ORIN 104
Ẹ̀bùn Ọlọ́run Ni Ẹ̀mí Mímọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Bàbá aláàánú ni ọ́, Jèhófà.
O nífẹ̀ẹ́ wa bá a tiẹ̀ jẹ́lẹ́ṣẹ̀.
Jọ̀ọ́ ràn wá lọ́wọ́, jẹ́ kára tù wá.
Fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ tù wá nínú.
2. Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ń mú ká ṣàṣìṣe,
Ká sì pàdánù ojúure rẹ.
Bàbá, a bẹ̀ ọ́, gbọ́ àdúrà wa:
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ máa darí wa.
3. Tá a bá sorí kọ́ tàbí tó rẹ̀ wá,
Bàbá, jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ
Fún wa lágbára bíi t’ẹyẹ idì;
Jẹ́ ká máa rí ẹ̀mí mímọ́ rẹ gbà.
(Tún wo Sm. 51:11; Jòh. 14:26; Ìṣe 9:31.)