Ọ̀nà Ìfẹ́ Kì í Kùnà Láé
“Ẹ máa fi tìtara-tìtara wá àwọn ẹ̀bùn títóbi jù. Síbẹ̀, èmi fi ọ̀nà títayọ ré kọjá hàn yín.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 12:31.
1-3. (a) Báwo ni kíkọ́ láti fìfẹ́ hàn ṣe dà bí kíkọ́ èdè tuntun? (b) Kí ni àwọn nǹkan tó lè mú kí kíkọ́ láti fìfẹ́ hàn ṣòro?
OHA ti gbìyànjú láti kọ́ èdè tuntun rí? Ìpèníjà ńlá ni, ká má sọ ọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ! Ṣùgbọ́n o, ọmọdé tètè máa ń gbọ́ èdè bó bá wà lágbègbè tí wọ́n ti ń sọ ọ́. Kíá ni ọpọlọ rẹ̀ yóò ti mòye àwọn ìró àti ìtumọ̀ ọ̀rọ̀, tí yóò fi jẹ́ pé láìpẹ́ láìjìnnà, ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ ti mọ ọ̀rọ̀ọ́ sọ, ó ti ń da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuru. Àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún àgbàlagbà. Lemọ́lemọ́ la óò máa ṣí ìwé atúmọ̀ èdè, ká sáà lè rántí gbólóhùn díẹ̀ tó ṣe kókó nínú èdè àjèjì. Àmọ́ ṣá o, tó bá wá pẹ́ táa ti ń kọ́ èdè ọ̀hún, a óò wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú lọ́nà tó bá èdè tuntun náà mu, yóò sì wá túbọ̀ rọrùn láti sọ.
2 Kíkọ́ báa ṣe ń fìfẹ́ hàn kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí kíkọ́ èdè tuntun. Òtítọ́ ni pé Ọlọ́run dá ànímọ́ yìí mọ́ ènìyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; fi wé 1 Jòhánù 4:8.) Síbẹ̀síbẹ̀, kíkọ́ láti fìfẹ́ hàn tún gba àkànṣe ìsapá—pàápàá lónìí, tí ìfẹ́ni àdánidá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dàwátì. (2 Tímótì 3:1-5) Nígbà mìíràn, bọ́ràn ṣe máa ń rí nìyẹn nínú ìdílé pàápàá. Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ ló ń dàgbà nínú àyíká tí ń dáni lágara, níbi tó jẹ́ pé níjọ́kanlọ́gbọ̀n ni wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́—ìyẹn bí wọ́n bá tilẹ̀ gbọ́ ọ rárá. (Éfésù 4:29-31; 6:4) Báwo wá ni a ṣe lè mọ báa ṣe ń fìfẹ́ hàn—bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè máà tíì fìfẹ́ hàn sí wa rí?
3 Bíbélì lè ṣèrànwọ́. Ní 1 Kọ́ríńtì 13:4-8, ohun tí Pọ́ọ̀lù gbé kalẹ̀ kì í kàn-án ṣe àlàyé oréfèé nípa ohun tí ìfẹ́ jẹ́, bí kò ṣe àpèjúwe bí ìfẹ́ tó ga jù lọ yìí ṣe ń hùwà. Àgbéyẹ̀wò ẹsẹ wọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mòye ohun tí ànímọ́ Ọlọ́run yìí jẹ́ gan-an, yóò sì jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti fi ṣèwà hù. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìhà tí ìfẹ́ ní, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣàpèjúwe rẹ̀. A óò kó wọn pa pọ̀ sọ́nà mẹ́ta: ìwà wa lápapọ̀; lẹ́yìn náà, ní pàtó, àjọṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn; àti, èyí tó kẹ́yìn, ìfaradà wa.
Ìfẹ́ Máa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Borí Ìgbéraga
4. Ìjìnlẹ̀ òye wo ni Bíbélì fún wa nípa owú?
4 Lẹ́yìn àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ sọ nípa ìfẹ́, ó kọ̀wé sí àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ìfẹ́ kì í jowú.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Owú lè fara hàn nígbà téèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara aásìkí tàbí àṣeyọrí àwọn ẹlòmíràn. Irú owú yìí ń jẹni run—nípa tara, ní ti èrò ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí.—Òwe 14:30; Róòmù 13:13; Jákọ́bù 3:14-16.
5. Báwo ni ìfẹ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí owú, tó bá jọ pé wọ́n gbé àǹfààní kan tó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run fò wá dá?
5 Fún ìdí yìí, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Mo ha ń ṣe ìlara tó bá jọ pé wọ́n gbé àǹfààní tó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run fò mí dá?’ Bóo bá dáhùn bẹ́ẹ̀ ni, má bọkàn jẹ́ jù. Òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Jákọ́bù, rán wa létí pé “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara” ń bẹ lára gbogbo ẹ̀dá ènìyàn aláìpé. (Jákọ́bù 4:5) Ìfẹ́ fún arákùnrin rẹ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú ara rẹ padà bọ̀ sípò. Ó lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti máa bá àwọn aláyọ̀ yọ̀, kí o má sì kà á sí pé ṣe ni wọ́n kó iyán ẹ kéré tó bá jẹ́ pé ẹlòmíràn ló rí ìbùkún tàbí ọ̀rọ̀ ìyìn gbà.—Fi wé 1 Sámúẹ́lì 18:7-9.
6. Ipò líle koko wo ló dìde nínú ìjọ Kọ́ríńtì ọ̀rúndún kìíní?
6 Pọ́ọ̀lù fi kún un pé ìfẹ́ “kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Báa bá ní ẹ̀bùn kan tàbí táa mọ kiní kan-án ṣe, kò sídìí láti máa ganpá. Ó jọ pé èyí ni ìṣòro tó ń yọ àwọn kan tí ń jìjàdù ipò lẹ́nu, àwọn tó yọ́ wọnú ìjọ Kọ́ríńtì ìgbàanì. Ó lè jẹ́ pé ọ̀gá ni wọ́n nídìí ká ṣàlàyé ọ̀rọ̀ kó yéni, tàbí kó jẹ́ pé wọ́n mọ nǹkan-án ṣe lọ́nà tó gún régé. Ó lè jẹ́ pípè tí wọ́n ń pe àfiyèsí sára wọn ló dá kún pípín tí ìjọ náà pín sí oríṣiríṣi ẹgbẹ́. (1 Kọ́ríńtì 3:3, 4; 2 Kọ́ríńtì 12:20) Nígbà tí ọ̀ràn náà le dójú ẹ̀, Pọ́ọ̀lù wá ní láti bá àwọn ará Kọ́ríńtì wí kíkankíkan nítorí ‘fífaradà á fún àwọn aláìlọ́gbọ́n-nínú,’ tí Pọ́ọ̀lù bẹnu àtẹ́ lù, tó pè ní ‘àwọn àpọ́sítélì adárarégèé.’—2 Kọ́ríńtì 11:5, 19, 20.
7, 8. Fi hàn láti inú Bíbélì báa ṣe lè lo ẹ̀bùn èyíkéyìí táa bá ní láti fi gbé ìṣọ̀kan lárugẹ.
7 Irú ipò yẹn lè dìde lónìí. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan lè ní ìtẹ̀sí láti máa fi àwọn àṣeyọrí wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí àwọn àǹfààní wọn nínú ètò àjọ Ọlọ́run yangàn. Ká tiẹ̀ sọ pé a ní òye tàbí ìmọ̀ kan tí àwọn mìíràn nínú ìjọ kò ní, ṣé ìyẹn wá ní ká máa wú fùkẹ̀? Bẹ́ẹ̀ rèé, ṣe ló yẹ ká máa fi ẹ̀bùn èyíkéyìí táa bá ní gbé ìṣọ̀kan lárugẹ—kì í ṣe ká máa fi gbéra ga.—Mátíù 23:12; 1 Pétérù 5:6.
8 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara, “Ọlọ́run pa ara pọ̀ ṣọ̀kan.” (1 Kọ́ríńtì 12:19-26) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “pa pọ̀ ṣọ̀kan” tọ́ka sí àpòpọ̀ di ọ̀kan, bí ìgbà táa bá po onírúurú àwọ̀ pọ̀. Nítorí náà, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú ìjọ máa wú fùkẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó mọ̀ ọ́n ṣe, kó sì wá fẹ́ máa jẹgàba lé àwọn yòókù lórí. Ìgbéraga àti dídu ipò kò yẹ ètò àjọ Ọlọ́run rárá.—Òwe 16:19; 1 Kọ́ríńtì 14:12; 1 Pétérù 5:2, 3.
9. Àwọn àpẹẹrẹ tí ń kini nílọ̀ wo ni Bíbélì pèsè nípa àwọn kan tí ń wá ire tara wọn?
9 Ìfẹ́ “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:5) Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ kì í fọgbọ́n àyínìke darí àwọn ẹlòmíràn kí wọ́n lè ṣe ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀. Bíbélì ní àwọn àpẹẹrẹ tí ń kini nílọ̀ nínú ọ̀ràn yìí. Láti ṣàkàwé: A kà nípa Dẹ̀lílà, Jésíbẹ́lì, àti Ataláyà—àwọn obìnrin tó fọgbọ́n àyínìke darí àwọn ẹlòmíràn kí wọ́n lè ṣe ohun tí ń bẹ lọ́kàn wọn. (Onídàájọ́ 16:16; 1 Ọba 21:25; 2 Kíróníkà 22:10-12) Bẹ́ẹ̀ náà ni Ábúsálómù, ọmọ Dáfídì Ọba. Ó máa ń lọ bá àwọn tó bá wá sí Jerúsálẹ́mù fún ìdájọ́, yóò sì fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ gbìn ín sí wọn lọ́kàn pé ilé ẹjọ́ ọba kò rí àyè fún tiwọn. Yóò wá là á mọ́lẹ̀ pé ohun tí ilé ẹjọ́ náà nílò ní gidi ni èèyàn bíi tòun tó lójú àánú! (2 Sámúẹ́lì 15:2-4) Ó dájú pé tara Ábúsálómù gan-an ló ń rò, kò ro tàwọn tójú ń pọ́n. Bí ó ti ń ṣe bí ẹni tó fi ara rẹ̀ jọba, ó yí ọkàn-àyà ọ̀pọ̀ ènìyàn padà. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n ṣẹ́gun Ábúsálómù yán-án yán-án. Nígbà tó kú, wọn kò tilẹ̀ sin òkú rẹ̀ bí èèyàn gidi.—2 Sámúẹ́lì 18:6-17.
10. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ń mójú tó ire àwọn ẹlòmíràn?
10 Ìkìlọ̀ nìyí fún àwọn Kristẹni lónìí. Yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, a lè ní àbùdá mímọ báa ṣe lè fọ̀rọ̀ yíni lérò padà. A lè jẹ́ ẹni tó rọrùn fún láti ṣe é débi pé ohun tí a bá sọ láwùjọ ni abẹ gé, nípa ṣíṣàìfún àwọn tí wọ́n ní èrò tó yàtọ̀ sí tiwa láǹfààní láti sọ̀rọ̀, tàbí nípa títẹpẹlẹ mọ́ ọ̀rọ̀ títí a ó fi borí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́, a óò máa mójú tó ire àwọn ẹlòmíràn. (Fílípì 2:2-4) A ò ní máa tú àwọn ẹlòmíràn jẹ tàbí ká máa gbé àwọn èròǹgbà tí ń kọni lóminú lárugẹ nítorí ìrírí wa tàbí ipò wa nínú ètò àjọ Ọlọ́run, bí ẹni pé ojú ìwòye tiwa nìkan ló mọ́gbọ́n dání. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò máa rántí òwe Bíbélì tó sọ pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.”—Òwe 16:18.
Ìfẹ́ Máa Ń Jẹ́ Kí A Ní Àjọṣepọ̀ Alálàáfíà
11. (a) Lọ́nà wo la lè gbà fi ìfẹ́ tó ní inú rere tó sì ń hùwà lọ́nà tó bójú mu hàn? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo?
11 Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé pé ìfẹ́ ní “inú rere” àti pé “kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ kò ní jẹ́ ká hùwà lọ́nà tó fi hàn pé a jọ ara wa lójú, pé a ò mọ ohun tó tọ́, tàbí tó fi hàn pé a láfojúdi. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò máa gba tàwọn ẹlòmíràn rò. Fún àpẹẹrẹ, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ yóò yàgò fún ṣíṣe àwọn nǹkan tí yóò yọ ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn lẹ́nu. (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 8:13.) Ìfẹ́ “kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:6) Báa bá nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà, a ò ní fojú kékeré wo ìṣekúṣe, tàbí kí nǹkan tí Ọlọ́run kórìíra jẹ́ ohun ìgbádùn fún wa. (Sáàmù 119:97) Ìfẹ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa rí ayọ̀ nínú àwọn nǹkan tí ń gbéni ró, dípò àwọn nǹkan tí ń fa ìṣubú.—Róòmù 15:2; 1 Kọ́ríńtì 10:23, 24; 14:26.
12, 13. (a) Báwo ló ṣe yẹ ká hùwà padà tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá? (b) Mú àwọn àpẹẹrẹ kan wá láti inú Bíbélì láti fi hàn pé ìbínú tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ pàápàá lè jẹ́ ká hu ìwà tí kò bọ́gbọ́n mu.
12 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “a kì í tán [ìfẹ́] ní sùúrù” (“kì í kanra,” Phillips). (1 Kọ́ríńtì 13:5) Òtítọ́ ni pé kíá ni ara àwa ẹ̀dá ènìyàn aláìpé máa ń gbọgbẹ́ tàbí kí a bínú dé ìwọ̀n kan nígbà tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá. Ṣùgbọ́n, yóò lòdì láti máa di kùnrùngbùn tàbí ká sáà wà nínú ipò ìbínú yẹn títí. (Sáàmù 4:4; Éfésù 4:26) Bí a kò bá ṣàkóso ìbínú, ìbínú tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ pàápàá lè jẹ́ ká hu ìwà tí kò bọ́gbọ́n mu, Jèhófà sì lè dá wa lẹ́bi fún irú ìwà bẹ́ẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 34:1-31; 49:5-7; Númérì 12:3; 20:10-12; Sáàmù 106:32, 33.
13 Àwọn kan ti jẹ́ kí àìpé àwọn ẹlòmíràn nípa lórí ìpinnu wọn láti máa wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni tàbí láti máa nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Ọ̀pọ̀ lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ló ti ṣe gudugudu méje tẹ́lẹ̀ rí nínú jíja ìjà líle fún ìgbàgbọ́ wọn, bóyá ní fífarada àtakò ìdílé, ẹ̀gàn látọ̀dọ̀ àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n fara da irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n kà wọ́n sí ìdánwò ìwà títọ́, bẹ́ẹ̀ ló sì rí lóòótọ́. Ṣùgbọ́n kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ bí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn bá sọ nǹkan kan tàbí tó ṣe nǹkan kan tí kò fìfẹ́ hàn? Ṣé èyí náà kì í ṣe ìdánwò ìwà títọ́ ni? Ìdánwò ìwà títọ́ ni o, nítorí pé táa bá ń bá a lọ nínú ipò ìbínú, a lè “fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.”—Éfésù 4:27.
14, 15. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti “kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe”? (b) Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà nínú dídáríjini?
14 Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi fi kún un pé ìfẹ́ “kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” (1 Kọ́ríńtì 13:5) Èdè àwọn oníṣirò owó ló lò níhìn-ín, ó sì jọ pé ó lò ó láti fi hàn pé ẹni náà ń kọ ẹ̀ṣẹ̀ náà sínú ìwé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan, kó má bàa gbàgbé. Ǹjẹ́ ó fìfẹ́ hàn láti fi ọ̀rọ̀ tàbí ìwà kan tó dùn wá pa mọ́ sínú ọpọlọ wa, bí ẹni pé yóò tún wúlò lọ́jọ́ iwájú bí? Àbí ẹ ò rí bí inú wa ti dùn tó pé Jèhófà kì í ṣe òfíntótó wa lọ́nà àìláàánú bẹ́ẹ̀! (Sáàmù 130:3) Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ń pa ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́ nígbà táa bá ronú pìwà dà.—Ìṣe 3:19.
15 A lè fara wé Jèhófà nínú ọ̀ràn yìí. Kò yẹ kí a bínú kọjá ààlà nígbà tó bá jọ pé ẹnì kan tàbùkù wa. Bí a bá tètè ń bínú, a lè máa pa ara wa lára gidigidi ju bí ẹni tó ṣẹ̀ wá ti lè pa wá lára. (Oníwàásù 7:9, 22) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé ìfẹ́ “a máa gba ohun gbogbo gbọ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:7) Ṣùgbọ́n o, kò sí ìkankan nínú wa tó fẹ́ jẹ́ sùgọ́mù, ṣùgbọ́n kò tún wá yẹ ká máa fura láìnídìí nípa èrò ọkàn àwọn arákùnrin wa. Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ẹ jẹ́ ká gbà pé ẹnì kejì kò ní ète búburú lọ́kàn.—Kólósè 3:13.
Ìfẹ́ Máa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Ní Ìfaradà
16. Nínú àwọn ipò wo ni ìfẹ́ ti lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìpamọ́ra?
16 Pọ́ọ̀lù wá sọ fún wa pé “ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Ó ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti forí ti àwọn ipò ìṣòro, bóyá fún àkókò gígùn. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni ọ̀pọ̀ Kristẹni ti ń gbé nínú ìdílé tí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn mìíràn jẹ́ àpọ́n, kì í ṣe nítorí pé wọ́n fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí pé wọn kò rí ẹni tí wọ́n lè fẹ́ “nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39; 2 Kọ́ríńtì 6:14) Àwọn kan tún wà tí àìsàn tí ń sọni di hẹ́gẹhẹ̀gẹ kò jẹ́ kí wọ́n gbádùn. (Gálátíà 4:13, 14; Fílípì 2:25-30) Ká sòótọ́, nínú ètò aláìpé yìí, kò sẹ́ni tí kò nílò ìfaradà lọ́nà kan tàbí òmíràn nínú ìgbésí ayé rẹ̀.—Mátíù 10:22; Jákọ́bù 1:12.
17. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ohun gbogbo?
17 Pọ́ọ̀lù mú un dá wa lójú pé ìfẹ́ “a máa mú ohun gbogbo mọ́ra, . . . a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 13:7) Ìfẹ́ fún Jèhófà yóò mú kó ṣeé ṣe fún wa láti jìyà lábẹ́ ipò èyíkéyìí nítorí òdodo. (Mátíù 16:24; 1 Kọ́ríńtì 10:13) A kì í tìtorí ìgbàgbọ́ wa fọwọ́ ara wa fa ikú. Dípò bẹ́ẹ̀, góńgó wa ni láti máa gbé ìgbé-ayé alálàáfíà àti onídàákẹ́jẹ́. (Róòmù 12:18; 1 Tẹsalóníkà 4:11, 12) Síbẹ̀síbẹ̀, bí ìdánwò ìgbàgbọ́ bá dé, a ó fi tayọ̀tayọ̀ fara dà á gẹ́gẹ́ bí ara ohun tí jíjẹ́ Kristẹni ọmọlẹ́yìn ń ná wa. (Lúùkù 14:28-33) Báa ti ń fara dà á, a óò máa gbìyànjú láti ní ẹ̀mí tó dáa, a óò nírètí pé adùn ni yóò gbẹ̀yìn ipò líle koko wọ̀nyí.
18. Báwo la ṣe nílò ìfaradà lásìkò tó rọgbọ pàápàá?
18 Ìpọ́njú nìkan kọ́ ni ipò tí ń béèrè fún ìfaradà. Nígbà mìíràn, ohun tí ìfaradà túmọ̀ sí kò ju ká sáà máa bá ohun táa ń ṣe nìṣó, ká máa tọ ipa ọ̀nà táa ti fẹsẹ̀ lé, yálà àwọn ipò líle koko ń bẹ tàbí wọn ò sí. Ìfaradà wé mọ́ lílọ́wọ́ déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, ìwọ ha ń ní ìpín tó ṣe gúnmọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà bí, ní ìbámu pẹ̀lú ipò tó yí ẹ ká? O ha ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tóo ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀, tóo sì ń bá Baba rẹ ọ̀run sọ̀rọ̀ nínú àdúrà bí? O ha máa ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé, o ha sì máa ń jàǹfààní nínú pàṣípààrọ̀ ìṣírí pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ? Bóo bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà náà, yálà lásìkò tó rọgbọ tàbí lásìkò tó kún fún ìdààmú nísinsìnyí, o ń lo ìfaradà. Má ṣe juwọ́ sílẹ̀, “nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—Gálátíà 6:9.
Ìfẹ́ Jẹ́ “Ọ̀nà Títayọ Ré Kọjá”
19. Báwo ni ìfẹ́ ṣe jẹ́ “ọ̀nà títayọ ré kọjá”?
19 Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì fífìfẹ́ hàn nípa pípe ànímọ́ Ọlọ́run yìí ní “ọ̀nà títayọ ré kọjá.” (1 Kọ́ríńtì 12:31) Báwo ló ṣe jẹ́ “ọ̀nà títayọ ré kọjá”? Tóò, Pọ́ọ̀lù ṣẹ̀ṣẹ̀ ka àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí lẹ́sẹẹsẹ ni, èyí tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. A fún àwọn kan lágbára sísọ àsọtẹ́lẹ̀, àwọn mìíràn gba agbára wíwo àìsàn sàn, a fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ lágbára láti máa fi ẹ̀bùn ahọ́n sọ̀rọ̀. Àwọn àgbàyanu ẹ̀bùn mà ni ìwọ̀nyí ní tòótọ́! Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Bí mo bá ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n ènìyàn àti ti áńgẹ́lì ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, mo ti di abala idẹ kan tí ń dún tàbí aro aláriwo gooro. Bí mo bá sì ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì di ojúlùmọ̀ gbogbo àṣírí ọlọ́wọ̀ àti gbogbo ìmọ̀, bí mo bá sì ní gbogbo ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè ńláńlá nípò padà, ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ nǹkan kan.” (1 Kọ́ríńtì 13:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ìṣe táa lè gbà pé wọ́n ní láárí pàápàá lè di “òkú iṣẹ́,” bí kì í báá ṣe ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún aládùúgbò ló sún wa ṣe wọ́n.—Hébérù 6:1.
20. Èé ṣe táa fi nílò ìsapá tí kò dáwọ́ dúró bí a óò bá mú ìfẹ́ dàgbà?
20 Jésù fún wa ní ìdí mìíràn tó fi yẹ ká mú ìfẹ́ tó jẹ́ ànímọ́ Ọlọ́run yìí dàgbà. Ó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ọ̀rọ̀ náà “bí” dá a dá Kristẹni kọ̀ọ̀kan láti yàn yálà òun yóò kọ́ báa ṣe ń fìfẹ́ hàn tàbí òun kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, gbígbé ní ilẹ̀ àjèjì nìkan kò lè sọ ọ́ di dandan fún wa láti kọ́ sísọ èdè ilẹ̀ náà. Bẹ́ẹ̀ náà ni wíwulẹ̀ máa lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí dídarapọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni nìkan kò tóó kọ́ wa láti máa fìfẹ́ hàn. Kíkọ́ “èdè” yìí gba ìsapá tí kò dáwọ́ dúró.
21, 22. (a) Báwo ló ṣe yẹ ká hùwà padà bí a kò bá kúnjú ìwọ̀n àwọn apá kan tí Pọ́ọ̀lù jíròrò nípa ìfẹ́? (b) Lọ́nà wo la fi lè sọ pé “ìfẹ́ kì í kùnà láé”?
21 Nígbà mìíràn, o lè máà dójú ìwọ̀n àwọn apá kan tí Pọ́ọ̀lù jíròrò nípa ìfẹ́. Ṣùgbọ́n má jọ̀gọ̀nù. Máa tiraka nìṣó. Máa bá a lọ ní kíka Bíbélì, kí o sì máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò nínú ìbálò rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Má ṣe gbàgbé àpẹẹrẹ tí Jèhófà alára fi lélẹ̀ fún wa láé. Pọ́ọ̀lù ṣí àwọn ará Éfésù létí pé: “Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.”—Éfésù 4:32.
22 Àní gẹ́gẹ́ bí kíkọ́ láti sọ èdè tuntun ti máa ń rọrùn sí i lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn, ó jọ pé nígbà tó bá yá, ìwọ yóò rí i pé fífìfẹ́ hàn túbọ̀ ń rọrùn sí i. Pọ́ọ̀lù mú un dá wa lójú pé “ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (1 Kọ́ríńtì 13:8) Láìdàbí àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí tí a fi ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, títí ayé ni ìfẹ́ yóò máa wà. Nítorí náà, máa kọ́ bí a ṣe ń fi ànímọ́ Ọlọ́run yìí hàn. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti pè é, òun ni “ọ̀nà títayọ ré kọjá.”
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
◻ Báwo ni ìfẹ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìgbéraga?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni ìfẹ́ fi lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé àlàáfíà lárugẹ nínú ìjọ?
◻ Báwo ni ìfẹ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfaradà?
◻ Báwo ni ìfẹ́ ṣe jẹ́ “ọ̀nà títayọ ré kọjá”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ìfẹ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbójú fo àṣìṣe àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìfaradà túmọ̀ sí lílọ́wọ́ déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò ti ìṣàkóso Ọlọ́run