ORÍ 30
“Máa Bá A Lọ ní Rírìn Nínú Ìfẹ́”
1-3. Kí ni yóò jẹ́ ìyọrísí rẹ̀ bá a bá ń fara wé àpẹẹrẹ Jèhófà nínú fífi ìfẹ́ hàn?
“AYỌ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí tẹnu mọ́ òtítọ́ pàtàkì náà pé: Ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan ní èrè tirẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayọ̀ púpọ̀ wà nínú rírí ìfẹ́ gbà, ayọ̀ tó wà nínú fífúnni tàbí fífi ìfẹ́ hàn tún pọ̀ ju ti rírí i gbà lọ.
2 Kò sẹ́ni tó lóye òtítọ́ yìí tó Baba wa ọ̀run. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé láwọn àkòrí tó ṣáájú nínú ìsọ̀rí yìí, Jèhófà ni àpẹẹrẹ gíga jù lọ ní ti ká ní ìfẹ́. Kò sẹ́ni tó tíì fìfẹ́ hàn lọ́nà tó ga tó tirẹ̀ tàbí tó fìfẹ́ hàn fún sáà tó gùn tó tirẹ̀. Ṣé ẹ wá rí ìdí tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀”?—1 Tímótì 1:11.
3 Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ fẹ́ ká gbìyànjú láti dà bí òun, àgàgà nínú ọ̀ràn fífi ìfẹ́ hàn. Éfésù 5:1, 2 sọ fún wa pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.” Bá a bá fara wé àpẹẹrẹ Jèhófà nínú fífi ìfẹ́ hàn, a óò rí ayọ̀ púpọ̀ tó wà nínú fífúnni. Inú wa á tún dùn pé à ń múnú Jèhófà dùn, torí pé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé ká “nífẹ̀ẹ́ ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 13:8) Àmọ́ àwọn ìdí mìíràn wà tó fi yẹ ká “máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.”
Ìdí Tí Ìfẹ́ Fi Ṣe Kókó
4, 5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn sáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa?
4 Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa? Ní ṣókí, ìfẹ́ ni òpómúléró ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́. Láìsí ìfẹ́ a ò lè ní ìdè tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ò ní já mọ́ nǹkan kan lójú Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe tẹnu mọ́ òtítọ́ wọ̀nyí.
5 Ní alẹ́ tó gbẹ̀yìn ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Kíyè sí i pé ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín.” Bẹ́ẹ̀ ni o, irú ìfẹ́ tí Jésù fi hàn la pàṣẹ fún wa pé ká fi hàn. Ní Orí 29, a ṣàlàyé pé Jésù fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ nínú fífi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn. Ó jẹ́ kí àìní àti ire tàwọn ẹlòmíràn ká òun lára ju tara òun lọ. Àwa náà ní láti máa fi ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan hàn, a sì gbọ́dọ̀ fi í hàn gbangba-gbàǹgbà débi pé àwọn tó wà lóde ìjọ Kristẹni pàápàá á rí i pé à ń fi hàn lóòótọ́. Ní ti gidi, ìfẹ́ ará tó kún fún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ni àmì tí a fi ń dá wa mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi.
6, 7. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Jèhófà kò kóyán ìfẹ́ kéré rárá? (b) Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4-8 dá lé apá wo nínú ìfẹ́?
6 Bí ìfẹ́ ò bá sí nínú wa ńkọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí . . . èmi kò [bá] ní ìfẹ́, mo ti di abala idẹ kan tí ń dún tàbí aro aláriwo gooro.” (1 Kọ́ríńtì 13:1) Ńṣe ni aro aláriwo gooro máa ń hanni létí. Abala idẹ tí ń dún ńkọ́? Àwọn ìtumọ̀ mìíràn pè é ní “agogo tí ariwo rẹ̀ lè dini létí” tàbí “agogo tí ń dún lákọlákọ.” Àpèjúwe wọ̀nyí mà ṣe wẹ́kú o! Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ dà bí ohun èlò orin tí ń dún lákọlákọ, tó máa ń hanni létí, tó sì ń léni sá dípò kó fani mọ́ra. Báwo ni àárín irú ẹni bẹ́ẹ̀ àtàwọn ẹlòmíràn ṣe lè gún? Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: “Bí mo bá sì ní gbogbo ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè ńláńlá nípò padà, ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ nǹkan kan.” (1 Kọ́ríńtì 13:2) Àbí ẹ ò rí nǹkan, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ jẹ́ “aláìwúlò fún nǹkan kan,” láìka àwọn iṣẹ́ yòówù kí ó máa ṣe sí! (The Amplified Bible) Ǹjẹ́ kò ṣe kedere pé Ọ̀rọ̀ Jèhófà kò kóyán ìfẹ́ kéré rárá?
7 Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè fi ànímọ́ yìí hàn nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4-8. Ohun tí ẹsẹ wọ̀nyí ń sọ̀rọ̀ lé lórí gan-an kì í ṣe ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún wa tàbí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù dá lé ni bó ṣe yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sí ara wa. Ó ṣàpèjúwe àwọn nǹkan kan tí ìfẹ́ jẹ́, àtàwọn nǹkan kan tí kò jẹ́.
Ohun Tí Ìfẹ́ Jẹ́
8. Báwo ni ìpamọ́ra ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?
8 “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra.” Níní ìpamọ́ra túmọ̀ sí fífi sùúrù fara dà á fáwọn ẹlòmíràn. (Kólósè 3:13) Ǹjẹ́ a ò nílò irú ìfaradà bẹ́ẹ̀? Níwọ̀n bí a ti jẹ́ ẹ̀dá aláìpé tí ń sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, kò ní ṣàì máa ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé àwọn Kristẹni arákùnrin wa á ṣe ohun tó bí wa nínú, kí àwa náà sì ṣe ohun tó bí wọn nínú. Àmọ́ sùúrù àti ìfaradà lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbójú fo àwọn ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí àwọn ẹlòmíràn ṣe tó bí wa nínú—láìfi dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ.
9. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ṣe inú rere sáwọn ẹlòmíràn?
9 “Ìfẹ́ a máa ní . . . inú rere.” A máa ń ṣe inú rere nípa ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn ẹlòmíràn àti sísọ̀rọ̀ lọ́nà ìgbatẹnirò. Ìfẹ́ máa ń sún wa láti wá ọ̀nà tá a lè gbà ṣe inú rere, pàápàá jù lọ sí àwọn tí àìní tiwọn pọ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àgbàlagbà tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lè dá wà, kí ó sì fẹ́ ẹni tá máa wá kí i láti fún un níṣìírí. Ìyá tó ń dá tọ́mọ tàbí arábìnrin tí àwọn kan nínú ilé rẹ̀ ń ṣe ẹ̀sìn mìíràn lè fẹ́ àwọn ìrànlọ́wọ́ kan. Ẹnì kan tí ń ṣàìsàn tàbí tó wà nínú ìpọ́njú kan lè fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú látẹnu ọ̀rẹ́ adúrótini lọ́jọ́ ìṣòro. (Òwe 12:25; 17:17) Bí a bá gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe inú rere ní irú àwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé ojúlówó ìfẹ́ la ní lóòótọ́.—2 Kọ́ríńtì 8:8.
10. Báwo ni ìfẹ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ òtítọ́, ká sì máa sọ òtítọ́, kódà nígbà tí kò bá rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀?
10 “Ìfẹ́ . . . a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.” Ìtumọ̀ mìíràn sọ pé: “Ìfẹ́ . . . a máa fi tayọ̀tayọ̀ gbè sẹ́yìn òtítọ́.” Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká rọ̀ mọ́ òtítọ́, ká sì máa “bá ara [wa] sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì.” (Sekaráyà 8:16) Bí àpẹẹrẹ, bí èèyàn wa bá dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, ìfẹ́ fún Jèhófà, àti fún ẹlẹ́ṣẹ̀ náà, yóò jẹ́ ká rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run dípò ká máa gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀ tàbí ká máa wí àwíjàre tàbí ká tilẹ̀ máa purọ́ nípa ẹ̀ṣẹ̀ náà. Òótọ́ ni pé ọ̀rọ̀ náà lè bọ́ síbi tí kò dáa lára wa. Àmọ́ bí a bá ń fẹ́ kí ó dáa fún èèyàn wa ọ̀hún, a óò fẹ́ kí ó gba ìbáwí onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kí ó sì mú un lò. (Òwe 3:11, 12) A tún ń fẹ́ “láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo” nítorí pé Kristẹni onífẹ̀ẹ́ ni wá.—Hébérù 13:18.
11. Nítorí pé ìfẹ́ “a máa mú ohun gbogbo mọ́ra,” kí ló yẹ ká gbìyànjú láti ṣe nípa kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa?
11 “Ìfẹ́ . . . a máa mú ohun gbogbo mọ́ra.” Ohun tí gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí ní ṣáńgílítí ni pé “gbogbo nǹkan ni ó ń bò.” (Bíbélì Kingdom Interlinear) Ìwé 1 Pétérù 4:8 sọ pé: “Ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” Òdodo ọ̀rọ̀, nítorí pé Kristẹni tí ìfẹ́ ń darí kò ní máa wá ọ̀nà láti tú gbogbo àìpé àti kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ̀ síta. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn àṣìṣe àti àléébù àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kì í tó nǹkan, a sì lè rọra fi ìfẹ́ bò ó.—Òwe 10:12; 17:9.
12. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun gba ẹ̀rí Fílémónì jẹ́, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?
12 “Ìfẹ́ . . . a máa gba ohun gbogbo gbọ́.” Bíbélì Moffatt sọ pé ìfẹ́ “máa ń múra tán láti gba ẹ̀rí àwọn èèyàn jẹ́.” A kì í ní ìfura òdì sáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, kí ó jẹ́ pé gbogbo ìgbésẹ̀ tí wọ́n bá sáà ti gbé la óò máa kọminú sí. Ìfẹ́ ń jẹ́ ká ‘gba ẹ̀rí àwọn ará wa jẹ́,’ ká sì fọkàn tán wọn.a Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan tó wà nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí Fílémónì. Ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ lẹ́tà yìí ni láti rọ Fílémónì pé kí ó jọ̀wọ́ tẹ́wọ́ gba Ónésímù ìsáǹsá ẹrú rẹ̀ tó ti di Kristẹni báyìí, nígbà tó bá padà wálé. Kàkà kí Pọ́ọ̀lù ṣe é ní túláàsì fún Fílémónì, ńṣe ló fi tìfẹ́tìfẹ́ rọ̀ ọ́. Ó fi hàn pé ó dá òun lójú pé Fílémónì ò ní ṣàìṣe ohun tó tọ́, ó sọ pé: “Ní gbígbẹ́kẹ̀lé ìfohùnṣọ̀kan rẹ, mo ń kọ̀wé sí ọ, ní mímọ̀ pé ìwọ yóò tilẹ̀ ṣe ju àwọn ohun tí mo wí.” (Ẹsẹ 21) Nígbà tí ìfẹ́ bá sún wa fọkàn tán àwọn arákùnrin wa bẹ́ẹ̀, èyí á mú kí wọ́n túbọ̀ sa gbogbo ipá wọn.
13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìrètí pé àwọn ará wa ṣì ń bọ̀ wá ṣe dáadáa?
13 “Ìfẹ́ . . a máa retí ohun gbogbo.” Bí ìfẹ́ ṣe ń fọkàn tánni, bẹ́ẹ̀ náà ló kún fún ìrètí. Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká nírètí pé àwọn ará wa ṣì ń bọ̀ wá ṣe dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, bí arákùnrin kan bá “tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀,” a nírètí pé yóò tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ tá a fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe láti tọ́ ọ sọ́nà. (Gálátíà 6:1) A tún nírètí pé àwọn tí ẹsẹ̀ ìgbàgbọ́ wọ́n ń mì á túnra mú. A máa ń mú sùúrù fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, a sì máa ń sa gbogbo ipá wa láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọ́n tún lè fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Róòmù 15:1; 1 Tẹsalóníkà 5:14) Bí èèyàn wa kan bá tilẹ̀ ṣáko lọ, a kì í sọ̀rètí nù, a mọ̀ pé níjọ́ ọjọ́ kan orí rẹ̀ á pé wálé, á sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, bí ọmọ onínàákúnàá inú àkàwé Jésù.—Lúùkù 15:17, 18.
14. Àwọn ọ̀nà wo la ti lè dán ìfaradà wa wò nínú ìjọ, ìhà wo sì ni ìfẹ́ yóò mú ká kọ sí wọn?
14 “Ìfẹ́ . . . a máa fara da ohun gbogbo.” Ìfaradà máa ń jẹ́ ká lè dúró gbọn-in nígbà tí ìjákulẹ̀ tàbí ìṣòro bá dé. Kì í ṣe ọ̀dọ̀ àwọn ará ìta nìkan làwọn ohun tó ń dán ìfaradà wò ti ń wá. Nígbà mìíràn, a lè rí ìdánwò látinú ìjọ. Nítorí àìpé, àwọn ará lè já wa kulẹ̀ nígbà mìíràn. Ẹnì kan lè ṣèèṣì sọ̀rọ̀ kan, kó sì dùn wá gan-an. (Òwe 12:18) Ó sì lè jẹ́ pé nǹkan kan ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ tí a gbà pé wọn ò bójú tó dáadáa. Arákùnrin kan tó níyì lójú wa lè hu ìwà kan tó run wá nínú, ká wá máa rò ó pé: ‘Báwo lẹni tó pera rẹ̀ ní Kristẹni ṣe lè hu irú ìwà yẹn?’ Nígbà tá a bá bára wa nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ṣé a óò wá tìtorí ìyẹn sọ pé kí wọ́n máa fọwọ́ mú ìjọ wọn, ká sì ṣíwọ́ sísin Jèhófà? A ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ bá a bá ní ìfẹ́! Dájúdájú, ìfẹ́ kò ní jẹ́ ká tìtorí nǹkan kan tí arákùnrin kan ṣe tó kù díẹ̀ káàtó, ká wá dijú sí gbogbo ibi tí arákùnrin ọ̀hún dáa sí, tàbí ká wá máa fojú burúkú wo ìjọ lódindi. Ìfẹ́ yóò jẹ́ ká ṣe olóòótọ́ sí Ọlọ́run, ká sì dúró gbágbáágbá ti ìjọ, láìka ohun tí ẹ̀dá aláìpé kan sọ tàbí tó ṣe sí.—Sáàmù 119:165.
Ohun Tí Ìfẹ́ Kò Jẹ́
15. Kí ni owú, báwo sì ni ìfẹ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ẹ̀mí tó lè ba nǹkan jẹ́ yìí?
15 “Ìfẹ́ kì í jowú.” Owú lè jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara àwọn ẹlòmíràn nítorí ohun tí wọ́n ní, ìyẹn bóyá dúkìá tàbí àǹfààní tàbí ànímọ́ wọn. Irú owú bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan, ẹ̀mí tó sì lè ba nǹkan jẹ́ ni. Ó lè dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ nínú ìjọ, téèyàn ò bá tètè ṣíwọ́ rẹ̀. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara”? (Jákọ́bù 4:5) Lọ́rọ̀ kan, ìfẹ́ ni. Ànímọ́ àtàtà yìí yóò jẹ́ ká máa bá àwọn tó dà bíi pé wọ́n ní àwọn àǹfààní kan nígbèésí ayé tí àwa kò ní yọ̀. (Róòmù 12:15) Ìfẹ́ kò ní jẹ́ ká kà á sí pé à ń fojú pa wá rẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń gbóríyìn fún ẹnì kan nítorí ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ kan tàbí nítorí gudugudu méje tó ṣe.
16. Bá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lóòótọ́, èé ṣe tí a ó fi yẹra fún fífi àṣeyọrí tí a bá ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà yangàn?
16 “Ìfẹ́ . . . kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀.” Ìfẹ́ kì í jẹ́ ká máa fi àwọn ẹ̀bùn àbínibí tàbí àṣeyọrí wa ṣe fọ́rífọ́rí. Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, báwo la ṣe lè máa fọ́nnu kiri nítorí ohun tá a ṣe láṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà tàbí nítorí àwọn àǹfààní tá a ní nínú ìjọ? Irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀ lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n wá máa ka ara wọn sí èrò ẹ̀yìn. Ìfẹ́ kò ní jẹ́ ká máa fi àwọn àṣeyọrí tí Ọlọ́run fún wa ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ yán àwọn èèyàn lójú. (1 Kọ́ríńtì 3:5-9) Síwájú sí i, ìfẹ́ “kì í wú fùkẹ̀,” tàbí bíi Bíbélì kan ṣe túmọ̀ rẹ̀, ìfẹ́ kì í “gbé ara rẹ̀ gẹṣin aáyán.” Ìfẹ́ kò ní jẹ́ ká jọ ara wa lójú jù.—Róòmù 12:3.
17. Ìfẹ́ ń sún wa láti fi irú ìgbatẹnirò wo hàn fún ọmọnìkejì wa, a ó sì tipa báyìí yàgò fún irú ìwà wo?
17 “Ìfẹ́ . . . kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu.” Ẹnì kan tí ń hùwà lọ́nà tí kò bójú mu máa ń hùwà tí ń buni kù tàbí tí ń kóni nírìíra. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà àìnífẹ̀ẹ́, nítorí pé kì í ka èrò àwọn ẹlòmíràn kún rárá, kì í sì í wá ire wọn. Yàtọ̀ pátápátá sí èyí, ìwà ẹ̀yẹ kan wà nínú ìfẹ́ tó ń mú ká máa gba tàwọn ẹlòmíràn rò. Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká hùwà ọmọlúwàbí, àti irú ìwà tí Ọlọ́run fẹ́, ká sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Nítorí náà, ìfẹ́ kò ní jẹ́ ká lọ́wọ́ sí “ìwà tí ń tini lójú,” ìyẹn ìwà èyíkéyìí tí kò ṣeé gbọ́ sétí tàbí tó máa burú lójú àwọn Kristẹni arákùnrin wa.—Éfésù 5:3, 4.
18. Kí nìdí tí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ kì í fi dandan lé e pé ohun tóun bá sọ labẹ gé?
18 “Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” Ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn sọ níhìn-ín pé: “Ìfẹ́ kì í rin kinkin mọ́ ọ̀nà tirẹ̀.” Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ kì í ranrí pé ohun tóun bá sọ labẹ gé, bíi pé gbogbo ohun tó bá sọ ló ń tọ̀nà. Kò ní máa fọgbọ́n àyínìke darí àwọn èèyàn, kí ó máa rin kinkin mọ́ èrò tirẹ̀ títí yóò fi pa àwọn tí èrò tiwọn yàtọ̀ sí tirẹ̀ lẹ́nu mọ́. Irú ẹ̀mí kìígbọ́-kìígbà bẹ́ẹ̀ yóò fi hàn pé ìgbéraga ló ń yọ onítọ̀hún lẹ́nu. Bíbélì sì sọ pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá.” (Òwe 16:18) Bá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lóòótọ́, a ò ní kóyán ọ̀rọ̀ wọn kéré, bó bá sì ṣeé ṣe, a óò múra tán láti juwọ́ sílẹ̀. Níní ẹ̀mí ìjuwọ́sílẹ̀ wà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.
19. Kí ni ìfẹ́ ń sún wa láti ṣe nígbà táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá?
19 “A kì í tán [ìfẹ́] ní sùúrù . . . , kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” Ohun táwọn èèyàn sọ tàbí tí wọ́n ṣe kì í tètè bí ìfẹ́ nínú. Òótọ́ ni pé inú lè bí wa tí àwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá. Àmọ́ bí ìdí gúnmọ́ bá tilẹ̀ wà láti bínú, ìfẹ́ kò ní jẹ́ ká takú pé ọ̀ràn náà ò ní tán nínú wa. (Éfésù 4:26, 27) A ò ní gbin ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ tàbí nǹkan kan tẹ́nì kan ṣe tó dùn wá sọ́kàn, bí ẹni pé a lọ kọ ọ́ síbì kan tí a kò ti ní gbàgbé, ká lè ṣíwèé kàn án lọ́jọ́ iwájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ máa ń sún wa láti fara wé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú Orí 26, Jèhófà máa ń dárí jini nígbà tí ìdí gúnmọ́ bá wà fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tó bá sì dárí jì wá, ó gbàgbé nìyẹn, ìyẹn ni pé, kò ní sọ pé òun tún fẹ́ fìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyẹn jẹ wá mọ́ lọ́jọ́ iwájú. Ǹjẹ́ a ò dúpẹ́ pé Jèhófà kì í pa àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe mọ́?
20. Kí ló yẹ kí ó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa bí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa bá kó sí pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ rí láburú?
20 “Ìfẹ́ . . . kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo.” Ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn kà níhìn-ín pé: “Ìfẹ́ . . . kì í fi ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn yọ̀ wọ́n.” Bíbélì Moffatt sọ pé: “Ìfẹ́ kì í yọ̀ rárá nígbà táwọn èèyàn bá ṣe ohun tí kò dáa.” Ìfẹ́ kì í fi ìwà àìṣòdodo ṣayọ̀, fún ìdí yìí, a kì í gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún ìwà ìṣekúṣe èyíkéyìí. Kí ni ìṣarasíhùwà wa bí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa bá kó sí pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ rí láburú? Ìfẹ́ kò ní jẹ́ ká máa yọ̀ ọ́, ká máa sọ lọ́kàn wa pé, ‘Ọwọ́ ti bà á! Kò tán nídìí ẹ̀!’ (Òwe 17:5) Ṣùgbọ́n a máa ń yọ̀ nígbà tí arákùnrin kan tó ṣi ẹsẹ̀ gbé bá gbéra sọ nípa tẹ̀mí.
“Ọ̀nà Títayọ Ré Kọjá”
21-23. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ìfẹ́ kì í kùnà láé”? (b) Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò ní àkòrí tó gbẹ̀yìn?
21 “Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” Kí ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí túmọ̀ sí? Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ tó yí i ká ti fi hàn, ohun tó ń sọ̀rọ̀ lé lórí ni àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ní. Ẹ̀bùn wọ̀nyẹn jẹ́ àmì pé Ọlọ́run ń fojú rere wo ìjọ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo Kristẹni ló lè ṣe ìwòsàn, kì í ṣe gbogbo wọn ló lè sọ àsọtẹ́lẹ̀, kì í sì í ṣe gbogbo wọn ló lè fi èdè fọ̀. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀bùn wọ̀nyẹn kì í ṣe nǹkan bàbàrà; nítorí pé bó pẹ́ bó yá, ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu á kásẹ̀ nílẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun kan wà tí kò ní kásẹ̀ nílẹ̀, ohun kan tí gbogbo Kristẹni lè fi kọ́ra. Ó ta àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu yọ, ó sì máa wà pẹ́ jù wọ́n lọ. Pọ́ọ̀lù tilẹ̀ pè é ní “ọ̀nà títayọ ré kọjá.” (1 Kọ́ríńtì 12:31) Kí ni “ọ̀nà títayọ ré kọjá” yìí? Ọ̀nà ìfẹ́ ni.
Ìfẹ́ tí àwọn èèyàn Jèhófà ní sí ara wọn la fi ń dá wọn mọ̀
22 Láìsí àní-àní, ìfẹ́ Kristẹni tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ “kì í kùnà láé,” ìyẹn ni pé, kò ní dópin láé. Títí di òní olónìí, ìfẹ́ ará tó kún fún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ la fi ń dá àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀. Ǹjẹ́ a kò rí ẹ̀rí pé ìfẹ́ yẹn wà nínú ìjọ àwọn olùjọsìn Jèhófà kárí ayé? Ìfẹ́ yẹn yóò wà títí ayé, nítorí Jèhófà ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. (Sáàmù 37:9-11, 29) Ǹjẹ́ ká máa sa gbogbo ipá wa láti “máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.” Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò rí ayọ̀ púpọ̀ tó wà nínú fífúnni. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ó lè máa wà láàyè nìṣó, àní sẹ́, a ó lè máa fìfẹ́ hàn nìṣó, títí ayérayé, ní àfarawé Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́.
23 Nínú àkòrí yìí tá a fi ń kádìí apá tó sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ nílẹ̀, a ti sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè fìfẹ́ hàn sí ara wa. Ṣùgbọ́n nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà tá a gbà ń jàǹfààní ìfẹ́ Jèhófà, tá a sì tún ń jàǹfààní agbára, ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n rẹ̀, yóò dáa ká béèrè pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ òun lóòótọ́?’ A óò dáhùn ìbéèrè yẹn ní àkòrí tó gbẹ̀yìn ìwé yìí.
a Àmọ́ ṣá o, ìfẹ́ Kristẹni kì í gbàgbàkugbà. Bíbélì rọ̀ wá pé: “[Ẹ] máa ṣọ́ àwọn tí ń fa ìpínyà àti àwọn àyè fún ìkọ̀sẹ̀ . . . , ẹ sì yẹra fún wọn.”—Róòmù 16:17.