Báwo Lo Ṣe Lè Dẹni Tó Sún Mọ́ Ọlọ́run?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ sọ pé: “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú, ṣùgbọ́n gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.” (Róòmù 8:6) Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì yìí sọ fi hàn pé sísúnmọ́ Ọlọ́run kì í kàn ṣe ọ̀rọ̀ pé ó wuni láti ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí ọ̀rọ̀ ibi tọ́kàn ẹni fà sí. Dájúdájú, ọ̀rọ̀ ìyè tàbí ikú ni. Àmọ́ ọ̀nà wo lẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run ń gbà ní “ìyè àti àlàáfíà”? Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti fi hàn, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ní àlàáfíà nísinsìnyí, ìyẹn ni pé ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ó sì tún wà lálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, bákan náà ni yóò tún rí ẹ̀bùn ìyè ayérayé gbà lọ́jọ́ iwájú. (Róòmù 6:23; Fílípì 4:7) Abájọ tí Jésù fi sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn”!—Mátíù 5:3.
Kíkà tí ò ń ka ìwé ìròyìn yìí fi hàn pé o fẹ́ jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run, èyí sì bọ́gbọ́n mu. Síbẹ̀ èrò àwọn èèyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí yàtọ̀ síra gan-an, èyí sì lè mú kó o máa ronú pé: ‘Kí tiẹ̀ ni sísúnmọ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí? Àti pé báwo lèèyàn ṣe lè dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run?’
‘Èrò Inú Kristi’
Yàtọ̀ sí pé àpọ́sítẹ́lì Pọ́ọ̀lù sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run àtàwọn àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó tún sọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń fi hàn pé ẹnì kan sún mọ́ Ọlọ́run lóòótọ́. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé fáwọn Kristẹni tó wà nílùú Kọ́ríńtì ayé ọjọ́un nípa ìyàtọ̀ tó wà nínú ẹnì kan tó jẹ́ ẹni ti ara, ìyẹn ẹni tó máa ń ṣe ohunkóhun tí ara bá ṣáà ti fẹ́, àti ẹni tẹ̀mí, ìyẹn ẹni tó mọyì àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ènìyàn ti ara kì í gba àwọn nǹkan ti ẹ̀mí Ọlọ́run, nítorí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni wọ́n jẹ́ lójú rẹ̀.” Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ẹni tẹ̀mí lẹni tó ní “èrò inú ti Kristi.”—1 Kọ́ríńtì 2:14-16.
Ohun tí níní ‘èrò inú Kristi’ túmọ̀ sí ní pọ́ńbélé ni kéèyàn ní irú “ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.” (Róòmù 15:5; Fílípì 2:5) Ká sọ ọ́ lọ́nà mìíràn, ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run lẹni tó máa ń ronú bí Jésù ṣe ń ronú tó sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (1 Pétérù 2:21; 4:1) Bí ọ̀nà tẹ́nì kan ń gbà ronú bá ṣe túbọ̀ ń jọ ti Kristi sí, lẹni náà á ṣe máa sún mọ́ Ọlọ́run tó, tí yóò sì túbọ̀ máa dẹni tó máa ní “ìyè àti àlàáfíà.”—Róòmù 13:14.
Bó O Ṣe Lè Mọ ‘Èrò Inú Kristi’
Àmọ́ kí ẹnì kan tó lè ní èrò inú Kristi, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ohun tí èrò inú yẹn jẹ́. Nípa báyìí, ohun téèyàn máa kọ́kọ́ ṣe láti lè dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run ni pé kéèyàn mọ bí Jésù ṣe ń ronú. Àmọ́ báwo lo ṣe lè mọ ọ̀nà tí ẹnì kan tó gbé ayé ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn ṣe ń ronú? Ó dáa, báwo lo ṣe mọ̀ nípa àwọn tó o máa ń gbórúkọ wọn nínú ìtàn orílẹ̀-èdè rẹ? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe lo kàwé tó sọ̀rọ̀ nípa wọn. Bákan náà lọ̀rọ̀ mímọ Kristi ṣe rí, kíka ìtàn rẹ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì téèyàn fi lè mọ bí Kristi ṣe ń ronú.—Jòhánù 17:3.
Téèyàn bá fẹ́ mọ̀ nípa Jésù, àkọsílẹ̀ mẹ́rin ló wà tó ṣàlàyé ìtàn rẹ̀ ní kedere. Ìwé Ìhìn Rere ni wọ́n ń pe àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí, àwọn tó sì kọ wọ́n ni Mátíù, Máàkù, Lúùkù, àti Jòhánù. Tó o bá ń fara balẹ̀ ka àwọn ìtàn wọ̀nyí, á jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tí Jésù ń gbà ronú, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀, àtohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ tó mú kó ṣe àwọn ohun tó ṣe. Tó o bá wá ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó o kà nípa Jésù, wàá bẹ̀rẹ̀ sí í fojú inú rí irú ẹni tí Jésù jẹ́. Kódà, ká tiẹ̀ ní o gbà pé ọmọlẹ́yìn Kristi ni ọ́, tó o bá ka àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí tó o sì ronú jinlẹ̀ lórí wọn, èyí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti “máa bá a lọ ní dídàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.”—2 Pétérù 3:18.
Níbi tá a ṣàlàyé dé yìí, jẹ́ ká ka àwọn ibì kan nínú Ìwé Ìhìn Rere láti lè rí ohun tó mú kí Jésù jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run gan-an. Lẹ́yìn náà, wá bi ara rẹ bó o ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀.—Jòhánù 13:15.
Bí “Èso Ti Ẹ̀mí” Ṣe Ń Mú Kéèyàn Dẹni Tó Sún Mọ́ Ọlọ́run
Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ pé Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí Jésù nígbà tó ṣèrìbọmi àti pé Jésù “kún fún ẹ̀mí mímọ́.” (Lúùkù 3:21, 22; 4:1) Jésù fúnra rẹ̀ jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tàbí ‘agbára ìṣiṣẹ́’ rẹ̀ máa darí wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2; Lúùkù 11:9-13) Kí nìdí téyìí fi ṣe pàtàkì gan-an? Nítorí pé ẹ̀mí Ọlọ́run lágbára láti yí èrò inú èèyàn padà, débi pé èrò inú ẹni yẹn á bẹ̀rẹ̀ sí í jọ èrò inú ti Kristi. (Róòmù 12:1, 2) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ń jẹ́ kéèyàn ní àwọn ànímọ́ bí “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” Bí ẹnì kan bá ṣe fi àwọn ànímọ́ yìí, tí Bíbélì pè ní “èso ti ẹ̀mí” hàn tó, la fi ń mọ bó ṣe sún mọ́ Ọlọ́run tó. (Gálátíà 5:22, 23) Ní kúkúrú, ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run lẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí rẹ̀.
Jésù fi èso tẹ̀mí hàn nínú ìwà rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, inú rere, àti ìwà rere hàn gan-an nínú ọ̀nà tó gbà hùwà sáwọn èèyàn táwọn kan kà sẹ́ni tí kò já mọ́ nǹkan kan láwùjọ. (Mátíù 9:36) Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí ohun kan tó ṣẹlẹ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. A kà pé: “Bí [Jésù] ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí.” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí ọkùnrin yìí, àmọ́ ojú pé ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n fi wò ó. Èyí ló mú kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ta ni ó ṣẹ̀, ọkùnrin yìí ni tàbí àwọn òbí rẹ̀?” Àwọn aládùúgbò ọkùnrin yẹn náà máa ń rí i, àmọ́ alágbe lásán ni wọ́n kà á sí. Wọ́n sọ pé: “Èyí ni ọkùnrin tí ó ti máa ń jókòó ṣagbe, àbí òun kọ́?” Àmọ́ Jésù rí ọkùnrin yìí gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tó nílò ìrànlọ́wọ́. Ó bá ọkùnrin afọ́jú náà sọ̀rọ̀ ó sì wò ó sàn.—Jòhánù 9:1-8.
Kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa ọ̀nà tí Jésù ń gbà ronú? Àkọ́kọ́, Jésù kì í fojú pa àwọn ẹni rírẹlẹ̀ rẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló máa ń fi ìyọ́nú bá wọn lò. Èkejì, ó nífẹ̀ẹ́ sí ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ǹjẹ́ o rò pé ò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ yìí? Ṣé ojú tí Jésù fi ń wo àwọn èèyàn lo fi ń wò wọ́n, ṣé o máa ń ṣèrànwọ́ tí wọ́n nílò fún wọn káyé wọn lè túbọ̀ dára sí i nísinsìnyí kí wọ́n sì lè nírètí pé ọjọ́ ọ̀la àwọn á dára? Àbí àwọn tó rọ́wọ́ mú nìkan lo máa ń ṣe dáadáa sí tó o sì máa ń fojú pa àwọn tó jẹ́ tálákà rẹ́? Bó o bá ń wo àwọn èèyàn lọ́nà tí Jésù ń gbà wò wọ́n, a jẹ́ pé ò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lóòótọ́.—Sáàmù 72:12-14.
Àdúrà Ń Múni Sún Mọ́ Ọlọ́run
Àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìhìn Rere fi hàn pé ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run. (Máàkù 1:35; Lúùkù 5:16; 22:41) Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó máa ń dìídì ya àkókò sọ́tọ̀ láti gbàdúrà. Mátíù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn rírán àwọn ogunlọ́gọ̀ náà lọ, [Jésù] gun òkè ńlá lọ ní òun nìkan láti gbàdúrà.” (Mátíù 14:23) Jésù rí okun gbà láwọn àkókò tó fi ń bá Baba rẹ̀ ọ̀run sọ̀rọ̀ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ yìí. (Mátíù 26:36-44) Lóde òní, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an máa ń wá àkókò tí wọ́n á fi bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé èyí á mú kí àjọṣe àárín àwọn àti Ọlọ́run túbọ̀ dán mọ́rán sí i, á sì jẹ́ kí ìrònú àwọn túbọ̀ máa jọ ti Kristi sí i.
Jésù sábà máa ń lo àkókò gígùn tó bá ń gbàdúrà. (Jòhánù 17:1-26) Bí àpẹẹrẹ, kí Jésù tó yan àwọn ọkùnrin méjìlá tó wá di àpọ́sítélì rẹ̀, ó “lọ sórí òkè ńlá láti gbàdúrà, ó sì ń bá a lọ nínú àdúrà gbígbà sí Ọlọ́run ní gbogbo òru náà.” (Lúùkù 6:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó sún mọ́ Ọlọ́run lè má fi gbogbo òru gbàdúrà, síbẹ̀ wọ́n máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Kí wọ́n tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé wọn, wọ́n á wá àkókò tó pọ̀ tó láti gbàdúrà sí Ọlọ́run, wọ́n á bẹ̀ ẹ́ pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tọ́ àwọn sọ́nà káwọn lè ṣe ìpinnu tó máa jẹ́ káwọn lè túbọ̀ sún mọ́ ọn.
Nínú àwọn àdúrà tí Jésù gbà, ó tún jẹ́ ká rí i pé àwọn àdúrà náà jẹ òun lọ́kàn gan-an, èyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ ká tẹ̀ lé nígbà tá a bá ń gbàdúrà. Kíyè sí ohun tí Lúùkù sọ nípa bí Jésù ṣe gbàdúrà lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí Jésù kú? Ó ní: “Bí ó ti wà nínú ìroragógó, ó ń bá a lọ ní títúbọ̀ fi taratara gbàdúrà; òógùn rẹ̀ sì wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sí ilẹ̀.” (Lúùkù 22:44) Jésù ti máa ń fi taratara gbàdúrà tẹ́lẹ̀, àmọ́ lákòókò yìí, tó dojú kọ àdánwò tó le jù lọ nínú gbogbo àdánwò tó rí nígbà tó wà láyé, ó ‘túbọ̀ fi’ taratara gbàdúrà, Ọlọ́run sì dáhùn àdúrà rẹ̀. (Hébérù 5:7) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Nígbà tí wọ́n bá dojú kọ àdánwò tó le gan-an, wọ́n máa ń ‘túbọ̀ fi taratara’ gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún àwọn ní ẹ̀mí mímọ́, pé kó tọ́ àwọn sọ́nà, kó sì ran àwọn lọ́wọ́.
Níwọ̀n bó ti hàn kedere pé Jésù jẹ́ ẹni tó máa ń gbàdúrà gan-an, kò yani lẹ́nu pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fẹ́ láti fara wé e nínú ọ̀rọ̀ àdúrà gbígbà. Ìdí rèé tí wọ́n fi sọ fún un pé: “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.” (Lúùkù 11:1) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, àwọn tó sún mọ́ Ọlọ́run lóòótọ́ tí wọ́n sì fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ máa darí àwọn máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú bí wọ́n ṣe máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run. Èèyàn ò lè jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run láìjẹ́ ẹni tó máa ń gbàdúrà.
Wíwàásù Ìhìn Rere Ń Múni Sún Mọ́ Ọlọ́run
Nínú ìwé Ìhìn Rere ti Máàkù, a kà nípa bí Jésù ṣe wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tára wọn ò dá sàn, tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ títí dòru ọ̀gànjọ́. Láàárọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, nígbà tó dá nìkan wà tó ń gbàdúrà lọ́wọ́, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wá wọ́n sì sọ fún un pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń fẹ́ láti rí i, bóyá wọ́n fẹ́ kó wo àwọn sàn. Àmọ́ Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibòmíràn, sí àwọn ìlú abúlé tí ó wà nítòsí, kí èmi lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú.” Lẹ́yìn náà ni Jésù wá sọ ìdí tó fi sọ ohun tó sọ yìí, ó ní: “Nítorí fún ète yìí ni mo ṣe jáde lọ.” (Máàkù 1:32-38; Lúùkù 4:43) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ka wíwo àwọn èèyàn sàn sóhun tó ṣe pàtàkì, síbẹ̀ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni olórí iṣẹ́ tí Jésù torí ẹ̀ wá sáyé.—Máàkù 1:14, 15.
Lóde òní, sísọ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn ṣì jẹ́ ọ̀kan lára àmì tá a fi ń dá àwọn tó ní irú èrò tí Kristi ní mọ̀. Jésù pàṣẹ fún gbogbo àwọn tó fẹ́ láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Bákan náà, Jésù tún sàsọtẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Níwọ̀n bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti fi hàn pé nípa agbára ẹ̀mí mímọ́ ni iṣẹ́ ìwàásù á fi ṣeé ṣe, kíkópa gan-an nínú iṣẹ́ yìí jẹ́ àmì tó ń fi hàn pé ẹnì kan sún mọ́ Ọlọ́run lóòótọ́.—Ìṣe 1:8.
Láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn tó ń gbé láyé gba pé kí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tó ń ṣe iṣẹ́ náà wà níṣọ̀kan. (Jòhánù 17:20, 21) Kì í ṣe pé àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ yìí ní láti jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún gbọ́dọ̀ wà létòlétò jákèjádò ayé. Ǹjẹ́ o lè sọ àwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi tí wọ́n sì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run níbi gbogbo láyé?
Ǹjẹ́ O Sún Mọ́ Ọlọ́run?
Lóòótọ́, àwọn nǹkan mìíràn tún wà tá a fi ń dá ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run mọ̀, àmọ́ báwo ni ìwọ́ ṣe ń ṣe sí nínú àwọn tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí? Tó o bá fẹ́ mọ̀, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mò ń ka Bíbélì tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ṣé mo sì ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí mo bá kà? Ǹjẹ́ mò ń fi èso ti ẹ̀mí hàn nínú ìgbésí ayé mi? Ṣé mo jẹ́ ẹni tó ń gbàdúrà nígbà gbogbo? Ǹjẹ́ mo fẹ́ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ayé?’
Tó o bá fi òótọ́ inú yẹ ara rẹ wò, èyí lè jẹ́ kó o mọ bó o ṣe sún mọ́ Ọlọ́run tó. A rọ̀ ọ́ pé kó o ṣe àwọn ohun tó tọ́ àtohun tó yẹ nísinsìnyí kí “ìyè àti àlàáfíà” lè jẹ́ tìrẹ.—Róòmù 8:6; Mátíù 7:13, 14; 2 Pétérù 1:5-11.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
ÀWỌN OHUN TÁ A FI Ń DÁ ẸNI TÓ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN MỌ̀
◆ Jíjẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
◆ Fífi èso ti ẹ̀mí hàn
◆ Fífi gbogbo ọkàn gbàdúrà sí Ọlọ́run déédéé
◆ Wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíràn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Bíbélì yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ‘èrò inú Kristi’