Àkọsílẹ̀ Jòhánù
4 Nígbà tí Olúwa mọ̀ pé àwọn Farisí ti gbọ́ pé àwọn tí Jésù ń sọ di ọmọ ẹ̀yìn, tó sì ń ṣèrìbọmi+ fún pọ̀ ju ti Jòhánù lọ— 2 bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù fúnra rẹ̀ kọ́ ló ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni— 3 ó kúrò ní Jùdíà, ó sì tún lọ sí Gálílì. 4 Àmọ́ ó pọn dandan pé kó gba Samáríà kọjá. 5 Ó wá dé ìlú kan ní Samáríà tí wọ́n ń pè ní Síkárì, nítòsí pápá tí Jékọ́bù fún Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀.+ 6 Kódà, kànga Jékọ́bù wà níbẹ̀.+ Àmọ́ ìrìn àjò náà ti mú kó rẹ Jésù, torí náà, ó jókòó síbi kànga* náà. Ó jẹ́ nǹkan bíi wákàtí kẹfà.*
7 Obìnrin ará Samáríà kan wá fa omi. Jésù sọ fún un pé: “Fún mi lómi mu.” 8 (Torí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sínú ìlú láti ra oúnjẹ.) 9 Obìnrin ará Samáríà náà wá sọ fún un pé: “Báwo ni ìwọ, tí o jẹ́ Júù, ṣe máa ní kí èmi, obìnrin ará Samáríà fún ọ lómi?” (Torí àwọn Júù kì í ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ará Samáríà.)+ 10 Jésù dá a lóhùn pé: “Ká ní o mọ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run+ ni, tí o sì mọ ẹni tó sọ fún ọ pé, ‘Fún mi lómi mu,’ ṣe lò bá bi í, ì bá sì ti fún ọ ní omi ìyè.”+ 11 Obìnrin náà sọ fún un pé: “Ọ̀gá, o ò tiẹ̀ ní korobá tí o máa fi fa omi, kànga náà sì jìn. Ibo lo ti wá fẹ́ rí omi ìyè yìí? 12 O ò tóbi ju Jékọ́bù baba ńlá wa lọ, ẹni tó fún wa ní kànga náà, tí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹran rẹ̀ mu nínú rẹ̀, àbí o tóbi jù ú lọ?” 13 Jésù dá a lóhùn pé: “Gbogbo ẹni tó bá ń mu látinú omi yìí, òùngbẹ tún máa gbẹ ẹ́. 14 Ẹnikẹ́ni tó bá mu látinú omi tí màá fún un, òùngbẹ ò ní gbẹ ẹ́ láé,+ àmọ́ omi tí màá fún un á di ìsun omi nínú rẹ̀, á sì máa tú yàà jáde láti fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun.”+ 15 Obìnrin náà sọ fún un pé: “Ọ̀gá, fún mi ní omi yìí, kí òùngbẹ má bàa gbẹ mí, kí n má sì máa wá síbí yìí láti fa omi.”
16 Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ẹ sì wá síbí yìí.” 17 Obìnrin náà fèsì pé: “Mi ò ní ọkọ.” Jésù sọ fún un pé: “Òótọ́ lo sọ, bí o ṣe sọ pé, ‘Mi ò ní ọkọ.’ 18 Torí o ti ní ọkọ márùn-ún rí, ọkùnrin tí o sì ń fẹ́ báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Òótọ́ lohun tí o sọ yìí.” 19 Obìnrin náà sọ fún un pé: “Ọ̀gá, mo rí i pé wòlíì ni ọ́.+ 20 Orí òkè yìí ni àwọn baba ńlá wa ti jọ́sìn, àmọ́ ẹ̀yin sọ pé Jerúsálẹ́mù ni àwọn èèyàn ti gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn.”+ 21 Jésù sọ fún un pé: “Gbà mí gbọ́, obìnrin yìí, wákàtí náà ń bọ̀ tí ẹ ò ní máa jọ́sìn Baba lórí òkè yìí tàbí ní Jerúsálẹ́mù. 22 Ẹ̀ ń jọ́sìn ohun tí ẹ ò mọ̀;+ àwa ń jọ́sìn ohun tí a mọ̀, torí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ni ìgbàlà ti bẹ̀rẹ̀.+ 23 Síbẹ̀, wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ á máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, torí ní tòótọ́, irú àwọn ẹni yìí ni Baba ń wá pé kí wọ́n máa jọ́sìn òun.+ 24 Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,+ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”+ 25 Obìnrin náà sọ fún un pé: “Mo mọ̀ pé Mèsáyà ń bọ̀, ẹni tí wọ́n ń pè ní Kristi. Nígbàkigbà tí ẹni yẹn bá dé, ó máa sọ gbogbo nǹkan fún wa ní gbangba.” 26 Jésù sọ fún un pé: “Èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni ẹni náà.”+
27 Ìgbà yẹn ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ó sì yà wọ́n lẹ́nu pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀. Lóòótọ́, kò sẹ́ni tó sọ pé: “Kí lò ń wá?” tàbí “Kí ló dé tó ò ń bá obìnrin náà sọ̀rọ̀?” 28 Torí náà, obìnrin náà fi ìṣà omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sínú ìlú, ó sì sọ fún àwọn èèyàn pé: 29 “Ẹ wá wo ọkùnrin kan tó sọ gbogbo ohun tí mo ṣe fún mi. Ṣé kì í ṣe pé òun ni Kristi?” 30 Wọ́n wá kúrò nínú ìlú, wọ́n sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.
31 Ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń rọ̀ ọ́, pé: “Rábì,+ jẹun.” 32 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Mo ní oúnjẹ tí màá jẹ tí ẹ ò mọ̀ nípa rẹ̀.” 33 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ láàárín ara wọn pé: “Ẹnì kankan ò gbé oúnjẹ wá fún un, àbí?” 34 Jésù sọ fún wọn pé: “Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi,+ kí n sì parí iṣẹ́ rẹ̀.+ 35 Ṣebí ẹ sọ pé ó ṣì ku oṣù mẹ́rin kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀? Ẹ wò ó! Mò ń sọ fún yín pé: Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun, wọ́n ti tó kórè.+ Ní báyìí, 36 olùkórè ti ń gba èrè, ó sì ń kó èso jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun, kí afúnrúgbìn àti olùkórè lè jọ yọ̀.+ 37 Lórí ọ̀rọ̀ yìí, òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà pé: Ẹnì kan ni afúnrúgbìn, ẹlòmíì sì ni olùkórè. 38 Mo rán yín pé kí ẹ lọ kórè ohun tí ẹ ò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíì ti ṣiṣẹ́, ẹ sì ti wọlé láti jàǹfààní iṣẹ́ wọn.”
39 Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà láti ìlú yẹn gbà á gbọ́ torí ọ̀rọ̀ obìnrin tó jẹ́rìí sí i pé: “Gbogbo ohun tí mo ṣe ló sọ fún mi.”+ 40 Torí náà, nígbà tí àwọn ará Samáríà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ní kó dúró sọ́dọ̀ àwọn, ó sì dúró síbẹ̀ fún ọjọ́ méjì. 41 Torí èyí, àwọn tó gbà á gbọ́ pọ̀ sí i torí ohun tó sọ, 42 wọ́n sì sọ fún obìnrin náà pé: “Kì í ṣe ohun tí o sọ nìkan ló mú ká gbà gbọ́; torí àwa fúnra wa ti gbọ́, a sì mọ̀ pé olùgbàlà ayé ni ọkùnrin yìí lóòótọ́.”+
43 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì náà, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Gálílì. 44 Jésù fúnra rẹ̀ jẹ́rìí sí i pé wòlíì kì í gbayì ní ìlú rẹ̀.+ 45 Torí náà, nígbà tó dé Gálílì, àwọn ará Gálílì tẹ́wọ́ gbà á, torí pé wọ́n ti rí gbogbo ohun tó ṣe ní Jerúsálẹ́mù nígbà àjọyọ̀,+ torí àwọn náà lọ síbi àjọyọ̀ náà.+
46 Ó tún wá sí Kánà ti Gálílì, níbi tó ti sọ omi di wáìnì.+ Òṣìṣẹ́ ọba kan wà tí ọmọkùnrin rẹ̀ ń ṣàìsàn ní Kápánáúmù. 47 Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ pé Jésù ti kúrò ní Jùdíà wá sí Gálílì, ó lọ bá a, ó sì ní kó máa bọ̀ wá wo ọmọ òun sàn, torí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. 48 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Láìjẹ́ pé ẹ̀yin rí àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ ò ní gbà gbọ́ láé.”+ 49 Òṣìṣẹ́ ọba náà sọ fún un pé: “Olúwa, sọ̀ kalẹ̀ wá kí ọmọ mi kékeré tó kú.” 50 Jésù sọ fún un pé: “Máa lọ; ọmọ rẹ ti yè.”+ Ọkùnrin náà gba ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún un gbọ́, ó sì lọ. 51 Àmọ́ bó ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ, àwọn ẹrú rẹ̀ pàdé rẹ̀ kí wọ́n lè sọ fún un pé ọmọ rẹ̀ ti yè.* 52 Ó wá bi wọ́n nípa wákàtí tí ara rẹ̀ yá. Wọ́n dá a lóhùn pé: “Wákàtí keje* ni ibà náà fi í sílẹ̀ lánàá.” 53 Bàbá náà wá mọ̀ pé wákàtí yẹn gangan ni Jésù sọ fún òun pé: “Ọmọ rẹ ti yè.”+ Torí náà, òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ gbà á gbọ́. 54 Iṣẹ́ àmì kejì+ tí Jésù ṣe nìyí nígbà tó kúrò ní Jùdíà wá sí Gálílì.