àti ìjọ ṣe pọ̀ tó. Ẹlẹ́ṣẹ̀ náà gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà, kó fi tọkàntọkàn gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí ji òun, kó sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run. Nígbà tó bá ń béèrè pé kí wọ́n gba òun padà, ó gbọ́dọ̀ lè fẹ̀rí hàn pé òun tí ronú pìwà dà, òun sì ti ń ṣe “àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.”—Ìṣe 26:20.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kéèyàn Jẹ́wọ́ Ìwà Àìtọ́?
10, 11. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ra?
10 Àwọn kan tó ti dẹ́ṣẹ̀ lè ronú pé: ‘Bí mo bá tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ẹnikẹ́ni, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa bi mí ní ìbéèrè táá dójú tì mí, wọ́n sì lè torí ẹ̀ yọ mí lẹ́gbẹ́. Àmọ́ bí mo bá bò ó mọ́ra, ìyẹn ò ní wáyé, ẹnikẹ́ni ò sì ní mọ̀ láé nínú ìjọ.’ Àwọn ohun kan wà tí ẹní bá ń ronú lọ́nà yìí gbójú fò dá. Àwọn nǹkan wo nìyẹn ná?
11 Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.” Síbẹ̀, ó máa ń tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7; Jeremáyà 30:11) Bó o bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, báwo lo ṣe lè rí àánú Ọlọ́run gbà bó o bá gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́lẹ̀? Jèhófà mọ pó o dẹ́ṣẹ̀, kì í sì í wulẹ̀ gbójú fo ìwà àìtọ́ dá.—Òwe 15:3; Hábákúkù 1:13.
12, 13. Kí ló lè tìdí ẹ̀ yọ béèyàn bá ń gbìyànjú láti bo ìwà àìtọ́ mọ́lẹ̀?
12 Bó o bá ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tún padà ní ẹ̀rí ọkàn rere. (1 Tímótì 1:18-20) Ṣùgbọ́n, bó o bá kọ̀ láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ó lè ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn rẹ kí ìyẹn sì mú kó o túbọ̀ dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí i. Rántí pé kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀dá èèyàn mìíràn kan tàbí ìjọ nìkan lo dẹ́ṣẹ̀ sí. Ọlọ́run lo dẹ́ṣẹ̀ sí. Onísáàmù kọrin pé: “Jèhófà—ọ̀run ni ìtẹ́ rẹ̀. Ojú rẹ̀ ń wò, ojú rẹ̀ títàn yanran ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ ènìyàn. Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú.”—Sáàmù 11:4, 5.
13 Ẹnikẹ́ni tó bá bo ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì mọ́lẹ̀ tó sì gbìyànjú láti dúró sínú ìjọ Kristẹni mímọ́ ò ní rí ìbùkún Jèhófà gbà. (Jákọ́bù 4:6) Nítorí náà, bó o bá ti dẹ́ṣẹ̀ tó o sì fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́, tètè lọ jẹ́wọ́ bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀rí ọkàn rẹ á máa dá ọ lẹ́bi, pàápàá nígbà tó o bá ka ìmọ̀ràn kan nípa irú ọ̀ràn bíburú jáì bẹ́ẹ̀ tàbí tó o gbọ́ ohun kan nípa rẹ̀. Bí Jèhófà bá gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò lára ẹ ńkọ́, bó ṣe ṣe fún Sọ́ọ̀lù Ọba? (1 Sámúẹ́lì 16:14) Bí Ọlọ́run bá gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ pẹ́nrẹ́n, o lè dẹ́ṣẹ̀ tó burú ju èyí tó o dá lọ.
Ní Ìgbọ́kànlé Nínú Àwọn Arákùnrin Rẹ Tó Jẹ́ Olóòótọ́
14. Kí nìdí tí oníwà àìtọ́ fi gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Jákọ́bù 5:14, 15?
14 Wàyí o, kí ló wá yẹ kí oníwà àìtọ́ tó ní ẹ̀mí ìrònúpìwàdà ṣe? “Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde.” (Jákọ́bù 5:14, 15) Títọ àwọn alàgbà lọ jẹ́ ọ̀nà kan téèyàn lè gbà “mú èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà jáde.” (Mátíù 3:8) Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ àti ọlọ́kàn rere yìí á “gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà.” Bí òróró atura, ìmọ̀ràn tó bá Bíbélì mu tí wọ́n bá fún ẹnikẹ́ni tó ronú pìwà dà lóòótọ́, á tù ú lára.—Jeremáyà 8:22.
15, 16. Báwo làwọn alàgbà ìjọ Kristẹni ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ bó ṣe wà nínú Ìsíkíẹ́lì 34:15, 16?
15 Ẹ ò rí i pé Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn wa, fi àpẹẹrẹ pé òun jẹ́ onífẹ̀ẹ́ lélẹ̀ nígbà tó dá àwọn Júù sílẹ̀ kúrò nígbèkùn lórílẹ̀-èdè Bábílónì, lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni àti nígbà tó dá Ísírẹ́lì tẹ̀mí nídè kúrò ní “Bábílónì Ńlá” lọ́dún 1919 Sànmánì Kristẹni! (Ìṣípayá 17:3-5; Gálátíà 6:16) Ó tipa bẹ́ẹ̀ mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, pé: “Èmi alára yóò bọ́ àwọn àgùntàn mi, èmi alára yóò sì mú kí wọ́n dùbúlẹ̀ . . . Èyí tí ó sọnù ni èmi yóò wá kiri, èyí tí a lé lọ ni èmi yóò sì mú padà bọ̀, èyí tí ó fara pa ni èmi yóò sì fi ọ̀já wé, èyí tí ń ṣòjòjò ni èmi yóò sì fún lókun.”—Ìsíkíẹ́lì 34:15, 16.
16 Jèhófà bọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ tó dà bí àgùntàn, ó mú kí wọ́n dùbúlẹ̀ láìléwu, ó sì wá àwọn tó sọ nù. Bákan náà, àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn ń rí sí i pé agbo Ọlọ́run ń jẹ àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù nípa tẹ̀mí, ewu kankan ò sì wu wọ́n. Àwọn alàgbà máa ń wá àwọn àgùntàn tí wọ́n bá ṣáko lọ kúrò nínú ìjọ. Bí Ọlọ́run ṣe máa ń fi ‘ọ̀já wé èyí tí ó fara pa,’ bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn alábòójútó ṣe máa ń “fi ọ̀já wé” àgùntàn tí ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ tàbí ohun tẹ́nì kan ṣe bá ṣèpalára fún. Bí Ọlọ́run sì ‘ṣe ń fún ẹni tó ń ṣòjòjò lókun,’ bẹ́ẹ̀ náà làwọn alàgbà ṣe máa ń ran àwọn tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí lọ́wọ́, bóyá àwọn tó jẹ́ pé ìwà àìtọ́ tí wọ́n hù ló fa irú àìsàn bẹ́ẹ̀.
Báwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ṣe Ń Ṣèrànwọ́
17. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ lọ́ tìkọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà?
17 Tayọ̀tayọ̀ làwọn alàgbà fi ń ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn náà pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífi àánú hàn . . . , ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù.” (Júúdà 23) Àwọn Kristẹni kan ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì nípa ṣíṣèṣekúṣe. Àmọ́ bí wọ́n bá ronú pìwà dà ní tòótọ́, kí wọ́n fọkàn balẹ̀ pé àwọn alàgbà tó ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí á fi àánú àti ìfẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù ò yọ ara ẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sọ nípa irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ pé: “Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín.” (2 Kọ́ríńtì 1:24) Nítorí náà, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí lọ sọ́dọ̀ wọn.
18. Báwo làwọn alàgbà ṣe ń gbẹ́jọ́ onígbàgbọ́ bíi tiwọn tó bá ṣe ohun tí kò tọ́?
18 Bó o bá ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, kí nìdí tó o fi lè ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn alàgbà? Ìdí ni pé torí iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn agbo gan-an ni Ọlọ́run ṣe yàn wọ́n sípò. (1 Pétérù 5:1-4) Kò sí olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ tó máa fẹ́ láti fìyà jẹ ọ̀dọ́ àgùntàn tó ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu bí irú ọ̀dọ́ àgùntàn bẹ́ẹ̀ bá ń ké nítorí pé ó fara pa. Nítorí náà, báwọn alàgbà bá ń gbẹ́jọ́ onígbàgbọ́ bíi tiwọn tó ṣe ohun tí kò tọ́, wọn ò ní wò ó níwò ọ̀daràn tó gbọ́dọ̀ jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀. Ojú tí wọ́n á fi wò ó ni pé àwọn ń gbẹ́jọ́ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀, bó bá sì ṣeé ṣe, àwọn fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́ láti padà ní ìdúró rere nínú ìjọ. (Jákọ́bù 5:13-20) Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ máa fi òdodo ṣe ìdájọ́ kí wọ́n sì máa “fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo.” (Ìṣe 20:29, 30; Aísáyà 32:1, 2) Bíi tàwọn Kristẹni yòókù, ó tọ́ káwọn alàgbà máa ‘ṣe ìdájọ́ òdodo, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rìn.’ (Míkà 6:8) Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ìpinnu lórí ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ẹ̀mí àwọn “àgùntàn pápá ìjẹko [Jèhófà]” lọ, tó sì tún jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wọn.—Sáàmù 100:3.
19. Àwọn ànímọ́ wo làwọn alàgbà inú ìjọ Kristẹni máa ń lò bí wọ́n bá ń gbìyànjú láti tọ́ ẹnì kan sọ́nà padà?
19 Ẹ̀mí mímọ́ ló yan àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn sípò, wọ́n sì máa ń fẹ́ kó darí àwọn. Bí “ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀,” bóyá nítorí pé kò fura, kí àwọn ọkùnrin tó tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti “tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù.” (Gálátíà 6:1; Ìṣe 20:28) Àwọn alàgbà á gbìyànjú láti tún èrò rẹ̀ ṣe pẹ̀lú ìwà tútù, àmọ́ láìfi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ìlànà Ọlọ́run. Èyí dà bí ìgbà tí dókítà tó lójú àánú bá ń fẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ to egungun tó ṣẹ́, kí ẹni tí eegun ẹ̀ ṣẹ́ má bàa mọ ìrora tó pọ̀ síbẹ̀ táá fún un ní ìtọ́jú tó yẹ. (Kólósè 3:12) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àdúrà àti Ìwé Mímọ́ ni wọ́n máa gbé àánú èyíkéyìí tí wọ́n bá fi hàn sí oníwà àìtọ́ náà kà, ìpinnu àwọn alàgbà á fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọ̀ràn hàn.—Mátíù 18:18.
20. Kí ló lè mú kó pọn dandan láti ṣèfilọ̀ pé ìgbìmọ̀ onídàájọ́ ti fún ẹnì kan ní ìbáwí?
20 Bí ẹ̀ṣẹ̀ kan bá ti di ohun táwọn èèyàn mọ̀ tàbí tó dájú pé àwọn èèyàn ṣì máa mọ̀ nípa ẹ̀, ó ṣeé ṣe ká ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ ká bàa lè pa orúkọ rere ìjọ mọ́. Bá a bá sì rí ìdí míì tó fi yẹ ká fi tó ìjọ létí, a ó ṣe ìfilọ̀. Láwọn àkókò tí ẹnì kan tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ bá wí fi ń padà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí, a lè fi í wé ẹnì kan tí ara ẹ̀ ń jẹ bò lẹ́yìn tó ti fara pa, èyí tó máa dín ìgbòkègbodò rẹ̀ kù. Fáwọn àkókò kan, bóyá ì bá ṣàǹfààní fún ẹni tó ronú pìwà dà náà láti máa fetí sílẹ̀ dípò kó máa lóhùn sí ìpàdé. Àwọn alàgbà lè ṣètò fún ẹnì kan láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀ kí wọ́n bàa lè fún un lókun níbi tó bá ti ní àìlera kó lè padà di “onílera nínú ìgbàgbọ́.” (Títù 2:2) Ìfẹ́ ló máa sún wọn ṣe gbogbo èyí, kì í ṣe nítorí kí wọ́n lè fìyà jẹ oníwà àìtọ́ náà.
21. Báwo ló ṣe yẹ ká bójú tó àwọn ẹjọ́ ìwà àìtọ́ kan?
21 Onírúurú ọ̀nà làwọn alàgbà lè gbà ranni lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé arákùnrin kan tó ti ní ìṣòro ọtí mímu nígbà kan rí mu àmujù lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì nígbà tóun nìkan wà nínú ilé. Tàbí kó jẹ́ pé ẹnì kan tó ti fi sìgá mímu sílẹ̀ tipẹ́ yọ́ sìgá mu lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì nígbà tí ẹran ara lò ó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti gbàdúrà tó sì nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run ti dárí ji òun, ó yẹ kó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ alàgbà kan kírú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ má bàa di bárakú. Alàgbà kan tàbí méjì lè bójú tó ọ̀ràn náà. Àmọ́ kí wọ́n sọ fún alága àwọn alábòójútó, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn nǹkan míì lè wé mọ́ ọ̀ràn náà.
Má Ṣe Ṣíwọ́ Gbígba Ìbáwí
22, 23. Kí nìdí tó fi yẹ kó o má ṣe ṣíwọ́ gbígba ìbáwí Ọlọ́run?
22 Káwọn Kristẹni kọ̀ọ̀kan bàa lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, wọ́n gbọ́dọ̀ máa fiyè sí ìbáwí Jèhófà. (1 Tímótì 5:20) Nítorí náà, nígbà tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni tàbí nígbà tó o bá gbọ́ ìbáwí tá a fúnni ní ìpàdé ìjọ, àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè àwọn èèyàn Jèhófà, fi ìbáwí èyíkéyìí tó o bá rí gbà sọ́kàn. Máa rí i dájú pé ò ń ṣe ohun gbogbo ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, ìbáwí Ọlọ́run á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun tó dà bí odi tẹ̀mí yí ara ẹ ká. Odi yìí ni ohun ìdènà lílágbára kan tí ò ní jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ rí ẹ gbé ṣe.
23 Gbígba ìbáwí Ọlọ́run á mú kó ṣeé ṣe fún ẹ láti dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Lóòótọ́, a ti yọ àwọn kan kúrò nínú ìjọ Kristẹni, àmọ́ kò pọn dandan kí ìyẹn ṣẹlẹ̀ sí ọ bó o bá ń “fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ” tó o sì ń ‘rìn bí ọlọ́gbọ́n.’ (Òwe 4:23; Éfésù 5:15) Àmọ́ ṣá o, bó bá jẹ́ pé wọ́n ti yọ ẹ́ lẹ́gbẹ́, o ò ṣe kúkú ṣe àwọn nǹkan tó yẹ ní ṣíṣe kí wọ́n lè gbà ọ́ padà? Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún òun máa fi ìṣòtítọ́ sin òun pẹ̀lú “ìdùnnú ọkàn-àyà.” (Diutarónómì 28:47) O lè ṣe bẹ́ẹ̀ títí láé bó o bá ń gba ìbáwí Jèhófà ní gbogbo ìgbà.—Sáàmù 100:2.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tí wọ́n fi ń yọ àwọn kan kúrò nínú ìjọ Kristẹni?
• Àwọn nǹkan wo la fi lè mọ̀ pé ẹnì kan ronú pìwà dà tọkàntọkàn?
• Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì?
• Àwọn ọ̀nà wo làwọn alàgbà ìjọ ń gbà ran àwọn oníwà àìtọ́ tó ronú pìwà dà lọ́wọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi fi ìtọ́ni nípa ìyọlẹ́gbẹ́ ránṣẹ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Bíi tàwọn olùṣọ́ àgùntàn ìgbàanì, àwọn Kristẹni alàgbà ‘ń fi ọ̀já wé’ àwọn àgùntàn Ọlọ́run tó fara pa