Ẹ Mú Ìfòyebánilò Dàgbà
“Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn. Oluwa ń bẹ nítòsí.”—FILIPPI 4:5, NW.
1. Èéṣe tí ó fi jẹ́ ìpèníjà láti fòyebánilò lóde-òní?
“AFÒYEBÁNILÒ”—akọ̀ròyìn ilẹ̀ England náà Ọ̀gbẹ́ni Alan Patrick Herbert pè é ní ìtàn àròsọ lásán kan. Nítòótọ́, ní àwọn ìgbà mìíràn ó lè dàbí ẹni pé kò sí àwọn ènìyàn tí ń fòyebánilò mọ́ nínú ayé tí ìjà ti pínníyà yìí. Bibeli sọtẹ́lẹ̀ pé ní àwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” lílekoko wọ̀nyí, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “òǹrorò,” “olùwarùnkì,” àti “aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan”—ní èdè mìíràn, wọn kì yóò jẹ́ afòyebánilò rara. (2 Timoteu 3:1-5, NW) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Kristian tòótọ́ ní ọ̀wọ̀ gíga fún ìfòyebánilò, ní mímọ̀ pé ó jẹ́ àmì ọgbọ́n àtọ̀runwá. (Jakọbu 3:17) A kò lérò pé kò ṣeéṣe láti jẹ́ afòyebánilò nínú ayé kan tí ó jẹ́ aláìfòyebánilò. Kàkà bẹ́ẹ̀, a fi àìṣiyèméjì tẹ́wọ́gba ìpèníjà náà tí ó wà nínú ìmọ̀ràn onímìísí ti aposteli Paulu tí a rí nínú Filippi 4:5 (NW) pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.”
2. Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu ní Filippi 4:5 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu yálà a jẹ́ afòyebánilò?
2 Ṣàkíyèsí bí ọ̀rọ̀ Paulu ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò bóyá a ń fòyebánilò. Kò fi púpọ̀ ní ṣe pẹ̀lú ojú tí a fi ń wo araawa; ó jẹ́ ọ̀ràn nípa ojú tí àwọn ẹlòmíràn fi ń wò wá, ohun tí a mọ̀ wá sí. Ìtumọ̀ ti Phillips túmọ̀ ẹsẹ̀ yìí pé: “Ní orúkọ rere fún jíjẹ́ afòyebánilò.” Ó tún dára kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa béèrè pé, ‘Báwo ni a ṣe mọ̀ mí sí? A ha ń ròyìn mi ní rere pé mo jẹ́ afòyebánilò, ẹni tí ń juwọ́sílẹ̀, tí ó sì jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ bí? Tàbí a ha mọ̀ mí sí ẹni tí kìí yípadà, tí ó lekoko, tàbí tí ń warùnkì?’
3. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀sí “ìfòyebánilò” jẹ́, èésìtiṣe tí ànímọ́ yìí fi fanimọ́ra? (b) Báwo ni Kristian kan ṣe lè kọ́ láti túbọ̀ jẹ́ afòyebánilò?
3 Bí a bá ṣe ròyìn wa sí lórí ọ̀ràn yìí ni yóò wulẹ̀ fi ibi tí a ń ṣàfarawé Jesu Kristi dé hàn. (1 Korinti 11:1) Nígbà tí ó wà níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé, Jesu ṣàgbéyọ àpẹẹrẹ ìfòyebánilò gíga jùlọ ti Baba rẹ̀ lọ́nà pípé pérépéré. (Johannu 14:9) Ní tòótọ́, nígbà tí Paulu kọ̀wé nípa “ìwàtútù ati inúrere Kristi,” ọ̀rọ̀ Griki náà tí ó lò fún inúrere (e·pi·ei·kiʹas) tún jẹ́ “ìfòyebánilò” tàbí, ní olówuuru, “ìjuwọ́sílẹ̀.” (2 Korinti 10:1, NW) Ìwé The Expositor’s Bible Commentary pe èyí ní “ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ ńlá tí ó ṣàpèjúwe ànímọ́ nínú Májẹ̀mú Titun.” Ó ṣàpèjúwe ànímọ́ kan tí ó fanimọ́ra gan-an débi tí ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan fi túmọ̀ rẹ̀ sí “ìfòyebánilò tí ó fanimọ́ra.” Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a jíròrò àwọn ọ̀nà mẹ́ta tí Jesu gbà fi ìfòyebánilò bíi ti Baba rẹ̀, Jehofa hàn. A lè tipa báyìí kọ́ bí a ṣe lè túbọ̀ jẹ́ afòyebánilò fúnraawa.—1 Peteru 2:21.
‘Múra Láti Dáríjì’
4. Báwo ni Jesu ṣe fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó “múra àti dáríjì”?
4 Bíi ti Baba rẹ̀, Jesu fi ìfòyebánilò hàn nípa ‘mímúra láti dáríjì’ léraléra. (Orin Dafidi 86:5) Ronú nípa àkókò náà nígbà tí Peteru, alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ kan, sẹ́ Jesu nígbà mẹ́ta ní alẹ́ ọjọ́ tí a fàṣẹ-ọba mú Jesu tí a sì ṣe ìgbẹ́jọ́ rẹ̀. Jesu fúnraarẹ̀ ti sọ ṣáájú pé: “Bí ẹnìkan bá sì sẹ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi óò sẹ́ pẹ̀lú níwájú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Matteu 10:33) Jesu ha fi àìṣeéyípadà àti àìláàánú lo ìlànà yìí fún Peteru bí? Bẹ́ẹ̀kọ́; lẹ́yìn àjíǹde Rẹ̀, Jesu bẹ Peteru fúnraarẹ̀ wò, kò sì sí iyèméjì pé èyí jẹ́ láti tu aposteli onírònúpìwàdà, oníròbìnújẹ́ ọkàn yìí nínú kí ó sì tún fi í lọ́kànbalẹ̀. (Luku 24:34; 1 Korinti 15:5) Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, Jesu yọ̀ọ̀da fún Peteru láti ní ẹrù-iṣẹ́ ńlá. (Iṣe 2:1-41) Ẹ wo bí ó ti lo ìfòyebánilò tí ó fanimọ́ra lọ́nà dídára jùlọ níhìn-ín! Kò ha tuninínú láti ronú pé Jehofa ti yan Jesu sípò gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ lórí gbogbo aráyé bí?—Isaiah 11:1-4; Johannu 5:22.
5. (a) Orúkọ wo ni ó yẹ kí àwọn alàgbà ní láàárín àwọn àgùtàn? (b) Àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wo ni àwọn alàgbà lè ṣàtúnyẹ̀wò ṣáájú bíbójútó àwọn ọ̀ràn ìdájọ́, èésìtiṣe?
5 Nígbà tí àwọn alàgbà bá ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ nínú ìjọ, wọ́n ń sakun láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìfòyebánilò Jesu. Wọn kò fẹ́ kí àwọn àgùtàn máa bẹ̀rù wọn gẹ́gẹ́ bí afìyàjẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń wá ọ̀nà láti ṣàfarawé Jesu kí àwọn àgùtàn baà lè nímọ̀lára àìléwu fún níní wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn olùṣọ́-àgùtàn onífẹ̀ẹ́. Nínú àwọn ọ̀ràn ìdájọ́, wọ́n ń sa gbogbo ipá láti jẹ́ afòyebánilò, tí ó múratán láti dáríjì. Ṣáájú bíbójútó irúfẹ́ ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà kan ti rí i pé ó ṣèrànwọ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Jehofa, Aláìṣègbè ‘Onidaajọ Gbogbo Ayé’” àti “Ẹyin Alagba, Ẹ Fi Ododo Ṣe Idajọ,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà July 1, 1992. Wọ́n ń tipa báyìí fi àkópọ̀ ọ̀nà tí Jehofa ń gbà ṣèdájọ́ sọ́kàn: “Ìdúrógbọnyingbọnyin nibi ti o bá ti pọndandan, aanu nibi ti o bá ti ṣeeṣe.” Kìí ṣe àṣìṣe láti lo ojú àánú nínú ìdájọ́ nígbà tí ìdí tí ó lọ́gbọ́n-nínú bá wà fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. (Matteu 12:7) Àṣìṣe gbígbópọn ni láti lekoko tàbí jẹ́ aláìláàánú. (Esekieli 34:4) Àwọn alàgbà ń tipa báyìí yẹra fún ṣíṣàṣìṣe nípa fífi pẹ̀lú akitiyan wá ọ̀nà onífẹ̀ẹ́, àti aláàánú jùlọ tí ó bá ṣeéṣe láti gbà láìrékọjá ohun tí ìdájọ́ òdodo béèrè fún.—Fiwé Matteu 23:23; Jakọbu 2:13.
Ìṣeétẹ̀síhìn-ín-sọ́hùn-ún Lójú Àwọn Àyíká-Ipò tí Ń Yípadà
6. Báwo ni Jesu ṣe fi ìfòyebánilò hàn nípa ọwọ́ tí ó fi mú obìnrin Keferi náà tí ẹ̀mí-èṣù ń dá ọmọbìnrin rẹ̀ lóró?
6 Bíi ti Jehofa, Jesu fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń yára láti yí ìgbésẹ̀ padà tàbí mú ara rẹ̀ bá àwọn ipò titun mu bí wọ́n ti ń dìde. Ní àkókò kan obìnrin Keferi kan bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wo ọmọbìnrin òun tí ẹ̀mí-èṣù ń dálóró gidigidi sàn. Ní àwọn ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Jesu kọ́kọ́ fihàn pé òun kò ní ràn án lọ́wọ́—àkọ́kọ́, nípa kíkọ̀ láti dá a lóhùn; èkejì, nípa sísọ ní tààràtà pé a rán òun sí àwọn Ju, kìí ṣe sí àwọn Kèfèrí; àti ẹ̀kẹta, nípa ṣíṣe àkàwé kan tí ó sọ kókó kan náà lọ́nà tí ó fi inúrere hàn. Ṣùgbọ́n, obìnrin náà tẹpẹlẹ mọ́ ọn jálẹ̀ gbogbo èyí, ní fífúnni ní ẹ̀rí ìgbàgbọ́ àrà-ọ̀tọ̀. Ní gbígbé ti àyíká ipò àrà-ọ̀tọ̀ yìí yẹ̀wò, Jesu lè rí i pé èyí kìí ṣe àkókò láti fipá mú ìlànà gbogbogbòò kan ṣẹ; ó jẹ́ àkókò láti tẹ̀ síhà kan ní ìdáhùn sí àwọn ìlànà gíga jù.a Nípa báyìí, Jesu ṣe ohun náà gan-an tí ó ti fihàn ní ìgbà mẹ́ta pé òun kò ní ṣe. Ó wo ọmọbìnrin obìnrin náà sàn!—Matteu 15:21-28.
7. Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn òbí lè gbà láti fi ìfòyebánilò hàn, èésìtiṣe?
7 A ha mọ àwa pẹ̀lú fún ìmúratán wa láti tẹ̀ nígbà tí ó bá yẹ bí? Àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa fi irú ìfòyebánilò bẹ́ẹ̀ hàn lemọ́lemọ́. Níwọ̀n bí ọmọ kọ̀ọ̀kan ti ní ànímọ́ ọ̀tọ̀ tí ó jẹ́ tirẹ̀, ọ̀nà ìgbà bánilò tí ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọmọ kan lè jẹ́ aláìyẹ fún ọmọ mìíràn. Síwájú síi, bí àwọn ọmọ ti ń dàgbà, àwọn àìní wọn ń yípadà. Ẹ ha níláti yí àkókò tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé padà bí? Yóò ha mú àǹfààní wá bí a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ní ọ̀nà kan tí ó túbọ̀ ń dánilárayá bí? Nígbà tí ìhùwàpadà òbí kan sí àwọn ìrélànàkọjá tí kò tó nǹkan bá rékọjá ààlà, òun ha ń múratán láti lo ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí ó sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́ bí? Àwọn òbí tí wọ́n ń juwọ́sílẹ̀ ní irú àwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ń yẹra fún mímú àwọn ọmọ wọn bínú àti sísọ wọ́n di àjèjì sí Jehofa láìnídìí.—Efesu 6:4.
8. Báwo ni àwọn alàgbà ìjọ ṣe lè mú ipò iwájú nínú mímú ara wọn bá ipò àìní tí ó wà ní àgbègbè ìpínlẹ̀ mu?
8 Àwọn alàgbà pẹ̀lú, ni àìní wà fún láti yípadà bí àwọn àyíká ipò titun ti ń dìde, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì yóò fi àwọn òfin pàtó kan tí ó jẹ́ ti Ọlọrun bánidọ́rẹ̀ẹ́ láé. Ní bíbójútó iṣẹ́ ìwàásù, ìwọ ha wà lójúfò sí àwọn ìyípadà nínú àgbègbè ìpínlẹ̀ bí? Bí àwọn ọ̀nà ìgbà gbé ìgbésí-ayé ní àdúgbò ti ń yípadà, bóyá ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́, ìjẹ́rìí òpópónà, tàbí ìjẹ́rìí nípasẹ̀ tẹlifóònù ni a níláti gbélárugẹ. Yíyíwọ́padà ní irú àwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú iṣẹ́ ìwàásù wa ṣẹ lọ́nà tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́. (Matteu 28:19, 20; 1 Korinti 9:26) Paulu pẹ̀lú kà á sí ohun tí ó ṣe pàtàkì láti mú araarẹ̀ bá onírúurú àwọn ènìyàn mu nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwa ha ń ṣe ohun kan náà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ tó nípa àwọn ìsìn àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àdúgbò kí ó baà lè ṣeéṣe fún wa láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́?—1 Korinti 9:19-23.
9. Èéṣe tí alàgbà kan kò fi níláti máa rinkinkin mọ́ bíbójútó àwọn ìṣòro nígbà gbogbo ní ọ̀nà tí òun gbà ń bójútó wọn ní ìgbà tí ó ti kọjá?
9 Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí ti túbọ̀ ń lekoko lọ́pọ̀lọpọ̀ síi, àwọn olùṣọ́-àgùtàn pẹ̀lú lè fẹ́ láti ṣèyípadà ní ìbámu pẹ̀lú ìlọ́júpọ̀ àti ìburú-bùrùjà akódààmúbáni ti díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí ń dojúkọ agbo wọn nísinsìnyí. (2 Timoteu 3:1) Ẹ̀yin alàgbà, kìí ṣe àkókò nìyí fún àìfẹ́ẹ́yípadà! Dájúdájú alàgbà kan kì yóò fẹ́ láti rinkinkin mọ́ bíbójútó àwọn ìṣòro gẹ́gẹ́ bí òun ti ń ṣe ní àwọn ìgbà tí ó ti kọjá bí àwọn ọ̀nà tí ó ń gbà bá ti di aláìgbéṣẹ́ tàbí bí “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” bá ti rí i bí ohun yíyẹ láti tẹ àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ titun lórí irú àwọn kókó-ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. (Matteu 24:45, NW; fiwé Oniwasu 7:10; 1 Korinti 7:31.) Alàgbà kan tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ fi pẹ̀lú òtítọ́-inú gbìyànjú láti ran arábìnrin kan tí ó ní ìsoríkọ́ tí ó sì ní àìní púpọ̀ gan-an fún ẹnìkan tí ó jẹ́ olùgbọ́ rere lọ́wọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, kò fi ojú tí ó ṣe pàtàkì wo ìsoríkọ́ rẹ̀ ó sì fún un ní àwọn ojútùú kan lásán. Lẹ́yìn náà ni Watch Tower Society tẹ àwọn ìsọfúnni kan tí a gbékarí Bibeli èyí tí ó sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro rẹ̀ gan-an. Alàgbà náà rí i dájú pé òun tún bá a sọ̀rọ̀, ní lílo àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ titun náà ní àkókò yìí tí ó sì fi ẹ̀mí ìfọ̀rànrora-ẹni hàn fún ìṣòro rẹ̀. (Fiwé 1 Tessalonika 5:14, 15.) Ẹ wo àpẹẹrẹ rere tí ìyẹn jẹ́ níti ìfòyebánilò!
10. (a) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe níláti fi ìṣarasíhùwà ìjuwọ́sílẹ̀ hàn fún araawọn lẹ́nìkín-ní kejì àti sí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà lódindi? (b) Ojú wo ni ẹgbẹ́ alàgbà níláti fi wo àwọn wọnnì tí wọ́n bá fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí aláìfòyebánilò?
10 Ó tún yẹ kí àwọn alàgbà fi ìṣarasíhùwà ìjuwọ́sílẹ̀ fún araawọn lẹ́nìkín-ní kejì hàn. Nígbà ti ẹgbẹ́ àwọn alàgbà bá pàdé pọ̀, ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí alàgbà kan máṣe jẹgàba lé ìjíròrò náà lórí! (Luku 9:48) Ẹni náà tí ń ṣe alága ní pàtàkì gbọ́dọ̀ lo ìṣọ́ra nínú ọ̀ràn yìí. Nígbà tí alàgbà kan tàbí méjì kò bá sì fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú ìpinnu gbogbo ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yòókù, wọn kì yóò tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé tiwọn ṣáá ni a gbọ́dọ̀ ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ pé a kò tẹ ìlànà Ìwé Mímọ́ kankan lójú, wọn yóò juwọ́sílẹ̀, ní rírántí pé ìfòyebánilò ni a béèrè fún lọ́wọ́ àwọn alàgbà. (1 Timoteu 3:2, 3) Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà níláti fi í sọ́kàn pé Paulu bá ìjọ Korinti wí fún ‘fífaradà á fún awọn aláìlọ́gbọ́n-nínú’ tí wọ́n fi araawọn hàn gẹ́gẹ́ bí ‘awọn aposteli adárarégèé.’ (2 Korinti 11:5, 19, 20, NW) Nítorí náà ó yẹ kí wọ́n wà ní ìmúratán láti fún alàgbà ẹlẹgbẹ́ wọn kan tí ń hùwà pẹ̀lú agídí, lọ́nà tí kò fi ìfòyebánilò hàn ní ìmọ̀ràn, ṣùgbọ́n àwọn fúnraawọn níláti jẹ́ oníwàtútù àti onínúrere ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀.—Galatia 6:1.
Ìfòyebánilò Nínú Lílo Ọlá-Àṣẹ
11. Ìyàtọ̀ wo ni ó wà láàárín bí àwọn aṣáájú ìsìn Ju ní ọjọ́ Jesu ṣe lo ọlá-àṣẹ àti bí Jesu ti ṣe lò ó?
11 Nígbà tí Jesu fi rìn lórí ilẹ̀-ayé, òtítọ́ ni pé ìfòyebánilò rẹ̀ hàn gbangba nínú ọ̀nà tí ó gbà lo ọlá-àṣẹ rẹ̀ tí Ọlọrun fifún un. Ẹ wo bí ó ti yàtọ̀ sí àwọn aṣáájú ìsìn ti ọjọ́ rẹ̀ tó! Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀wò. Òfin Ọlọrun ti pa á láṣẹ pé a kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan, kìí tilẹ̀ ṣe ṣíṣẹ́gi pàápàá, ní Ọjọ́ Ìsinmi. (Eksodu 20:10; Numeri 15:32-36) Àwọn aṣáájú ìsìn fẹ́ láti darí bí àwọn ènìyàn ṣe ń fi òfin yẹn sílò gan-an. Nítorí náà wọ́n gbà á kanrí láti ṣòfin ohun pàtó náà tí ẹnìkan lè gbésókè ní Ọjọ́ Ìsinmi. Wọ́n fi ìlànà lélẹ̀ pé: ohun tí kò bá ti wúwo ju ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ méjì lọ. Àní wọ́n tilẹ̀ gbé ìfòfindè jáde lórí àwọn sálúbàtà tí ìtẹ̀lẹ̀ wọn ní ìṣó, ní jíjẹ́wọ́ pé gbígbé àfikún ìwúwo ìṣó náà sókè yóò túmọ̀sí ṣíṣe iṣẹ́! A sọ pé, ní àpapọ̀, àwọn rabi fi ìlànà 39 kún òfin Ọlọrun nípa Ọjọ́ Ìsinmi tí wọ́n sì wá ń fikún àwọn ìlànà wọ̀nyí láìlópin. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jesu kò wá ọ̀nà láti darí àwọn ènìyàn nípasẹ̀ ìtìjú nípa fífi àwọn ìlànà tí ń kánilọ́wọ́kò láìlópin lélẹ̀ tàbí nípa gbígbé àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n aláìṣeéyípadà, tí kò ṣe é pamọ́ lélẹ̀.—Matteu 23:2-4; Johannu 7:47-49.
12. Èéṣe tí a fi lè sọ pé Jesu kò mikàn nígbà tí ó di ti ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Jehofa?
12 Nígbà náà, ó ha yẹ kí a tànmọ́ọ̀ pé Jesu kò fi ọwọ́ danyindanyin mú àwọn ìlànà òdodo Ọlọrun bí? Dájúdájú ó ṣe bẹ́ẹ̀! Ó lóye pé àwọn òfin gbéṣẹ́ jùlọ nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àwọn ìlànà tí ń bẹ lẹ́yìn àwọn òfin wọnnì sọ́kàn. Nígbà tí ó jẹ àwọn Farisi lógún láti gbìyànjú láti darí àwọn ènìyàn pẹ̀lú àìníye àwọn ìlànà, Jesu wá ọ̀nà láti dé inú ọkàn-àyà. Fún àpẹẹrẹ, ó mọ̀ dáradára pé kò sí jíjuwọ́sílẹ̀ nígbà tí ó bá di ti irú àwọn òfin àtọ̀runwá bíi “sá fún àgbèrè.” (1 Korinti 6:18) Nítorí náà Jesu kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nípa èrò tí ó lè yọrísí ìwà pálapàla. (Matteu 5:28) Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ gba ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ tí ó pọ̀ fíìfíì ju wíwulẹ̀ fi àwọn ìlànà tí kò ṣeé yípadà, tí ó kún fún àkójọ ọ̀pá ìdíwọ̀n lélẹ̀.
13. (a) Èéṣe tí àwọn alàgbà fi níláti yẹra fún ṣíṣe àwọn òfin àti ìlànà tí kò ṣeé tẹ̀síhìn-ín sọ́hùn-ún? (b) Kí ni àwọn agbègbè díẹ̀ nínú èyí tí ó ti ṣe pàtàkì láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí-ọkàn ti ẹnìkọ̀ọ̀kan?
13 Bákan náà ni àwọn arákùnrin ẹlẹ́rù-iṣẹ́ lónìí lọ́kàn-ìfẹ́ nínú dídé inú ọkàn-àyà. Nípa báyìí, wọ́n ń yẹra fún fífi àwọn ìlànà kòdúrógbẹ́jọ́, tí kò ṣeé yípadà lẹ́lè tàbí sísọ àwọn ojú-ìwòye ara-ẹni àti èrò tiwọn di òfin. (Fiwé Danieli 6:7-16.) Láti ìgbà dé ìgbà, àwọn ìránnilétí onínúure lórí irú àwọn ọ̀ràn bí aṣọ wíwọ̀ àti ìtúnraṣe lè bójúmu kí ó sì bọ́sákòókò, ṣùgbọ́n alàgbà kan lè fi bí a ti ń ròyìn rẹ̀ ní rere gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń fòyebánilò sábẹ́ ewu bí ó bá ń rinkinkin jù mọ́ irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ tàbí tí ó ń gbìyànjú láti gbé àwọn ohun tí ó jẹ́ ẹwù tirẹ̀ ka àwọn ẹlòmíràn lórí. Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ìjọ níláti yẹra fún gbígbìyànjú láti darí àwọn ẹlòmíràn.—Fiwé 2 Korinti 1:24; Filippi 2:12.
14. Báwo ni Jesu ṣe fihàn pé òun jẹ́ afòyebánilò níti ohun tí ó retí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn?
14 Àwọn alàgbà lè fẹ́ láti yẹ ara wọn wò lórí kókó ọ̀ràn mìíràn: ‘Mo ha ń fi ìfòyebánilò hàn níti ohun tí mo ń retí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn bí?’ Dájúdájú Jesu ṣe bẹ́ẹ̀. Ó fihan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́nà ṣíṣedéédéé pé òun kò retí ohun tí ó rékọjá ìsapá àfitọkàntọkànṣe láti ọ̀dọ̀ wọn àti pé òun mọ ìníyelórí èyí lọ́nà gíga. Ó yin òtòṣì opó náà fún fífi ẹyọ-owó rẹ̀ tí ìníyelórí rẹ̀ kò tó nǹkan tọrẹ. (Marku 12:42, 43) Ó bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wí nígbà tí wọ́n ṣe lámèyítọ́ ọrẹ gbígbówólórí tí Maria ṣe, ní wíwí pé: “Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀ sí; . . . Ó ṣe èyí tí ó lè ṣe.” (Marku 14:6, 8) Kódà nígbà tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ já a kulẹ̀ ó fòye bá wọn lò. Fún àpẹẹrẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rọ mẹ́ta nínú àwọn aposteli rẹ̀ tí wọ́n súnmọ́ ọ́n jùlọ láti wà lójúfò kí wọ́n sì máa ṣọ́nà pẹ̀lú òun ní alẹ́ ọjọ́ tí a fàṣẹ-ọba mú un, wọ́n já a kulẹ̀ nípa sísùn léraléra. Síbẹ̀, ó fi ìbánikẹ́dùn sọ pé: “Ẹ̀mí ń fẹ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.”—Marku 14:34-38.
15, 16. (a) Èéṣe tí àwọn alàgbà fi níláti ṣọ́ra láti máṣe fagbára mú tàbí kódààmú bá agbo? (b) Báwo ni arábìnrin olùṣòtítọ́ kan ṣe wá ṣàtúnṣe ohun tí ó ń retí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn?
15 Lóòótọ́, Jesu fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìṣírí láti “fi tokuntokun tiraka.” (Luku 13:24, NW) Ṣùgbọ́n kò fagbára mú wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ rí! Ó ru wọ́n sókè, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, ó mú ipò iwájú, ó sì wá ọ̀nà láti dé inú ọkàn-àyà wọn. Ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀mí Jehofa yóò ṣe èyí tí ó kù. Bákan náà ni àwọn alàgbà lónìí ṣe níláti fún agbo ní ìṣírí láti ṣiṣẹ́sin Jehofa tọkàntọkàn ṣùgbọ́n wọ́n níláti yẹra fún fífi ìdálẹ́bi tàbí ìtìjú kódààmú bá wọn, ní dídọ́gbọ́n fihàn pé ohun tí wọ́n ń ṣe ní lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa kò tó tàbí kò ní ìtẹ́wọ́gbà ní irú àwọn ọ̀nà kan. Ìbánilò lọ́nà “ẹ túbọ̀ ṣe síi, ẹ túbọ̀ ṣe síi, ẹ túbọ̀ ṣe síi!” aláìṣeéyípadà, tí ń tini lọ́pọnpọ̀n-ọ́n lè mú àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe sọ̀rètínù. Báwo ni yóò ti baninínújẹ́ tó bí alàgbà kan bá sọ ara rẹ̀ lórúkọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó “ṣòro lati tẹ́lọ́rùn”—ìyẹn yàtọ̀ gedegbe sí jíjẹ́ afòyebánilò!—1 Peteru 2:18, NW.
16 Gbogbo wa níláti jẹ́ afòyebánilò nínú ohun tí a ń retí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn! Arábìnrin kan, lẹ́yìn tí òun àti ọkọ rẹ̀ ti fi iṣẹ́ àyànfúnni míṣọ́nnárì sílẹ̀ nítorí àtibójútó ìyá rẹ̀ tí ń ṣòjòjò, kọ̀wé pé: “Àwọn àkókò yìí lekoko níti tòótọ́ fún àwa akéde tí a wà nínú ìjọ níta níbí. Bí ó ti jẹ́ pé a ti wà nínú iṣẹ́ àyíká àti àgbègbè, tí a pa wá mọ́ kúrò nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìkìmọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀, lójijì àti lọ́nà kan tí ó kún fún ìrora ni a fi mú ojú wa là gbòò sí èyí. Fún àpẹẹrẹ, mo máa ń sọ fún ara mi pé, ‘Èéṣe tí arábìnrin yẹn kò fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó bá a mú lọni lóṣù yìí? Ṣé kò ka Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ni?’ Nísinsìnyí mo mọ ìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀. Fún àwọn kan gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti jáde [nínú iṣẹ́-ìsìn] náà nìyẹn.’ Ẹ sì wo bí ó ti sàn jù tó láti gbóríyìn fún àwọn ará wa fún ohun tí wọ́n bá ṣe dípò kí a ṣèdájọ́ wọn fún ohun tí wọn kò ṣe!
17. Báwo ni Jesu ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa níti ìfòyebánilò?
17 Gbé àpẹẹrẹ tí ó gbẹ̀yìn yẹ̀wò nípa bí Jesu ṣe lo ọlá-àṣẹ rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó fi ìfòyebánilò hàn. Gẹ́gẹ́ bíi ti Baba rẹ̀, Jesu kò fi owú dáàbòbo ọlá-àṣẹ rẹ̀. Òun pẹ̀lú jẹ́ ọ̀gá nínú yíyannisípò, ní yíyanṣẹ́ fún ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ ẹrú rẹ̀ láti bójútó “gbogbo awọn nǹkan ìní rẹ̀” níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé. (Matteu 24:45-47, NW) Kò sì bẹ̀rù láti fetísílẹ̀ sí èrò àwọn ẹlòmíràn. Ó sábà máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ti rò ó sí?” (Matteu 17:25; 18:12; 21:28; 22:42) Bí ó ṣe yẹ kí ó rí láàárín gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lónìí nìyẹn. Kò sí iye ọlá-àṣẹ tí ó níláti sọ wọ́n di ẹni tí kò múratán láti fetísílẹ̀. Ẹ̀yin òbí, ẹ tẹ́tísílẹ̀! Ẹ̀yin ọkọ, ẹ tẹ́tísílẹ̀! Ẹ̀yin alàgbà, ẹ tẹ́tísílẹ̀!
18. (a) Báwo ni a ṣe lè wádìí wò bí a bá ní orúkọ rere fún jíjẹ́ afòyebánilò? (b) Ìgbèròpinnu wo ni yóò dára pé kí gbogbo wa ṣe?
18 Tìpinnu-tìpinnu, ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wa yóò fẹ́ láti “ní orúkọ rere fún jíjẹ́ afòyebánilò.” (Filippi 4:5, Phillips) Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè mọ̀ bí a bá ní irú orúkọ rere bẹ́ẹ̀? Ó dára, nígbà tí Jesu fẹ́ láti mọ̀ nípa ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa rẹ̀, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tí ó fọkàntán. (Matteu 16:13) Èéṣe tí o kò fi tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀? O lè béèrè lọ́wọ́ ẹnìkan tí o gba ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́ níti àìfọ̀rọ̀bọpobọyọ̀ bóyá a ń ròyìn rẹ ní rere fún jíjẹ́ ènìyàn kan tí ń fòyebánilò, tí ó sì ń juwọ́sílẹ̀. Dájúdájú ohun púpọ̀ wà tí gbogbo wa lè ṣe láti ṣàfarawé àpẹẹrẹ pípé Jesu níti ìfòyebánilò lọ́nà tí ó túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ síi! Ní pàtàkì jùlọ bí a bá ń lo ìwọ̀n ọlá-àṣẹ kan lórí àwọn ẹlòmíràn, ẹ jẹ́ kí a máa fìgbà gbogbo tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jehofa àti Jesu, kí a máa fìgbà gbogbo lò ó lọ́nà tí ó fi ìfòyebánilò hàn, kí a wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti dáríjinni, tẹ̀, tàbí juwọ́sílẹ̀ nígbà tí ó bá yẹ. Nítòótọ́, ǹjẹ́ kí olúkúlùkù wa làkàkà láti “jẹ́ afòyebánilò”!—Titu 3:2, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé náà New Testament Words ṣàlàyé pé: “Ọkùnrin kan tí ó jẹ́ epieikēs [afòyebánilò] mọ̀ pé àwọn àkókò kan máa ń wà nígbà tí oun kan lè bá ìdájọ́ òdodo mú pátápátá lábẹ́ òfin síbẹ̀ kí ó lòdì pátápátá lọ́nà ti ìwàrere. Ọkùnrin náà tí ó jẹ́ epieikēs mọ ìgbà tí ó yẹ láti mú òfin rọjú lábẹ́ ìmúnilápàpàǹdodo ipá kan tí ó ga jù tí ó sì tóbi ju òfin lọ.”
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èéṣe tí àwọn Kristian fi níláti fẹ́ láti fòyebánilò?
◻ Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè ṣàfarawé Jesu níti mímúratán láti dáríjì?
◻ Èéṣe tí a fi níláti làkàkà láti ṣeétẹ̀síhìn-ín sọ́hùn-ún gẹ́gẹ́ bíi ti Jesu?
◻ Báwo ni a ṣe lè fi ìfòyebánilò hàn nínú ọ̀nà tí a gbà ń lo ọlá-àṣẹ?
◻ Báwo ni a ṣe lè yẹ ara wa wò níti bóyá a jẹ́ afòyebánilò nítòótọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jesu fi ìmúratán dáríji Peteru onírònúpìwàdà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Nígbà tí obìnrin kan fi ìgbàgbọ́ àrà-ọ̀tọ̀ hàn, Jesu rí i pé èyí kìí ṣe àkókò láti fipá mú ìlànà gbogbogbòò kan ṣẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹ̀yin òbí ẹ tẹ́tísílẹ̀!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹ̀yin ọkọ ẹ tẹ́tísílẹ̀!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹ̀yin alàgbà ẹ tẹ́tísílẹ̀!