Tímótì—“Ojúlówó Ọmọ Nínú Ìgbàgbọ́”
TÍMÓTÌ ṣì kéré gan-an nígbà tí Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yàn án gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò máa bá òun rìnrìn àjò. Bí àjọṣe kan tí yóò wà fún nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣe bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ nìyẹn. Àjọṣe tó wà láàárín àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí lágbára débi tí Pọ́ọ̀lù fi lè pe Tímótì ní “ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa,” ó sì tún pè é ní “ojúlówó ọmọ nínú ìgbàgbọ́.”—1 Kọ́ríńtì 4:17; 1 Tímótì 1:2.
Irú ènìyàn wo ni Tímótì jẹ́ gan-an tó fi jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ò lè fọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣeré rárá? Báwo ni Tímótì ṣe di ọ̀rẹ́ tó ṣeyebíye bẹ́ẹ̀? Ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní wo la lè rí kọ́ nínú àwọn àkọsílẹ̀ onímìísí nípa ìgbòkègbodò Tímótì?
Pọ́ọ̀lù Ló Yàn Án
Pọ́ọ̀lù rí ọ̀dọ́mọdé ọmọlẹ́yìn yìí nígbà tí àpọ́sítélì náà ṣèbẹ̀wò sí Lísírà (níbi tí a ń pè ní Turkey lónìí) nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Tiwa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tímótì lè má tí ì tó ọmọ ogún ọdún tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ lógún ọdún, àwọn Kristẹni tó wà ní Lísírà àti Íkóníónì sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa. (Ìṣe 16:1-3) Orúkọ rẹ̀ tó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run” sì rò ó. Láti ìgbà ọmọdé ni Lọ́ìsì, ìyá Tímótì àgbà àti Yùníìsì, ìyá rẹ̀, ti ń fi Ìwé Mímọ́ kọ́ ọ. (2 Tímótì 1:5; 3:14, 15) Ó lè jẹ́ pé ìgbà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò sí ìlú yẹn lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn ni wọ́n gba ìsìn Kristẹni. Ní báyìí, àwítẹ́lẹ̀ kan nípasẹ̀ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ wá fi bí ọjọ́ ọ̀la Tímótì yóò ṣe rí hàn. (1 Tímótì 1:18) Láti lè ṣe ohun tí àṣẹ yẹn wí, Pọ́ọ̀lù àti àwọn àgbà ọkùnrin tó wà nínú ìjọ gbé ọwọ́ lé ọ̀dọ́kùnrin náà lórí, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ yà á sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pàtàkì kan, àpọ́sítélì náà sì yàn án gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò máa bá òun rìnrìn àjò míṣọ́nnárì.—1 Tímótì 4:14; 2 Tímótì 1:6.
Títí dìgbà táà ń wí yìí, Tímótì kò tí ì dádọ̀dọ́, nítorí pé Gíríìkì aláìgbàgbọ́ ni baba rẹ̀. Ká sọ tòótọ́, èyí kò pọndandan kí ẹnì kan tó di Kristẹni. Àmọ́, kí ó má bàa di pé Tímótì ń mú àwọn Júù tí yóò máa bẹ̀ wò kọsẹ̀, ó ní láti fara da ohun aronilára gógó yìí.—Ìṣe 16:3.
Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ fìgbà kan ka Tímótì sí Júù? Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àwọn rábì aláṣẹ, “ìyá ni yóò pinnu ìlú tó jẹ́ ti ọmọ tí tọkọtaya tó jẹ́ ọmọ ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá bí, kì í ṣe baba.” Ìyẹn ni pé, “obìnrin tó jẹ́ Júù yóò bí ọmọ tó jẹ́ Júù.” Síbẹ̀, òǹkọ̀wé Shaye Cohen béèrè bóyá irú “òfin rábì bẹ́ẹ̀ nípa ènìyàn ti wà ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa” àti pé bóyá òfin náà kan àwọn Júù tó wà ní Éṣíà Kékeré. Lẹ́yìn gbígbé ẹ̀rí tó ti ìtàn náà lẹ́yìn yẹ̀ wò, ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí pé nígbà tí àwọn ọkùnrin Kèfèrí bá fẹ́ àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, “ọmọ tí irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ bá mú jáde lè jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì kìkì tí ìdílé náà bá ń gbé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ìgbà tí wọ́n bá ń gbé ìlú ìyá ni ìlà ìran jẹ́ ti ìyá. Ìgbà tí ọmọbìnrin Ísírẹ́lì bá ti lọ bá ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ Kèfèrí nílùú rẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ̀ náà di Kèfèrí.” Ohun yòówù kó jẹ́, ọmọ ẹ̀yà méjì tí Tímótì jẹ́ ti ní láti ṣèrànwọ́ gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Bó ṣe máa láǹfààní láti bá àwọn Júù sọ̀rọ̀ náà ló ṣe máa láǹfààní láti bá àwọn Kèfèrí sọ̀rọ̀, bóyá ìyẹn tiẹ̀ lè mú kó ṣeé ṣe fún un láti fòpin sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó wà láàárín wọn.
Ìbẹ̀wò Pọ́ọ̀lù sí Lísírà jẹ́ ìyípadà ńlá nínú ìgbésí ayé Tímótì. Ìmúratán ọ̀dọ́mọkùnrin náà láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ àti láti fi ìrẹ̀lẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni alàgbà mú kí ó rí ìbùkún ńlá àti àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn gbà. Yálà ó mọ̀ nígbà yẹn ni tàbí kò mọ̀, ó dájú pé lábẹ́ ìdarí Pọ́ọ̀lù, Tímótì yóò di ẹni tí a lò fún àwọn iṣẹ́ pàtàkì tó jẹ́ tí ìṣàkóso Ọlọ́run, tí yóò tilẹ̀ mú kó lọ sí àwọn ìlú jíjìnnà réré bíi Róòmù, tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ ọba náà.
Tímótì Gbé Ire Ìjọba Náà Lárugẹ
Ìwọ̀nba ni àkọsílẹ̀ tí a rí nípa ìgbòkègbodò Tímótì, àmọ́, ó rìnrìn àjò gan-an láti gbé ire Ìjọba náà lárugẹ. Ìrìn àjò àkọ́kọ́ tí Tímótì bá Pọ́ọ̀lù àti Sílà rìn ní ọdún 50 Sànmánì Tiwa mú kí ó gba Éṣíà Kékeré lọ sí Yúróòpù. Ibẹ̀ ló ti kópa nínú wíwàásù ní ìlú Fílípì, Tẹsalóníkà, àti Bèróà. Lẹ́yìn tí àtakò mú kí Pọ́ọ̀lù lọ sí Áténì, ó fi Tímótì àti Sílà sílẹ̀ sí Bèróà láti bójú tó àwùjọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà níbẹ̀. (Ìṣe 16:6–17:14) Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù rán Tímótì lọ sí Tẹsalóníkà láti lọ fún ìjọ tuntun tó wà níbẹ̀ lókun. Tímótì fún Pọ́ọ̀lù ní ìròyìn rere nípa bí ìjọ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú nígbà tó pàdé rẹ̀ ní Kọ́ríńtì.—Ìṣe 18:5; 1 Tẹsalóníkà 3:1-7.
Ìwé Mímọ́ kò sọ bí Tímótì ṣe pẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì tó. (2 Kọ́ríńtì 1:19) Àmọ́, ó dà bí pé ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù tún ronú àtirán an padà sọ́dọ̀ wọn nítorí ìròyìn dídaniláàmú tó rí gbà nípa ipò tí wọ́n wà. (1 Kọ́ríńtì 4:17; 16:10) Nígbà tó yá, ó tún rán Érásítù òun Tímótì láti Éfésù lọ sí Makedóníà. Ìgbà tí Pọ́ọ̀lù sì fi máa kọ̀wé sí àwọn ará Róòmù láti Kọ́ríńtì, Tímótì tún ti wà lọ́dọ̀ rẹ̀.—Ìṣe 19:22; Róòmù 16:21.
Tímótì àtàwọn mìíràn ló bá Pọ́ọ̀lù kúrò ní Kọ́ríńtì nígbà tó ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó sì kéré tán, wọ́n sin àpọ́sítélì náà dé Tíróásì. A ò wá lè sọ bóyá Tímótì tẹ̀ lé e dé Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, orúkọ rẹ̀ wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn lẹ́tà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí Pọ́ọ̀lù kọ nígbà tó wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù ní nǹkan bí ọdún 60 sí 61 Sànmánì Tiwa.a (Ìṣe 20:4; Fílípì 1:1; Kólósè 1:1; Fílémónì 1) Pọ́ọ̀lù tún ń ṣètò àtirán Tímótì láti Róòmù sí Fílípì. (Fílípì 2:19) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù tún jáde lẹ́wọ̀n tán, Tímótì ní láti dúró sí Éfésù lábẹ́ àṣẹ àpọ́sítélì náà.—1 Tímótì 1:3.
Níwọ̀n bí kò ti rọrùn láti rìnrìn àjò ní ọ̀rúndún kìíní, a gbóríyìn gidi fún mímúra tí Tímótì múra tán láti rin ọ̀pọ̀ ìrìn àjò nítorí àwọn ìjọ. (Wo Ilé Ìṣọ́, August 15, 1996, ojú ìwé 29, àpótí.) Ẹ jẹ́ kí a gbé ọ̀kan péré yẹ̀ wò nínú àwọn ìrìn àjò rẹ̀, kí a sì wo ohun tí èyí ń sọ fún wa nípa Tímótì.
Lílóye Irú Ẹni Tí Tímótì Jẹ́
Tímótì wà lọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù ní Róòmù nígbà tí àpọ́sítélì tó wà lẹ́wọ̀n náà kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ní Fílípì pé: “Mo ní ìrètí nínú Jésù Olúwa láti rán Tímótì sí yín láìpẹ́, kí n lè jẹ́ ọkàn tí a mú lórí yá gágá nígbà tí mo bá mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín. Nítorí èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín. Nítorí gbogbo àwọn yòókù ń wá ire ara wọn, kì í ṣe ti Kristi Jésù. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ ẹ̀rí tí ó fúnni nípa ara rẹ̀, pé bí ọmọ lọ́dọ̀ baba ni ó sìnrú pẹ̀lú mi fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.”—Fílípì 1:1, 13, 28-30; 2:19-22.
Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túbọ̀ fi bí Tímótì ṣe ń ṣàníyàn nípa àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ hàn. Béèyàn ò bá wọ ọkọ̀ ojú omi, irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀ ń gba fífi ẹsẹ̀ rin ìrìn ogójì ọjọ́ láti Róòmù sí Fílípì, pẹ̀lú gbígba orí Òkun Ádíríà kọjá fúngbà díẹ̀, àti ìrìn ogójì ọjọ́ mìíràn láti padà sí Róòmù. Tímótì ṣe tán láti ṣe gbogbo ìwọ̀nyẹn kí ó lè bẹ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ wò.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tímótì rìnrìn àjò tó pọ̀ báyẹn, àwọn ìgbà kan wà tí ara rẹ̀ kò yá. Ó hàn gbangba pé inú máa ń yọ ọ́ lẹ́nu, ó sì tún ní ìṣòro ‘àìsàn tó ń ṣe é lemọ́lemọ́.’ (Tímótì 5:23) Síbẹ̀, ó tiraka nítorí ìhìn rere náà. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi ní irú ìbátan tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀!
Lábẹ́ àbójútó àpọ́sítélì náà àti nípasẹ̀ àwọn ìrírí tí wọ́n jọ ní pa pọ̀, Tímótì wá mú ìwà Pọ́ọ̀lù. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi lè sọ fún un pé: “Ìwọ ti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ mi pẹ́kípẹ́kí, ipa ọ̀nà ìgbésí ayé mi, ète mi, ìgbàgbọ́ mi, ìpamọ́ra mi, ìfẹ́ mi, ìfaradà mi, àwọn inúnibíni mi, àwọn ìjìyà mi, irú àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní Áńtíókù, ní Íkóníónì, ní Lísírà, irú àwọn inúnibíni tí mo ti mú mọ́ra.” Tímótì bá Pọ́ọ̀lù sọkún pọ̀, ó bá a gbàdúrà pọ̀, ó sì tún sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ láti gbé ire Ìjọba náà lárugẹ.—2 Tímótì 1:3, 4; 3:10, 11.
Pọ́ọ̀lù gba Tímótì nímọ̀ràn láti ‘má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fojú tẹ́ńbẹ́lú èwe rẹ̀ láé.’ Èyí lè fi hàn pé Tímótì jẹ́ onítìjú ẹ̀dá, tí kì í fẹ́ fi bí ọlá àṣẹ òun ṣe tó hàn. (1 Tímótì 4:12; 1 Kọ́ríńtì 16:10, 11) Àmọ́ ṣá o, ó lè dá ṣiṣẹ́, ọkàn Pọ́ọ̀lù sì balẹ̀ láti rán an lọ ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì. (1 Tẹsalóníkà 3:1, 2) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí i pé ìjọ tó wà ní Éfésù nílò àbójútó ìṣàkóso Ọlọ́run lójú méjèèjì, ó rọ Tímótì kí ó dúró níbẹ̀ láti “pàṣẹ fún àwọn kan láti má ṣe fi ẹ̀kọ́ tí ó yàtọ̀ kọ́ni.” (1 Tímótì 1:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ la fi síkàáwọ́ Tímótì, síbẹ̀ kò kọjá àyè ẹ̀. Bó sì tilẹ̀ jẹ́ pé onítìjú ẹ̀dá ni tẹ́lẹ̀, kò bẹ̀rù rárá. Fún àpẹẹrẹ, ó lọ sí Róòmù láti ṣèrànwọ́ fún Pọ́ọ̀lù, ẹni tó ń jẹ́jọ́ lọ́wọ́ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ní ti gidi, Tímótì fúnra rẹ̀ ṣẹ̀wọ̀n ní àkókò kan, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ lórí ẹ̀sùn kan náà.—Hébérù 13:23.
Láìsí àní-àní, Tímótì kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ lára Pọ́ọ̀lù. Òtítọ́ náà pé àpọ́sítélì yìí kọ ìwé onímìísí àtọ̀runwá méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a rí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sí alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ yìí fi bí ó ṣe kà á sí tó hàn. Ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí i pé ikú òun gẹ́gẹ́ bí ajẹ́rìíkú ti sún mọ́lé, ó tún ránṣẹ́ pe Tímótì lẹ́ẹ̀kan sí i. (2 Tímótì 4:6, 9) Bóyá Tímótì rọ́nà láti rí Pọ́ọ̀lù kí wọ́n tó pa àpọ́sítélì náà bóyá kò rí i, Ìwé Mímọ́ ò sọ.
Yọ̀ǹda Ara Rẹ!
Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ rere Tímótì. Ó jàǹfààní gan-an nínú bíbá Pọ́ọ̀lù kẹ́gbẹ́, ó ti ọ̀dọ́mọdé onítìjú dàgbà di alábòójútó. Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin lè jèrè púpọ̀ nínú irú ìbákẹ́gbẹ́ kan náà lónìí. Bí wọ́n bá sì fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe góńgó wọn, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó buyì kúnni wà tí wọ́n lè ṣe. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Wọ́n lè di aṣáájú ọ̀nà, tàbí oníwàásù alákòókò kíkún, nínú ìjọ tiwọn, tàbí kí wọ́n lọ sìn ní ibi tí àìní fún àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà ti pọ̀. Lára ọ̀pọ̀ àǹfààní tó tún ṣí sílẹ̀ ni iṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè mìíràn tàbí sísìn ní orílé iṣẹ́ Watch Tower Society tàbí ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Dájúdájú, gbogbo Kristẹni ló lè fi ẹ̀mí kan náà bíi ti Tímótì hàn, nípa fífi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Jèhófà.
Ṣé ó wu ìwọ náà láti máa dàgbà nípa tẹ̀mí, kí o wúlò fún ètò àjọ Jèhófà ní apá èyíkéyìí tó bá rí i pé ó tọ́ sí ọ? Ṣe bíi ti Tímótì nígbà náà. Yọ̀ǹda ara rẹ dé ibi tó bá lè ṣeé ṣe dé. Ta ló mọ àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó lè ṣí sílẹ̀ fún ọ lọ́jọ́ iwájú?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tún mẹ́nu kan Tímótì nínú mẹ́rin lára àwọn lẹ́tà mìíràn tí Pọ́ọ̀lù kọ.—Róòmù 16:21; 2 Kọ́ríńtì 1:1; 1 Tẹsalóníkà 1:1; 2 Tẹsalóníkà 1:1.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
“Èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀”