Gbígbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìyàsímímọ́ Wa “Lati Ọjọ́ Dé Ọjọ́”
“Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀ kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ lati ọjọ́ dé ọjọ́ kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.”—LUKU 9:23, NW.
1. Kí ni ọ̀na kan tí a lè gbà díwọ̀n àṣeyọrí wa gẹ́gẹ́ bí Kristian?
“ÀWA ha jẹ́ olùfọkànsìn níti tòótọ́ bí?” Gẹ́gẹ́ bí John F. Kennedy, Ààrẹ karùndínlógójì ti United States ṣe sọ, ìdáhùn sí ìbéèrè yìí jẹ́ kókó abájọ kan fún dídíwọ̀n àṣeyọrí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní ipò ńláńlá lẹ́nu iṣẹ́ ọba. Bí a bá fún un ní ìjẹ́pàtàkì jíjinlẹ̀ ìbéèrè náà lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí dídán àṣeyọrí àwọn Kristian òjíṣẹ́ wò.
2. Báwo ni ìwé atúmọ̀ èdè kan ṣe túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìyàsímímọ́”?
2 Ṣùgbọ́n, kí ni ìyàsímímọ́? Ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary túmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìṣe tàbí ààtò ìyàsímímọ́ fún ọlọrun kan tàbí fún ìlò mímọ́ ọlọ́wọ̀,” “fífi jìn tàbí yíyà sọ́tọ̀ fún ète kan pàtó,” “ìfọkànsìn onífara-ẹni-rúbọ.” Ó dàbí ẹni pé John F. Kennedy ń lo ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tí ó túmọ̀ sí “ìfọkànsìn onífara-ẹni-rúbọ.” Fún Kristian kan, ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí ohun tí ó ju ìyẹn lọ.
3. Kí ni ìyàsímímọ́ Kristian?
3 Jesu Kristi wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀ kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Matteu 16:24, NW) Dídi ẹni tí a yà sọ́tọ̀ fún ìlò Ọlọrun kò wulẹ̀ wémọ́ ṣíṣe ìṣe ìjọsìn ní ọjọ́ Sunday tàbí nígbà tí a bá ń ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ibi ìjọsìn. Ó wémọ́ ọ̀nà ìgbésí-ayé ẹnì kan lódindi. Láti jẹ́ Kristian túmọ̀ sí láti sẹ ara ẹni tàbí láti fi nǹkan du ara ẹni nígbà tí a bá ń ṣiṣẹ́sin Ọlọrun náà tí Jesu Kristi ṣiṣẹ́sìn, Jehofa. Ní àfikún síi, Kristian kan ń gbé “òpó igi oró” rẹ̀ nípa fífàyà rán an lábẹ́ ìjìyà èyíkéyìí tí a lè fi jẹ ẹ́ nítorí jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi.
Àpẹẹrẹ Pípé
4. Kí ni ìrìbọmi Jesu dúró fún?
4 Nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé, Jesu fi ohun tí yíya ara ẹni sí mímọ́ fún Jehofa ní nínú hàn. Àwọn ìrònú ìmọ̀lára rẹ̀ ni pé: “Ẹbọ ati ọrẹ-ẹbọ iwọ kò fẹ́, ṣugbọn iwọ pèsè ara kan fún mi.” Nígbà náà ni ó fikún un pé: “Wò ó! Mo dé (ninu àkájọ ìwé ni a gbé kọ ọ́ nipa mi) lati ṣe ìfẹ́-inú rẹ, Óò Ọlọrun.” (Heberu 10:5-7, NW) Gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ḿbà orílẹ̀-èdè kan tí a ti yà sí mímọ́, a yà á sí mímọ́ fún Jehofa nígbà tí a bí i. Síbẹ̀, nígbà ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, ó yọ̀ọ̀da ara rẹ̀ fún ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fífi ara rẹ̀ lélẹ̀ láti ṣe ìfẹ́-inú Jehofa, èyí tí ó jẹ́ pé níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ yóò ní nínú fífi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà. Nípa bẹ́ẹ̀ ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn Kristian láti ṣe ohunkóhun yòówù tí ó bá jẹ́ ìfẹ́-inú Jehofa.
5. Báwo ni Jesu ṣe fi ojú-ìwòye àwòfiṣàpẹẹrẹ níti àwọn ohun-ìní ti ara hàn?
5 Lẹ́yìn ìrìbọmi rẹ̀ Jesu rin ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé kan tí ó yọrí sí ikú ìfara-ẹni-rúbọ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Kò ní ọkàn-ìfẹ́ nínú wíwá owó kiri tàbí gbígbé ìgbésí-ayé oníyọ̀tọ̀mì. Kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ni ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí-ayé rẹ̀. Ó rọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti “máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba naa ati òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́,” òun fúnra rẹ̀ sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. (Matteu 6:33, NW) Họ́wù, ó tilẹ̀ sọ nígbà kan pé: “Awọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò ibùgbé awọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣugbọn Ọmọkùnrin ènìyàn kò ní ibi kankan lati gbé orí rẹ̀ lé.” (Matteu 8:20, NW) Òun ìbá ti dọ́gbọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ láti lè lọ́ owó gbà mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́. Níti pé ó jẹ́ káfíńtà òun ìbá ti gba àyè kúrò lẹ́nu iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ láti ṣe ohun ọ̀ṣọ́-ilé rèterète kan fún títà kí ó baà lè rí àfikún owó fàdákà díẹ̀. Ṣùgbọ́n kò lo òye-iṣẹ́ rẹ̀ láti wa aásìkí nípa ti ara. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọrun tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́, àwa ha ń ṣàfarawé Jesu nípa níní ojú-ìwòye tí ó tọ́ nípa àwọn ohun-ìní ti ara?—Matteu 6:24-34.
6. Báwo ni a ṣe lè ṣàfarawé Jesu nípa jíjẹ́ ìránṣẹ́ onífara-ẹni-rúbọ, olùṣèyàsímímọ́ fún Ọlọrun?
6 Jesu kò wá ire ti ara rẹ̀, nínú fífi iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ sí Ọlọrun sí ipò àkọ́kọ́. Ìgbésí-ayé rẹ̀ láàárín ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ tí iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn jẹ́ ti onífara-ẹni-rúbọ. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan lẹ́yìn ọjọ́ kan tí ó kún fún iṣẹ́, láì tilẹ̀ rí àyè jẹun, Jesu múratán láti kọ́ àwọn ènìyàn tí ‘a bó láwọ tí a sì fọ́n ká bí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn.’ (Matteu 9:36, NW; Marku 6:31-34) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘ó ti rẹ̀ ẹ́ lati inú ìrìn-àjò naa,’ ó lo ọgbọ́n àtinúdá láti bá obìnrin ará Samaria kan tí ó wá síbi ìsun omi Jekọbu ní Sikari sọ̀rọ̀. (Johannu 4:6, 7, 13-15, NW) Nígbà gbogbo ni ó máa ń fi ire ti àwọn ẹlòmíràn ṣáájú ti ara rẹ̀. (Johannu 11:5-15) A lè ṣàfarawé Jesu nípa fífi pẹ̀lú ọ̀làwọ́ fi ire tiwa rúbọ láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun àti àwọn ẹlòmíràn. (Johannu 6:38) Nípa ríronú nípa bí a ṣe lè tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn níti tòótọ́ dípò kí a ṣe kìkì ohun kíkéré jù tí a béèrè fún, àwa yóò máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa.
7. Báwo ni a ṣe lè ṣàfarawé Jesu nípa fífi ọlá fún Jehofa nígbà gbogbo?
7 Jesu kò fẹ́ lọ́nàkọnà láti gbìyànjú láti darí àfiyèsí sí ara rẹ̀ nípa ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́. Ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọrun láti ṣe ìfẹ́-inú Rẹ̀. Nítorí náà nígbà gbogbo ni ó máa ń rí i dájú pé Jehofa, Bàbá òun, gba gbogbo ògo fún ohunkóhun yòówù tí òun bá ṣe àṣeparí rẹ̀. Nígbà tí alákòóso kan báyìí pè é ni “Olukọ Rere,” ní lílo ọ̀rọ̀ náà “rere” gẹ́gẹ́ bí orúkọ oyè, Jesu tọ́ ọ sọ́nà nípa sísọ pé: “Kò sí ẹni tí ó jẹ́ rere, àyàfi ẹni kan, Ọlọrun.” (Luku 18:18, 19, NW; Johannu 5:19, 30) Bíi ti Jesu, àwa ha ń tètè darí ọlá kúrò lọ́dọ̀ ara wa sọ́dọ̀ Jehofa bí?
8. (a) Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin olùṣèyàsímímọ́, báwo ní Jesu ṣe ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé? (b) Báwo ni a ṣe níláti ṣàfarawé rẹ̀?
8 Jálẹ̀ ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ̀ tí ó yàsímímọ́ lórí ilẹ̀-ayé, Jesu fi hàn pé òun ti ya ara òun sọ́tọ̀ fún iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun. Ó pa ara rẹ̀ mọ́ ní mímọ́ tónítóní kí ó baà lè fi ara rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí “ọ̀dọ́ àgùtàn aláìlábààwọ́n ati aláìléèérí” láti jẹ́ ẹbọ ìràpadà. (1 Peteru 1:19, NW; Heberu 7:26) Ó kíyèsí gbogbo ìlànà Òfin Mose, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú Òfin yẹn ṣẹ. (Matteu 5:17; 2 Korinti 1:20) Ó gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tirẹ̀ lórí ìwàhíhù. (Matteu 5:27, 28) Kò sí ẹnì kankan tí ó lè fi ẹ̀sùn kàn án lọ́nà títọ́ pé ó ní àwọn ète ìsúnniṣe búburú. Níti tòótọ́, ó “kórìíra ìwà-àìlófin.” (Heberu 1:9, NW) Gẹ́gẹ́ bí ẹrú Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí a ṣàfarawé Jesu ní pípa ìgbésí-ayé wa àti àwọn ète ìsúnniṣe wa pàápàá mọ́ ní mímọ́ tónítóní ní ojú Jehofa.
Àwọn Àpẹẹrẹ Ìkìlọ̀
9. Àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ wo ní Paulu tọka sí, èésìtiṣe tí a fi níláti gbé àpẹẹrẹ yìí yẹ̀wò?
9 Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àpẹẹrẹ Jesu, a ní àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ ti àwọn ọmọ Israeli. Àní lẹ́yìn tí wọ́n ti polongo pé àwọn yóò ṣe gbogbo ohun tí Jehofa ti sọ fún wọn láti ṣe, wọ́n kùnà láti ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. (Danieli 9:11) Aposteli Paulu gba àwọn Kristian níyànjú láti kọ́ ẹ̀kọ́ lára ohun tí ó ṣubú tẹ àwọn ọmọ Israeli. Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mélòókan tí Paulu tọ́ka sí nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Korinti kí a sì rí àwọn ọ̀fìn tí ó yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun tí wọ́n ti ṣèyàsímímọ́ ní ọjọ́ tiwa yẹra fún.—1 Korinti 10:1-6, 11.
10. (a) Báwo ni àwọn ọmọ Israeli ṣe ‘ní ọkàn-ìfẹ́ sí àwọn ohun aṣeniléṣe’? (b) Èéṣe tí a fi mú kí àwọn ọmọ Israeli jíhìn nígbà tí wọ́n kùn lẹ́ẹ̀kejì nípa oúnjẹ, kí ni a sì lè kọ́ láti inú àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ yìí?
10 Lákọ̀ọ́kọ́, Paulu kìlọ̀ fún wa láti máṣe “ní ìfẹ́-ọkàn sí awọn ohun aṣeniléṣe.” (1 Korinti 10:6, NW) Ìyẹn lè rán ọ létí nípa àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà nígbà tí àwọn ọmọ Israeli ráhùn nípa níní kìkì manna láti jẹ. Jehofa fi àparò ránṣẹ́ sí wọn. Ohun kan tí ó farajọ ọ́ ti ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọdún kan ṣáájú nínú aginjù Sini, gẹ́rẹ́ ṣáájú kí àwọn ọmọ Israeli tó polongo ìyàsímímọ́ wọn fún Jehofa. (Eksodu 16:1-3, 12, 13) Ṣùgbọ́n ipò ọ̀ràn náà kò rí bákan náà. Nígbà tí Jehofa pèsè àparò nígbà àkọ́kọ́, òun kò késí àwọn ọmọ Israeli láti jíhìn fún kíkùn tí wọ́n kùn. Ṣùgbọ́n, lọ́tẹ̀ yìí, ipò nǹkan yàtọ̀. “Ẹran náà sì ń bẹ láàárín eyín wọn, kí wọn kí ó tó jẹ ẹ́, ìbínú OLUWA sì ru sí àwọn ènìyàn náà, OLUWA sì fi àrùn ńlá gidigidi kọlu àwọn ènìyàn náà.” (Numeri 11:4-6, 31-34) Kí ni ó ti yípadà? Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan tí a ti yàsímímọ́, nísinsìnyí a mú kí wọ́n jíhìn fún ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé. Àìní ìmọrírì wọn fún àwọn ìpèsè Jehofa sún wọn láti ráhùn nípa Jehofa, láìka ìlérí tí wọ́n ti ṣe láti máa ṣe gbogbo ohun tí Jehofa ti sọ sí! Ríráhùn nípa tábìlì Jehofa lónìí rí bákan náà. Àwọn kan kùnà láti mọrírì àwọn ìpèsè tẹ̀mí ti Jehofa nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ ati ọlọgbọ́n-inú ẹrú.” (Matteu 24:45-47, NW) Bí ó ti wù kí ó rí, rántí pé ìyàsímímọ́ wa ń béèrè lọ́wọ́ wa láti fi tìmoore-tìmoore fi àwọn ohun tí Jehofa ti ṣe fún wa sọ́kàn kí a sì tẹ́wọ́gba oúnjẹ tẹ̀mí tí Jehofa ń pèsè.
11. (a) Báwo ni àwọn ọmọ Israeli ṣe fi ìbọ̀rìṣà ba ìjọ́sìn wọn sí Jehofa jẹ́? (b) Báwo ni irú ìbọ̀rìṣà kan ṣe lè nípa ìdarí lórí wa?
11 Tẹ̀lé èyí, Paulu kìlọ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máṣe di abọ̀rìṣà, bí awọn kan ninu wọn ti ṣe.” (1 Korinti 10:7, NW) Lórí ìpìlẹ̀ àwọn ẹ̀rí tí ó rí aposteli náà níhìn-ín ń tọ́ka sí ìjọsìn ọmọ màlúù tí ó wáyé kété lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israeli ti parí májẹ̀mú pẹ̀lú Jehofa ní Òkè Sinai. Ìwọ lè sọ pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí olùṣèyàsímímọ́ ìránṣẹ́ Jehofa, èmi kò jẹ́ lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà láé.’ Bí ó ti wù kí ó rí, kíyèsí i pé lójú-ìwòye àwọn ọmọ Israeli, wọn kò ṣíwọ́ láti máa jọ́sìn Jehofa; síbẹ̀, wọ́n mú àṣà ìjọ́sìn ọmọ màlúù wọlé—ohun kan tí ó jẹ́ ìríra sí Ọlọrun. Kí ni ohun tí irú ìjọ́sìn báyìí ní nínú? Àwọn ènìyàn náà ṣe ìrúbọ níwájú ọmọ màlúù, nígbà náà ni wọ́n “sì jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣiré.” (Eksodu 32:4-6) Lónìí, àwọn kan lè jẹ́wọ́ pé àwọn ń jọ́sìn Jehofa. Ṣùgbọ́n ó lè jẹ́ pé orí ìgbádùn àwọn nǹkan tí ń bẹ nínú ayé yìí ni wọ́n gbé ìgbésí-ayé wọn kà, tí kì í sì í ṣe ìjọsìn Jehofa, tí wọn a sì máa gbìyànjú láti fi iṣẹ́-ìsìn wọn sí Jehofa há sáàárín ìwọ̀nyí. Lóòótọ́, èyí kò tí ì lọ jìnnà tó títẹríba fún ère ọmọ màlúù oníwúrà, ṣùgbọ́n nínú ìlànà kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Sísọ ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́-ọkàn ẹni di ọlọrun jìnnà fíìfíì sí gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ ẹni fún Jehofa.—Filippi 3:19.
12. Láti inú ìrírí àwọn ọmọ Israeli pẹ̀lú Baali Peoru, kí ni a rí kọ́ nípa sísẹ́ ara wa?
12 Àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ tí Paulu mẹ́nukàn tún wémọ́ irú eré ìnàjú kan. “Bẹ́ẹ̀ ni kí a máṣe fi àgbèrè ṣèwàhù, bí awọn kan ninu wọ́n ti ṣe àgbèrè, kìkì lati ṣubú, ẹgbẹ̀rún mẹ́tà-lé-lógún ninu wọn ní ọjọ́ kanṣoṣo.” (1 Korinti 10:8, NW) Àwọn ọmọ Israeli, tí adùn ìwà pálapàla tí àwọn ọmọbìnrin Moabu nawọ́ rẹ̀ fà mọ́ra, ni a sún láti máa jọ́sìn Baali Peoru ní Ṣittimu. (Numeri 25:1-3, 9) Sísẹ́ ara wa láti ṣe ìfẹ́-inú Jehofa wémọ́ títẹ́wọ́gba ọ̀pá-ìdiwọ̀n rẹ̀ fún ohun tí ó bá dára níti ìwàhíhù. (Matteu 5:27-30) Nínú sànmánì tí ọ̀pá-ìdiwọ̀n ti ń jórẹ̀hìn yìí, a rán wa létí nípa àìní náà láti máa pa ara wa mọ́ ní mímọ́ tónítóní kúrò nínú onírúurú ìwà pálapàla, ní jíjọ̀wọ́ ara wa fún ọlá-àṣẹ Jehofa láti pinnu ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú.—1 Korinti 6:9-11.
13. Báwo ni àpẹẹrẹ Finehasi ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ìyàsímímọ́ fún Jehofa ní nínú?
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ kó sínú páńpẹ́ panṣágà ní Ṣittimu, àwọn kan gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ orílẹ̀-èdè wọn fún Jehofa. Lára wọn, ìtara Finehasi tayọlọ́lá. Nígbà tí ó tajúkán rí ọmọ olórí-ẹ̀yà Israeli kan tí ń mú ará Midiani kan wọ inú àgọ́, lójú ẹsẹ̀ Finehasi fa ọ̀kọ̀ kan yọ ó sì gún wọn ní àgúnyọ. Jehofa sọ fún Mose pé: “Finehasi . . . ti yí ìrunú mi padà kúrò lórí àwọn ọmọ Israeli, nítìtorí àìkò fàyègba ìbániṣorogún rárá síhà ọ̀dọ̀ mi láàárín wọn, kí èmi kí ó máṣe run àwọn ọmọ Israeli nínú ìrinkinkin mi mọ́ ìfọkànsìn tí a yàsọ́tọ̀ gédégbé.” (Numeri 25:11, NW) Àìkò fàyègba ìbániṣorogún rárá níhà ọ̀dọ̀ Jehofa—ohun tí ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí nìyẹn. A kò lè gba ohunkóhun láyè láti gba ipò tí ó yẹ kí ìyàsímímọ́ wa fún Jehofa gbà nínú ọkàn-àyà wa. Ìtara wa fún Jehofa pẹ̀lú ń sún wa láti mú kí ìjọ wà ní mímọ́ tónítóní nípa fífi ẹ̀sùn ìwà pálapàla gbígbópọn tó àwọn alàgbà létí, kì í ṣe kí a fàyègbà á.
14. (a) Báwo ni àwọn ọmọ Israeli ṣe dán Jehofa wò? (b) Báwo ni ìyàsímímọ́ pátápátá fún Jehofa ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti máṣe “juwọ́sílẹ̀”?
14 Paulu tọ́ka sí àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ mìíràn: “Bẹ́ẹ̀ ni kí a máṣe dán Jehofa wò, bí awọn kan ninu wọ́n ti dán an wò, kìkì lati ṣègbé nípasẹ̀ awọn ejò.” (1 Korinti 10:9, NW) Níhìn-ín Paulu ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò náà nígbà tí àwọn ọmọ Israeli ráhùn nípa Ọlọrun fún Mose nígbà tí ‘sùúrù tán wọn púpọ̀púpọ̀ nítorí ọ̀nà náà.’ (Numeri 21:4) Ìwọ ha ti ṣe irú àṣìṣe yẹn rí bí? Nígbà tí o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jehofa, ìwọ ha rò pé Armageddoni ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán? Sùúrù Jehofa ha ti ń pẹ́ ju bí o ṣe rò lọ bí? Rántí pé, a kò ya ara wa sí mímọ́ fún Jehofa fún kìkì sáà àkókò kan tàbí kìkì títí di Armageddoni. Ìyàsímímọ́ wa ń bá a nìṣó títí láéláé. Nígbà náà, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, “ẹ máṣe jẹ́ kí a juwọ́sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nitori ní àsìkò yíyẹ awa yoo kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—Galatia 6:9, NW.
15. (a) Àwọn wo ni àwọn ọmọ Israeli kùn sí? (b) Báwo ni ìyàsímímọ́ wa fún Jehofa ṣe lè sún wa láti bọ̀wọ̀ fún ọlá-àṣẹ ìṣàkóso Ọlọrun?
15 Lákòótán, Paulu kìlọ̀ nípa dídi “oníkùnsínú” sí àwọn ìránṣẹ́ tí Jehofa yànsípò. (1 Korinti 10:10, NW) Àwọn ọmọ Israeli kùn yunmuyunmu mọ́ Mose àti Aaroni nígbà tí 10 lára àwọn amí 12 tí a rán lọ sí ilẹ̀ Kenaani mú ìròyìn búburú wá. Wọ́n tilẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa fífi aṣáájú mìíràn rọ́pò Mose kí wọ́n sì padà lọ sí Egipti. (Numeri 14:1-4) Lónìí, a ha ń tẹ́wọ́gba ipò orí tí a fi fún wa nípasẹ̀ ìgbésẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Jehofa bí? Ní rírí tábìlì tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ tí a tipasẹ̀ ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú pèsè, àwọn ẹni tí Jesu ń lò láti fún wa ní ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu’ farahàn gbangba. (Matteu 24:45, NW) Ìyàsímímọ́ tọkàntọkàn fún Jehofa ń béèrè pé kí a fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó yànsípò. Ǹjẹ́ kí a máṣe dàbí àwọn oníkùnsínú kan ní òde-òní tí wọ́n ti yíjú sí orí mìíràn, láti sìn wọn lọ sínú ayé, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀.
Gbogbo Ohun Tí Mo Lè Ṣe Ha Ni Mo Ń Ṣe Bí?
16. Àwọn ìbéèrè wo ni àwọn ìránṣẹ́ olùṣèyàsímímọ́ fún Ọlọrun lè fẹ́ láti bi ara wọn?
16 Àwọn ọmọ Israeli kì bá tí ṣubú sínú irú àṣìṣe búburú jáì bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá ti rántí pé ìyàsímímọ́ wọn fún Jehofa kò ní ipò-àfilélẹ̀. Láìdàbí àwọn ọmọ Israeli aláìnígbàgbọ́ wọ̀nyẹn, Jesu Kristi gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ rẹ̀ títí dé òpin. Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi, a ń ṣàfarawé àpẹẹrẹ ti ìfọkànsìn tọkàntọkàn rẹ̀, ní gbígbé ìgbésí-ayé wa “kì í tún ṣe fún ìfẹ́-ọkàn ènìyàn mọ́, bíkòṣe fún ìfẹ́-inú Ọlọrun.” (1 Peteru 4:2, NW; fiwé 2 Korinti 5:15.) Ìfẹ́-inú Jehofa lónìí ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọn sì wá sí ìmọ̀ pípéye nipa òtítọ́.” (1 Timoteu 2:4, NW) Pẹ̀lú ète ìlépa yẹn, a níláti wàásù “ìhìnrere ìjọba yii” ṣáájú kí òpin tó dé. (Matteu 24:14, NW) Báwo ni ìsapá tí a ń lò nínú isẹ́-ìsìn yìí ti pọ̀ tó? A lè fẹ́ láti bi ara wa pé, ‘Gbogbo ohun ti mo lè ṣe ha ni mo ń ṣe bí?’ (2 Timoteu 2:15) Àwọn àyíká ipò máa ń yàtọ̀ síra. Ó máa ń dùnmọ́ Jehofa nínú pé kí a ṣiṣẹ́sìn ín “ní ìbámu pẹlu ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹlu ohun tí ènìyàn kò ní.” (2 Korinti 8:12, NW; Luku 21:1-4) Ẹnikẹ́ni kò níláti ṣèdájọ́ bí ìyàsímímọ́ ẹlòmíràn ṣe jinlẹ̀ tí ó sì jẹ́ pẹ̀lú òtítọ́-inú tó. Ẹnìkọ̀ọ̀kan níláti fúnra rẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìfọkànsìn tòun fún Jehofa ṣe lọ jìnnà tó. (Galatia 6:4) Ìfẹ́ wa fún Jehofa níláti sún wa láti béèrè pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè mú inú Jehofa dùn?’
17. Ìbátan wo ni ó wà láàárín ìfọkànsìn àti ìmọrírì? Ṣàkàwé.
17 Ìfọkànsìn wa sí Jehofa túbọ̀ ń jinlẹ̀ bí a ṣe ń dàgbà síi nínú ìmọrírì wa fún un. Ọ̀dọ́mọdékùnrin ọlọ́dún 14 kan ní Japan ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa ó sì fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ yìí hàn nípa ìrìbọmi nínú omi. Lẹ́yìn náà, ó fẹ́ láti lépa ẹ̀kọ́-ìwé gíga kí ó baà lè di onímọ̀-ìjìnlẹ̀. Kò fìgbà kan ronú nípa iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún rí, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tí ó ti ṣèyàsímímọ́, kò fẹ́ láti fi Jehofa àti ètò-àjọ rẹ̀ tí a lè fojúrí sílẹ̀. Láti lé góńgó iṣẹ́ ìgbésí-ayé rẹ̀ bá, ó lọ sí yunifásítì. Níbẹ̀ ni o ti rí àwọn tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́yege ní yunifásítì tí a ti fipá mú láti ya ìgbésí-ayé wọn látòkèdélẹ̀ sí mímọ́ fún ilé-iṣẹ́ wọn tàbí fún ẹ̀kọ́ wọn. Ó ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ni mo ń ṣe níhìn-ín? Mo ha lè lépa ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn kí n sì ya ara mi sí mímọ́ fún iṣẹ́ oúnjẹ-òòjọ́ bí? Èmi kò ha ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jehofa ṣáájú bí?’ Pẹ̀lú ìmọrírì tí a mú sọjí, ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Òye rẹ̀ nípa ìyàsímímọ́ rẹ̀ jinlẹ̀ síi ó sì sún un láti ṣe ìpinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀ láti lọ sí ibikíbi tí a bá ti nílò rẹ̀. Ó lọ sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ ó sì tẹ́wọ́gba iṣẹ́-àyànfúnni láti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní òkè-òkun.
18. (a) Kí ni àwọn ohun tí ó wémọ́ ìyàsímímọ́ wa fún Jehofa? (b) Kí ni èrè tí àwa yóò ká láti inú ìyàsímímọ́ wa fún Jehofa?
18 Ìyàsímímọ́ wémọ́ ìgbésí-ayé wa lódindi. A gbọ́dọ̀ sẹ́ ara wa kí a sì máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere ti Jesu “lati ọjọ́ dé ọjọ́.” (Luku 9:23, NW) Lẹ́yìn tí a bá ti sẹ́ ara wa, a kò níláti béèrè ìyọ̀ǹda àkókò dákun-èmi-ò-ní-sí-nílé, ìyọ̀ǹda àkókò họlidé lọ́wọ́ Jehofa. Ìgbésí-ayé wa rọ̀ mọ́ ìlànà tí Jehofa fi lélẹ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àní ní àwọn agbègbè tí a ti lè dá ṣe yíyàn pàápàá, àwa yóò ṣe dáradára láti yiiri rẹ̀ wò bóyá àwa ń ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti lè gbé ìgbésí-ayé tí a yà sí mímọ́ fún Jehofa. Bí a ti ń ṣiṣẹ́sìn ín láti ọjọ́ dé ọjọ́, tí a ń ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti lè mú inú rẹ̀ dùn, àwa yóò ṣàṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí Kristian a óò sì bùkún wa pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ onítẹ̀ẹ́wọ́gbà láti ọ̀dọ̀ Jehofa, Ẹni náà tí ó yẹ fún ìfọkànsìn tọkàntọkàn wa.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Kí ni ohun tí ìyàsímímọ́ ní nínú fún Jesu Kristi?
◻ Èéṣe tí a fi níláti yẹra fún kíkùn sí Jehofa?
◻ Ní ọ̀nà wo ni a lè gbà yẹra fún jíjẹ́ kí ìbọ̀rìṣà yọ́kẹ́lẹ́ wọ inú ìgbésí-ayé wa?
◻ Kí ni a lè máa rántí tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máṣe “juwọ́sílẹ̀” ní ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn Kristian olùṣèyàsímímọ́ ‘kì í juwọ́sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára’