Àkọsílẹ̀ Máàkù
14 Ó ku ọjọ́ méjì+ kí wọ́n ṣe Ìrékọjá+ àti Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.+ Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin sì ń wá bí wọ́n ṣe máa fi ọgbọ́n àrékérekè* mú un,* kí wọ́n sì pa á;+ 2 torí wọ́n sọ pé: “Kì í ṣe nígbà àjọyọ̀; torí ariwo lè sọ látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn.”
3 Nígbà tó wà ní Bẹ́tánì, tó ń jẹun* ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀, obìnrin kan mú orùba* alabásítà tí wọ́n rọ òróró onílọ́fínńdà sí wá, ojúlówó náádì tó wọ́n gan-an ni. Ó já orùba alabásítà náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da òróró náà sórí rẹ̀.+ 4 Ni àwọn kan wá bẹ̀rẹ̀ sí í fìbínú sọ láàárín ara wọn pé: “Kí ló dé tó ń fi òróró onílọ́fínńdà yìí ṣòfò báyìí? 5 Torí à bá ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní iye tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) owó dínárì,* ká sì kó owó náà fún àwọn aláìní!” Inú bí wọn gidigidi sí obìnrin náà.* 6 Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹ fi í sílẹ̀. Kí ló dé tí ẹ fẹ́ máa yọ ọ́ lẹ́nu? Ohun tó dáa gan-an ló ṣe sí mi.+ 7 Torí ìgbà gbogbo ni àwọn aláìní wà láàárín yín,+ ẹ sì lè ṣe ohun rere sí wọn nígbàkigbà tí ẹ bá fẹ́, àmọ́ ìgbà gbogbo kọ́ ni màá wà láàárín yín.+ 8 Ó ṣe ohun tó lè ṣe; ó da òróró onílọ́fínńdà sí ara mi ṣáájú nítorí ìsìnkú.+ 9 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ibikíbi tí a bá ti ń wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ayé,+ wọ́n á máa sọ ohun tí obìnrin yìí ṣe láti fi rántí rẹ̀.”+
10 Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ọ̀kan nínú àwọn Méjìlá náà, lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.+ 11 Inú wọn dùn nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn máa fún un ní owó fàdákà.+ Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá ìgbà tó máa dáa jù láti fà á lé wọn lọ́wọ́.
12 Ní ọjọ́ kìíní Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ nígbà tí wọ́n máa ń fi ẹran Ìrékọjá rúbọ,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “Ibo lo fẹ́ ká lọ ṣètò fún ọ láti jẹ Ìrékọjá?”+ 13 Ó wá rán méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru ìṣà omi máa pàdé yín. Ẹ tẹ̀ lé e,+ 14 ibikíbi tó bá wọlé sí, ẹ sọ fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ sọ pé: “Ibo ni yàrá àlejò wà, tí èmi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi ti lè jẹ Ìrékọjá?”’ 15 Ó sì máa fi yàrá ńlá kan hàn yín lókè, tó ti ní àwọn ohun tí a nílò, tó sì ti wà ní sẹpẹ́. Ẹ ṣètò rẹ̀ síbẹ̀ fún wa.” 16 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà jáde lọ, wọ́n sì wọnú ìlú náà, wọ́n rí i bó ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá.
17 Nígbà tó di alẹ́, òun àti àwọn Méjìlá náà wá.+ 18 Bí wọ́n sì ṣe jókòó* sídìí tábìlì, tí wọ́n ń jẹun, Jésù sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tó ń bá mi jẹun máa dà mí.”+ 19 Ẹ̀dùn ọkàn bá wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un lọ́kọ̀ọ̀kan pé: “Èmi kọ́ o, àbí èmi ni?” 20 Ó sọ fún wọn pé: “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin Méjìlá tí a jọ ń ki ọwọ́ bọ inú abọ́ ni.+ 21 Torí Ọmọ èèyàn ń lọ, bí a ṣe kọ ọ́ nípa rẹ̀, àmọ́ ọkùnrin tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi Ọmọ èèyàn léni lọ́wọ́ gbé!+ Ì bá sàn fún ọkùnrin náà ká ní wọn ò bí i.”+
22 Bí wọ́n ṣe ń jẹun, ó mú búrẹ́dì, ó súre, ó bù ú, ó sì fún wọn, ó sọ pé: “Ẹ gbà; èyí túmọ̀ sí ara mi.”+ 23 Ó mú ife kan, ó dúpẹ́, ó sì gbé e fún wọn, gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.+ 24 Ó sọ fún wọn pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀+ májẹ̀mú’ mi,+ tí a máa dà jáde nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn.+ 25 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé mi ò ní mu nínú ohun tí wọ́n fi àjàrà ṣe mọ́, títí di ọjọ́ yẹn tí màá mu ún ní tuntun nínú Ìjọba Ọlọ́run.” 26 Níkẹyìn, lẹ́yìn tí wọ́n kọrin ìyìn,* wọ́n lọ sí Òkè Ólífì.+
27 Jésù sì sọ fún wọn pé: “Gbogbo yín lẹ máa kọsẹ̀, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Màá kọ lu olùṣọ́ àgùntàn,+ àwọn àgùntàn sì máa tú ká.’+ 28 Àmọ́ lẹ́yìn tí mo bá jíǹde, màá lọ sí Gálílì ṣáájú yín.”+ 29 Ṣùgbọ́n Pétérù sọ fún un pé: “Tí gbogbo àwọn yòókù bá tiẹ̀ kọsẹ̀, èmi ò ní kọsẹ̀.”+ 30 Ni Jésù bá sọ fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ pé lónìí, àní, lóru òní yìí, kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ 31 Àmọ́ ó ń sọ ṣáá pé: “Tó bá tiẹ̀ gba pé kí n kú pẹ̀lú rẹ, ó dájú pé mi ò ní sẹ́ ọ.” Ohun tí gbogbo àwọn yòókù náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ nìyẹn.+
32 Wọ́n wá dé ibì kan tí wọ́n ń pè ní Gẹ́tísémánì, ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jókòó síbí, kí èmi máa gbàdúrà.”+ 33 Ó mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù dání pẹ̀lú rẹ̀,+ ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ní ẹ̀dùn ọkàn gidigidi,* ìdààmú sì bá a gan-an. 34 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi* gan-an,+ àní títí dé ikú. Ẹ dúró síbí, kí ẹ sì máa ṣọ́nà.”+ 35 Ó lọ síwájú díẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà pé, tó bá ṣeé ṣe, kí wákàtí náà ré òun kọjá. 36 Ó sì sọ pé: “Ábà,* Bàbá,+ ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ọ; mú ife yìí kúrò lórí mi. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí èmi fẹ́, àmọ́ ohun tí ìwọ fẹ́.”+ 37 Ó pa dà wá, ó sì rí i pé wọ́n ń sùn, ó wá sọ fún Pétérù pé: “Símónì, ò ń sùn ni? Ṣé o ò lókun láti ṣọ́nà fún wákàtí kan ni?+ 38 Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.+ Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́,* àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.”+ 39 Ó tún lọ gbàdúrà, ó ń sọ ohun kan náà.+ 40 Ó tún pa dà wá, ó sì rí i pé wọ́n ń sùn, torí oorun ń kùn wọ́n gan-an, torí náà, wọn ò mọ èsì tí wọ́n máa fún un. 41 Ó pa dà wá lẹ́ẹ̀kẹta, ó sì sọ fún wọn pé: “Ní irú àkókò yìí, ẹ̀ ń sùn, ẹ sì ń sinmi! Ó tó! Wákàtí náà ti dé!+ Ẹ wò ó! A fi Ọmọ èèyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 42 Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká lọ. Ẹ wò ó! Ẹni tó máa dà mí ti dé tán.”+
43 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Júdásì, ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà dé pẹ̀lú èrò tí wọ́n kó idà àti kùmọ̀ dání, àwọn olórí àlùfáà, àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà ló rán wọn wá.+ 44 Ẹni tó fẹ́ dà á ti fún wọn ní àmì kan tó jọ yé wọn, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; kí ẹ mú un, kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ bí ẹ ṣe ń mú un lọ.” 45 Ó wá tààràtà, ó sì sún mọ́ ọn, ó sọ pé: “Rábì!” ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 46 Torí náà, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un sọ́dọ̀. 47 Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n dúró nítòsí fa idà rẹ̀ yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ dà nù.+ 48 Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣé èmi lẹ wá fi idà àti kùmọ̀ mú bí olè?+ 49 Ojoojúmọ́ ni mò ń wà pẹ̀lú yín nínú tẹ́ńpìlì, tí mò ń kọ́ni,+ àmọ́ ẹ ò mú mi. Ṣùgbọ́n kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ ni.”+
50 Gbogbo wọn fi í sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ.+ 51 Àmọ́ ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ pé aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa nìkan ló wọ láti bo ìhòòhò ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí, wọ́n sì fẹ́ mú un, 52 àmọ́ ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì sá lọ ní ìhòòhò.*
53 Wọ́n wá mú Jésù lọ sọ́dọ̀ àlùfáà àgbà,+ gbogbo àwọn olórí àlùfáà, àwọn àgbààgbà àti àwọn akọ̀wé òfin sì kóra jọ.+ 54 Àmọ́ Pétérù ń tẹ̀ lé e ní òkèèrè, títí wọnú àgbàlá àlùfáà àgbà; ó jókòó pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì ń yáná nídìí iná kan tó mọ́lẹ̀ yòò.+ 55 Àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sàhẹ́ndìrìn ń wá ẹ̀rí tí wọ́n máa fi mú Jésù kí wọ́n lè pa á, àmọ́ wọn ò rí ìkankan.+ 56 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ń jẹ́rìí èké sí i,+ àmọ́ ẹ̀rí wọn ò bára mu. 57 Bákan náà, àwọn kan ń dìde, wọ́n sì ń jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ń sọ pé: 58 “A gbọ́ tó sọ pé, ‘Màá wó tẹ́ńpìlì yìí tí wọ́n fi ọwọ́ kọ́ palẹ̀, màá sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ òmíràn tí wọn ò fi ọwọ́ kọ́.’”+ 59 Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n sọ yìí, ẹ̀rí wọn ò bára mu.
60 Àlùfáà àgbà wá dìde láàárín wọn, ó sì bi Jésù pé: “Ṣé o ò ní fèsì rárá ni? Ẹ̀rí tí àwọn èèyàn yìí ń jẹ́ lòdì sí ọ ńkọ́?”+ 61 Àmọ́ kò sọ̀rọ̀, kò sì fèsì rárá.+ Àlùfáà àgbà tún bẹ̀rẹ̀ sí í bi í ní ìbéèrè, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ ni Kristi Ọmọ Ẹni Ìbùkún?” 62 Jésù wá sọ pé: “Èmi ni; ẹ sì máa rí Ọmọ èèyàn+ tó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára,+ tó sì ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà* ojú ọ̀run.”+ 63 Ni àlùfáà àgbà bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọ pé: “Kí la tún fẹ́ fi àwọn ẹlẹ́rìí ṣe?+ 64 Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì náà. Kí lẹ pinnu?”* Gbogbo wọn dá a lẹ́bi pé ikú tọ́ sí i.+ 65 Àwọn kan wá bẹ̀rẹ̀ sí í tutọ́ sí i lára,+ wọ́n sì bo ojú rẹ̀, wọ́n gbá a ní ẹ̀ṣẹ́, wọ́n sì ń sọ fún un pé: “Sọ tẹ́lẹ̀!” Wọ́n gbá a lójú, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ sì mú un.+
66 Nígbà tí Pétérù wà nísàlẹ̀ nínú àgbàlá, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà wá.+ 67 Bó ṣe rí Pétérù tó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó sì sọ pé: “Ìwọ náà wà pẹ̀lú Jésù ará Násárẹ́tì yìí.” 68 Àmọ́ ó sẹ́, ó ní: “Mi ò mọ̀ ọ́n, ohun tí ò ń sọ ò sì yé mi,” ló bá jáde lọ sí ibi àbáwọlé.* 69 Ìránṣẹ́bìnrin náà rí i níbẹ̀, ló bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn tó dúró nítòsí pé: “Ọ̀kan lára wọn nìyí.” 70 Ó tún ń sẹ́. Lẹ́yìn tó ṣe díẹ̀, àwọn tó dúró nítòsí tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún Pétérù pé: “Ó dájú pé o wà lára wọn, torí ká sòótọ́, ará Gálílì ni ọ́.” 71 Àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í gégùn-ún, ó sì ń búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí!” 72 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ kọ lẹ́ẹ̀kejì,+ Pétérù sì rántí ohun tí Jésù sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ Ló bá bara jẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.