Ìdí Tí Ìyọlẹ́gbẹ́ Fi Jẹ́ Ìpèsè Onífẹ̀ẹ́
JULIAN sọ pé: “Nígbà tí wọ́n ṣèfilọ̀ pé wọ́n ti yọ ọmọkùnrin mi lẹ́gbẹ́, ńṣe ló dà bíi pé gbogbo nǹkan dojú rú fún mi. Òun ni àkọ́bí mi, a sì mọwọ́ ara wa gan-an ni; ọ̀pọ̀ nǹkan la máa ń ṣe pa pọ̀. Ó ń ṣe dáadáa tẹ́lẹ̀ o, ṣàdédé ló bẹ̀rẹ̀ sí í hùwàkiwà. Gbogbo ìgbà ni ìyàwó mi máa ń sunkún, mi ò sì mọ bí mo ṣe lè rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún. A ṣáà ń bi ara wa bóyá àwa òbí ẹ̀ la ò ṣe ipa tiwa.”
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé torí ìfẹ́ la ṣe ń yọ Kristẹni kan lẹ́gbẹ́ tó bá ń kó ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ báni? Kí nìdí tí Ìwé Mímọ́ fi sọ pé ká máa gbé irú ìgbésẹ̀ tó le bẹ́ẹ̀? Àti pé, àwọn ohun wo ló máa mú ká yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ?
OHUN MÉJÌ TÓ MÁA Ń YỌRÍ SÍ ÌYỌLẸ́GBẸ́
Ká tó yọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lẹ́gbẹ́, ohun méjì kan gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Àkọ́kọ́ ni pé, Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi náà ti gbọ́dọ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Ìkejì ni pé, kò ronú pìwà dà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà mọ̀ pé a kì í ṣe ẹni pípé, ó ní àwọn ìlànà mímọ́ tó fẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa tẹ̀ lé. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ pé a kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì irú bí ìṣekúṣe, ìbọ̀rìṣà, olè jíjà, ìlọ́nilọ́wọ́gbà, ìpànìyàn àti ìbẹ́mìílò.—1 Kọ́r. 6:9, 10; Ìṣí. 21:8.
Ṣó o gbà pé àwọn ìlànà mímọ́ tí Jèhófà ní ká máa tẹ̀ lé yẹn bọ́gbọ́n mu, wọ́n sì máa ń dáàbò bò wá? Ṣé kò wù ẹ́ kó o máa gbé láàárín àwọn èèyàn jẹ́jẹ́, tó níwà tó dáa tí wọ́n sì ṣeé fọkàn tán? Irú èèyàn táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ètò Jèhófà jẹ́ nìyẹn, torí a ti ṣèlérí nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run pé a óò máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Àmọ́, ká sọ pé àìpé mú kí Kristẹni kan tó ti ṣèrìbọmi dá ẹ̀ṣẹ̀ kan tó burú jáì ńkọ́? Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ pẹ̀lú ṣe irú àwọn àṣìṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ Ọlọ́run kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pátápátá. Àpẹẹrẹ pàtàkì kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ni Dáfídì Ọba. Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ panṣágà ó tún pa èèyàn; síbẹ̀, wòlíì Nátánì sọ fún un pé: “Jèhófà . . . jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kọjá lọ.”—2 Sám. 12:13.
Ọlọ́run dárí ji Dáfídì torí pé ó ronú pìwà dà látọkàn wá. (Sm. 32:1-5) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, àfi tí ìránṣẹ́ Jèhófà kan kò bá ronú pìwà dà tàbí tó ń bá a nìṣó láti ṣe ohun tí kò dáa ni wọ́n máa yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. (Ìṣe 3:19; 26:20) Bí àwọn alàgbà tó wà nínú ìgbìmọ̀ onídàájọ́ kò bá rí ẹ̀rí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ronú pìwà dà látọkàn wá, wọ́n gbọ́dọ̀ yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.
Ó lè kọ́kọ́ máa ṣe wá bíi pé bí wọ́n ṣe yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́ ti le jù tàbí pé kò fàánú hàn rárá, pàápàá tí ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ náà bá sún mọ́ wa gan-an. Àmọ́ ṣá o, Ọ̀rọ̀ Jèhófà jẹ́ ká rí ìdí tó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ìgbésẹ̀ yẹn jẹ́ ìpinnu tó fìfẹ́ hàn.
ÌYỌLẸ́GBẸ́ LÈ ṢE ÀWỌN TÍ Ọ̀RỌ̀ KÀN LÁǸFÀÀNÍ
Jésù sọ pé, “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mát. 11:19) Ó bọ́gbọ́n mu táwọn alàgbà bá pinnu láti yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́ torí ó máa so èso òdodo. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa mẹ́ta lára rẹ̀:
Ó máa bọlá fún orúkọ Jèhófà tá a bá yọ oníwà àìtọ́ lẹ́gbẹ́. Nítorí à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, kò sí bí ìwà wa kò ṣe ní máa nípa lórí ojú táwọn èèyàn á máa fi wo orúkọ yẹn. (Aísá. 43:10) Bó ṣe jẹ́ pé ìwà tí ọmọ kan bá hù lè pọ́n àwọn òbí ẹ̀ lé tàbí kó bà wọ́n lórúkọ jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé ìwà rere tàbí búburú táwa èèyàn Jèhófà bá hù máa nípa lórí ojú táwọn èèyàn á máa fi wo Ọlọ́run wa. Táwọn tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run bá ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ ṣèwà hù ó máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì tó jẹ́ pé àwọn Júù làwọn èèyàn mọ̀ mọ orúkọ Jèhófà.—Ìsík. 36:19-23.
Tá a bá ń ṣèṣekúṣe, a máa mú ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Gẹ́gẹ́ bí onígbọràn ọmọ, ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ rí nínú àìmọ̀kan yín, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.’” (1 Pét. 1:14-16) Ìwà mímọ́ tí kò ní àbàwọ́n máa ń bọlá fún orúkọ Ọlọ́run.
Bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan bá hùwàkiwà, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ wá mọ̀ nípa rẹ̀. Nítorí náà, bá a ṣe ń yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́ fi hàn pé Jèhófà ní àwọn èèyàn mímọ́ tí wọ́n rọ̀ mọ́ ìlànà Ìwé Mímọ́ kí wọ́n lè máa wà ní mímọ́. Àlejò kan wá sì Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́jọ́ kan ní orílẹ̀-èdè Switzerland nígbà tí wọ́n ń ṣèpàdé lọ́wọ́, ó sì sọ pé òun fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ìjọ yẹn. Wọ́n yọ ọmọ ìyá ẹ̀ lẹ́gbẹ́ torí pé ó ṣèṣekúṣe. Ó sọ pé òun fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ètò “tí kò fàyè gba ìwà búburú.”
Tá a bá yọ oníwà àìtọ́ lẹ́gbẹ́ ó máa ń dáàbò bo ìjọ Kristẹni kó lè máa wà ní mímọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ káwọn Kristẹni tó wà nílùú Kọ́ríńtì mọ ewu tó wà níbẹ̀ tí wọ́n bá jẹ́ kí ẹni tó mọ̀ọ́mọ̀ hùwà àìtọ́ máa wà nìṣó láàárín wọn. Ó fi èèràn tírú ẹni bẹ́ẹ̀ lè kó ran ìjọ wé ìwúkàrà tó lè mú kí gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú. Ó sọ pé: “Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìṣùpọ̀ di wíwú.” Ó wá fún wọn ní ìtọ́ni pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú náà kúrò láàárín ara yín.”—1 Kọ́r. 5:6, 11-13.
Ó ṣeé ṣe kí “ènìyàn burúkú” tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí máa mọ̀ọ́mọ̀ hùwà ìṣekúṣe. Àwọn ará ìjọ tó kù kò sì rí ohun tó burú nínú ohun tó ń ṣe yìí. (1 Kọ́r. 5:1, 2) Tí wọ́n bá fàyè gba irú ìwà àìtọ́ bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe káwọn Kristẹni tó kù náà fẹ́ máa tẹ̀ lé àṣàkaṣà tó kún inú ìlú oníwà pálapàla tí wọ́n ń gbé. Gbígbójúfo ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan mọ̀ọ́mọ̀ dá máa jẹ́ káwọn èèyàn fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú àwọn ìlànà Ọlọ́run. (Oníw. 8:11) Bí “àpáta tí ó fara sin lábẹ́ omi,” ṣe lè jẹ́ kí ọkọ̀ rì, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà lè jin ìgbàgbọ́ àwọn ará tó kù nínú ìjọ lẹ́sẹ̀.—Júúdà 4, 12.
Ìyọlẹ́gbẹ́ lè pe orí oníwà àìtọ́ wálé. Ìgbà kan wà tí Jésù sọ̀rọ̀ ọ̀dọ́kùnrin kan tó kúrò nílé bàbá rẹ̀ tó sì lọ ná ogún rẹ̀ nínàá àpà. Ọmọ onínàákúnàá yẹn kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó le koko pé òfo àti ìyà ló wà lóde ilé bàbá òun. Ọmọkùnrin náà pe orí ara rẹ̀ wálé, ó ronú pìwà dà, ó sì pa dà sílé. (Lúùkù 15:11-24) Bí Jésù ṣe ṣàpèjúwe pé inú bàbá onífẹ̀ẹ́ yẹn dùn nígbà tí ọmọ rẹ̀ yí pa dà jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà. Ohun tí Jèhófà fi dá wa lójú ni pé: “Èmi kò ní inú dídùn sí ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí padà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó ní tòótọ́.”—Ìsík. 33:11.
Lọ́nà kan náà, ó ṣeé ṣe káwọn tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ tí wọn kì í sì í ṣe apá kan ìjọ Kristẹni tó jẹ́ ìdílé wọn nípa tẹ̀mí mọ́ wá pa dà mọ̀ pé àwọn ti pàdánù nǹkan ńlá. Bí wọ́n ṣe ń ronú lórí àbàjáde ìwà búburú tí wọ́n hù, tí wọ́n sì ń rántí àwọn ìgbà kan tí wọ́n máa ń láyọ̀ torí pé wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀, ó ṣeé ṣe kí èyí pe orí wọn wálé.
Kí èyí tó lè ṣeé ṣe, ó ṣe pàtàkì pé ká lo ìfẹ́, ká sì fọwọ́ pàtàkì mú ìlànà Jèhófà. Onísáàmù náà, Dáfídì sọ pé: “Bí olódodo bá gbá mi, yóò jẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́; bí ó bá sì fi ìbáwí tọ́ mi sọ́nà, yóò jẹ́ òróró ní orí” mi. (Sm. 141:5) Ẹ jẹ́ ká ṣe àpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yìí: Ká sọ pé òkèlè ńlá kan há sí ọmọdé kan lọ́nà ọ̀fun, kò lè gbé e mì, kò lè pọ̀ ọ́ jáde, èyí ò sì jẹ́ kó lè mí dáadáa. Kí òkèlè yẹn tó lè jáde, ìyá rẹ̀ ní láti máa gbá a lábàrá lẹ́yìn léraléra. Àbàrá yẹn lè má rọrùn, àmọ́ ó tún lè gba ẹ̀mí ẹ̀ là. Lọ́nà kan náà, Dáfídì mọ̀ pé ó máa ṣe òun láǹfààní tí olódodo bá fi ìbáwí tọ́ òun sọ́nà.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ìyọlẹ́gbẹ́ ni ìbáwí tí ẹni tó hùwà àìtọ́ tó burú jáì nílò. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́wàá, ọmọ Julian tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí tún ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, ó pa dà sínú ìjọ, ní báyìí ó ti di alàgbà nínú ìjọ. Ó sọ pé: “Nígbà tí wọ́n yọ mí lẹ́gbẹ́, mo wá jìyà àbájáde ìgbésí ayé tí mo yàn. Ìbáwí tó tọ́ sí mi gan-an nìyẹn.”—Héb. 12:7-11.
ỌWỌ́ ÌFẸ́ TÁ A LÈ FI MÚ ÀWỌN TÍ WỌ́N YỌ LẸ́GBẸ́
Ká sòótọ́, àjálù ni ìyọlẹ́gbẹ́ jẹ́ sí àjọṣe tó wà láàárín ẹnì kan àti Jèhófà, àmọ́ kò pọn dandan kí àjálù náà wà bẹ́ẹ̀ láìsí àtúnṣe. Gbogbo wa la lohun tá a lè ṣe ká lè rí i dájú pé ìdí tí wọ́n fi yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ yọrí sí rere.
Àwọn alàgbà tó máa sọ ìpinnu wọn tó dunni wọra fún ẹni tí wọ́n máa yọ lẹ́gbẹ́, máa ń sapá láti fi ìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà. Tí wọ́n bá ń sọ ìpinnu wọn fún onítọ̀hún, wọ́n máa ń ṣàlàyé àwọn ìgbésẹ̀ tí ẹni náà lè gbé kó tó lè pa dà sínú ìjọ, wọ́n sì máa ń rí i pé àlàyé náà ṣe kedere ó sì jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àwọn alàgbà máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ tí wọ́n sì ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti yí ìgbésí ayé wọn pa dà, kí wọ́n lè máa rán wọn létí ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.a
Àwọn ará ìdílé le fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ìjọ àti ẹni tó hùwà àìtọ́ náà tí wọ́n bá gbà pẹ̀lú ìpinnu tí ìjọ ṣe láti yọ èèyàn wọn náà lẹ́gbẹ́. Julian sọ pé: “Kì í ṣe pé mo kọ̀ ọ́ lọ́mọ, àmọ́ ìgbésí ayé tó ń gbé ti pààlà sáàárín wa.”
Gbogbo àwọn ará ìjọ lè fi ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà hàn tí wọn kò bá jẹ́ kí ohunkóhun da àwọn àti ẹni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ pọ̀ tí wọ́n ò sì bá a sọ̀rọ̀. (1 Kọ́r. 5:11; 2 Jòh. 10, 11) Wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ kọ́wọ́ ti ìbáwí tí Jèhófà lo àwọn alàgbà láti fún onítọ̀hún. Bákan náà, wọ́n lè túbọ̀ fi ìfẹ́ hàn sáwọn ìdílé ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ kí wọ́n sì tì wọ́n lẹ́yìn, torí pé àwọn ìdílé náà á pín nínú ọgbẹ́ ọkàn tí ìyọlẹ́gbẹ́ náà fà, kò sì yẹ ká ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n rò pé àwọn náà ò láǹfààní láti bá àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ kẹ́gbẹ́.—Róòmù 12:13, 15.
Julian kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Ó dáa bí ètò ṣe wà láti máa yọ àwọn oníwà àìtọ́ lẹ́gbẹ́, ó ń jẹ́ ká lè máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò nígbèésí ayé wa. Láìka ẹ̀dùn ọkàn tó wà níbẹ̀ sí, bópẹ́ bóyá ó máa ń yọrí sí rere. Ká sọ pé mo fàyè gba ìwà ìbàjẹ́ tí ọmọ mi hù ni, kó ní yí pa dà láé.”