Tẹ̀lé Ọ̀nà Ìfẹ́ Ti O Tayọ Rekọja
JEHOFA ỌLỌRUN jẹ́ ogidi apẹẹrẹ ìfẹ́. (1 Johannu 4:8) Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, sọ pe a gbọdọ nifẹẹ Ọlọrun ati aladuugbo wa. (Matteu 22:37-40) Họ́wù, Ọlọrun ń dari gbogbo agbaye lori ipilẹ animọ yii! Nitori naa fun ìyè ainipẹkun ni ibikibi, a gbọdọ tẹle ọ̀nà ìfẹ́.
Ọlọrun fi ìfẹ́ hàn fun orilẹ-ede Israeli ṣugbọn lẹhin naa ó kọ eto-ajọ yẹn silẹ nitori aiṣotitọ. Ó wá fi ijọ awọn ọmọ-ẹhin Jesu hàn lẹhin naa gẹgẹ bi eto-ajọ Rẹ̀ titun. Bawo? Nipa ìfihàn akanṣe ti ẹmi mimọ ti ń fun wọn lagbara lati sọrọ ni èdè ahọ́n ati lati sọtẹlẹ. Nipa bayii, ni Pentekosti 33 C.E., 3,000 awọn Ju ati alawọṣe Ju di onigbagbọ wọn sì fi eto-ajọ ogbologboo naa silẹ lati darapọ mọ́ titun ti o jẹ ti Ọlọrun. (Iṣe 2:1-41) Niwọn bi o ti jẹ pe awọn ẹbun ẹmi naa ni a tú jade nipasẹ awọn aposteli Jesu lẹhin ìgbà naa, iru awọn ìfihàn bẹẹ dawọduro lẹhin ikú wọn. (Iṣe 8:5-18; 19:1-6) Ṣugbọn nigba naa lọhun-un ẹmi naa ti fihàn pe ojurere Ọlọrun wà lara Israeli tẹmi.—Galatia 6:16.
Awọn iṣẹ iyanu ti ń jẹ jade lati inu awọn ẹbun ẹmi ṣanfaani. Bi o ti wu ki o ri, fifi ifẹ tabi idaniyan aimọtara-ẹni-nikan hàn fun awọn ẹlomiran ṣe pataki ju níní awọn ẹbun ẹmi lọ. Aposteli Paulu fi eyi hàn ninu lẹta rẹ̀ akọkọ si awọn ará Korinti (ni nǹkan bii 55 C.E.). Ninu rẹ̀ ó sọrọ nipa ifẹ gẹgẹ bi “ọ̀nà kan ti o tayọ rekọja.” (1 Korinti 12:31) Ọ̀nà yẹn ni a jiroro ni 1 Korinti ori 13.
Laisi Ifẹ, A Kò Jámọ́ Nǹkan
Paulu sọ asọye pe: “Bi mo tilẹ ń fọ oniruuru èdè ati ti angẹli, ti emi kò sì ní ìfẹ́, emi dabi idẹ ti ń dún, tabi bii kimbali olóhùn gooro.” (1 Korinti 13:1) Laisi ìfẹ́, kì yoo tumọsi ohunkohun lati sọrọ ni èdè ti ẹmi fi funni tabi ni ahọ́n ti angẹli ọ̀run. Paulu yàn lati sọ awọn ọ̀rọ̀ marun-un tí ń gbéniró dipo ẹgbẹrun mẹwaa ni ahọ́n ti awọn eniyan kò loye lọ. (1 Korinti 14:19) Ẹnikan tí kò nifẹẹ yoo dabi “idẹ ti ń dún”—agogo aláriwo, tí ń bíni ninu—tabi “kimbali olóhùn gooro” ti kò lóhùn orin adùnyùngbà. Sisọrọ ni awọn ahọ́n aláìnífẹ̀ẹ́ kì í ṣe ọ̀nà titunilara, tí ń gbeniro nipa tẹmi lati fogo fun Ọlọrun ki a sì ran awọn eniyan rẹ̀ lọwọ. Lonii, a ń fi ìfẹ́ hàn nipa lilo ohùn ọ̀rọ̀ ti o ṣeelóye ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian.
Aposteli naa sọ tẹle e pe: “Bi mo sì ní ẹbun isọtẹlẹ, ti mo sì ni òye gbogbo ohun ijinlẹ, ati gbogbo ìmọ̀; bi mo sì ni gbogbo igbagbọ, tobẹẹ ti mo lè ṣí awọn òkè ńlá nipo, ti emi kò sì ní ìfẹ́, emi ko jẹ nǹkan.” (1 Korinti 13:2) Sisọtẹlẹ lọna iyanu, ìlóye akanṣe ti awọn aṣiri mímọ́, ati ìmọ̀ tí ẹmi ń fifunni lè ṣanfaani fun awọn miiran ṣugbọn kì í ṣe awọn wọnni ti wọn ní iru awọn ẹbun bẹẹ bi awọn ti ó ni ẹbun kò bá nífẹ̀ẹ́. Paulu lo ìlóye akanṣe ti awọn aṣiri mímọ́ lati ran awọn ẹlomiran lọwọ, ẹbun ìmọ̀ sì jẹ́ ki o ṣeeṣe fun un lati sọ asọtẹlẹ lilaaja awọn ti wọn jiya ọkọ̀ rírì. (Iṣe 27:20-44; 1 Korinti 4:1, 2) Sibẹ, bi ó bá ni ‘gbogbo ìmọ̀ ati gbogbo igbagbọ’ ṣugbọn tí kò ni ìfẹ́, oun kì yoo jámọ́ nǹkan ni iwaju Jehofa.
Lonii, ẹmi Jehofa mú ki ó ṣeeṣe fun Awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ lati loye awọn asọtẹlẹ Bibeli ati awọn aṣiri mímọ́ ó sì ń tọ́ wọn sọna ninu fifun awọn miiran ni iru ìmọ̀ bẹẹ. (Joeli 2:28, 29) Ẹmi tún ń mú igbagbọ ti a nilo lati bori awọn idena bi oke nla jade. (Matteu 17:20) Niwọn bi ẹmi ti ń ṣe awọn nǹkan wọnyi, kò tọna lati wá ogo ara-ẹni lati inu wọn. A kò jámọ́ nǹkan ayafi bi a bá ṣe awọn nǹkan fun ogo Ọlọrun ati pẹlu ìfẹ́ fun un ati fun awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa.—Galatia 5:6.
Irubọ Aláìnífẹ̀ẹ́ Kò Ní Èrè
Paulu sọ pe: “Bi mo sì ń fi gbogbo ohun ìní mi bọ́ awọn talaka, bi mo sì fi araami funni lati sùn, ti emi kò sì ni ìfẹ́, kò ni èrè kan fun mi.” (1 Korinti 13:3) Laisi ìfẹ́, Paulu ki yoo jèrè bi ó bá fi ohun gbogbo tí ó ní bọ́ awọn ẹlomiran. Ọlọrun ń san ẹ̀san rere fun wa nitori ìfẹ́ tí ó wà lẹhin awọn ẹbun wa, kì í ṣe nitori iniyelori ohun ti ara wọn tabi nitori pe a ń wá ogo gẹgẹ bi olùfúnni, bii Anania ati Safira onírọ́. (Iṣe 5:1-11) Paulu fi apẹẹrẹ rere lélẹ̀ nipa fifi tifẹtifẹ fi araarẹ̀ funni ni isopọ pẹlu iṣẹ-ojiṣẹ fun itura-alaafia fun awọn onigbagbọ ni Judea.—1 Korinti 16:1-4; 2 Korinti 8:1-24; 9:7.
Àní ajẹ́rìíkú gẹgẹ bi ẹlẹ́rìí si otitọ ti kò nífẹ̀ẹ́ kò tumọsi ohun kan fun Ọlọrun. (Owe 25:27) Jesu sọrọ nipa irubọ rẹ̀ ṣugbọn kò fọ́nnu nipa rẹ̀. Dipo fífọ́nnu ó fi araarẹ̀ funni pẹlu imuratan lati inu ìfẹ́. (Marku 10:45; Efesu 5:2; Heberu 10:5-10) Awọn arakunrin rẹ̀ tẹmi ‘gbé araawọn kalẹ ni ẹbọ ti ó wà láàyè’ ninu iṣẹ-isin Ọlọrun kì í ṣe ninu ijẹ́rìíkú lọna ìfògo fúnra-ẹni ṣugbọn ni awọn ọ̀nà ti kò pafiyesi ti ó fògo fun Jehofa ti ó sì fi ìfẹ́ wọn fun un hàn.—Romu 12:1, 2.
Awọn Ọ̀nà Diẹ Tí Ìfẹ́ Yoo Gbà Mú Wa Hùwà
Paulu kọwe pe: “Ìfẹ́ a maa mú suuru [“a maa ní ipamọra,” NW], a sì maa ṣeun [“ní inurere,” NW].” (1 Korinti 13:4a) Fun ọpọlọpọ, ipamọra Ọlọrun lati ìgbà ẹṣẹ Adamu ti tumọsi ironupiwada ti ń ṣamọna si igbala. (2 Peteru 3:9, 15) Bi a bá ni ìfẹ́, awa yoo fi suuru kọ́ awọn ẹlomiran ni otitọ. Awa yoo yẹra fun ìrujáde onigboonara awa yoo sì jẹ́ agbatẹniro ati adarijini. (Matteu 18:21, 22) Ifẹ tún ní inurere, a sì fà wá sunmọ ọ̀dọ̀ Ọlọrun nitori inurere rẹ̀. Eso ẹmi rẹ̀ ti inurere pa wá mọ́ kuro ninu jíjẹ́ ẹni ti ń beere lọwọ awọn ẹlomiran ju bi oun ti ń beere lọwọ wa lọ. (Efesu 4:32) Ìfẹ́ tilẹ mú wa jẹ́ oninurere si awọn eniyan alailọpẹ.—Luku 6:35.
Paulu fikun un pe: “Ìfẹ́ kì í ṣe ìlara [“kì í jowú,” NW], ifẹ kì í sọrọ igberaga, kì í fẹ̀.” (1 Korinti 13:4b) Owú jẹ́ iṣẹ ti ẹran-ara ti ó lè yọ ẹnikan kuro ni Ijọba Ọlọrun. (Galatia 5:19-21) Ìfẹ́ pa wá mọ́ kuro ninu jijowu awọn ohun ìní tabi awọn ipo ojurere ti ẹlomiran. Bi ó bá gba anfaani iṣẹ-isin kan ti a fọkànfẹ́, ìfẹ́ yoo mú wa yọ̀ pẹlu rẹ̀, fun un ni itilẹhin wa, ki a sì dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ó lè jẹ́ ẹni ti a lò lati ṣanfaani fun ijọ.
Niwọn bi o ti jẹ pe ìfẹ́ “kì í sọrọ igberaga,” kì í sún wa lati fọ́nnu nipa ohun ti Ọlọrun ti jẹ́ ki a ṣe ninu iṣẹ-isin rẹ̀. Awọn ará Korinti diẹ fọ́nnu bi ẹni pe awọn ni wọn pilẹṣẹ ẹbun ẹmi, ṣugbọn iwọnyi wá lati ọdọ Ọlọrun, gẹgẹ bi awọn anfaani ninu eto-ajọ rẹ̀ ode-oni ti jẹ́. Dipo fífọ́nnu nipa iduro wa ninu eto-ajọ Ọlọrun, nigba naa, ẹ jẹ ki a ṣọra pe a kò ṣubu. (1 Korinti 1:31; 4:7; 10:12) Ìfẹ́ “kì í fẹ̀,” ṣugbọn èrò-inú ẹnikan tí kò nífẹ̀ẹ́ le di eyi ti ó wú fùkẹ̀ fun ìjẹ́pàtàkì loju ara-ẹni. Awọn eniyan onífẹ̀ẹ́ kì í nimọlara ìlọ́láju awọn elọmiran lọ.—1 Korinti 4:18, 19; Galatia 6:3.
Kì í ṣe Àìbójúmu, Onimọtara-ẹni-nikan, Afìbínúhàn
Ìfẹ́ “kì í huwa aitọ [“lọna aibojumu,” NW], kì í wá ohun ti araarẹ̀, a kì í mú un binu.” (1 Korinti 13:5a) Ó ń gbé ọ̀nà iwarere, ihuwasi oniwa-bi-Ọlọrun, ọ̀wọ̀ fun aṣẹ, ati iṣesi ti o bojumu ni awọn ipade Kristian larugẹ. (Efesu 5:3-5; 1 Korinti 11:17-34; 14:40; fiwe Juda 4, 8-10.) Niwọn bi ìfẹ́ ti mú gbogbo eniyan nimọlara pe a nilo wọn, bii gbogbo apá ara eniyan, ijọ onifẹẹ kan jẹ́ ibi alaafia ati ibi ìsádi kan. (1 Korinti 12:22-25) Dipo fifi imọtara-ẹni-nikan ‘wá awọn ire ti araarẹ nikan,’ ìfẹ́ ń mú ki a fi awọn ẹ̀tọ́ wa rubọ nigba miiran ki a sì fi ọkàn-ìfẹ́ hàn ninu awọn ẹlomiran ati ninu ire alaafia wọn. (Filippi 2:1-4) Ìfẹ́ ń mú wa ‘di ohun gbogbo fun oniruuru eniyan, ki a lè gba awọn diẹ là’ nipasẹ iṣẹ-ojiṣẹ wa.—1 Korinti 9:22, 23.
“A kì í mú” ìfẹ́ “binu.” Ìrufùfù ibinu jẹ́ awọn iṣẹ ti ẹran-ara ti ó kun fun ẹṣẹ, ṣugbọn ìfẹ́ mú wa “lọ́ra lati binu.” (Jakọbu 1:19; Galatia 5:19, 20) Àní bi a bá di onibiinu lọna ti o ba idajọ òdodo mu, ìfẹ́ kì í mú wa maa baa lọ ninu ibinu, ni titipa bayii fi àyè silẹ fun Eṣu. (Efesu 4:26, 27) Ni pataki ni awọn alagba gbọdọ yẹra fun ibinu bi awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn bá kùnà ninu ṣiṣe awọn ohun kan ti wọn damọran.
Paulu tun sọ nipa ìfẹ́ pe: “Kì í gbìrò ohun buburu [“Kì í kọ akọsilẹ iṣenileṣe,” NW].” (1 Korinti 13:5b) Ìfẹ́ kì í pa akọsilẹ lẹsẹẹsẹ nipa awọn iwa aitọ mọ, bii akọsilẹ iwe iṣiro kan. Ó ń rí ohun ti o dara ninu awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ kì í sìí fi oró ya oró fun awọn aitọ gidi tabi ti a finuro. (Owe 20:22; 24:29; 25:21, 22) Ìfẹ́ ń ràn wá lọwọ lati “lepa ohun ti i ṣe ti alaafia.” (Romu 14:19) Paulu ati Barnaba ní gbolohun asọ̀ wọn sì dá lọ lọtọọtọ ninu iṣẹ-isin Ọlọrun, ṣugbọn ìfẹ́ dí àfo naa ó sì pa wọn mọ kuro ninu didi kùnrùngbùn.—Lefitiku 19:17, 18; Iṣe 15:36-41.
Ó Ní Ìtẹ̀sí si Ododo ati Otitọ
Nipa ìfẹ́, Paulu ń baa lọ lati sọ pe: “Kì í yọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a maa yọ̀ ninu otitọ.” (1 Korinti 13:6) Awọn kan ní iru inudidun bẹẹ ninu aiṣododo debi pe “wọn kì í sùn bikoṣepe wọn huwa buburu.” (Owe 4:16) Ṣugbọn ninu eto-ajọ Ọlọrun awa kìí bá araawa jà tabi yọ̀ bi ẹṣẹ bá dẹkun mú ẹnikan. (Owe 17:5; 24:17, 18) Bí ìfẹ́ ti ó tó fun Ọlọrun ati ododo bá ti wà ninu ijọ Korinti, iwa palapala ni wọn kì bá tí fààyè gbà nibẹ. (1 Korinti 5:1-13) Yatọ si awọn nǹkan miiran, ìfẹ́ fun ododo pa wá mọ́ kuro ninu gbigbadun aiṣododo ti a fihàn lọna aworan ninu tẹlifiṣọn, aworan ara ogiri, tabi awọn eré ori ìtàgé.
Ìfẹ́ “a maa yọ̀ ninu otitọ.” Nihin-in otitọ ni a fi iyatọ rẹ̀ wéra pẹlu aiṣododo. Eyi ni kedere tumọsi pe ìfẹ́ ń mú wa yọ̀ lori agbara idari fun ododo ti otitọ ní lori awọn eniyan. A ń rí ayọ ninu awọn ohun ti ń gbé awọn eniyan ró tí ó sì ń mú ipa-ọna otitọ ati ododo tẹsiwaju. Ìfẹ́ dí wa lọwọ lati maṣe parọ, ó ń fun wa ni ayọ nigba ti a bá fi awọn aduroṣanṣan hàn gẹgẹ bi alaimọwọmẹsẹ, ó sì ń mú wa yọ̀ ninu ayọ iṣẹgun ti otitọ Ọlọrun.—Orin Dafidi 45:4.
Bi Ìfẹ́ Ṣe Ń Bojuto Ohun Gbogbo
Ní biba itumọ ìfẹ́ rẹ̀ lọ, Paulu wi pe: “A maa farada ohun gbogbo, a maa gba ohun gbogbo gbọ́, a maa reti ohun gbogbo, a maa fàyàrán ohun gbogbo.” (1 Korinti 13:7) ‘Ni fifarada ohun gbogbo,’ ìfẹ́ ti ifibinuhan mọ́ ìta gẹgẹ bi òrùlé daradara kan ti ń ṣe fun òjò. Bi ẹnikan bá ṣe laifi si wa ṣugbọn ti ó tọrọ aforiji lẹhin naa, ìfẹ́ ń jẹ́ ki a mú iṣeleṣe mọra, ni didariji onilaifi naa dipo ṣiṣe òfófó nipa awọn ọ̀ràn. Ninu ìfẹ́ a ń gbiyanju lati ‘jere arakunrin wa.’—Matteu 18:15-17; Kolosse 3:13.
Ìfẹ́ “a maa gba ohun gbogbo” ti ó wà ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun “gbọ́” ó sì ń mú wa kun fun imoore fun ounjẹ tẹmi ti a ń pese nipasẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọ-inu.” (Matteu 24:45-47, NW) Bi o tilẹ jẹ pe a kì í ṣe ẹni ti ń fi tirọruntirọrun gba ohun gbogbo gbọ́, ìfẹ́ ń dí wa lọwọ kuro ninu níní ọkan-aya ti kìí gbagbọ ó sì ń pa wá mọ kuro ninu kíka awọn isunniṣe buburu si awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa lọrun. (Oniwaasu 7:21, 22) Ìfẹ́ ‘a tún maa reti ohun gbogbo’ ti a kọsilẹ ninu Iwe Mimọ, iru bii awọn otitọ nipa Ijọba Ọlọrun. Bi a ti sún wa nipasẹ ìfẹ́, a nireti a sì gbadura fun abajade ti o dara julọ ninu awọn ipo tí ń dánniwò. Ìfẹ́ tún ń sún wa lati sọ idi fun ireti wa fun awọn ẹlomiran. (1 Peteru 3:15) Ni afikun, ìfẹ́ “a maa fàyàrán [“farada,” NW] ohun gbogbo,” papọ pẹlu awọn ẹṣẹ ti a dá lodisi wa. (Owe 10:12) Ìfẹ́ fun Ọlọrun tún ń ràn wá lọwọ lati farada inunibini ati awọn adanwo miiran.
Paulu fikun un pe: “Ìfẹ́ kì í yẹ̀ lae.” (1 Korinti 13:8a) Gan-an gẹgẹ bi Jehofa kò ti lè kùnà bẹẹ gẹgẹ ni ìfẹ́ kò ti lè kùnà. Niwọn bi Ọlọrun ayeraye wa ti jẹ́ ẹdaya apẹẹrẹ ìfẹ́, animọ yii kò lè dawọ duro lae. (1 Timoteu 1:17; 1 Johannu 4:16) Agbaye ni ìfẹ́ yoo maa dari nigba gbogbo. Nitori naa ẹ jẹ ki a gbadura pe Ọlọrun yoo ràn wá lọwọ lati ṣẹpa awọn animọ iwa imọtara-ẹni-nikan ki a sì fi eso ti ẹmi rẹ̀ ti kìí kùnà yii hàn.—Luku 11:13.
Awọn Nǹkan Ti Yoo Kọjalọ
Ni títọ́ka siwaju, Paulu kọwe pe: “Ṣugbọn bi o ba ṣepe isọtẹlẹ ni, wọn óò dopin; bi o ba ṣe pe ẹbun ahọ́n ni, wọn óò dakẹ; bi o ba ṣe pe ìmọ̀ ni, yoo di asán.” (1 Korinti 13:8b) ‘Awọn ẹbun isọtẹlẹ’ mú ki o ṣeeṣe fun awọn ti o ní wọn lati sọ awọn asọtẹlẹ titun jade. Bi o tilẹ jẹ pe iru awọn isọtẹlẹ bẹẹ kọja lọ lẹhin ti a ti fidii ijọ Kristian mulẹ gẹgẹ bi eto-ajọ Ọlọrun, agbara isọtẹlẹ rẹ̀ kò tíì kọjalọ, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ní gbogbo asọtẹlẹ ti a nilo nisinsinyi ninu. Agbara lati sọrọ ni awọn ahọ́n ti ẹmi ń fifunni tún dawọ duro pẹlu, ìmọ̀ akanṣe ni o sì “di asán,” gẹgẹ bi a ti sọ ọ́ tẹlẹ. Ṣugbọn Ọ̀rọ̀ Jehofa ti o pe perepere ń pese ohun ti a nilati mọ fun igbala. (Romu 10:8-10) Ju bẹẹ lọ, awọn eniyan Ọlọrun ni a fi ẹmi rẹ̀ kún ti wọn sì ń mú eso rẹ̀ jade.
Paulu ń baa lọ pe: “Nitori awa mọ̀ ni apakan, awa sì ń sọtẹlẹ ni apakan. Ṣugbọn nigba ti eyi ti o pe bá dé, eyi ti i ṣe ti apakan yoo dopin.” (1 Korinti 13:9, 10) Awọn ẹbun ìmọ̀ ati asọtẹlẹ kò pé perepere. Lọna ti o hàn gbangba, iru asọtẹlẹ bẹẹ kò lọ sinu kulẹkulẹ, wolii kọọkan kò sì pé perepere ni sisọ ọjọ-ọla di mimọ, bi oun kò ti ni ìmọ̀ pipe nipa ohun ti ó sọtẹlẹ. Bi o ti wu ki o ri, nisinsinyi, òye asọtẹlẹ naa ni ó ń di pipe perepere ni kẹrẹkẹrẹ. Fun apẹẹrẹ, awọn otitọ tí ń mú asọtẹlẹ Bibeli ṣẹ jẹrii sii pe Jesu gba aṣẹ ọlọba lori araye ni 1914. Lati ìgbà naa, a ti wà ni “ìgbà ikẹhin” a sì ń gbadun ibisi ti ń baa lọ ninu ìmọ̀ tẹmi ati òye asọtẹlẹ Bibeli. (Danieli 12:4) Fun idi yii, a ń wá sinu ìmọ̀ pipe “eyi ti o pé” sì gbọdọ sunmọtosi.
Animọ Ti O Tobi Julọ Wà Titilọ
Ni pipaṣamọ mọ itẹsiwaju ijọ, Paulu kọwe pe: “Nigba ti mo wà ni èwe, emi a maa moye bi èwe, emi a maa gbèrò bi èwe: ṣugbọn nigba ti mo di ọkunrin tán, mo fi iwa èwe silẹ.” (1 Korinti 13:11) Niwọn bi èwe kan ti ń gbegbeesẹ lori ìmọ̀ ati idagbasoke ti ara ìyára ti kò tó nǹkan, oun ni a lè bì sihin-in sọhun-un, gẹgẹ bi ẹni pe a ń tì í ninu ibusun ọmọ titun. Ṣugbọn ọkunrin kan ni o ti dagba niti ara ìyára, ó ní ìmọ̀ ti o tubọ pọ, kò sì sábà rọrun lati tì í sihin-in sọhun-un. Ó ti fopin si awọn ironu, iṣarasihuwa, ati ọ̀nà igbaṣe nǹkan, ti ìgbà ọmọde rẹ́. Bakan naa, lẹhin ti eto-ajọ ori ilẹ̀-ayé ti Ọlọrun ti dagba lati ìgbà ọmọ-ọwọ rẹ̀, Oun pinnu pe kò nilo ẹbun ẹmi ti asọtẹlẹ, ahọ́n, ati ìmọ̀ mọ́. Bi o tilẹ jẹ pe awọn mẹmba ijọ ode-oni, ti o wà ni ìgbà ogbó rẹ̀ nisinsinyi, kò tún ni imọlara fun iru ẹbun bẹẹ, inu wọn dùn lati ṣiṣẹsin Ọlọrun lạbẹ idari ẹmi rẹ̀.
Paulu fi kun un pe: “Nitori pe nisinsinyi awa ń ríran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigba naa ni ojukoju: nisinsinyi mọ mọ̀ ni apakan; ṣugbọn nigba naa ni emi yoo mọ̀ gẹgẹ bi mo sì ti di mímọ́ pẹlu.” (1 Korinti 13:12) Ni ìgbà ọmọ-ọwọ ijọ naa, akoko kò ti i tó fun Ọlọrun lati ṣi awọn ohun kan paya. Fun idi yii, a rí wọn ni bàìbàì, gẹgẹ bi ẹni pe awọn Kristian ń wo awojiji ti a fi irin ṣe ti ó ṣalaini ìtẹ́jú didara tí ń fi nǹkan hàn. (Iṣe 1:6, 7) Ṣugbọn awa ti kọja iriran bàìbàì. Imuṣẹ asọtẹlẹ ati afijọ ni o ṣe kedere, nitori eyi ni akoko iṣipaya Ọlọrun. (Orin Dafidi 97:11; Danieli 2:28) Bi o tilẹ jẹ pe Paulu funraarẹ mọ Ọlọrun, otente ìmọ̀ nipa Jehofa ati ipo ibatan timọtimọ julọ pẹlu Rẹ̀ yoo dé nigba ti a o jí aposteli naa dide si ìyè ti ọ̀run, ni titipa bayii gba èrè kikun ti ipa-ọna Kristian rẹ̀.
Ni pipari ẹdaya apẹẹrẹ ìfẹ́ rẹ̀, Paulu kọwe pe: “Ǹjẹ́ nisinsinyi igbagbọ, ireti, ati ìfẹ́ ń bẹ, awọn mẹta yii: ṣugbọn eyi ti o tobi ju ninu wọn ni ìfẹ́.” (1 Korinti 13:13) Laika aisinibẹ awọn ẹbun oniṣẹ iyanu si, ijọ naa ní ìmọ̀ ti o tubọ pé perepere ati idi fun igbagbọ, ireti, ati ìfẹ́ ti o tubọ pọ̀ sii. Ó ní igbagbọ pe ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣeleri ni imuṣẹ rẹ̀ daju lai tilẹ ti i ṣẹ. (Heberu 11:1) Awọn apa ẹ̀ka igbagbọ yoo dopin bi ọwọ́ ba ti ń tẹ awọn ohun ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọtẹlẹ. Awọn apa iha ti ireti yoo ṣiwọ nigba ti a ba ri awọn ohun ti a ń reti. Ṣugbọn ìfẹ́ yoo wà titilae. Fun idi yii, ẹ jẹ ki gbogbo Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa maa baa lọ lati tẹle ọ̀nà ìfẹ́ titayọ rekọja.