ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 45
Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́
“Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”—FÍLÍ. 4:13.
ORIN 104 Ẹ̀bùn Ọlọ́run Ni Ẹ̀mí Mímọ́
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. (a) Kí ló ń jẹ́ ká lè máa fara da ìṣòro? Ṣàlàyé. (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
TÁWỌN kan bá ń ronú nípa ohun tí wọ́n ti fara dà, wọ́n máa ń sọ pé Jèhófà ló ran àwọn lọ́wọ́, kì í ṣe agbára àwọn. Ṣé ìwọ náà ti sọ bẹ́ẹ̀ rí, bóyá lẹ́yìn tó o fara da àìsàn tó le gan-an tàbí lẹ́yìn ikú ẹnì kan tó o fẹ́ràn? Nígbà tó o wá ń ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, o rí i pé Jèhófà ló fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o fi ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.”—2 Kọ́r. 4:7-9.
2 Yàtọ̀ síyẹn, a tún nílò ẹ̀mí mímọ́ kí ayé yìí má bàa kéèràn ràn wá. (1 Jòh. 5:19) Bákan náà, a nílò ẹ̀mí mímọ́ ká lè bá àwọn “ẹ̀mí burúkú” wọ̀yá ìjà. (Éfé. 6:12) Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà méjì tí ẹ̀mí mímọ́ ń gbà ràn wá lọ́wọ́. A tún máa sọ àwọn ohun tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ dáadáa láyé wa.
Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ MÁA Ń FÚN WA LÁGBÁRA
3. Sọ ọ̀nà kan tí Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro.
3 Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ní ti pé ó máa ń fún wa lágbára tàbí okun ká lè ṣe gbogbo ohun tó yẹ láìka ìṣòro wa sí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé “agbára Kristi” ló ran òun lọ́wọ́ láti máa fara dà á kóun sì máa bá iṣẹ́ òun lọ. (2 Kọ́r. 12:9) Nígbà tó rìnrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, kì í ṣe iṣẹ́ ìwàásù nìkan ló ṣe, ó tún ṣiṣẹ́ kára kó lè rówó gbọ́ bùkátà ara ẹ̀. Nígbà tó wà nílùú Kọ́ríńtì, ilé Ákúílà àti Pírísílà ló dé sí. Iṣẹ́ àgọ́ pípa ni tọkọtaya yìí ń ṣe, torí pé iṣẹ́ yìí kan náà ni Pọ́ọ̀lù ń ṣe, ó máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn láwọn ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀. (Ìṣe 18:1-4) Ẹ̀mí mímọ́ ló fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, òun náà ló sì jẹ́ kó ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú.
4. Bó ṣe wà nínú 2 Kọ́ríńtì 12:7b-9, ìṣòro wo ni Pọ́ọ̀lù ní?
4 Ka 2 Kọ́ríńtì 12:7b-9. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé òun ní ‘ẹ̀gún kan nínú ara’? Tí ẹ̀gún tàbí ìgbálẹ̀ bá gún èèyàn lọ́wọ́, tí kò sì tíì yọ, ó máa ń dunni gan-an. Torí náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé òun láwọn ìṣòro kan tó ń bá òun fínra. Ó sọ pé ìṣòro náà dà bí ìgbà tí “áńgẹ́lì Sátánì” ń ‘gbá òun ní àbàrá’ (‘lu òun’ àlàyé ìsàlẹ̀). Ó lè má jẹ́ Sátánì tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ gangan ló fa ìṣòro Pọ́ọ̀lù bí ẹni pé àwọn ló ki ẹ̀gún sínú ara ẹ̀. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nígbà táwọn ẹ̀mí burúkú yìí rí i pé ó níṣòro tó dà bí “ẹ̀gún,” ṣe ni wọ́n mú kó túbọ̀ nira fún un bíi pé wọ́n ń gbá ẹ̀gún náà wọnú sí i. Kí ni Pọ́ọ̀lù wá ṣe?
5. Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà Pọ́ọ̀lù?
5 Ohun tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ ni pé kí Jèhófà bá òun yọ “ẹ̀gún” náà kúrò pátápátá. Ó sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀mẹta ni mo bẹ Olúwa [Jèhófà] . . . kó lè kúrò lára mi.” Láìka gbogbo àdúrà tí Pọ́ọ̀lù gbà, ẹ̀gún ọ̀hún ò mà kúrò níbẹ̀. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà ẹ̀ ni? Rárá o. Ó dáhùn ẹ̀, lóòótọ́ Jèhófà ò mú ìṣòro náà kúrò, àmọ́ ó fún un lágbára kó lè fara dà á. Jèhófà fi dá a lójú pé: “À ń sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” (2 Kọ́r. 12:8, 9) Torí pé Jèhófà ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ gan-an, ó láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ọkàn ẹ̀ sì balẹ̀!—Fílí. 4:4-7.
6. (a) Àwọn ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí Jèhófà gbà dáhùn àdúrà wa? (b) Èwo ló fún ẹ lókun nínú àwọn ìlérí Jèhófà tó wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà ní ìpínrọ̀ yìí?
6 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ṣé ìwọ náà ti bẹ Jèhófà rí pé kó yọ ẹ́ kúrò nínú ìṣòro kan àmọ́ tí ìṣòro náà ò lọ? Bóyá ṣe ló tiẹ̀ ń le sí i, tó o wá ń ronú pé àbí inú Jèhófà ò dùn sí ẹ ni? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù. Jèhófà máa dáhùn àdúrà ẹ bó ṣe dáhùn àdúrà Pọ́ọ̀lù. Jèhófà lè má mú ìṣòro náà kúrò. Àmọ́ ó lè fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ kó o lè fara da ìṣòro náà. (Sm. 61:3, 4) ‘Wọ́n lè gbé ẹ ṣánlẹ̀,’ àmọ́ Jèhófà ò ní pa ọ́ tì láé.—2 Kọ́r. 4:8, 9; Fílí. 4:13.
Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ Ń MÚ KÁ MÁA SIN JÈHÓFÀ
7-8. (a) Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe máa ń ṣiṣẹ́ bí atẹ́gùn? (b) Báwo ni Pétérù ṣe ṣàpèjúwe bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣiṣẹ́?
7 Ọ̀nà míì wo ni ẹ̀mí mímọ́ máa ń gbà ràn wá lọ́wọ́? Bí ìjì tí kò le tàbí atẹ́gùn ṣe máa ń rọra darí ọkọ̀ ojú omi lọ síbi tí ọkọ̀ náà fẹ́ lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́, tó sì máa ń tì wá lẹ́yìn ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí wọnú ayé tuntun láìka àwọn ìṣòro wa sí.
8 Àpọ́sítélì Pétérù mọ bí wọ́n ṣe ń wa ọkọ̀ ojú omi dáadáa torí pé apẹja ni. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu nígbà tó fi bí wọ́n ṣe ń wọkọ̀ ojú omi wé bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣiṣẹ́. Ó sọ pé: “A ò fìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípasẹ̀ ìfẹ́ èèyàn, àmọ́ àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.” Ní tààràtà, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “darí” túmọ̀ sí “sún wọn; mú kí wọ́n gba ìmísí.”—2 Pét. 1:21; àlàyé ìsàlẹ̀.
9. Kí ni Pétérù fẹ́ ká mọ̀ nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “darí”?
9 Kí ni Pétérù fẹ́ ká mọ̀ nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “darí” tàbí sún wọn? Lúùkù tó kọ ìwé Ìṣe náà lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó jọ èyí nígbà tó ń sọ bí ‘ìjì ṣe ń gbá ọkọ̀ kan lọ.’ (Ìṣe 27:15) Kódà, ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ pé nígbà tí Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó kọ Bíbélì, ó lo ọ̀rọ̀ náà “sún wọn,” ọ̀rọ̀ yìí jọ bí atẹ́gùn ṣe máa ń sún ọkọ̀ ojú omi síwájú. Ohun tí Pétérù ń sọ ni pé bí atẹ́gùn ṣe ń sún ọkọ̀ ojú omi kan dé ibi tó ń lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí àwọn wòlíì àtàwọn tó kọ Bíbélì kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. Ọ̀mọ̀wé kan náà yẹn sọ pé: “A lè sọ pé àwọn wòlíì yẹn ta ìgbòkun ọkọ̀ wọn, [ìyẹn aṣọ tó máa ń wà lórí ọkọ̀].” Jèhófà ṣe ipa tirẹ̀ torí òun ló pèsè “ìjì” tàbí atẹ́gùn, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́. Àwọn tó kọ Bíbélì náà sì ṣe ipa tiwọn torí wọ́n jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ darí wọn.
10-11. Àwọn nǹkan méjì wo ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣiṣẹ́ láyé wa? Sọ àpèjúwe kan.
10 Lónìí, ó dájú pé ẹ̀mí mímọ́ ò darí àwọn èèyàn mọ́ láti kọ Ìwé Mímọ́. Síbẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ ṣì ń darí àwa èèyàn Ọlọ́run. Ó dájú pé Jèhófà ń ṣe ipa tiẹ̀. Àmọ́, kí ló yẹ ká ṣe kí ẹ̀mí mímọ́ lè máa darí àwa náà? A gbọ́dọ̀ rí i pé à ń ṣe ipa tiwa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
11 Ẹ wo àpèjúwe yìí ná. Kí atẹ́gùn tó lè ṣe awakọ̀ kan láǹfààní, àwọn nǹkan méjì kan wà tó gbọ́dọ̀ ṣe. Àkọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ gbé ọkọ̀ ẹ̀ lọ síbi tí afẹ́fẹ́ ti ń fẹ́. Ó ṣe tán, ọkọ̀ náà ò ní kúrò lójú kan tí awakọ̀ ò bá kúrò ní èbúté níbi tó so ọkọ̀ náà sí. Ìkejì, ó gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun ta ìgbòkun ọkọ̀ náà sókè. Síbẹ̀, ó dìgbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ lu aṣọ tó ta sókè ọkọ̀ náà kó tó kúrò níbi tó wà. Lọ́nà kan náà, ẹ̀mí mímọ́ nìkan ló lè mú ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́ tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣiṣẹ́ dáadáa láyé wa, àwọn nǹkan méjì kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ wà níbi tí ẹ̀mí mímọ́ ti lè darí wa, ìyẹn ni pé ká máa ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe. Ìkejì, a gbọ́dọ̀ “ta ìgbòkun ọkọ̀” wa bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, lédè míì, ká máa ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé bá a ti ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Sm. 119:32) Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ẹ̀mí mímọ́ á máa darí wa nínú ayé tó kún fún wàhálà àti àdánwò yìí, á sì mú ká jẹ́ olóòótọ́ wọnú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.
12. Kí la máa jíròrò báyìí?
12 A ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà méjì tí ẹ̀mí mímọ́ ń gbà ràn wá lọ́wọ́. Àkọ́kọ́ ni pé ó máa ń fún wa lágbára, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ tá a bá kojú àdánwò. Ó tún máa ń darí wa lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, kò sì ní jẹ́ ká kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ní báyìí, a máa jíròrò nǹkan mẹ́rin tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣiṣẹ́ láyé wa fàlàlà.
OHUN TÁÁ MÚ KÍ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ MÁA ṢIṢẸ́ LÁYÉ WA FÀLÀLÀ
13. Bó ṣe wà nínú 2 Tímótì 3:16, 17, kí ni Ìwé Mímọ́ máa ń ṣe fún wa, àmọ́ kí làwa náà gbọ́dọ̀ ṣe?
13 Àkọ́kọ́, máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ka 2 Tímótì 3:16, 17.) Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti “mí sí” àwọn tó kọ Bíbélì. Tá a bá ka Bíbélì, tá a sì ronú jinlẹ̀ nípa ohun tá a kà, ìyẹn á mú káwọn ìtọ́ni Ọlọ́run wọnú ọkàn wa. Àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run mí sí yẹn á wá jẹ́ ká máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Héb. 4:12) Àmọ́, tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣiṣẹ́ lára wa fàlàlà, a gbọ́dọ̀ ṣètò àkókò wa ká lè máa ka Bíbélì déédéé, ká sì máa ronú jinlẹ̀ nípa ohun tá a kà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń darí wa.
14. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé afẹ́fẹ́ Jèhófà ń fẹ́ láwọn ìpàdé wa? (b) Báwo la ṣe lè túbọ̀ rí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ gbà láwọn ìpàdé wa?
14 Ìkejì, máa jọ́sìn Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ará. (Sm. 22:22) Lọ́nà kan, a lè sọ pé afẹ́fẹ́ Jèhófà ń fẹ́ láwọn ìpàdé wa torí pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà wà níbẹ̀. (Ìfi. 2:29) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a máa ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà nípàdé, a tún máa ń kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn arákùnrin tí ẹ̀mí mímọ́ yàn máa ń fún wa láwọn ìtọ́ni tá a gbé karí Bíbélì. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ẹ̀mí mímọ́ tún máa ń ran àwọn arábìnrin lọ́wọ́ láti múra iṣẹ́ wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì ṣe é nípàdé. Torí náà, tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣiṣẹ́ lára wa fàlàlà, a gbọ́dọ̀ máa múra ìpàdé sílẹ̀, ká sì máa kópa níbẹ̀. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ṣe ló dà bíi pé a ta “ìgbòkun” ọkọ̀ wa.
15. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
15 Ìkẹta, máa wàásù déédéé. Gbogbo ìgbà tá a bá ń lo Bíbélì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni là ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. (Róòmù 15:18, 19) Tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ṣiṣẹ́ lára wa fàlàlà, a gbọ́dọ̀ máa wàásù déédéé, ká sì máa lo Bíbélì dáadáa bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ọ̀nà kan tá a lè gbà mú kí iṣẹ́ ìwàásù wa túbọ̀ nítumọ̀ ni pé ká máa lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́.
16. Ọ̀nà wo ló ṣe tààràtà jù tá a lè gbà rí ẹ̀mí mímọ́ gbà?
16 Ìkẹrin, máa gbàdúrà sí Jèhófà. (Mát. 7:7-11; Lúùkù 11:13) Ọ̀nà tó ṣe tààràtà jù tá a lè gbà rí ẹ̀mí mímọ́ gbà ni pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Kò sí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni tó lè dènà àdúrà wa tàbí tó lè ní ká má rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà. Ti pé a wà nínú ẹ̀wọ̀n kò ní ká má rí i gbà, bẹ́ẹ̀ sì ni Sátánì alára ò lè dènà ẹ̀. (Jém. 1:17) Torí náà, báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà tá a bá fẹ́ rí ẹ̀mí mímọ́ gbà? Ká lè rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àpèjúwe kan tó jẹ́ ká mọ púpọ̀ sí i nípa àdúrà, inú ìwé Ìhìn Rere Lúùkù nìkan ni àpèjúwe yìí wà.b
MÁA GBÀDÚRÀ LÉRALÉRA
17. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nínú Lúùkù 11:5-9, 13?
17 Ka Lúùkù 11:5-9, 13. Àpèjúwe tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí mímọ́. Nínú àpèjúwe yẹn, ọkùnrin náà rí ohun tó fẹ́ gbà torí pé “ó ń fi ìgboyà béèrè léraléra.” Kò bẹ̀rù láti sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé kó ran òun lọ́wọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ ti ṣú. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lúùkù 11:8 nínú Ìwé Ìpàdé July 2018.) Kí ni Jésù fẹ́ fi àpèjúwe yìí kọ́ wa? Ó ní: “Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín.” Torí náà, ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́? Tá a bá fẹ́ rí ẹ̀mí mímọ́ gbà, a gbọ́dọ̀ máa bẹ̀bẹ̀ fún un léraléra.
18. Níbàámu pẹ̀lú àpèjúwe Jésù, kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀?
18 Àpèjúwe Jésù jẹ́ ká rí ìdí tí Jèhófà fi máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ọkùnrin tí Jésù sọ nínú àpèjúwe yẹn fẹ́ fi hàn pé òun lẹ́mìí aájò àlejò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ní nǹkan kan nílé, ilẹ̀ sì ti ṣú, ó mọ̀ pé ó yẹ kóun wá nǹkan fi ṣe àlejò òun tó dé lóru yẹn. Jésù sọ pé ọ̀rẹ́ ọkùnrin yẹn dá a lóhùn torí pé onítọ̀hún kò yéé bẹ̀ ẹ́ pé kó fún òun ní búrẹ́dì. Kí ni Jésù fẹ́ fi àpèjúwe yìí kọ́ wa? Tí èèyàn tó jẹ́ aláìpé bá lè ran aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́ torí pé kò yéé bẹ̀ ẹ́, mélòómélòó ni Jèhófà tó jẹ́ Baba wa onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú. Ó dájú pé ó máa dáhùn àdúrà gbogbo àwọn tó bá ń béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ tí wọn ò sì jẹ́ kó sú wọn! Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà tó ò ń gbà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—Sm. 10:17; 66:19.
19. Kí ló mú kó dá wa lójú pé a máa ṣẹ́gun?
19 Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé láìka gbogbo bí Sátánì ṣe ń halẹ̀ mọ́ wa, tó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti borí wa, àwa la máa ṣẹ́gun ẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Kí nìdí tó fi dá wa lójú tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀nà méjì ni ẹ̀mí mímọ́ ń gbà ràn wá lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, ó ń fún wa lágbára láti borí àdánwò. Ìkejì, ó ń darí wa nínú ayé tó kún fún wàhálà àti àdánwò yìí, ó ń mú ká jẹ́ olóòótọ́, á sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó títí tá a fi máa wọnú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a máa gba ẹ̀mí mímọ́ láyè láti ṣiṣẹ́ fàlàlà nígbèésí ayé wa!
ORIN 41 Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da ìṣòro. A tún máa rí ohun tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ láyé wa.
c ÀWÒRÁN: ÌGBÉSẸ̀ 1: Arákùnrin àti arábìnrin kan dé Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí wọ́n ṣe ń wà nípàdé pẹ̀lú àwọn ará fi hàn pé wọ́n ń pésẹ̀ síbi tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà wà. ÌGBÉSẸ̀ 2: Wọ́n múra sílẹ̀ dáadáa kí wọ́n lè dáhùn nípàdé. Àwọn ìgbésẹ̀ méjì tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí náà ló yẹ ká gbé tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá à ń wàásù, tá a sì ń gbàdúrà sí Jèhófà.