Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
2 Mo ti pinnu lọ́kàn mi pé mi ò ní wá sọ́dọ̀ yín nínú ìbànújẹ́ mọ́. 2 Torí tí mo bá bà yín nínú jẹ́, ta ló máa múnú mi dùn tí kì í bá ṣe ẹni tí mo bà nínú jẹ́? 3 Ìdí tí mo fi kọ ìwé tí mo kọ sí yín ni pé, tí mo bá dé mi ò ní banú jẹ́ lórí àwọn tó yẹ kí n máa yọ̀ nítorí wọn, torí ó dá mi lójú pé ohun tó ń fún mi láyọ̀ ń fún gbogbo yín náà láyọ̀. 4 Nítorí nínú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú àti ìdààmú ọkàn ni mo kọ̀wé sí yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ omijé, kì í ṣe láti bà yín nínú jẹ́,+ àmọ́ ó jẹ́ láti mú kí ẹ mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.
5 Tí ẹnikẹ́ni bá ti fa ìbànújẹ́,+ èmi kọ́ ló bà nínú jẹ́, gbogbo yín ni dé àyè kan. Mi ò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi le koko jù. 6 Ìbáwí tó múná tí èyí tó pọ̀ jù lára yín ti fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti tó; 7 ní báyìí, ṣe ló yẹ kí ẹ dárí jì í tinútinú, kí ẹ sì tù ú nínú,+ kí ìbànújẹ́ tó pọ̀ lápọ̀jù má bàa bò ó mọ́lẹ̀.*+ 8 Torí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ jẹ́ kó mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ òun.+ 9 Ìdí nìyí tí mo tún fi kọ̀wé sí yín: kí n lè mọ̀ bóyá ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ jẹ́ onígbọràn nínú ohun gbogbo. 10 Tí ẹ bá dárí ohunkóhun ji ẹnikẹ́ni, èmi náà ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, ohunkóhun tí mo bá ti dárí rẹ̀ jini (ìyẹn tí mo bá ti dárí ohunkóhun jini) ó jẹ́ nítorí yín níwájú Kristi, 11 kí Sátánì má bàa fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n* borí wa,+ nítorí a mọ àwọn ọgbọ́n* rẹ̀.+
12 Nígbà tí mo dé Tíróásì+ láti kéde ìhìn rere nípa Kristi, tí ilẹ̀kùn kan sì ṣí fún mi nínú Olúwa, 13 ẹ̀mí mi ò lélẹ̀ torí mi ò rí Títù + arákùnrin mi. Torí náà, mo dágbére fún wọn, mo sì forí lé Makedóníà.+
14 Àmọ́ ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tó máa ń darí wa nínu ìjáde àwọn tó ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun pẹ̀lú Kristi, tó sì ń tipasẹ̀ wa mú kí òórùn ìmọ̀ nípa rẹ̀ ta sánsán* dé ibi gbogbo! 15 Nítorí lójú Ọlọ́run, a jẹ́ òórùn dídùn ti Kristi, tó ń ta sánsán láàárín àwọn tó ń rí ìgbàlà àti láàárín àwọn tó ń ṣègbé; 16 lójú àwọn tó ń ṣègbé, a jẹ́ òórùn* ikú tó ń yọrí sí ikú,+ lójú àwọn tó ń rí ìgbàlà, a jẹ́ òórùn dídùn ti ìyè tó ń yọrí sí ìyè. Ta ló sì kúnjú ìwọ̀n fún nǹkan wọ̀nyí? 17 Àwa ni, nítorí a kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run*+ bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe jẹ́, àmọ́ à ń fi òótọ́ inú sọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe rán wa, àní, níwájú Ọlọ́run àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi.