Kí Ló Túmọ̀ Sí Pé Kéèyàn Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí?
“Kí [Ọlọ́run] yọ̀ǹda fún yín láti ní láàárín ara yín ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.”—RÓÒMÙ 15:5.
1, 2. (a) Kí làwọn kan sọ nípa jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?
ARÁBÌNRIN kan lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Bí mo ṣe jẹ́ ẹni tẹ̀mí máa ń mú inú mi dùn gan-an, ó sì tún jẹ́ kí n lè máa borí àwọn àdánwò tí mò ń kojú lójoojúmọ́.” Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Ọdún kẹtàlélógún [23] rèé témi àtìyàwó mi ṣègbéyàwó, a sì mọwọ́ ara wa gan-an. Kí ni àṣírí ayọ̀ wa? Àwọn nǹkan tẹ̀mí la jẹ́ kó gbà wá lọ́kàn.” Arákùnrin míì lórílẹ̀-èdè Philippines sọ pé: “Bí mo ṣe jẹ́ ẹni tẹ̀mí mú kí n ní àlàáfíà ọkàn, ó sì tún mú kí àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn ará sunwọ̀n sí i láìka ibi tí wọ́n ti wá sí.”
2 Ohun táwọn ará wa yìí sọ jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ ẹni tẹ̀mí. A lè wá bi ara wa pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ di ẹni tẹ̀mí kí èmi náà lè jàǹfààní bíi tàwọn tá a mẹ́nu bà tán yìí?’ Àmọ́ ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ó yẹ ká kọ́kọ́ lóye ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ẹni tẹ̀mí, ìyẹn àwọn tí nǹkan tẹ̀mí jẹ lọ́kàn. Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta yìí. (1) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ ẹni tẹ̀mí? (2) Àwọn wo la lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn táá jẹ́ ká túbọ̀ di ẹni tẹ̀mí? (3) Tá a bá sapá láti ní “èrò inú ti Kristi,” báwo nìyẹn ṣe máa mú ká jẹ́ ẹni tẹ̀mí?
KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ PÉ KÉÈYÀN JẸ́ ẸNI TẸ̀MÍ?
3. Ìyàtọ̀ wo ni Bíbélì sọ pé ó wà láàárín ẹni tẹ̀mí àti ẹni tara?
3 Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìyàtọ̀ sáàárín “ènìyàn ti ara” àti “ènìyàn ti ẹ̀mí” jẹ́ ká lóye irú èèyàn tí ẹni tẹ̀mí jẹ́. (Ka 1 Kọ́ríńtì 2:14-16.) Ìyàtọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó wà láàárín wọn? Ó sọ pé, “ènìyàn ti ara kì í gba àwọn nǹkan ti ẹ̀mí Ọlọ́run, nítorí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni wọ́n jẹ́ lójú rẹ̀; kò sì lè mọ̀ wọ́n.” Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, “ènìyàn ti ẹ̀mí” máa ń “wádìí ohun gbogbo wò,” ó sì ní “èrò inú ti Kristi.” Pọ́ọ̀lù wá rọ̀ wá pé ká jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Àwọn ìyàtọ̀ míì wo ló wà láàárín ẹni tẹ̀mí àti ẹni tara?
4, 5. Irú ìwà wo làwọn ẹni tara máa ń hù?
4 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìwà tẹ́ni tara máa ń hù. Nínú ayé lónìí, báwọn èèyàn ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn ló jẹ wọ́n lógún. Pọ́ọ̀lù pe ohun tó ń darí àwọn èèyàn náà ní “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” (Éfé. 2:2) Ẹ̀mí yìí ló ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa hùwà kan náà, ibi táyé bá kọjú sí làwọn náà máa ń kọjú sí, wọn ò sì mọ̀ ju nǹkan tara lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tó tọ́ lójú ara wọn ni ọ̀pọ̀ ń ṣe, kò sóhun tó kàn wọ́n nípa ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó tọ́ tàbí kò tọ́. Ohun tó jẹ ẹni tara lọ́kàn kò ju bó ṣe máa wà nípò gíga, táá sì lówó lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ láìgba tàwọn míì rò.
5 Kí lohun míì tá a fi lè dá ẹni tara mọ̀? Ẹni tara ni ẹni tó bá ń lọ́wọ́ nínú ohun tí Bíbélì pè ní “àwọn iṣẹ́ ti ara.” (Gál. 5:19-21) Lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará ní Kọ́ríńtì sọ àwọn ìwà míì táwọn ẹni tara máa ń hù. Díẹ̀ rèé lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe: Wọ́n máa ń fa ìpínyà, wọ́n máa ń gbè sẹ́yìn àwọn tó ń fa aáwọ̀, wọ́n máa ń gba ìwà ọ̀tẹ̀ láyè, wọ́n máa ń gbé ara wọn lọ sílé ẹjọ́, wọn kì í bọ̀wọ̀ fún ipò orí, wọ́n sì máa ń ṣàṣejù nídìí oúnjẹ àti ọtí. Yàtọ̀ síyẹn, wẹ́rẹ́ ni ẹni tara máa ń ṣubú sínú ìdẹwò. (Òwe 7:21, 22) Júúdà tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn sọ pé ipò ẹni tara máa ń burú débi pé á di “aláìní ìfẹ́ nǹkan tẹ̀mí.”—Júúdà 18, 19.
6. Irú èèyàn wo la lè pè ní ẹni tẹ̀mí?
6 Kí wá ló túmọ̀ sí pé ẹnì kan jẹ́ “ènìyàn ti ẹ̀mí”? Ẹni tẹ̀mí yàtọ̀ pátápátá sí ẹni tara ní ti pé èrò Ọlọ́run lẹni tẹ̀mí máa ń ní. Ẹni tẹ̀mí máa ń sapá kó lè “di aláfarawé Ọlọ́run.” (Éfé. 5:1) Lédè míì, ó máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú èrò rẹ̀ bá ti Ọlọ́run mu, ó sì máa ń fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan wò ó. Ó máa ń ro ti Ọlọ́run mọ́ gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Àwọn nǹkan tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu làwọn ẹni tẹ̀mí máa ń ṣe, wọn ò dà bí àwọn ẹni tara tí kò mọ̀ ju nǹkan tara lọ. (Sm. 119:33; 143:10) Ẹni tẹ̀mí kì í lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tí Bíbélì pè ní iṣẹ́ ti ara, kàkà bẹ́ẹ̀ “èso ti ẹ̀mí” ló fi ń ṣèwà hù. (Gál. 5:22, 23) Ẹ jẹ́ ká ṣàkàwé ẹni tẹ̀mí báyìí: Tẹ́nì kan bá já fáfá nídìí iṣẹ́ rẹ̀ tí kì í sì í fi iṣẹ́ ṣeré, a máa ń pe onítọ̀hún ní akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Lọ́nà kan náà, tẹ́nì kan bá ń fọwọ́ gidi mú àwọn nǹkan tẹ̀mí, ìyẹn àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, a máa ń pè é ní ẹni tẹ̀mí.
7. Kí ni Bíbélì sọ nípa àwọn ẹni tẹ̀mí?
7 Bíbélì sọ àwọn nǹkan dáadáa nípa àwọn ẹni tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, Mátíù 5:3 sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” Ìwé Róòmù 8:6 sọ àǹfààní táwọn ẹni tẹ̀mí máa ń rí, ó ní: “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú, ṣùgbọ́n gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.” Èyí túmọ̀ sí pé tá a bá gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí, ní báyìí àárín àwa àti Ọlọ́run máa gún régé, àá sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Lọ́jọ́ iwájú, àá ní ìyè àìnípẹ̀kun.
8. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí ká má sì jó àjórẹ̀yìn?
8 Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé inú ayé Èṣù là ń gbé. Torí pé ìfẹ́ tara ló gba àwọn èèyàn tó yí wa ká lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti di ẹni tẹ̀mí, ká má sì jó àjórẹ̀yìn. Tẹ́nì kan bá ń jó àjórẹ̀yìn nípa tẹ̀mí, kò ní lágbára mọ́, wẹ́rẹ́ báyìí ni “afẹ́fẹ́” ayé yìí máa gbé e ṣubú. Kí la lè ṣe tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò fi ní ṣẹlẹ̀ sí wa? Báwo la ṣe lè túbọ̀ dẹni tẹ̀mí?
ÀWỌN TÁ A LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA WỌN
9. (a) Kí ló máa mú ká túbọ̀ dẹni tẹ̀mí? (b) Àpẹẹrẹ àwọn ẹni tẹ̀mí wo la máa jíròrò?
9 Bí ọmọ kan bá ń kíyè sí àpẹẹrẹ rere àwọn òbí rẹ̀ tó sì ń fara wé wọn, á jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń kíyè sí àpẹẹrẹ àwọn ẹni tẹ̀mí tá a sì ń fara wé wọn, àá túbọ̀ dẹni tẹ̀mí. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìgbésí ayé àwọn ẹni tara máa jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa. (1 Kọ́r. 3:1-4) Tá a bá sì wo inú Bíbélì, àá rí àwọn àpẹẹrẹ tó ṣeé tẹ̀ lé àtèyí tí kò ṣeé tẹ̀ lé. Àmọ́ torí pé bá a ṣe máa túbọ̀ dẹni tẹ̀mí ló jẹ wá lógún, ẹ jẹ́ ká wo àwọn mélòó kan tó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ àti bá a ṣe lè fara wé wọn. A máa jíròrò nípa Jékọ́bù, Màríà àti Jésù.
10. Kí ni Jékọ́bù ṣe tó fi hàn pé ẹni tẹ̀mí ni?
10 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Jékọ́bù. Bíi ti ọ̀pọ̀ wa lónìí, nǹkan ò rọrùn fún Jékọ́bù nígbà ayé rẹ̀. Ó ní láti fara dà á fún Ísọ̀ ìkejì rẹ̀ torí pé ìyẹn ò mọ̀ ju nǹkan tara lọ àti pé Ísọ̀ tiẹ̀ ń wọ́nà bó ṣe máa pa á. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni bàbá ìyàwó Jékọ́bù rẹ́ ẹ jẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn “ènìyàn ti ara” ló yí Jékọ́bù ká, kò ṣìwà hù, àwọn nǹkan tẹ̀mí ló jẹ ẹ́ lógún. Ó nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù, ó sì bójú tó ìdílé rẹ̀ dáadáa torí ó mọ̀ pé ìdílé òun ni Mèsáyà ti máa jáde táá sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. (Jẹ́n. 28:10-15) Jékọ́bù fi hàn lọ́rọ̀ àti ní ìṣe pé ìlànà Ọlọ́run lòun ń tẹ̀ lé, ìfẹ́ rẹ̀ lòun sì ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ẹ̀rù ń bà á pé Ísọ̀ lè gba ẹ̀mí òun, Jékọ́bù gbàdúrà pé: “Mo bẹ̀ ọ́, dá mi nídè . . . Ìwọ ti sọ pé, ‘Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, èmi yóò ṣe dáadáa sí ọ, èmi yóò sì mú irú-ọmọ rẹ dà bí àwọn egunrín iyanrìn òkun.’ ” (Jẹ́n. 32:6-12) Ó ṣe kedere pé Jékọ́bù nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ìfẹ́ Ọlọ́run lè ṣẹ.
11. Báwo la ṣe mọ̀ pé ẹni tẹ̀mí ni Màríà?
11 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Màríà. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé òun ni Jèhófà yàn láti jẹ́ ìyá Jésù? Kò sí àní-àní, torí pé ó jẹ́ ẹni tẹ̀mí ni Jèhófà fi yàn án. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ohun tó sọ nígbà tó lọ sílé Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì tí wọ́n jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fi hàn pé ẹni tẹ̀mí ni. (Ka Lúùkù 1:46-55.) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ fi hàn pé ó mọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dáadáa, ó sì fẹ́ràn rẹ̀. (Jẹ́n. 30:13; 1 Sám. 2:1-10; Mál. 3:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun àti Jósẹ́fù ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, wọn ò ní ìbálòpọ̀ títí tí Màríà fi bí Jésù. Kí nìyẹn fi hàn? Èyí fi hàn pé ìfẹ́ Ọlọ́run ló gbawájú ní ìgbésí ayé àwọn méjèèjì, ó sì ṣe pàtàkì sí wọn ju ìfẹ́ tara wọn lọ. (Mát. 1:25) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Màríà ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Jésù ń ṣe, ó sì ń tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tó ń sọ. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń “pa gbogbo àsọjáde wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Lúùkù 2:51) Bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ nípasẹ̀ Mèsáyà ló jẹ ẹ́ lógún. Ǹjẹ́ àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Màríà, ká sì jẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run gbawájú ní ìgbésí ayé wa?
12. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jọ Baba rẹ̀? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
12 Nínú gbogbo àwọn tó tíì gbé ayé rí, Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Ó fi hàn jálẹ̀ ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pé àpẹẹrẹ Jèhófà, Baba rẹ̀ lòun ń tẹ̀ lé. Ìfẹ́ Jèhófà ló ń ṣe lọ́rọ̀, lérò àti ní ìṣe, àwọn ìlànà Jèhófà ló sì ń tẹ̀ lé. (Jòh. 8:29; 14:9; 15:10) Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ohun tí wòlíì Aísáyà sọ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ aláàánú, kẹ́ ẹ wá fi wé ohun tí Máàkù sọ nípa bí Jésù náà ṣe jẹ́ aláàánú. (Ka Aísáyà 63:9; Máàkù 6:34.) Bíi ti Jésù, ṣé àwa náà máa ń fàánú hàn sáwọn èèyàn tá a mọ̀ pé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́? Ṣé iṣẹ́ ìwàásù ló gbawájú ní ìgbésí ayé tiwa náà? (Lúùkù 4:43) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé a jẹ́ ẹni tẹ̀mí.
13, 14. (a) Kí la lè kọ́ lára àwọn ará wa tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan.
13 Yàtọ̀ sáwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń fi hàn pé àwọn jẹ́ ẹni tẹ̀mí tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. Báwo la ṣe mọ̀? Ó ṣeé ṣe ká ti kíyè sí pé wọ́n máa ń lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àlejò ṣíṣe, wọ́n jẹ́ aláàánú, wọ́n sì tún láwọn ànímọ́ míì tó dáa. Èèyàn bíi tiwa ni wọ́n, wọ́n sì láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ, síbẹ̀ wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa hùwà bíi Kristi. Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Brazil tó ń jẹ́ Rachel sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń múra bíi tàwọn èèyàn ayé. Àmọ́ nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àyípadà kí n lè di ẹni tẹ̀mí. Kí n sòótọ́ kò rọrùn, àmọ́ bí mo ṣe ń ṣe àwọn àyípadà yẹn, mò ń láyọ̀, ìgbésí ayé mi sì nítumọ̀.”
14 Àpẹẹrẹ míì ni ti Arábìnrin Reylene láti orílẹ̀-èdè Philippines. Ohun tó gbájú mọ́ ni bó ṣe máa lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga àti bó ṣe máa níṣẹ́ gidi lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í dẹwọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà. Mo wá rí i pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ti ń bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́. Torí náà, mo tún èrò mi pa, mo sì gbájú mọ́ ìjọsìn Jèhófà.” Àtìgbà yẹn ni Reylene ti gbà pé òótọ́ ni ìlérí Jèhófà tó wà nínú Mátíù 6:33, 34. Reylene sọ pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà máa tọ́jú mi!” Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà mọ àwọn kan nínú ìjọ rẹ tí ọ̀rọ̀ wọn jọ tàwọn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu bà yìí. Ó dájú pé inú wa máa ń dùn láti rí àwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ó sì máa ń wù wá láti fara wé wọn.—1 Kọ́r. 11:1; 2 Tẹs. 3:7.
Ẹ NÍ “ÈRÒ INÚ TI KRISTI”
15, 16. (a) Tá a bá fẹ́ dà bíi Kristi, kí ló yẹ ká ṣe? (b) Báwo la ṣe lè mú èrò wa bá ti Kristi mu?
15 Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè fara wé Kristi? Ìwé 1 Kọ́ríńtì 2:16 sọ pé ká ní “èrò inú ti Kristi.” Bákan náà ni Róòmù 15:5 rọ̀ wá pé ká ní “ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.” Torí náà, tá a bá fẹ́ dà bíi Kristi, ó ṣe pàtàkì ká mọ bí Kristi ṣe ń ronú ká sì mọ ohun tó máa ṣe lábẹ́ ipò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Bí Jésù ṣe máa wu Ọlọ́run lohun tó jẹ ẹ́ lógún. Torí náà, tá a bá fìwà jọ Jésù, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ronú bí Jésù ṣe ń ronú.
16 Kí láá mú ká lè ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fojú rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, wọ́n gbọ́ ìwàásù rẹ̀, wọ́n rí bó ṣe fìfẹ́ bá onírúurú èèyàn lò àti bó ṣe ń fi ìlànà Ọlọ́run sílò. Abájọ tí wọ́n fi sọ pé: “Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe.” (Ìṣe 10:39) Lóòótọ́ àwa ò lè rí Jésù, àmọ́ Jèhófà ti fún wa láwọn ìwé Ìhìn Rere tó jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an, ìyẹn sì mú kó dà bíi pé a wà pẹ̀lú rẹ̀. Tá a bá ń ka àwọn ìwé Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà, ṣe là ń mú èrò wa bá ti Kristi mu. Èyí á mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí,” ká sì ní “èrò orí kan náà” tí Kristi ní.—1 Pét. 2:21; 4:1.
17. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ronú bíi ti Kristi?
17 Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ronú bíi ti Kristi? Bí oúnjẹ tó dáa ṣe máa ń ṣe ara lóore, bẹ́ẹ̀ la ṣe máa túbọ̀ lágbára nípa tẹ̀mí tá a bá ń mú èrò wa bá ti Kristi mu. Díẹ̀díẹ̀, àá mọ ohun tí Jésù máa ṣe láwọn ipò tó yàtọ̀ síra, èyí á sì jẹ́ ká máa ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Àá tipa bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, àá sì rí ojúure Ọlọ́run. Àwọn àǹfààní yìí tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ ò rí i pé ìdí pàtàkì nìyẹn tó fi yẹ ká “gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀!”—Róòmù 13:14.
18. Kí lo rí kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
18 A ti jíròrò ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ ẹni tẹ̀mí. A tún ti rí àpẹẹrẹ àwọn ẹni tẹ̀mí tá a lè fara wé. Paríparí rẹ̀, a ti wá mọ̀ pé tá a bá ní “èrò inú ti Kristi” àá túbọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Àmọ́, àwọn nǹkan míì ṣì wà tá a máa kọ́ nípa béèyàn ṣe lè túbọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, báwo la ṣe lè mọ bí ipò tẹ̀mí wa ṣe lágbára tó? Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ di ẹni tẹ̀mí? Tá a bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ nígbèésí ayé wa? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.