O Lè Fara Dà á Dé Òpin
“Ẹ jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.”—HÉBÉRÙ 12:1.
1, 2. Kí ló túmọ̀ sí láti fara dà?
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù pé: “Ẹ nílò ìfaradà.” (Hébérù 10:36) Kí a lè mọ bí ànímọ́ yìí ti ṣe pàtàkì tó, àpọ́sítélì Pétérù pẹ̀lú tún rọ àwọn Kristẹni pé: ‘Ẹ fi ìfaradà kún ìgbàgbọ́ yín.’ (2 Pétérù 1:5, 6) Àmọ́, kí ni ìfaradà gan-an?
2 Ìwé atúmọ̀ èdè Gíríìkì sí Gẹ̀ẹ́sì kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì fún “fara dà” sí “kí èèyàn dúró, dípò tí yóò fi sá . . . mímú ìdúró ẹni, dídúró láìyẹsẹ̀.” Nípa ọ̀rọ̀ orúkọ tí Gíríìkì ní fún “ìfaradà,” ìwé kan táa ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Ó jẹ́ ẹ̀mí tó lè fàyà rán nǹkan, kì í ṣe èyí tó ń juwọ́ sílẹ̀, bí kò ṣe èyí tí ìrètí rẹ̀ gbóná janjan . . . Ó jẹ́ ànímọ́ kan tó jẹ́ pé, bí ìṣòro bá dé, bó ti wù kó le tó, onítọ̀hún ò ní bọ́hùn, yóò dúró gbọn-in gbọn-in. Ó jẹ́ ànímọ́ rere tó jẹ́ pé lójú àdánwò lílekoko jù lọ pàápàá, onítọ̀hún yóò lẹ́mìí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa, nítorí tó gbà pé bó ti wù kí nǹkan le tó, ó ń bọ̀ wá dẹ̀.” Nítorí náà, ìfaradà máa ń mú kí ẹnì kan lè dúró gbọn-in nígbà tó bá dojú kọ ìṣòro àti wàhálà, kò sì ní jẹ́ kó sọ ìrètí nù. Àwọn wo gan-an ló nílò ànímọ́ yìí jù?
3, 4. (a) Àwọn wo ló nílò ìfaradà? (b) Èé ṣe tó fi yẹ ká fara dà á dé òpin?
3 Lọ́nà àfiwé, gbogbo Kristẹni ló ń sáré ìje tó gba ìfaradà. Ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìdánilójú wọ̀nyí sí Tímótì, tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀, tó sì tún jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.” (2 Tímótì 4:7) Pẹ̀lú bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí,” ó ń fi ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni wé eré ìje kan tó ní ìbẹ̀rẹ̀, tó sì tún ní ibi tí yóò parí sí. Ní àkókò yẹn, Pọ́ọ̀lù ti ń fi tayọ̀tayọ̀ sún mọ́ òpin eré ìje náà, ó sì ń fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọ̀nà fún rírí ẹ̀bùn náà gbà. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ ní wíwí pé: “Láti àkókò yìí lọ, a ti fi adé òdodo pa mọ́ dè mí, èyí tí Olúwa, onídàájọ́ òdodo, yóò fi san mí lẹ́san ní ọjọ́ yẹn.” (2 Tímótì 4:8) Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé òun ó rí ẹ̀bùn náà gbà nítorí pé ó ti fara dà á dé òpin. Àwa tó kù náà ńkọ́?
4 Kí Pọ́ọ̀lù lè gba àwọn tó ti bẹ̀rẹ̀ eré ìje náà níyànjú, ó kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.” (Hébérù 12:1) Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ìgbà tí a ti yara wa sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi la ti bẹ̀rẹ̀ eré ìje onífaradà yìí. Ó ṣe pàtàkì láti bẹ̀rẹ̀ eré ìje jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn lọ́nà tó dára, ṣùgbọ́n ohun tó ṣe kókó jù lọ ni pé kí a bá a dé òpin. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:13) Ìyè àìnípẹ̀kun mà ni ẹ̀bùn tó ń dúró de àwọn tó bá sá eré ìje náà dópin! Níwọ̀n bí àwa pẹ̀lú ti ní góńgó kan lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ fara dà á dé òpin. Kí ló lè jẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ góńgó yẹn?
Oúnjẹ Yíyẹ Pọndandan
5, 6. (a) Kí la gbọ́dọ̀ fún láfiyèsí tí a bá fẹ́ fara dà á nínú eré ìje ìyè? (b) Àwọn ìpèsè tẹ̀mí wo la gbọ́dọ̀ fi ara wa fún, èé sì ti ṣe?
5 Nítòsí ìlú Kọ́ríńtì, ní ilẹ̀ Gíríìsì, ni ibi tí wọ́n ti máa ń ṣe Eré Ìdárayá Isthmus tí a mọ̀ bí ẹní mowó wà láyé ọjọ́un. Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé eré ìdárayá àti àwọn ìdíje mìíràn tó ń wáyé níbi táà ń wí yìí kò ṣàjèjì sáwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì. Kí ó lè fa ọ̀rọ̀ yọ nínú ìmọ̀ tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀, ó rán wọn létí eré ìje ìyè tí wọ́n ń sá, ó wí pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé gbogbo àwọn sárésáré nínú eré ìje ní ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ní ń gba ẹ̀bùn náà? Ẹ sáré ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ yín lè tẹ̀ ẹ́.” Pọ́ọ̀lù tún tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì sísá eré ìje náà nìṣó àti fíforí tì í títí dé òpin. Àmọ́, kí ló máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ó fi kún un pé: “Olúkúlùkù ènìyàn tí ń kó ipa nínú ìdíje a máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo.” Dájúdájú, àwọn tó ń kópa nínú ìdíje eré ìdárayá ìgbàanì máa ń fi ara wọn fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó lágbára, wọ́n máa ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ gan-an, wọ́n tún máa ń ṣọ́ nǹkan mu pẹ̀lú, wọ́n sì máa ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe kí wọ́n ṣáà lè borí.—1 Kọ́ríńtì 9:24, 25.
6 Eré ìje táwa Kristẹni wà nínú rẹ̀ ńkọ́? Alàgbà kan nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “O gbọ́dọ̀ rí i pé ò ń jẹ oúnjẹ tí ń fúnni lókun tẹ̀mí dáadáa tóo bá fẹ́ fara dà á nínú eré ìje ìyè náà.” Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà, “Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà,” ti pèsè fún wa. (Róòmù 15:5) Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, ni olórí orísun oúnjẹ amáralókun nípa tẹ̀mí náà. Ǹjẹ́ kò yẹ kí a ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó mọ́yán lórí fún kíka Bíbélì? Jèhófà tún ti tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” pèsè àwọn ìwé àtìgbàdégbà bí Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí a gbé ka Bíbélì. (Mátíù 24:45) Fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ àwọn wọ̀nyí yóò fún wa lókun nípa tẹ̀mí. Bẹ́ẹ̀ ni, a gbọ́dọ̀ lo àkókò—‘kí a ra àkókò tí ó rọgbọ padà’—fún ìdákẹ́kọ̀ọ́.—Éfésù 5:16.
7. (a) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí wíwulẹ̀ lóye ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni nìkan tẹ́ wa lọ́rùn? (b) Báwo la ṣe lè “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú”?
7 Láti máa sá eré ìje jíjẹ́ Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn nìṣó, a gbọ́dọ̀ kúrò lórí “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́,” kí a “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Hébérù 6:1) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ sí “ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́, kí a sì gba okun láti inú “oúnjẹ líle [tí ó] jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú.” (Éfésù 3:18; Hébérù 5:12-14) Fún àpẹẹrẹ, wo àwọn àkọsílẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó ṣeé fọkàn tẹ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé—ìyẹn àwọn ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù, àti Jòhánù. Báa bá ṣàyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere wọ̀nyí fínnífínní, kì í ṣe àwọn ohun tí Jésù ṣe àti irú ẹni tó jẹ́ nìkan la ó mọ̀, a ó tún mọ ọ̀nà tó gbà ń ronú, èyí tó sún un láti ṣe àwọn nǹkan tó ṣe. Ìgbà náà la lè wá “ní èrò inú ti Kristi.”—1 Kọ́ríńtì 2:16.
8. Báwo ní àwọn ìpàdé Kristẹni ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á nínú eré ìje ìyè?
8 Pọ́ọ̀lù ṣí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ létí pé: “Ẹ jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Ẹ wo bí ìpàdé Kristẹni ṣe jẹ́ orísun ìṣírí tó! Ẹ sì tún wo bó ṣe ń tuni lára tó láti wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, tí wọ́n sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á dé òpin! Táa bá lọ fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ń fún wa yìí, ara wa là ń ṣe. Nípa fífi aápọn dá kẹ́kọ̀ọ́, tí a sì ń wá sí ìpàdé déédéé, a ó lè “di géńdé nínú agbára òye.”—1 Kọ́ríńtì 14:20.
Àwọn Òǹwòran Tí Ń Ṣe Kóríyá fún Ọ
9, 10. (a) Báwo ni àwọn òǹwòran ṣe lè fúnni níṣìírí nínú eré ìje kan tó gba ìfaradà? (b) Kí ni ‘àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí púpọ̀ tó yí wa ká’ tí a mẹ́nu kan nínú Hébérù 12:1?
9 Àmọ́ ṣá o, bó ti wù kí sárésáré kan ti múra sílẹ̀ tó, ìkọ́ lè kọ́ ọ lẹ́sẹ̀, kó sì fẹ́ẹ́ ṣubú. Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ẹ̀yin ti ń sáré dáadáa tẹ́lẹ̀. Ta ní dí yín lọ́wọ́ nínú bíbá a nìṣó ní ṣíṣègbọràn sí òtítọ́?” (Gálátíà 5:7) Táa bá wò ó dáadáa, ó dájú pé àwọn Kristẹni kan ní Gálátíà kẹ́gbẹ́ búburú, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọn kò lè pọkàn pọ̀ mọ́ nínú eré ìje ìyè tí wọ́n ń sá. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ìtìlẹ́yìn àti ìṣírí látọ̀dọ̀ àwọn mìíràn lè mú kí eré ìje náà rọrùn láti fara dà. Èyí ló dà bí ipa tí àwọn òǹwòran níbi eré ìdárayá kan lè ní lórí àwọn tó ń kópa. Ṣe làwọn òǹwòran tó nítara máa ń fi kún kóríyá tí wọ́n ń ṣe fún àwọn tó ń kópa nínú ìdíje, èyí ni yóò máa mórí àwọn olùdíje náà yá láti ìbẹ̀rẹ̀ títí ère yóò fi parí. Báwọn òǹwòran ti ń ṣàyẹ́sí, tí orin wọn ń ròkè lálá, tí àtẹ́wọ́ wọn ń dún wàá-wàá, ó lè fún àwọn tí ń kópa nínú ìdíje náà ní àfikún ìmóríyá tí wọ́n nílò láti bá eré ìje tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ náà dé òpin. Ní tòótọ́, àwọn òǹwòran tó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn lè ní ipa tó dára lórí àwọn tó ń kópa nínú eré ìje.
10 Àwọn wo wá ni òǹwòran nínú eré ìje tí àwọn Kristẹni ń sá? Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn olóòótọ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, tí wọ́n wà ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé, bó ṣe wà nínú orí kọkànlá ìwé Hébérù, ó kọ̀wé pé: “Nípa báyìí, nítorí tí a ní àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yí wa ká, . . . ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.” (Hébérù 12:1) Ní fífi àwọsánmà ṣàfiwé, Pọ́ọ̀lù ò lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tó ń ṣàpèjúwe àwọsánmà kan táa lè sọ pé bó ti tóbi tó àti bó ṣe rí rèé. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó lo èyí tí atúmọ̀ èdè náà, W. E. Vine, lò tó “ń fi ìṣùpọ̀ tó bojú ọ̀run hàn, èyí tó ṣú dùdù, tí a kò sì lè sọ pé bó ṣe rí rèé.” Ní kedere, ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni ògìdìgbó ńláǹlà àwọn ẹlẹ́rìí—tí wọ́n pọ̀ débi pé wọ́n dà bí ìṣùpọ̀ àwọsánmà.
11, 12. (a) Táa bá ní ká sọ ọ́ lọ́nà àpèjúwe, báwo ni àwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́, tó ti wà ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé, ṣe lè ṣe kóríyá fún wa láti lè fi ìfaradà sá eré ìje náà? (b) Báwo la ṣe lè túbọ̀ jàǹfààní kíkún sí i látọ̀dọ̀ “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” náà?
11 Ṣé àwọn olóòótọ́ ẹlẹ́rìí tó ti wà ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé lè wá jẹ́ òǹwòran lóde òní ni? Àgbẹdọ̀. Gbogbo wọn ló ń sùn nínú ikú báyìí tí wọ́n ń retí àjíǹde. Àmọ́, àwọn fúnra wọ́n kẹ́sẹ járí nínú eré tí wọ́n sá nígbà tí wọ́n wà láàyè, àpẹẹrẹ wọn tó sì wà nínú Bíbélì kò lè parẹ́ láé. Bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí lè máa wá sí wa lọ́kàn, kí wọ́n sì máa fún wa níṣìírí láti bá eré ìje náà dé òpin.—Róòmù 15:4.a
12 Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn àǹfààní kan tó jẹ́ ti ayé bá fẹ́ fà wá lọ, ǹjẹ́ ṣíṣe àgbéyẹ̀wò bí Mósè ṣe kọ àwọn ògo ilẹ̀ Íjíbítì kò ní sún wa láti máa sá eré ìje náà nìṣó? Bí àdánwò kan tó dojú kọ wá bá dà bí èyí tó fẹ́ le jù, ó dájú pe rírántí ìdánwò líle tí Ábúráhámù dojú kọ nígbà tí Ọlọ́run sọ pé kí ó fi ọmọ rẹ̀ Ísákì rúbọ yóò fún wa níṣìírí láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nínú ìdíje ìgbàgbọ́ náà. Báa bá ṣe fi ojú inú wa rí ‘àwọsánmà tí ó pọ̀,’ ìyẹn àwọn ẹlẹ́rìí wọ̀nyí, dáadáa tó ni yóò pinnu bí wọ́n ṣe lè ṣe kóríyá fún wa tó nínú eré ìje yìí.
13. Ọ̀nà wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà lóde òní ṣe ń ṣe kóríyá fún wa nínú eré ìje ìyè náà?
13 A tún ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà tó yí wa ká lóde òní. Ẹ wo àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ ńlá tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti fi lélẹ̀ fún wa, títí kan àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá”! (Ìṣípayá 7:9) A lè rí ìtàn nípa ìgbésí ayé wọn kà nínú ìwé ìròyìn yìí àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tó jẹ́ ti Watch Tower Society.b Bí a ṣe ń ronú nípa ìgbàgbọ́ wọn, ó ń fún wa níṣìírí láti fara dà á dé òpin. Ẹ sì tún wo bó ṣe dára tó láti rí ìtìlẹ́yìn àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ àti àwọn ìbátan tó jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ń fi tòótọ́tòótọ́ sin Jèhófà! Dájúdájú, a ní ọ̀pọ̀ ènìyàn tó lè ṣe kóríyá fún wa nínú eré ìje ìyè náà.
Máa Fọgbọ́n Gbé Ìṣísẹ̀ Rẹ
14, 15. (a) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti fọgbọ́n gbé ìṣísẹ̀ wa? (b) Èé ṣe tí a fi gbọ́dọ̀ fi òye gbé àwọn góńgó wa kalẹ̀?
14 Nígbà tí sárésáré kan bá ń kópa nínú eré onígbà pípẹ́, bí eré ẹlẹ́mìí ẹṣin, ó gbọ́dọ̀ fọgbọ́n gbé ìṣísẹ̀ ara rẹ̀. Ìwé ìròyìn New York Runner sọ pé: “Bí o bá fi eré àsápajúdé bẹ̀rẹ̀, a jẹ́ pé o kò ní sá eré náà dópin nìyẹn. Ohun tó ṣeé ṣe kó yọrí sí ni pé kóo tirakatiraka láti lè fagídí parí àwọn ibùsọ̀ tó kù tàbí kí o má lè sá eré ìje náà dópin.” Ọkùnrin kan tó jẹ́ eléré ẹlẹ́mìí ẹṣin rántí pé: “Olùbánisọ̀rọ̀ tó wà níbi tí mo ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí a ń múra sílẹ̀ fún eré ìje náà sọ ní kedere pé: ‘Má ṣe gbìyànjú láti sáré bá àwọn tí ẹsẹ̀ wọ́n yá ju tìẹ. Sáré tìẹ bí agbára ẹ bá ṣe mọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kíá ló máa rẹ̀ ọ́, tí oò sì ní lè parí eré náà.’ Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ràn mí lọ́wọ́ láti parí eré náà.”
15 Nínú eré ìje ìyè, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ tiraka tokuntokun. (Lúùkù 13:24) Àmọ́ ṣá o, ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè . . . ń fòye báni lò.” (Jákọ́bù 3:17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpẹẹrẹ rere àwọn ẹlòmíràn lè fún wa níṣìírí láti túbọ̀ fi kún ìsapá wa, ìfòyemọ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbé àwọn góńgó tí a lè lé bá kalẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ibi tí agbára wá mọ àti irú ipò tí a wà. Ìwé Mímọ́ rán wa létí pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn. Nítorí olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.”—Gálátíà 6:4, 5.
16. Báwo ni jíjẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìṣísẹ̀ wa?
16 Nínú Míkà 6:8, a béèrè ìbéèrè amúnironú-jinlẹ̀ yìí lọ́wọ́ wa pé: “Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé . . . kí o jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?” Ara ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ni mímọ ibi tí agbára wa mọ. Ṣé àìsàn tàbí ara tó ń dara àgbà ti dín ohun ti a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kù? Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Jèhófà ń tẹ́wọ́ gba àwọn ìsapá wa àti àwọn ẹbọ tí a ń rú ‘ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kò ní.’—2 Kọ́ríńtì 8:12; fi wé Lúùkù 21:1-4.
Tẹjú Mọ́ Èrè Náà
17, 18. Kí ló wà lórí ẹ̀mí Jésù tó ràn án lọ́wọ́ láti fara da òpó igi oró?
17 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ bí fífara dà á nínú eré ìje ìyè ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì, ó tún mẹ́nu kan apá mìíràn tó yẹ kí wọ́n fún láfiyèsí nínú Eré Ìdárayá Isthmus. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn tó ń kópa nínú ìdíje náà pé: “Wàyí o, dájúdájú, wọ́n ń [sáré] kí wọ́n lè gba adé tí ó lè díbàjẹ́, ṣùgbọ́n àwa kí a lè gba èyí tí kò lè díbàjẹ́. Nítorí náà, bí mo ti ń sáré kì í ṣe láìní ìdánilójú; bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 9:25, 26) Láyé ọjọ́un, adé, tàbí ẹ̀gbà ọrùn, táa fi ewé igi ahóyaya tàbí òdòdó mìíràn ṣe, la máa ń fún àwọn tó bá borí nínú ìdíje, nígbà mí-ìn wọ́n tilẹ̀ lè fi ewé celery tó ti gbẹ pàápàá ṣe é—ká má tanra wa jẹ, “adé tí ó lè díbàjẹ́,” ni wọ́n ń gbà. Kí ló wá ń dúró de àwọn Kristẹni tó bá fara dà á dé òpin?
18 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí Jésù Kristi, tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa, ó kọ̀wé pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” (Hébérù 12:2) Títí dé òpin ìwàláàyè Jésù gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, ó fara dà á nípa wíwo èrè tó wà fún òun lẹ́yìn fífara da òpó igi oró náà, lára rẹ ni ayọ̀ tó ní nínú kíkópa nínú sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, èyí tó ní nínú rírà tí ó ra ìdílé ènìyàn padà lọ́wọ́ ikú, àti èyí tó ní, bó ṣe ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Àlùfáà Àgbà àti èyí tí yóò ní nígbà tó bá ń mú àwọn onígbọràn ènìyàn padà bọ̀ sínú ìyè tí kò lópin nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 6:9, 10; 20:28; Hébérù 7:23-26.
19. Kí ló gbọ́dọ̀ wà lórí ẹ̀mí wa bí a ṣe ń sáré ìje jíjẹ́ Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn nìṣó?
19 Ìwọ náà ronú nípa ayọ̀ tí a gbé ka iwájú wa bí a ti ń sá eré ìje jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi nìṣó. Jèhófà ti fún wa ní iṣẹ́ tó ń fọkàn ẹni balẹ̀ gan-an, ìyẹn ni iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti gbígbin ìmọ̀ Bíbélì tí ń gba ẹ̀mí là sínú àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 28:19, 20) Ó mà máa ń múnú ẹni dùn o, láti rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí Ọlọ́run òtítọ́ náà, táa sì wá ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti wọ inú eré ìje ìyè! Ẹ̀mí yòówù tí àwọn tí à ń wàásù fún lè fi hàn, àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti kópa nínú iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. Nígbà táa bá fara dà á nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láìka ìwà ìdágunlá tàbí àtakò àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ tí a ti ń wàásù sí, inú wá ń dùn pé à ń mú ọkàn-àyà Jèhófà yọ̀. (Òwe 27:11) Ẹ̀bùn ńlá tó sì ṣèlérí pé òun yóò fún wa ni ìyè àìnípẹ̀kun. Ayọ̀ ńlá nìyẹn á mà jẹ́ o! O yẹ kí a jẹ́ kí ìbùkún yìí wà lórí ẹ̀mí wa, kí a sì tẹra mọ́ eré ìje náà.
Bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé
20. Báwo ni eré ìje ìyè ṣe lè túbọ̀ ṣòro sí i bí òpin ti ń sún mọ́lé?
20 Nínú eré ìje ìyè, a ní láti wọ̀yá ìjà pẹ̀lú olórí ọ̀tá wa nì, Sátánì Èṣù. Bí a tí ń sún mọ́ òpin, bẹ́ẹ̀ ló ń gbìyànjú láìsinmi rárá láti rí i pé ìkọ́ kọ́ wa lẹ́sẹ̀ tàbí láti káàárẹ̀ bá wa, ká má lè sáré dáadáa mọ́. (Ìṣípayá 12:12, 17) Táa bá sì ní ká fojú ogun tó ń jà lọ́wọ́, ìyàn tó mú, àjàkálẹ̀ àrùn tó wà, àti àwọn wàhálà mìíràn tó ń fi àmì “àkókò òpin” hàn wò ó, kò rọrùn rárá láti máa bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́, olúpòkìkí Ìjọba náà, tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́. (Dáníẹ́lì 12:4; Mátíù 24:3-14; Lúùkù 21:11; 2 Tímótì 3:1-5) Láfikún sí i, nígbà mí-ìn ó lè dà bí ẹni pé òpin náà ń pẹ́ ju báa ti retí lọ, pàápàá jù lọ tó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún sẹ́yìn la ti ń sáré náà bọ̀. Síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé òpin náà yóò dé. Jèhófà sọ pé kì yóò pẹ́. Òpin náà ti dé tán.—Hábákúkù 2:3; 2 Pétérù 3:9, 10.
21. (a) Kí ni yóò fún wa lókun bí a ti ń bá eré ìje ìyè náà nìṣó? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa bí òpin ti ń sún mọ́lé?
21 Báa bá wá fẹ́ kẹ́sẹ járí nínú eré ìje ìyè, nígbà náà, a gbọ́dọ̀ máa gba okun láti inú ohun tí Jèhófà ti fìfẹ́ pèsè láti lè fún wa lókun nípa tẹ̀mí. A tún nílò gbogbo ìṣírí tí a lè rí gba nínú dídara pọ̀ mọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, tó jẹ́ pé àwọn pàápàá ń sá eré ìje náà. Kódà bi inúnibíni líle koko àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò retí tí a ń bá pàdé lẹ́nu eré ìje náà bá mú kó túbọ̀ ṣòro sí i, a lè fara dà á dé òpin nítorí pé Jèhófà ń fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ẹ wo bó ṣe túbọ̀ fini lọ́kàn balẹ̀ tó pé Jèhófà fẹ́ ká fi tayọ̀tayọ̀ sá eré ìje náà parí! Pẹ̀lú ìpinnu tí kò lè yẹ̀, “ẹ jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa,” kí a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé “ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—Hébérù 12:1; Gálátíà 6:9.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìjíròrò lórí Hébérù 11:1–12:3, wo Ilé-ìṣọ́nà January 15, 1987, ojú ìwé 10 sí 20.
b Àpẹẹrẹ díẹ̀ tó jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí nípa irú àwọn ìrírí afúnniníṣìírí bẹ́ẹ̀ la lè rí nínú Ilé Ìṣọ́ ti June 1, 1998, ojú ìwé 28 sí 31; September 1, 1998, ojú ìwé 24 sí 28; February 1, 1999, ojú ìwé 25 sí 29.
Ǹjẹ́ O Rántí?
◻ Èé ṣe tó fi yẹ ká fara dà á dé òpin?
◻ Kí ni àwọn ìpèsè Jèhófà tí a kò gbọ́dọ̀ fojú kéré?
◻ Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti fọgbọ́n gbé ìṣísẹ̀ wa?
◻ Ayọ̀ wo ni a gbé ka ìwájú wa, bí a ti ń sáré ìje náà nìṣó?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Gba ìṣírí láti inú àwọn ìpàdé Kristẹni