Ìfẹ́—Ànímọ́ Kan Tó Ṣe Pàtàkì
LÁBẸ́ ìmísí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ mẹ́sàn-án tí ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ ká ní. (Gál. 5:22, 23) Ó ní àwọn ànímọ́ mẹ́sàn-án yìí ló para pọ̀ jẹ́ “èso ti ẹ̀mí.”a Èso tẹ̀mí yìí wà lára “àkópọ̀ ìwà tuntun” tí Bíbélì mẹ́nu kàn. (Kól. 3:10) Bó ṣe jẹ́ pé téèyàn bá ń ro oko ìdí igi kan tó sì ń bójú tó o, igi náà máa so dáadáa. Bákan náà, tẹ́nì kan bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ darí ìgbésí ayé rẹ̀, á túbọ̀ máa fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù.—Sm. 1:1-3.
Ìfẹ́ ni ànímọ́ àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn, ànímọ́ yìí sì ṣe pàtàkì gan-an. Àmọ́, báwo ló ti ṣe pàtàkì tó? Pọ́ọ̀lù sọ pé tí òun ò bá ní ìfẹ́, òun “kò jámọ́ nǹkan kan.” (1 Kọ́r. 13:2) Àmọ́, kí ni ìfẹ́, báwo la ṣe lè ní in ká sì máa fi í hàn lójoojúmọ́?
BÁ A ṢE LÈ FÌFẸ́ HÀN
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ kọjá ohun téèyàn lè fi ọ̀rọ̀ lásán ṣàlàyé, síbẹ̀ Bíbélì sọ ọ̀nà téèyàn lè gbà fi ìfẹ́ hàn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé ìfẹ́ máa ń ní “ìpamọ́ra àti inú rere.” Bákan náà, ó máa ń “yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́,” ó sì máa ń ‘mú ohun gbogbo mọ́ra, ó máa ń gba ohun gbogbo gbọ́, ó máa ń retí ohun gbogbo, ó máa ń fara da ohun gbogbo.’ Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ tún máa ń gba ti àwọn èèyàn rò, ọ̀rọ̀ àwọn míì máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, ó sì máa ń dúró tini nígbà ìṣòro. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tẹ́nì kan kò bá ní ìfẹ́, àwọn ànímọ́ burúkú láá máa gbé yọ, bí owú, ìgbéraga, ìwàkiwà, ìmọtara-ẹni nìkan, á sì ṣòro fún un láti dárí jini. Àmọ́, ìfẹ́ táwa Kristẹni ní kì í jẹ́ ká hu àwọn ìwà yìí torí pé ìfẹ́ “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọ́r. 13:4-8.
JÈHÓFÀ ÀTI JÉSÙ FI ÀPẸẸRẸ ÌFẸ́ TÓ GA JÙ LỌ LÉLẸ̀
Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Ká sòótọ́, Jèhófà ni àpẹẹrẹ ìfẹ́ tó ga jù lọ. (1 Jòh. 4:8) Gbogbo nǹkan tó dá àtàwọn nǹkan tó ń ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ìfẹ́ tó ga jù lọ tó fi hàn sí wa ni bó ṣe rán Jésù wá sáyé pé kó wá kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Jòh. 4:9, 10) Torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó máa ń dárí jì wá, ó ń tù wá nínú, ó sì ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun fún wa.
Jésù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn ní ti bó ṣe fínúfíndọ̀ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Bíbélì: “[Jésù] sọ ní ti gidi pé: ‘Wò ó! Mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.‘ . . . Nípasẹ̀ ‘ìfẹ́’ tí a sọ náà, a ti sọ wá di mímọ́ nípasẹ̀ ìfirúbọ ara Jésù Kristi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.” (Héb. 10:9, 10) Kò séèyàn tó lè fìfẹ́ tó tóyẹn hàn torí Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 15:13) Ǹjẹ́ àwa èèyàn aláìpé lè ṣe bíi ti Jèhófà àti Jésù tó bá di pé ká fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ṣe bẹ́ẹ̀! Ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè ṣe é.
‘Ẹ MÁA BÁ A LỌ NÍ RÍRÌN NÍNÚ ÌFẸ́’
Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ yín, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún yín.” (Éfé. 5:1, 2) Tá a bá ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe, ṣe là ń “bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.” Irú ìfẹ́ yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, ó gbọ́dọ̀ hàn nínú ìṣe wa pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Jòhánù sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòh. 3:18) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn èèyàn, á máa wù wá láti wàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run. (Mát. 24:14; Lúùkù 10:27) Tá a bá nífẹ̀ẹ́, àá máa ní sùúrù, àá jẹ́ onínúure, àá sì máa dárí jini. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá nímọ̀ràn pé: “Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”—Kól. 3:13.
Àmọ́ ṣá o, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ ru bò wá lójú débi tá a fi máa gbọ̀jẹ̀gẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ kan bá ń sunkún, òbí kan tó gbọ̀jẹ̀gẹ́ máa fẹ́ fún un ní gbogbo ohun tó fẹ́ kó má bàa sunkún mọ́. Àmọ́, òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ máa dúró lórí ohun tó sọ bí ọmọ náà tiẹ̀ ń sunkún. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe rí. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́, síbẹ̀ “ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí.” (Héb. 12:6) Ìfẹ́ tá a ní láá jẹ́ ká fúnni ní ìbáwí nígbà tó tọ́ àti nígbà tó yẹ. (Òwe 3:11, 12) Àmọ́ ṣá o, tá a bá ń fún ẹnì kan ní ìbáwí, ó yẹ ká rántí pé aláìpé làwa náà, àwọn ìgbà míì sì wà táwa náà máa ń ṣàṣìṣe. Torí náà, gbogbo wa la níbi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe tó bá dọ̀rọ̀ ká máa fìfẹ́ hàn. Àwọn nǹkan wo ló máa ràn wá lọ́wọ́? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan mẹ́ta.
BÁWO LA ṢE LÈ MÁA FÌFẸ́ HÀN?
Àkọ́kọ́, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó o lè máa fìfẹ́ hàn. Jésù sọ pé Jèhófà máa ń “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Tá a bá gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́, tá a sì ń sapá láti “máa rìn nípa ẹ̀mí,” ìfẹ́ tá a ní fáwọn èèyàn á máa pọ̀ sí i lójoojújmọ́. (Gál. 5:16) Bí àpẹẹrẹ, tó o bá jẹ́ alàgbà, o lè bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó o lè máa fi Ìwé Mímọ́ báni wí tìfẹ́tìfẹ́. Tó o bá sì jẹ́ òbí, o lè ní kí Jèhófà fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó o lè máa fìfẹ́ bá àwọn ọmọ rẹ wí dípò kó o máa fi ìbínú bá wọn wí.
Èkejì ni pé ká máa ronú lórí ohun tí Jésù ṣe nígbà tí wọ́n múnú bí i. (1 Pét. 2:21, 23) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nígbà táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá tàbí tí wọ́n rẹ́ wa jẹ. Ní irú àsìkò bẹ́ẹ̀, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Ká sọ pé Jésù ni irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, kí ló máa ṣe?’ Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Leigh sọ pé ìbéèrè yìí máa ń jẹ́ kóun ronú kóun tó gbé ìgbésẹ̀. Ó sọ pé: “Nígbà kan, ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ kọ ọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa mi àti nípa bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́, ó sì fi ránṣẹ́ sáwọn tó kù tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Ó dùn mí gan-an. Àmọ́, mo bi ara mi pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fara wé Jésù nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí?’ Lẹ́yìn tí mo ronú nípa ohun tí Jésù máa ṣe tó bá jẹ́ òun ni irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, mo pinnu pé màá gbàgbé ọ̀rọ̀ náà, mi ò sì ní jẹ́ kó di wàhálà. Ìgbà tó yá ni mo wá mọ̀ pé ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ yìí ń ṣàìsàn, nǹkan ò sì dẹrùn fún un. Mo wá gbà pé kì í ṣe ohun tó ní lọ́kàn ló kọ nípa mi. Bí mo ṣe ń ronú nípa ohun tí Jésù ṣe nígbà tí wọ́n hùwà àìdáa sí i ló jẹ́ kí èmi náà fìfẹ́ hàn sẹ́ni yẹn.” Tá a bá ń fara wé Jésù, àá máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn nígbà gbogbo.
Ẹ̀kẹta ni pé ká ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní. Ìfẹ́ ìfara-ẹni rúbọ yìí ló jẹ́ àmì ìdánimọ̀ àwa Kristẹni. (Jòh. 13:34, 35) Ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi rọ̀ wá pé ká ní “ẹ̀mí ìrònú” tí Jésù ní. Bó ṣe kúrò ní ọ̀run, ṣe ló “sọ ara rẹ̀ di òfìfo,” ó sì gbà kí wọ́n pa òun. (Fílí. 2:5-8) Bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ tí Jésù fi lélẹ̀, àá túbọ̀ máa ronú bíi Jésù, àá máa hùwà bíi tiẹ̀, àá sì máa fi ire àwọn míì ṣáájú tiwa. Àmọ́, àwọn àǹfààní míì wo la máa rí tá a bá ń fìfẹ́ hàn?
ÀWỌN ÀǸFÀÀNÍ TÁ A MÁA RÍ TÁ A BÁ Ń FÌFẸ́ HÀN
Tá a bá ń fìfẹ́ hàn, àwọn àǹfààní tá a máa rí á pọ̀ gan-an. Ẹ jẹ́ ká jíròrò méjì lára wọn:
ẸGBẸ́ ARÁ KÁRÍ AYÉ: Torí pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú, ìjọ yòówù ká lọ lágbàáyé, ṣe làwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa fìfẹ́ àti ọ̀yàyà gbà wá. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá gbáà ló jẹ́ pé à ń gbádùn ìfẹ́ ‘ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí ayé’! (1 Pét. 5:9) Ibòmíì wo la tún ti lè rí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ayé yìí bí kò ṣe láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run?
ÀLÀÁFÍÀ: Bá a ṣe ń ‘fara dà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́,’ à ń gbádùn “ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfé. 4:2, 3) A máa ń rí irú ìfẹ́ yìí láwọn ìpàdé wa àtàwọn àpéjọ wa. Ẹ ò rí i pé ohun àrà ọ̀tọ̀ gbáà ló jẹ́ pé àwa èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan nínú ayé tó ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí! (Sm. 119:165; Aísá. 54:13) Bá a ṣe ń wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, èyí sì ń múnú Jèhófà Baba wa ọ̀run dùn.—Sm. 133:1-3; Mát. 5:9.
‘ÌFẸ́ MÁA Ń GBÉNI RÓ’
Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìfẹ́ a máa gbéni ró.” (1 Kọ́r. 8:1) Báwo ni ìfẹ́ ṣe ń gbéni ró? Pọ́ọ̀lù sọ bó ṣe máa ń gbéni ró nínú Kọ́ríńtì kìíní orí kẹtàlá, èyí tí àwọn kan máa ń pè ní “Sáàmù Ìfẹ́.” Lára ohun tí ìfẹ́ máa ń ṣe ni pé, ó máa ń wá ire àwọn ẹlòmíì. (1 Kọ́r. 10:24; 13:5) Ó máa ń jẹ́ kéèyàn ronú jinlẹ̀, ó máa ń jẹ́ kéèyàn gba tàwọn míì rò, kéèyàn ní sùúrù, kó sì jẹ́ onínúure. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń jẹ́ kí ilé tòrò, kí àlàáfíà sì jọba nínú ìjọ.—Kól. 3:14.
Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù, òun ló sì lágbára jù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè wa, ẹ̀yà wa àti èdè wa yàtọ̀ síra, ìfẹ́ ló ń mú kí gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà wà níṣọ̀kan ká sì máa sìn ín “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sef. 3:9) Ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa fi ìfẹ́ tó jẹ́ apá kan èso tẹ̀mí yìí hàn lójoojúmọ́.
a Àpilẹ̀kọ yìí ni àkọ́kọ́ nínú àwọn àpilẹ̀kọ mẹ́sàn-án tá a ti máa jíròrò ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ èso tẹ̀mí.