Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Gálátíà, Éfésù, Fílípì àti Kólósè
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé àwọ́n ẹlẹ́sìn Júù ti mú káwọn Kristẹni kan fi ìjọsìn mímọ́ sílẹ̀, ó kọ lẹ́tà kan tó fa kíki “sí àwọn ìjọ Gálátíà.” (Gál. 1:2) Àkókò kan láàárín ọdún 50 sí 52 Sànmánì Kristẹni ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí, ìbáwí tó ṣe tààràtà àti ọ̀rọ̀ ìyànjú tó lágbára ló sì wà nínú lẹ́tà náà.
Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n gẹ́gẹ́ bí “ẹlẹ́wọ̀n Kristi Jésù” ní Róòmù, ó kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ tó wà ní Éfésù, Fílípì àti Kólósè. Ó fún wọn ní ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an àti ìṣírí onífẹ̀ẹ́. (Éfé. 3:1) Lóde òní, àwa pẹ̀lú lè jàǹfààní tá a bá ń fiyè sáwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Gálátíà, Éfésù, Fílípì àti Kólósè.—Héb. 4:12.
Ọ̀NÀ WO LA GBÀ ‘POLONGO WỌN NÍ OLÓDODO?’
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́sìn Júù ń wá ọ̀nà láti bẹnu àtẹ́ lu jíjẹ́ tí Pọ́ọ̀lù jẹ́ àpọ́sítélì, Pọ́ọ̀lù gbèjà iṣẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀ nípa sísọ díẹ̀ nínú ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀. (Gál. 1:11–2:14) Pọ́ọ̀lù sọ kókó kan láti fi hàn pé ẹ̀kọ́ èké làwọn ẹlẹ́sìn Júù ń kọ́ àwọn èèyàn, ó ní: “A kì í polongo ènìyàn ní olódodo nítorí àwọn iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe kìkì nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.”—Gál. 2:16.
Pọ́ọ̀lù sọ pé, Kristi “tú àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin sílẹ̀ nípa rírà,” ó sì dá wọn sílẹ̀ sínú òmìnira Kristẹni. Ó sọ ọ̀rọ̀ ìyànjú tó lágbára kan fáwọn ará Gálátíà, ó ní: “Ẹ dúró ṣinṣin, ẹ má sì jẹ́ kí a tún há yín mọ́ inú àjàgà ìsìnrú.”—Gál. 4:4, 5; 5:1.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
3:16-18, 28, 29—Ǹjẹ́ májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ṣì wà síbẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Àfikún ni májẹ̀mú Òfin jẹ́ sí májẹ̀mú tí Ọlọrun bá Ábúráhámù dá, kì í ṣe pé ó fi rọ́pò rẹ̀. Nítorí náà, májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ṣì wúlò lẹ́yìn tí Òfin ti wá sí “òpin.” (Éfé. 2:15) Àwọn ìlérí májẹ̀mú yẹn la fi fún “irú ọmọ” Ábúráhámù tòótọ́, ìyẹn Kristi Jésù, tó jẹ́ àkọ́kọ́ lára irú ọmọ náà, àtàwọn tó jẹ́ “ti Kristi.”
6:2—Kí ni “Òfin Kristi”? Òfin yìí ni gbogbo ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni àtàwọn àṣẹ tó pa. Ní pàtàkì, àṣẹ tó pa pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ‘nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Jòh. 13:34)
6:8—Báwo la ṣe ń “fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn”? Ọ̀nà tá à ń gbà ṣe èyí ni pé, à ń gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí ẹ̀mí Ọlọ́run á fi lè máa darí wa. Fífúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn jẹ mọ́ fífi tọkàntọkàn kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tó máa mú kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:6-9. Tí ìṣòro bá dé nínú ìjọ, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ wá ojútùú sí ìṣòro náà láìjáfara. Tí wọ́n bá ń ronú lọ́nà tó yèkooro tí wọ́n sì ń lo Ìwé Mímọ́, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti ta ko èrò èké.
2:20. Ìràpadà jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún àwa èèyàn. Ojú tá a sì gbọ́dọ̀ fi máa wò ó nìyẹn.—Jòh. 3:16.
5:7-9. Kíkó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ lè ‘dí wa lọ́wọ́ ṣíṣègbọràn sí òtítọ́.’ Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká yẹra fún ẹgbẹ́ búburú.
6:1, 2, 5. Àwọn tí wọ́n “tóótun nípa tẹ̀mí” lè bá wa gbé ẹ̀rù wíwúwo tá a bá ní, wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ko ìṣòro látàrí pé a ṣi ẹsẹ̀ gbé láìmọ̀ọ́mọ̀. Àmọ́ ṣá o, tó bá kan ṣíṣe ojúṣe wa nípa tẹ̀mí, àwa fúnra wa la gbọ́dọ̀ ṣe é.
‘KÍKÓ OHUN GBOGBO JỌPỌ̀ NÍNÚ KRISTI’
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó mú kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn Kristẹni nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Éfésù, ó sọ̀rọ̀ nípa “iṣẹ́ àbójútó kan ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ . . . láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” Kristi ti fún wa ní àwọn “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” láti mú kí gbogbo wa “dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́.”—Éfé. 1:10; 4:8, 13.
Táwa Kristẹni bá fẹ́ máa bọlá fún Ọlọ́run tá a sì fẹ́ kí ìṣọ̀kan máa wà láàárín wa, a gbọ́dọ̀ “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀” ká sì ‘wà ní ìtẹríba fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìbẹ̀rù Kristi.’ A tún gbọ́dọ̀ “dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù” nípa gbígbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.—Éfé. 4:24; 5:21; 6:11.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:4-7—Báwo ló ṣe jẹ́ pé Ọlọ́run ti yan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tipẹ́tipẹ́ ká tó bí wọn? Ńṣe ni Ọlọ́run yan àwọn ẹni àmì òróró lápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, kì í ṣe lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ tó tàn dé gbogbo ayé. Ọlọ́run ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣáájú kí á tó lóyún ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ èyíkéyìí. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì kan ìfẹ́ Ọlọ́run pé kí àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ lọ́run.—Gál. 3:16, 29.
2:2—Báwo ni ẹ̀mí ayé ṣe dà bí afẹ́fẹ́, báwo ló sì ṣe ń lo agbára lórí ayé? Bó ṣe jẹ́ pé afẹ́fẹ́ tá à ń mí símú wà káàkiri, bákan náà ni “ẹ̀mí ayé,” ìyẹn ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe àti àìgbọràn ṣe gbòde kan. (1 Kọ́r. 2:12) Ẹ̀mí ayé lágbára gan-an, ó lè tètè yíni lérò padà, kì í sì í fini lọ́rùn sílẹ̀ bọ̀rọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi lágbára gan-an lórí ayé.
2:6—Báwo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe wà ní “àwọn ibi ọ̀run” nígbà tó jẹ́ pé wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé? “Àwọn ibi ọ̀run” tá a sọ níbí yìí kì í ṣe ọ̀run gidi tí Ọlọ́run ṣèlérí láti fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń ṣàpẹẹrẹ ipò gíga nípa tẹ̀mí tí wọ́n wà, ní ti pé “a fi èdìdì dì wọ́n pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí.”—Éfé. 1:13, 14.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
4:8, 11-15. Jésù Kristi “kó àwọn òǹdè lọ,” ìyẹn túmọ̀ sí pé ó mú àwọn èèyàn kúrò lábẹ́ agbára Sátánì, ó sì lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti gbé ìjọ Kristẹni ró. A lè “fi ìfẹ́ dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú . . . Kristi” nípa ṣíṣègbọràn àti títẹríba fún àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín wa àti nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ètò tí ìjọ bá ṣe.—Héb. 13:7, 17.
5:22-24, 33. Yàtọ̀ sí pé aya gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀, ó tún gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún un. Ọ̀nà tí aya lè gbà ṣe èyí ni pé kí ó ní “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù” kó máa sapá láti máa pọ́n ọkọ rẹ̀ lé, kó máa sọ ohun tó dára nípa rẹ̀, kó sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ káwọn ìpinnu tí ọkọ rẹ̀ bá ṣe lè yọrí sí rere.—1 Pét. 3:3, 4; Títù 2:3-5.
5:25, 28, 29. Gẹ́gẹ́ bí ọkọ kan ti ń “bọ́” ara rẹ̀, bákan náà, ó gbọ́dọ̀ máa tọ́jú aya rẹ̀ nípa tara, kó máa tẹ́tí sí i nígbà tó bá fẹ́ sọ ohun tó ń dùn ún lọ́kàn, kí wọ́n sì jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bákan náà, ọkọ gbọ́dọ̀ máa ṣìkẹ́ aya rẹ̀ nípa lílo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì máa bá a lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe.
6:10-13. Tá a bá fẹ́ dènà àwọn ẹ̀mí èṣù, ó yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa gbé ìhámọ́ra ogun tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.
“Ẹ MÁA BÁ A LỌ NÍ RÍRÌN LÉTÒLÉTÒ”
Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ bí ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Fílípì. Ó sọ pé: “Èyí . . . ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún.” Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n láti má ṣe kó sínú ìdẹkùn dídá ara ẹni lójú ju bó ṣe yẹ lọ, ó ní: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.”—Fílí. 1:9; 2:12.
Pọ́ọ̀lù rọ àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wọn láti “lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run.” Ó ní: “Dé àyè tí a ti tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní rírìn létòletò nínú ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yìí.”—Fílí. 3:14-16.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:23—“Nǹkan méjì” wo ló kó ìdààmú bá Pọ́ọ̀lù, “ìtúsílẹ̀” wo ló sì ń fẹ́? Nítorí ipò tí Pọ́ọ̀lù wà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun méjì tó kó ìdààmú bá a ni, ikú àti ìyè. (Fílí. 1:21) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sọ èyí tó máa mú nínú méjèèjì, ó jẹ́ ká mọ nǹkan tóun ń fẹ́. Nǹkan náà sì ni, “ìtúsílẹ̀ àti wíwà pẹ̀lú Kristi.” (Fílí. 3:20, 21; 1 Tẹs. 4:16) “Ìtúsílẹ̀” tó máa wáyé nígbà wíwàníhìn-ín Kristi yìí, yóò mú kí Pọ́ọ̀lù gbà èrè tí Jèhófà ti pèsè sílẹ̀ fún un.—Mát. 24:3.
2:12, 13—Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń mú ká ‘fẹ́ láti ṣe, kí á sì gbé ìgbésẹ̀’? Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè ṣiṣẹ́ nínú ọkàn wa, ó sì lè tọ́ èrò wa láti mú ká túbọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ rẹ̀. Nítorí náà, Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ bá a ti ‘ń ṣiṣẹ́ ìgbàlà wa yọrí.’
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:3-5. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Fílípì kò ní ọrọ̀ nípa tara, wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa nínú jíjẹ́ ọ̀làwọ́.—2 Kọ́r. 8:1-6.
2:5-11. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú àpẹẹrẹ Jésù, béèyàn bá jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, èyí kò fi hàn pé òmùgọ̀ nírú ẹni bẹ́ẹ̀, ńṣe lo fi hàn pé ọmọlúwàbí ló jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà máa ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga.—Òwe 22:4.
3:13. “Àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn” lè jẹ́ àwọn nǹkan bí iṣẹ́ tó ń mówó rẹpẹtẹ wọlé, ìfọ̀kànbalẹ̀ téèyàn máa ń ní tó bá wá láti ìdílé olówó, ó sì lè jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tẹ́nì kan ti dá sẹ́yìn, àmọ́ tó ti ronú pìwà dà tá a sì ti ‘wẹ̀ ẹ́ mọ́.’ (1 Kọ́r. 6:11) Ńṣe ló yẹ ká gbàgbé àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìyẹn ni pé, ká má ṣe jẹ́ kí wọ́n gbà wá lọ́kàn mọ́, ká sì máa “nàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú.”
‘Ẹ FẸSẸ̀ MÚLẸ̀ NÍNÚ ÌGBÀGBỌ́’
Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè, ó fi èrò òdì táwọn olùkọ́ èké ní hàn kedere. Pọ́ọ̀lù sọ pé ìgbàlà kò sinmi lórí ohun tí Òfin ń béèrè, ohun tó sinmi lé ni ‘bíbá a lọ nínú ìgbàgbọ́.’ Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará Kólósè pé kí wọ́n ‘máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, kí wọ́n ta gbòǹgbò, kí a sì máa gbé wọn ró nínú rẹ̀, kí wọ́n sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.’ Báwo ni fífẹsẹ̀múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ ṣe yẹ kó nípa lórí wọn?—Kól. 1:23; 2:6, 7.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà yín.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún sọ fún wọn pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.” Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí kì í ṣe ara ìjọ Kristẹni, ó ní: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n sí” wọn.—Kól. 3:14, 15, 23; 4:5.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:8—Kí ni “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé” tí Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa wọn? Àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé ni àwọn nǹkan tó wà nínú ayé Sátánì, ìyẹn àwọn nǹkan táwọn èèyàn kà sí pàtàkì, tàbí àwọn ìlànà tó ń darí àwọn èèyàn nínú ayé tó sí ń tì wọ́n ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe. (1 Jòh. 2:16) Lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìmọ̀ ọgbọ́n orí, ìfẹ́ ọrọ̀, àti gbogbo ìsìn èké ayé yìí.
4:16—Kí nìdí tí lẹ́tà àwọn ará Laodíkíà kò fi sí lára àwọn ìwé Bíbélì? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí pé kò sí àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì fún àwa Kristẹni òde òní nínú lẹ́tà náà. Tàbí kó jẹ́ pé ó tún àwọn kókó kan sọ lára àwọn lẹ́tà yòókù tí Ọlọ́run mí sí.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:2, 20. Ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó fi hàn sí wa lè mú ká ní ẹ̀rí ọkàn tí kò dá wa lẹ́bi, ká sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn.
2:18, 23. “Ìrẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́yà,” ìyẹn kéèyàn máa ṣe bíi pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ torí àti gbayì lójú àwọn èèyàn, bóyá nípa kíkọ àwọn nǹkan ti ara sílẹ̀, tàbí fífi ìyà jẹ ara ẹni jẹ́ àmì pé ‘èrò inú ẹnì náà nípa ti ara ń mú un wú fùkẹ̀.’