Ẹyin Èwe—Ki Ni Ẹyin Ń Lépa?
“Maa sá fun ifẹkufẹẹ èwe: sì maa lépa òdodo, igbagbọ, ifẹ, alaafia, pẹlu awọn tí ń képe Oluwa lati inu ọkàn funfun wá.” —2 TIMOTEU 2:22.
1. Ki ni ireti wa fun awọn ọ̀dọ́ eniyan ti ń bẹ laaarin wa?
“AWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA, parapọ di awujọ ti ń jèrè iye awọn mẹmba titun ti o pọ julọ lọdọọdun ti o sì ní ogunlọgọ awọn èwe ti o pọ̀ julọ,” ni iwe awọn onisin Pentekosti ti Sweden Dagen (Ọjọ Naa) polongo. Boya iwọ jẹ́ apakan ogunlọgọ awọn èwe mimọ, olubẹru Ọlọrun yii. A ti lè tọ́ ọ dagba ni ọ̀nà Kristian lati ìgbà ọmọ-ọwọ, tabi iwọ lè ti gbọ́ ki o sì ti dahunpada si ihin-iṣẹ Ijọba naa funraarẹ. Bi o ti wu ki o ri, inu wa dùn lati ní ọ laaarin wa. Ó sì jẹ́ ireti wa pe iwọ yoo lépa ipa-ọna òdodo, gẹgẹ bi awọn èwe Kristian aduroṣinṣin ni ọrundun kìn-ín-ní ti ṣe. Awọn ọ̀rọ̀ aposteli Johannu lè ṣapejuwe rẹ daradara pe: “Nitori ti [iwọ] ni agbara, ti ọ̀rọ̀ Ọlọrun sì duro ninu [rẹ], ti [o] sì ṣẹgun ẹni buburu nì.”—1 Johannu 2:14.
2. Awọn kókó wo ni o lè mú lílépa ọ̀nà òdodo kan ṣoro nigba “itanna èwe”?
2 Ọpọlọpọ—bẹẹni ọpọ julọ—ninu awọn èwe Kristian lonii ni wọn mú iduro wọn lodisi awọn ikimọlẹ ayé. Bi o ti wu ki o ri, iwọ lè rí i pe pípa iru ipa-ọna bẹẹ mọ́ kò rọrun. Nigba ti o bá wà ni akoko “itanna ìgbà-èwe,” iwọ lè nimọlara pe awọn ero-imọlara titun ti o sì lagbara bò ọ́ mọ́lẹ̀. (1 Korinti 7:36, NW) Ni akoko kan-naa, iwọ lè maa nimọlara ẹrù-iṣẹ́ ti ń gasoke sii ni ile-ẹkọ, ni ile, ati ninu ijọ. Àní ikimọlẹ lati ọ̀dọ̀ Satani Eṣu funraarẹ tun wà. Bi o ti pinnu lati ṣi ọpọlọpọ eniyan bi o bá ti lè ṣeeṣe tó lọna, ó ń doju ìjà kọ awọn wọnni ti wọn dabi ẹni ti ó ṣee tètè sọ di ẹran-ìjẹ—gẹgẹ bi o ṣe ṣe ninu ọgbà Edeni. Nigba naa lọhun-un, ó dojú ẹ̀tàn ayíniléròpadà rẹ̀ kọ Efa, obinrin ti kò fi bẹẹ ni iriri, ti ọjọ-ori rẹ̀ kere, kìí ṣe si Adamu ti o dagba ju, ti o sì niriiri ju. (Genesisi 3:1-5) Ni ọpọ ọrundun lẹhin naa, Satani lo iru ọgbọ́n-ẹ̀tàn kan-naa lori ijọ Kristian ti o ṣẹṣẹ ń dagba ni Korinti. Aposteli Paulu sọ pe: “Ṣugbọn ẹ̀rù ń bà mi pe, ni ohunkohun, gẹgẹ bi ejo ti tan Efa jẹ nipasẹ arekereke rẹ̀, ki a maṣe mú ero-ọkan yin bajẹ kuro ninu inu kan ati iwa mimọ yin si Kristi.”—2 Korinti 11:3.
3, 4. Ki ni awọn ohun-eelo melookan ti Satani Eṣu ń lò lati ṣi awọn ọ̀dọ́ eniyan lọna, pẹlu abayọri ṣiṣeeṣe wo sì ni?
3 Lonii, awọn òbí rẹ ti wọn jẹ Kristian lè maa bẹru nipa rẹ bakan naa. Kìí ṣe pe wọn ronu pe o ní ọkàn iwa buburu, ṣugbọn wọn mọ lati inu iriri pe awọn ọ̀dọ́ eniyan ni wọn tètè lè di ẹran-ìjẹ ni pataki si “arekereke” Satani. (Efesu 6:11, akiyesi ẹsẹ-iwe) Jìnnà réré si eyi ti o farahan gẹgẹ bi alajaalu-ibi, awọn páńpẹ́ Satani ni a ń ṣe lati rí bi eyi ti o fanimọra lọna kan ṣáá, ti a sì nifẹẹ sí. Tẹlifiṣọn ń gbe ifẹ ọrọ̀-àlùmọ́nì, ibalopọ takọtabo alaibofinmu, iwa-ipa ṣiṣekedere, ati ibẹmiilo gẹgẹ bi eré-ìnàjú jade lọna ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́. Ọkàn awọn ọ̀dọ́ lè di eyi ti o kún fọfọ fun awọn nǹkan ti kìí ṣe ‘òótọ́, ọ̀wọ̀, títọ́, mímọ́, ati fífẹ́.’ (Filippi 4:8) Ikimọlẹ ojugba ni o tun jẹ́ ohun-eelo Satani miiran ti o gbéṣẹ́. Awọn ojugba rẹ lè fi ọ́ sabẹ ikimọlẹ kikankikan lati maa mú araarẹ ṣedeedee pẹlu ọ̀nà ìgbà gbé igbesi-aye, aṣọ, ati imura wọn. (1 Peteru 4:3, 4) Akọwe iwe-irohin William Brown ṣakiyesi pe: “Bi Ọlọrun eyikeyii kanṣoṣo, ti o jẹ́ ti ayé bá wà fun awọn ọdọlangba ó jẹ́ Ọlọrun ibaṣedeedee. . . . Jijẹ ẹni ti o yatọ fun awọn ògo wẹrẹ jẹ́ ohun ti o buru julọ ti o lè ṣẹlẹ si wọn.” Ọdọbinrin Ẹlẹ́rìí kan ni Italy jẹwọ pe: “Oju maa ń tì mi lati jẹ ki awọn ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ mi mọ̀ pe mo jẹ́ Ẹlẹ́rìí kan. Ati nitori ti mo mọ̀ pe inu Jehofa kò dun si mi, inu mi bajẹ mo sì sorikọ.”
4 Maṣe ṣe aṣiṣe—Satani ń fẹ́ lati sìn ọ́ lọ sinu iparun. Ọpọ awọn ọ̀dọ́ eniyan ninu ayé lọhun-un yoo jiya ipadanu iwalaaye wọn nigba ipọnju nla nitori pe wọn faaye gba ki a ṣi awọn lọna. (Esekieli 9:6) Ọ̀nà kanṣoṣo lati là á já ni lati lépa ohun ti ó tọ́.
Ṣọra fun Awọn Ẹgbẹ́ Buburu
5, 6. (a) Awọn ipenija wo ni ọdọkunrin naa Timoteu koju nigba ti o ń gbé ni Efesu? (b) Imọran wo ni Paulu ní fun Timoteu?
5 Iyẹn jẹ koko ọ̀ràn imọran ti aposteli Paulu fun ọdọkunrin naa Timoteu. Fun ohun ti o ju ọdun mẹwaa lọ, Timoteu ti bá aposteli Paulu rìn papọ nigba awọn irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun rẹ̀. Ni akoko kan nigba ti Timoteu ń ṣe iṣẹ-ojiṣẹ ninu ilu abọriṣa ti Efesu, Paulu jokoo sinu ọgba-ẹwọn Romu kan ni diduro de ifiya-iku-jẹni. Bi akoko iku rẹ̀ ti ń sunmọle, Paulu laiṣiyemeji daniyan nipa bi Timoteu yoo ṣe maa baa lọ. Efesu jẹ ilu-nla kan ti ó lokiki fun ọrọ̀, iwa-palapala, ati eré-ìnàjú rẹ̀ ti ń buniku, ti Timoteu kò sì tun ni ni itilẹhin olugbaninimọran rẹ̀ olufẹ mọ́.
6 Nitori naa Paulu kọ ohun ti o tẹle e yii si ‘ọmọ rẹ̀ olufẹ’ pe: “Ṣugbọn ninu ile ńlá, kìí ṣe kìkì ohun-eelo wura ati ti fadaka nikan ni ń bẹ nibẹ, ṣugbọn ti igi ati ti amọ̀ pẹlu; ati omiran si ọlá, ati omiran si ailọla. Bi ẹnikẹni bá wẹ araarẹ mọ́ kuro ninu iwọnyi, oun ó jẹ́ ohun-eelo si ọlá, ti a yà sí ọ̀tọ̀, ti ó sì yẹ fun ìlò baale, ti a sì ti pese silẹ si iṣẹ rere gbogbo. Maa sá fun ifẹkufẹẹ èwe: sì maa lépa òdodo, igbagbọ, ifẹ, alaafia, pẹlu awọn ti ń ké pe Oluwa lati inu ọkàn funfun wá.”—2 Timoteu 1:2; 2:20-22.
7. (a) Ki ni awọn ‘ohun-eelo ti o jẹ ti alailọla’ ti Paulu kilọ nipa rẹ̀? (b) Bawo ni awọn èwe lonii ṣe lè fi awọn ọ̀rọ̀ Paulu silo?
7 Paulu tipa bayii kilọ fun Timoteu pe laaarin awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ paapaa ‘awọn ohun-eelo alailọla’ tilẹ lè ti wà—awọn eniyan lẹnikọọkan ti wọn kò huwa lọna ti ó tọ́. Nisinsinyi bi ibakẹgbẹpọ pẹlu awọn Kristian ẹni-ami-ororo pàtó kan bá tilẹ jẹ́ eyi ti ó lè ṣepalara fun Timoteu, mélòó mélòó ni ibakẹgbẹpọ pẹlu awọn eniyan ayé yoo ṣe jẹ́ eyi tí ń sepalara fun Kristian ọ̀dọ́ kan lonii! (1 Korinti 15:33) Eyi kò tumọsi jíjẹ́ alaiwa-bi-ọrẹ si awọn ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ rẹ. Ṣugbọn o gbọdọ ṣọra lati maṣe di ẹni ti o ni ibaṣepọ pẹlu wọn ju bi o ṣe yẹ lọ, àní bi iyẹn bá tilẹ mú ki o dabi adánìkàndájẹ̀ nigba miiran. Eyi lè ṣoro gidigidi. Ọdọbinrin ọmọ Brazil kan wi pe: “Ó ṣoro. Awọn ọmọ ile-ẹkọ mi maa ń ké sí mi nigba gbogbo lati lọ si awọn ariya ati awọn ibi ti kò yẹ fun awọn ọ̀dọ́ Kristian. Wọn a maa sọ pe: ‘Kinla! Iwọ ò lọ kẹ̀? Ori rẹ ti dàrú!’”
8, 9. (a) Bawo ni ibakẹgbẹpọ, àní pẹlu awọn eniyan ayé ti wọn dabi ẹni ti o dara paapaa, ṣe lè jẹ́ ewu fun Kristian kan? (b) Nibo ni o ti lè rí awọn ọ̀rẹ́ ti o sunwọn?
8 Awọn èwe ayé kan lè dabi ẹni ti o dara kìkì nitori pe wọn kìí mu siga, lo awọn èdè ti kò dara, tabi lọwọ ninu ibalopọ takọtabo oniwa-palapala. Bi o ti wu ki o ri, bi wọn kò bá maa lepa òdodo, ironu ati iṣarasihuwa wọn nipa ti ara lè fi ìrọ̀rùn nipa lori rẹ. Yatọ si eyiini, ìfẹ́-ọkàn bíbáradọ́gba wo ni ó lè pa iwọ ati awọn alaigbagbọ pọ̀? (2 Korinti 6:14-16) Họwu, awọn iniyelori nipa tẹmi ti iwọ dimu lọna ọ̀wọ́n jẹ́ kìkì “were” si wọn! (1 Korinti 2:14) Iwọ ha lè pa ibadọrẹẹ wọn mọ laifi awọn ilana rẹ banidọrẹ bi?
9 Nitori naa yẹra fun awọn alabaakẹgbẹpọ ti kò sunwọn. Fi ibakẹgbẹpọ rẹ mọ si ọ̀dọ̀ awọn Kristian ti ohun tẹmi ń jẹ lọ́kàn ti wọn nifẹẹ Jehofa niti gidi. Ṣọra paapaa fun awọn èwe ninu ijọ ti wọn jẹ́ ọlọkan òdì tabi ti wọn ń ṣariwisi. Bi o ṣe ń dagba nipa tẹmi, iyanlaayo rẹ niti ọ̀rẹ́ ni o ṣeeṣe pe yoo yipada. Ọmọdebinrin ọdọlangba Ẹlẹ́rìí kan sọ pe: “Mo ti ń ní awọn ọ̀rẹ́ titun ni awọn ijọ yiyatọsira. Ó ti mú ki ń mọ bi awọn ọ̀rẹ́ ayé ti jẹ́ alainilaari tó.”
Sísá fun Awọn Ìfẹ́-Ọkàn ti Kò Tọ́
10, 11. (a) Ki ni ó tumọsi lati “sá fun ifẹkufẹẹ èwe”? (b) Bawo ni ẹnikan ṣe lè “sá fun agbere”?
10 Paulu tun rọ Timoteu pẹlu lati “maa sá fun ifẹkufẹẹ èwe.” Nigba ti o wà ni ọ̀dọ́, ifẹ naa lati jẹ́ ẹni ti o lokiki, lati gbadun araarẹ, tabi lati tẹ́ awọn ìfẹ́-ọkàn ibalopọ takọtabo lọ́rùn lè jẹ́ eyi ti ń fipa muni. Bi o bá fi wọn silẹ laiṣakoso, iru awọn ifasi-ọkan bẹẹ lè sìn ọ́ lọ sinu ẹṣẹ. Paulu tipa bayii sọ pe ki a sá fun awọn ìfẹ́-ọkàn ti ń panilara—lati sare bi ẹni pe igbesi-aye ẹnikan wà ninu ewu.a
11 Ìfẹ́-ọkàn onibaalopọ takọtabo, fun apẹẹrẹ, ti ṣamọna ọpọ awọn èwe Kristian sinu iparun tẹmi. Pẹlu idi rere, nigba naa, Bibeli sọ fun wa lati “sá fun agbere.” (1 Korinti 6:18) Bi awọn meji kan bá ń fẹra sọna, dajọ ijadelọ, wọn lè fi ilana yii silo nipa yiyẹra fun awọn ipo ayika ti ń danniwo—iru bii didanikan wà ninu ile adani kan tabi ibi igbọkọsi kan. Nini ẹ̀ṣọ́ kan lati maa sìn yín lọ lè dun bi ohun atijọ, ṣugbọn ó lè jẹ́ aabo gidi kan. Nigba ti awọn ìfihànjáde ìfẹ́ni kan sì lè jẹ́ eyi ti o yẹ, awọn ààlà ti o lọgbọn-ninu ni ẹ nilati gbekalẹ ki ẹ baa lè yẹra fun iwa ti kò mọ́. (1 Tessalonika 4:7) Sisa fun agbere yoo tun ní ninu pẹlu yiyẹra fun awọn sinima tabi aworan tẹlifiṣọn ti o lè ru ìfẹ́-ọkàn ti ko tọ́ soke. (Jakọbu 1:14, 15) Bi awọn èrò iwapalapala bá wọnu ọkàn rẹ lairotẹlẹ, yi ọrọ-ẹkọ naa pada kuro ninu ọpọlọ. Rìn lọ; kàwé; ṣe awọn iṣẹ ilé pẹẹpẹẹpẹ kan. Adura jẹ́ iranlọwọ alagbara pataki kan ninu ọ̀ràn yii.—Orin Dafidi 62:8.b
12. Bawo ni iwọ ṣe lè kẹkọọ lati koriira ohun ti kò dara? Ṣakawe.
12 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, o gbọdọ kẹkọọ lati koriira, ṣe họ́ọ̀ si, ki o sì kẹgan ohun ti o buru. (Orin Dafidi 97:10) Bawo ni o ṣe lè koriira ohun ti o lè dabi amuniloriya tabi igbadun lakọọkọ? Nipa rironu nipa awọn abajade rẹ̀! “Ki a má ṣe tàn yin jẹ; a kò lè gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan bá funrugbin, ohun ni yoo sì ká. Nitori ẹni ti o bá ń funrugbin sipa ti ara, nipa ti araarẹ ni yoo ká idibajẹ.” (Galatia 6:7, 8) Nigba ti a bá dán ọ wò lati juwọsilẹ fun ifẹ-ainijaanu, ronu nipa abajade ti ó ga julọ—bi eyi yoo ṣe dun Jehofa Ọlọrun. (Fiwe Orin Dafidi 78:41.) Ronu, pẹlu, nipa ṣiṣeeṣe oyún ti a kò fẹ́ tabi kíkó àrùn kan, iru bi AIDS. Ṣagbeyẹwo iparun niti ero-imọlara ati ipadanu ọ̀wọ̀ ara-ẹni ti iwọ yoo jiya rẹ̀. Awọn abajade ọlọjọ pipẹ lè wà pẹlu. Kristian obinrin kan jẹwọ pe: “Emi ati ọkọ mi ní ibalopọ takọtabo pẹlu awọn ẹlomiran ṣaaju ki a tó ri araawa. Bi o tilẹ jẹ pe a jẹ́ Kristian lonii, igbesi-aye wa nipa ti ibalopọ takọtabo jẹ́ orisun ìjà ati owú ninu igbeyawo wa.” Eyi ti kò tun yẹ lati gbojufoda, bi o ti wu ki o ri, ni ipadanu awọn anfaani iṣakoso Ọlọrun rẹ tabi ṣiṣeeṣe naa lati di ẹni ti a lé kuro ninu ijọ Kristian! (1 Korinti 5:9-13) Ǹjẹ́ igbadun onigba kukuru kan ha yẹ fun iru owó giga bẹẹ bi?
Lilepa Ipo-Ibatan Timọtimọ Pẹlu Jehofa
13, 14. (a) Eeṣe ti kò fi tó lati sá fun ohun ti kò dara? (b) Bawo ni ẹnikan ṣe lè “tẹramọ àtimọ Oluwa”?
13 Bi o ti wu ki o ri, kò tó lati sá fun ohun ti o buru. Timoteu ni a rọ̀ lati “maa lépa òdodo, igbagbọ, ifẹ, alaafia.” Iyẹn dabaa igbesẹ lilagbara. Wolii Hosea bẹ orilẹ-ede Israeli alaigbagbọ bakan naa pe: “Ẹ wá, ẹ jẹ ki a yipada si Oluwa . . . Bi a ba tẹramọ àtimọ Oluwa.” (Hosea 6:1-3) Iwọ funraarẹ ha ti ṣe iru ilepa kan bẹẹ bi? Ó ni ninu ju kìkì lilọ si awọn ipade ati kikẹgbẹpọ pẹlu awọn òbí rẹ ninu iṣẹ-isin pápá. Obinrin Kristian kan jẹwọ pe: “Awọn òbí mi tọ́ mi dagba ninu otitọ, a sì ṣe iribọmi fun mi nigba ti mo wà ni kekere. . . . Mo fẹrẹẹ ma pa ipade kan jẹ rí n kò sì pa iṣẹ-isin oṣu kan jẹ rí, ṣugbọn emi kò mú ipo-ibatan timọtimọ ti ara-ẹni kan dagba pẹlu Jehofa.”
14 Èwe miiran jẹwọ pe oun pẹlu kùnà lati mọ Jehofa gẹgẹ bi Ọ̀rẹ́ ati Baba kan, ní wíwò ó gẹgẹ bi Ẹmi àfòyemọ̀ kan. Ó ṣubú sinu iwapalapala ó sì di ìyá alaiṣegbeyawo kan ni ẹni ọdun 18. Maṣe ṣe iru aṣiṣe kan-naa! “Tẹra mọ àtimọ Oluwa,” gẹgẹ bi Hosea ti rọni. Nipa adura ati rírìn pẹlu Jehofa lojoojumọ, iwọ lè sọ ọ́ di ọ̀rẹ́ ikọkọ rẹ. (Fiwe Mika 6:8; Jeremiah 3:4.) “Kò jinna si olukuluku wa” bi a bá wá a. (Iṣe 17:27) Itolẹsẹẹsẹ ikẹkọọ Bibeli ara-ẹni deedee pọndandan nigba naa. Iru ọ̀nà igbakẹkọọ bẹẹ ni kò nilati jẹ́ eyi ti o pọ̀ rẹrẹrẹ ti o sì díjúpọ̀. “Lojoojumọ mo ń ka Bibeli fun nǹkan bi iṣẹju 15,” ni ọdọmọdebinrin ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Melody sọ. Ya akoko sọtọ lati ka itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji! kọọkan. Murasilẹ fun awọn ipade ijọ ki o baa lè “ru [awọn ẹlomiran] si ifẹ ati si iṣẹ rere.”—Heberu 10:24, 25.
Sọ Ohun ti Ń Bẹ Lọkan Rẹ fun Awọn Òbí Rẹ
15. (a) Eeṣe ti o fi maa ń ṣoro nigba miiran lati ṣegbọran si awọn òbí ẹni? (b) Eeṣe ti igbọran fi sábà maa ń jẹ́ si ire èwe kan?
15 Awọn òbí ti o bẹru Ọlọrun lè jẹ́ orisun iranlọwọ ati itilẹhin gidi. Ṣugbọn ṣakiyesi ipa ti o gbọdọ kó pe: “Ẹyin ọmọ, ẹ maa gbọ́ ti awọn òbí yin ninu Oluwa: nitori pe eyi ni ó tọ́. Bọ̀wọ̀ fun baba ati ìyá rẹ (eyi tii ṣe ofin ikinni pẹlu ileri), ki ó lè dara fun ọ, ati kí iwọ ki ó lè wà pẹ́ ni ayé.” (Efesu 6:1-3) Loootọ, iwọ ń dagba sii ó sì ṣeeṣe pe o ń fẹ́ ominira sii. Iwọ tilẹ lè maa fura si ààlà awọn òbí rẹ lọna ti ń ga sii pẹlu. “Awọn baba wa ti wọn jẹ́ eniyan,” ni aposteli Paulu jẹwọ, “lè ṣe kìkì ohun ti wọn rò pe ó dara julọ.” (Heberu 12:10, The Jerusalem Bible) Bi o tilẹ rí bẹẹ, ni opin gbogbo rẹ̀, ó ṣì jẹ́ anfaani rẹ lati ṣegbọran si wọn. Awọn òbí rẹ fẹran rẹ wọn sì mọ̀ ọ́ ju ẹnikẹni miiran lọ. Nigba ti o lè má maa gbà pẹlu wọn nigba gbogbo, wọn sábà maa ń ní ire rẹ ti o dara julọ lọkan. Eeṣe ti o fi ń yẹra fun isapa wọn lati tọ́ ọ “ninu ẹkọ ati ikilọ Oluwa”? (Efesu 6:4) Kìkì aṣiwere kan ni ó ń “gan ẹkọ baba rẹ̀.” (Owe 15:5) Èwe kan ti ó gbọ́n yoo mọ ọla-aṣẹ awọn òbí rẹ̀ ti yoo sì fi ọ̀wọ̀ ti o yẹ hàn.—Owe 1:8.
16. (a) Eeṣe ti ó fi jẹ́ ohun ti kò lọgbọn-ninu fun awọn èwe lati fi iṣoro wọn pamọ fun awọn òbí wọn? (b) Ki ni awọn èwe lè ṣe lati mú ki ijumọsọrọpọ pẹlu awọn òbí wọn sunwọn sii?
16 Iyẹn yoo ni sisọ otitọ fun awọn òbí rẹ ninu, ni jijẹ ki wọn mọ bi o bá ni awọn iṣoro, iru bi nini iyemeji nipa otitọ tabi rírì sinu iwa kan ti o yẹ fun ibawi. (Efesu 4:25) Fifi iru awọn ọ̀ràn apániláyà bẹẹ pamọ fun awọn òbí rẹ ń da iṣoro pupọ sii silẹ. (Orin Dafidi 26:4) Ki a gbà bẹẹ, awọn òbí melookan ṣe isapa ti kò tó nǹkan lati banisọrọpọ. “Mama mi kò jokoo ki o sì ni ijumọsọrọpọ pẹlu mi rí,” ni ọdọmọdebinrin kan ṣaroye. “Emi kò láyà rí lati sọ bi imọlara mi ti rí nitori pe mo ń bẹru pe yoo ṣe lámèyítọ́ mi.” Bi iwọ bá wà ninu iru ipo kan-naa, fi ọgbọn yan akoko ti o yẹ lati jẹ ki awọn òbí rẹ mọ bi imọlara rẹ ṣe rí. “Ọmọ mi, fi àyà rẹ fun mi,” ni Owe 23:26 rọni. Gbidanwo lati jiroro awọn aniyan rẹ pẹlu wọn deedee, ki awọn iṣoro wiwuwo tó gbèrú.
Maa Baa Lọ Ni Lilepa Òdodo
17, 18. Ki ni yoo ran èwe kan lọwọ lati maa baa lọ ninu ìlépa òdodo rẹ̀?
17 Ni apa ipari lẹta rẹ̀ keji, Paulu gba Timoteu niyanju pe: “Ṣugbọn iwọ duro ninu nǹkan wọnni ti iwọ ti kọ́, ti a sì ti jẹ ki oju rẹ dá ṣáṣá si.” (2 Timoteu 3:14) Iwọ gbọdọ ṣe bakan naa pẹlu. Maṣe jẹ ki ẹnikẹni tabi ohunkohun fà ọ́ lọ kuro ninu ilepa òdodo rẹ. Ayé Satani—nitori gbogbo òòfà rẹ̀—ni ó kún fọ́fọ́ fun iwa-buruku. Laipẹ oun ati gbogbo awọn ti wọn jẹ́ apakan rẹ̀ yoo jiya iparẹ raurau. (Orin Dafidi 92:7) Pinnu lati maṣe jẹ́ ẹni ti a parun pẹlu awọn ogunlọgọ Satani.
18 Pẹlu iyẹn lọkan, iwọ gbọdọ maa yẹ awọn ilepa, ìfẹ́-ọkàn, ati ifẹ rẹ wo nigba gbogbo. Beere lọwọ araarẹ, ‘Emi ha ń pa ọpa-idiwọn giga ti ọ̀rọ̀ sisọ ati iwahihu mọ́ nigba ti awọn òbí mi ati awọn mẹmba ijọ kò lè rí mi bi? Iru awọn ọ̀rẹ́ wo ni mo ń yàn? Ǹjẹ́ awọn ojugba ayé ha ń pinnu aṣọ ati imura mi bi? Awọn gongo wo ni mo ti fi lelẹ funraami? Ǹjẹ́ ọkàn mi ha nifẹẹ si iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun—tabi iṣẹ kan ninu awọn eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti Satani ti ń kú lọ yii bi?’
19, 20. (a) Eeṣe ti èwe kan kò fi nilati nimọlara idaamu nipa awọn ohun abeerefun Jehofa? (b) Awọn ipese wo ni awọn èwe lè mulo?
19 Boya o rí aini naa lati ṣe awọn atunṣebọsipo kan ninu ironu rẹ. (2 Korinti 13:11) Maṣe jẹ́ ẹni ti a dalaamu. Ranti, Jehofa kò beere ju bi o ti lọgbọn-ninu lọ lọwọ rẹ. Wolii Mika beere pe: “[Ki ni] Oluwa beere lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o sì fẹ́ aanu, ati ki o rìn ni irẹlẹ pẹlu Ọlọrun rẹ?” (Mika 6:8) Eyi kò ni ṣoro jù fun ọ lati ṣe bi o bá lo anfaani awọn ipese Jehofa lati ràn ọ́ lọwọ. Duro timọtimọ pẹlu awọn òbí rẹ. Maa darapọ mọ́ ijọ Kristian deedee. Ni pataki julọ, sapá lati mọ awọn alagba ijọ. Wọn ń daniyan nipa iwalalaafia rẹ wọn sì lè jẹ́ orisun itilẹhin ati itunu fun ọ. (Isaiah 32:2) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mú ipo-ibatan timọtimọ, ọlọ́yàyà dagba pẹlu Jehofa Ọlọrun. Oun yoo fun ọ ni agbara ati ifẹ-inu lati lépa ohun ti o tọ́!
20 Awọn èwe kan, bi o ti wu ki o ri, jin isapa wọn lati dagba nipa tẹmi lẹsẹ nipa fifetisi orin ti kò sunwọn. Ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e yoo fun koko-ẹkọ yii ni afiyesi ara-ọtọ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Griki naa fun “sá” ni a lò bakan naa ninu Matteu 2:13, nibi ti a ti sọ fun Maria ati Josẹfu lati “sá lọ si Egipti” lati jàbọ́ kuro lọwọ ìhùmọ̀ aṣekúpani ti Herodu.—Fiwe Matteu 10:23.
b Iwọ yoo rí awọn àbá rirannilọwọ melookan fun ṣiṣakoso ìfẹ́-ọkàn ibalopọ takọtabo ni ori 26 ninu iwe naa Questions Young People Ask—Answers That Work, ti a tẹjade lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Eeṣe ti awọn èwe ni pataki julọ fi jẹ́ ẹran-ì jẹ fun “arekereke” Satani?
◻ Eeṣe ti kikẹgbẹpọ timọtimọ pẹlu awọn èwe ayé fi jẹ́ eyi ti o léwu?
◻ Bawo ni o ṣe lè sá fun iwapalapala ibalopọ takọtabo?
◻ Bawo ni o ṣe lè lépa ipo-ibatan timọtimọ pẹlu Jehofa?
◻ Eeṣe ti o fi ṣe pataki lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn òbí rẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Awọn meji ti ń fẹ́ra sọna ń fi ọgbọn mọ araawọn lẹnikinni keji ninu ayika, iru bii ririn lori yinyin ti kò yà wọn sọtọ kuro lara awọn eniyan miiran