Omi Tó Ń Tú Yàà Sókè Láti Fúnni Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun
“Ẹnì yòówù tí ó bá ń mu láti inú omi tí èmi yóò fi fún un, òùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ láé, ṣùgbọ́n omi tí èmi yóò fi fún un yóò di ìsun omi nínú rẹ̀ tí ń tú yàà sókè láti fi ìyè àìnípẹ̀kun fúnni.”—JÒHÁNÙ 4:14.
“ÀFI wẹ́rẹ́ tá a rí tí ayé róbótó ẹlẹ́wà, tó ń dán gológoló rọra ń yọ bọ̀ bíi péálì iyebíye níbi ìpẹ̀kun òṣùpá. Ó ń yọ bọ̀ láàárín òfuurufú tó ṣókùnkùn biribiri, tóun ti àwọ̀ búlúù tó dà pọ̀ mọ́ funfun, tí ohun tó dà bí àwọsánmà funfun sì rọra ń ṣẹ́po wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ lára rẹ̀.”—Bí Edgar Mitchell, arìnrìn-àjò ní gbalasa òfuurufú, ṣe ṣàpèjúwe ayé nìyẹn nígbà tó ń wò ó láti gbalasa òfuurufú.
Kí ló mú kí ayé wa yìí dán tó bẹ́ẹ̀ tí arìnrìn-àjò ní ojúde òfuurufú yìí fi ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà tó ga lọ́lá bẹ́ẹ̀? Omi ni, èyí tó jẹ́ pé tí wọ́n bá dá ojú ilẹ̀ ayé sọ́nà mẹ́rin ó kó ohun tó tó apá mẹ́ta nínú rẹ̀. Ká sòótọ́, yàtọ̀ sí pé omi jẹ́ kí ayé wa yìí lẹ́wà; ó tún ń gbé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá alààyè inú rẹ̀ ró. Àní, èyí tó ju ìdájí lọ nínú ara èèyàn ló jẹ́ omi. Ìyẹn ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Encyclopædia Britannica fi sọ pé: “Omi ṣe kókó fún ìwàláàyè, torí kò sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ewéko àti ara ẹranko tí omi ò ní kópa níbẹ̀.”
Ètò ìyípoyípo omi tí Ọlọ́run ti ṣe fún ilé ayé ló ń sẹ́ ìdọ̀tí inú omi ayé kúrò déédéé, tó fi jẹ́ pé kò sídìí láti pààrọ̀ omi inú ayé rárá. Ìwé The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo omi tá a bá lò ló ń padà sínú òkun lọ́nà kan tàbí òmíràn. Oòrùn á sì wá fà á lọ sókè látinú òkun. Lẹ́yìn náà, á wá rọ̀ gẹ́gẹ́ bí òjò padà sórí ilẹ̀. Nítorí náà, àlòtúnlò là ń lo omi. Ohun àlò-ìlòtán ni.” Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ètò ìyípoyípo omi yìí ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, ó ní: “Gbogbo ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ń ṣàn lọ sínú òkun, síbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún. Ibi tí àwọn ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ti ń ṣàn jáde lọ, ibẹ̀ ni wọ́n ń padà sí, kí wọ́n bàa lè ṣàn jáde lọ.” Àgbàyanu gbáà ni ètò ìyípoyípo omi ayé tí Ẹlẹ́dàá ṣe yìí jẹ́!—Oníwàásù 1:7.
Nítorí bí omi ti ṣe pàtàkì tó fún ìwàláàyè, tó sì tún jẹ́ pé ọ̀nà àrà ni Ọlọ́run gbà pèsè omi, kò yani lẹ́nu pé ó ju ìgbà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] lọ tí Bíbélì mẹ́nu kan omi. Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tí omi gbà wúlò, pàápàá bó ṣe ń fọ nǹkan mọ́ àti bó ṣe ń gbé ìwàláàyè ró, láti fi ṣàpèjùwe ọ̀nà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè gbà sọ wá di mímọ́, kó sì gbé wa ró nínú ọ̀nà ìjọsìn wa.—Aísáyà 58:11; Jòhánù 4:14.
Agbára Tí Bíbélì Ní Láti Wẹni Mọ́
Nítorí pé ó ti mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára láti máa wẹ̀ kí wọ́n sì máa fomi bọ́jú-bọ́sẹ̀ déédéé, ṣàṣà èèyàn ló máa ń mọ́ tónítóní bíi tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ àṣà wọn láti wẹ́ ẹsẹ̀ tí wọ́n bá wọlé láti jẹun. (Lúùkù 7:44) Yàtọ̀ sí báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń rí i pé ara wọn àtàwọn ohun èlò wọn wà ní mímọ́, wọ́n tún máa ń fi omi ṣe ìwẹ̀nùmọ́. Àwọn àlùfáà tó ń sìn nínú àgọ́ ìjọsìn ní láti máa wẹ̀ kí wọ́n sì máa fọ aṣọ wọn lemọ́lemọ́. (Ẹ́kísódù 30:18-21) Nígbà tí wọ́n wá kọ́ tẹ́ńpìlì sí Jerúsálẹ́mù, Sólómọ́nì fi bàbà ṣe “òkun dídà” kan síbẹ̀, èyí tó ń gbà tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógójì [44,000] jálá omi. Ìyẹn sì tó fún ṣíṣe gbogbo ìwẹ̀nùmọ́ tí Òfin Ọlọ́run pa láṣẹ fún wọn. (2 Kíróníkà 4:2, 6) Ẹ̀kọ́ wo làwọn Kristẹni rí kọ́ látinú lílò tí wọ́n ń lo omi láwọn ọ̀nà wọ̀nyẹn?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Jésù ti wẹ ìjọ Kristẹni mọ́ “pẹ̀lú ìwẹ̀ omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà.” Bí omi ṣe lè wẹ ìdọ̀tí kúrò náà ni òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè bá wa wẹ ìwà àti ọ̀nà ìgbàjọ́sìn wa mọ́. Ìwẹ̀nùmọ́ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ṣe yìí máa ń mú kí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi wà ní “mímọ́ àti láìsí àbààwọ́n.” (Éfésù 5:25-27) Ìdí nìyẹn tí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run fi ní láti máa rí i pé, yálà nínú ìwà tàbí lọ́nà ìjọsìn wọn, àwọn wà “ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n.” (2 Pétérù 3:11, 14) Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe fún wọn?
Àwọn tó bá fẹ́ ṣe ohun tó wu Jèhófà Ọlọ́run máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé láti lè máa gba ìmọ̀ òtítọ́, bí ìgbà téèyàn ń mu omi. Bí ìmọ̀ òtítọ́ bá sì ti wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin, ó máa ń jẹ́ kó máa wù wọ́n láti ṣe ohun tí Bíbélì sọ, pé: “Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Róòmù 12:2.
Téèyàn bá ní ìmọ̀ tó péye nípa ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, ó máa ń jẹ́ kéèyàn lè rí àbàwọ́n àti àbùkù tó bá wà nínú ìwà àti èrò ẹni. Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sì wá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì déédéé, tó bá yá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò mú kó dẹni ‘tá a wẹ̀ mọ́’ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ bí ìgbà téèyàn fomi wẹ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
Ẹ wo bí irú àyípadà bẹ́ẹ̀ ṣe bá ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Alfonso nílẹ̀ Sípéènì. Ó ṣàlàyé pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún, ìgbésí ayé mi sú mi.” Ìdí ni pé ó ń lo oògùn olóró, ó sì jẹ́ ọ̀daràn paraku. Ó ní: “Mo ń wo ara mi bí ẹlẹ́gbin nítorí ìwà ìbàjẹ́ tí mò ń hù àti ọ̀nà tí mò ń gbà bá àwọn èèyàn lò.
“Mo kíyè sí ọmọbìnrin kan níléèwé wa tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́, pé ó jẹ́ni tí kì í rìnrìn ìdọ̀tí, kò sì ba ara rẹ̀ jẹ́ rárá, ìyẹn sì jẹ́ kó dá yàtọ̀ láàárín àwọn ọmọ iléèwé yòókù. Àpẹẹrẹ rere rẹ̀ mú kó wu èmi náà láti máa gbé ìgbé ayé rere bíi tiẹ̀. Mo lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bó ṣe gbà mí nímọ̀ràn. Kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run. Láàárín ọdún kan, mo ti jáwọ́ nínú gbogbo ìwà ìbàjẹ́ ti mò ń hù, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣèrìbọmi. Àyípadà ńláǹlà tí mo ṣe yìí mú káwọn òbí tó wà ládùúgbò mi máa wá bẹ̀ mí pé kí n bá wọn ran àwọn ọmọ wọn tó ń lo oògùn olóró lọ́wọ́.”
Omi Tó Máa Fúnni Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun
Nígbà kan, Jésù sọ̀rọ̀ nípa “omi ààyè” fún obìnrin ará Samaríà kan tó ń fa omi nínú kànga Jékọ́bù. Ó ní: “Ẹnì yòówù tí ó bá ń mu láti inú omi tí èmi yóò fi fún un, òùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ láé, ṣùgbọ́n omi tí èmi yóò fi fún un yóò di ìsun omi nínú rẹ̀ tí ń tú yàà sókè láti fi ìyè àìnípẹ̀kun fúnni.” (Jòhánù 4:10, 14) Ọ̀rọ̀ Jésù yìí fi hàn pé “omi ààyè” náà ṣàpẹẹrẹ àwọn ìpèsè Ọlọ́run tó lè fúnni ní ìyè, èyí tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé rẹ̀ fún wa. Àwọn ìpèsè yẹn máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún èèyàn láti wàláàyè títí láé. Ẹbọ ìràpadà Kristi Jésù jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ohun tó para pọ̀ jẹ́ omi ìṣàpẹẹrẹ yìí. Jésù ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
Ọ̀gbẹ́ni Alfonso tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan wá dẹni tó mọyì “omi ààyè” látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọn ò jáwọ́ nínú ìwà ọ̀daràn àti lílo oògùn olóró, ó ní: “Ẹ̀gbọ́n mi ti kú dà nù, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́ tí mo ní tẹ́lẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èmi náà ì bá ti kú dà nù. Àwọn ìpèsè Jèhófà ló sọ mí dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run, tí mo ṣì fi wà láàyè.” Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé, ẹ̀kọ́ tí Alfonso kọ́ nínú Bíbélì mú kó nírètí pé òun máa gbádùn ìyè ayérayé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.—2 Pétérù 3:13.
Gbogbo Èèyàn Ni Ọlọ́run Ń Pè
Ìwé tó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì ṣàpèjúwe ‘odò omi ìyè kan, tí ó mọ́ kedere bí kírísítálì, tí ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’ (Ìṣípayá 22:1) Odò yìí ṣàpẹẹrẹ àwọn ìpèsè Ọlọ́run tí yóò mú kí ọmọ aráyé di pípé níkẹyìn gẹ́gẹ́ bí Ádámù àti Éfà ṣe wà nígbà tí Ọlọ́run dá wọn.
Nígbà tí àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí ṣàpèjúwe odò yẹn tán, ó mẹ́nu kan ìpé yìí, ó ní: “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Ìpé yìí ń lọ jákèjádò ayé lóde òní. Lọ́dọọdún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè tó lé ní igba ó lé márùndínlógójì [235], ń lo ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí lẹ́nu ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè dẹni tó ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tó máa múni rí ìyè.
Ǹjẹ́ òùngbẹ omi ìyè ń gbẹ ọ́? Tó o bá ń mu omi tó mọ́ lóló yẹn, ìyẹn ni pé, kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìpèsè Ẹlẹ́dàá wa, kó o sì máa lò wọ́n, wàá lè wà lára àwọn tó ń “fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tímótì 6:19.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]
Bí omi ṣe ń wẹ ìdọ̀tí kúrò ni òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè wẹ ìwà àti ọ̀nà ìgbàjọ́sìn wa mọ́
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
BÍ WỌ́N ṢE Ń RÍ OMI LÁYÉ ÌGBÀANÌ
Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn èèyàn máa ń ṣe wàhálà tó pọ̀ kí wọ́n tó lè rí orísun omi tí kò ní máa gbẹ. Ábúráhámù àti Ísákì gbẹ́ àwọn kànga sí ìtòsí ìlú Bíá-Ṣébà kí agboolé wọn àtàwọn ẹran ọ̀sìn wọn lè máa rí omi mu dáadáa.—Jẹ́nẹ́sísì 21:30, 31; 26:18.
Kànga tí kò bá jìn sábà máa ń gbẹ nígbà ẹ̀rùn tó máa ń gùn tí ooru sì máa ń mú gan-an. Nítorí náà, kànga gbọ́dọ̀ jìn gan-an, kó tó lè máa lómi nígbà gbogbo. (Òwe 20:5) Kànga kan nílùú Lákíṣì jìn tó mítà mẹ́rìnlélógójì. Kànga míì, tó wà nílùú Gíbéónì jìn ju mítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lọ, ó sì fẹ̀ tó mítà mọ́kànlá. Ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta tọ́ọ̀nù òkúta tí wọ́n gbẹ́ jáde níbẹ̀ kí kànga yẹn tó parí. Obìnrin ará Samáríà tó wá pọnmi níbi ìsun omi Jékọ́bù sọ fún Jésù pé: ‘Kànga náà jìn.’ Àfàìmọ̀ ni kànga náà ò ní jìn tó mítà mẹ́tàlélógún.—Jòhánù 4:11.
Inú ìkùdu làwọn èèyàn tún ti máa ń pọn omi láyé àtijọ́ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Inú ìkùdu tí wọ́n gbẹ́ sínú ilẹ̀ yìí ni wọ́n máa ń tọ́jú omi òjò tó ń rọ̀ láàárín oṣù October sí April pa mọ́ sí. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ni pé, wọ́n á gbẹ́ àwọn ojú ọ̀gbàrá láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè wá sínú ìkùdu wọn, kí ọ̀gbàrá òjò lè máa gbabẹ̀ wá sínú ìkùdu náà. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sábà máa ń gbẹ́ ìkùdu ńláńlá láti fi tọ́jú omi pa mọ́.—2 Kíróníkà 26:10.
Títí dòní yìí, iṣẹ́ ńlá ni wọ́n máa ń ṣe níbẹ̀ kí wọ́n tó lè fa omi jáde nínú àwọn kànga àti ìkùdu. Iṣẹ́ pàtàkì làwọn obìnrin bíi Rèbékà àtàwọn ọmọbìnrin Jẹ́tírò ń ṣe, bí wọ́n ṣe ń pọnmi fún ìdílé wọn àti ẹran ọ̀sìn wọn lójoojúmọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 24:15-20; Ẹ́kísódù 2:16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Alfonso rèé lónìí, tó ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run