Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
16 Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù dé Déébè, ó sì dé Lísírà.+ Ọmọ ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀ tó ń jẹ́ Tímótì,+ ọmọkùnrin obìnrin Júù kan tó jẹ́ onígbàgbọ́, àmọ́ Gíríìkì ni bàbá rẹ̀, 2 àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì sì ròyìn rẹ̀ dáadáa. 3 Pọ́ọ̀lù sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ pé kí Tímótì tẹ̀ lé òun, ó mú un, ó sì dádọ̀dọ́ rẹ̀* nítorí àwọn Júù tó wà ní agbègbè yẹn,+ torí gbogbo wọn mọ̀ pé Gíríìkì ni bàbá rẹ̀. 4 Bí wọ́n ṣe ń rin ìrìn àjò gba àwọn ìlú náà kọjá, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ti pinnu lé lórí jíṣẹ́ fún wọn kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́.+ 5 Ní tòótọ́, àwọn ìjọ túbọ̀ ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́.
6 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n rìnrìn àjò gba Fíríjíà àti ilẹ̀ Gálátíà+ kọjá, torí pé ẹ̀mí mímọ́ ò fàyè gbà wọ́n láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ìpínlẹ̀ Éṣíà. 7 Síwájú sí i, nígbà tí wọ́n dé Máísíà, wọ́n sapá láti lọ sí Bítíníà,+ àmọ́ ẹ̀mí Jésù kò gbà wọ́n láyè. 8 Torí náà, wọ́n gba* Máísíà kọjá, wọ́n sì wá sí Tíróásì. 9 Ní òru, Pọ́ọ̀lù rí ìran kan, ọkùnrin ará Makedóníà kan dúró, ó sì ń rọ̀ ọ́ pé: “Sọdá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” 10 Gbàrà tí ó ti rí ìran náà, a múra láti lọ sí Makedóníà, torí a gbà pé Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wa láti kéde ìhìn rere fún wọn.
11 Torí náà, a wọkọ̀ òkun láti Tíróásì, a sì lọ tààrà sí Sámótírásì, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, a lọ sí Neapólísì; 12 láti ibẹ̀, a lọ sí ìlú Fílípì,+ ìlú tí wọ́n ń ṣàkóso rẹ̀ láti òkèèrè, tó jẹ́ olú ìlú ní agbègbè Makedóníà. A sì lo ọjọ́ díẹ̀ ní ìlú yìí. 13 Ní ọjọ́ Sábáàtì, a lọ sẹ́yìn ẹnubodè létí odò kan, níbi tí a rò pé àwọn èèyàn ti ń gbàdúrà, a jókòó, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn obìnrin tí wọ́n pé jọ sọ̀rọ̀. 14 Obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà, tó ń ta aṣọ aláwọ̀ pọ́pù, tó wá láti ìlú Tíátírà,+ tó sì jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run, ń fetí sílẹ̀, Jèhófà* sì ṣí ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ láti fiyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ. 15 Nígbà tí òun àti agbo ilé rẹ̀ ti ṣèrìbọmi,+ ó rọ̀ wá pé: “Tí ẹ bá kà mí sí olóòótọ́ sí Jèhófà,* ẹ wá sí ilé mi kí ẹ sì dúró níbẹ̀.” Ó rí i dájú pé a wá.
16 Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí à ń lọ síbi àdúrà, ìránṣẹ́bìnrin kan tó ní ẹ̀mí kan, ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́,+ pàdé wa. Ó máa ń fi iṣẹ́ wíwò* mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀. 17 Ọmọbìnrin yìí ń tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti àwa náà, ó sì ń ké jáde pé: “Ẹrú Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ ni àwọn ọkùnrin yìí,+ wọ́n sì ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yín.” 18 Ó ṣe èyí fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Níkẹyìn, ó sú Pọ́ọ̀lù, ó yíjú pa dà, ó sì sọ fún ẹ̀mí náà pé: “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jésù Kristi pé kí o jáde nínú rẹ̀.” Ó sì jáde ní wákàtí yẹn gan-an.+
19 Tóò, nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ rí i pé ọ̀nà ìjẹ wọn ti dí,+ wọ́n gbá Pọ́ọ̀lù àti Sílà mú, wọ́n sì wọ́ wọn lọ sí ibi ọjà lọ́dọ̀ àwọn alákòóso.+ 20 Wọ́n mú wọn dé ọ̀dọ̀ àwọn adájọ́ kéékèèké, wọ́n sọ pé: “Àwọn ọkùnrin yìí ń yọ ìlú wa lẹ́nu gan-an ni.+ Júù ni wọ́n, 21 wọ́n sì ń kéde àwọn àṣà tí kò bófin mu fún wa láti tẹ́wọ́ gbà tàbí láti máa tẹ̀ lé, bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ará Róòmù ni wá.” 22 Àwọn èrò tó wà níbẹ̀ dìde sí wọn lẹ́ẹ̀kan náà, lẹ́yìn tí àwọn adájọ́ kéékèèké sì ti ya aṣọ kúrò lára wọn, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n fi ọ̀pá nà wọ́n.+ 23 Lẹ́yìn tí wọ́n ti lù wọ́n nílùkulù, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì pa àṣẹ pé kí ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n máa ṣọ́ wọn lójú méjèèjì.+ 24 Torí pé irú àṣẹ yẹn ni wọ́n pa fún un, ó jù wọ́n sí ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún, ó sì de ẹsẹ̀ wọn mọ́ inú àbà.
25 Àmọ́ láàárín òru, Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń gbàdúrà, wọ́n ń fi orin yin Ọlọ́run,+ àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì ń fetí sí wọn. 26 Lójijì, ìmìtìtì ilẹ̀ ńlá ṣẹlẹ̀, débi pé àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀wọ̀n mì tìtì. Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo ilẹ̀kùn ṣí sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀, ìdè gbogbo àwọn tí wọ́n dè sì tú.+ 27 Nígbà tí ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n jí, tó sì rí i pé àwọn ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n ṣí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó rò pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sá lọ.+ 28 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù kígbe sókè pé: “Má ṣe ara rẹ léṣe o, gbogbo wa wà níbí!” 29 Torí náà, ó ní kí wọ́n gbé iná wá, ó sì bẹ́ wọlé, jìnnìjìnnì ti bò ó, ló bá wólẹ̀ níwájú Pọ́ọ̀lù àti Sílà. 30 Ó mú wọn jáde, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ọ̀gá, kí ni kí n ṣe kí n lè rí ìgbàlà?” 31 Wọ́n sọ pé: “Gba Jésù Olúwa gbọ́, wàá sì rí ìgbàlà, ìwọ àti agbo ilé rẹ.”+ 32 Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà* fún òun àti gbogbo àwọn tó wà nílé rẹ̀. 33 Ó mú wọn lọ ní òru yẹn, ó sì wẹ ojú ọgbẹ́ wọn. Lẹ́yìn náà, òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ ṣèrìbọmi láìjáfara.+ 34 Ó mú wọn wá sínú ilé rẹ̀, ó tẹ́ tábìlì síwájú wọn, inú òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ sì ń dùn gidigidi ní báyìí tí wọ́n ti gba Ọlọ́run gbọ́.
35 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn adájọ́ kéékèèké rán àwọn akọ́dà lọ láti sọ pé: “Tú àwọn ọkùnrin yẹn sílẹ̀.” 36 Ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ròyìn ohun tí wọ́n sọ fún Pọ́ọ̀lù, pé: “Àwọn adájọ́ kéékèèké ti rán àwọn èèyàn wá pé kí á tú ẹ̀yin méjèèjì sílẹ̀. Torí náà, ẹ jáde ní báyìí, kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.” 37 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Wọ́n nà wá lẹ́gba ní gbangba láìdá wa lẹ́bi,* bó tiẹ̀ jẹ́ pé ará Róòmù ni wá,+ wọ́n jù wá sẹ́wọ̀n. Ṣé wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde ní bòókẹ́lẹ́ ni? Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá mú wa jáde.” 38 Àwọn akọ́dà ròyìn ohun tí wọ́n sọ fún àwọn adájọ́ kéékèèké. Ẹ̀rù bà wọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Róòmù+ ni àwọn ọkùnrin náà. 39 Torí náà, wọ́n wá, wọ́n bẹ̀ wọ́n, lẹ́yìn tí wọ́n sì mú wọn jáde, wọ́n rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kúrò ní ìlú náà. 40 Àmọ́ wọ́n jáde kúrò ní ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì lọ sí ilé Lìdíà; nígbà tí wọ́n rí àwọn ará, wọ́n fún wọn ní ìṣírí,+ wọ́n sì lọ.