Ǹjẹ́ “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí Lóòótọ́?
OHUN méjì kan lè jẹ́ ká mọ àkókò tí Bíbélì pè ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ìwé Mímọ́ sọ àwọn ohun tí yóò máa ṣẹlẹ̀ ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3) Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa bí ìwà àti ìṣesí àwọn èèyàn yóò ṣe yí padà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”—2 Tímótì 3:1.
Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé pa pọ̀ pẹ̀lú ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn jẹ́ ẹ̀rí pé ìkẹyìn ọjọ́ la wà yìí àti pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó mú kí àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní ayọ̀ ayérayé. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé àwọn ohun mẹ́ta tí Jésù sọ pé yóò jẹ́ ẹ̀rí pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yẹ̀ wò.
“Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ìroragógó Wàhálà”
Jésù sọ pé: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.” Ó wá fi kún un pé: “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.” (Mátíù 24:7, 8) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn “nǹkan wọ̀nyí” lọ́kọ̀ọ̀kan.
Láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, àwọn ogun ńláńlá àti ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti fẹ̀mí ẹgbàágbèje èèyàn ṣòfò. Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Rí sí Àwọn Ohun Tó Ń Lọ Lágbàáyé sọ pé: “Àwọn tí ogun pa ní ọ̀rúndún ogún nìkan jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta iye àwọn tí ogun ti ń pa láti ọ̀rúndún kìíní Ọdún Olúwa Wa títí di ọdún 1899.” Nínú ìwé Humanity—A Moral History of the Twentieth Century (Ẹ̀dá Èèyàn—Ìwà àti Ìṣe Wọn Ní Ọ̀rúndún Ogún) tí Jonathan Glover kọ, ó ní: “Wọ́n fojú bù ú pé mílíọ̀nù mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86,000,000] èèyàn ni ogun gbẹ̀mí wọn láti ọdún 1900 sí 1989. . . . Ká sòótọ́, iye àwọn tó kú nínú ogun ní ọ̀rúndún ogún pọ̀ kọjá ohun tí ẹ̀dá èèyàn lè mọ̀. Tá a bá ní ká pín iye tí wọ́n fojú bù pé ó kú yìí sí ọdún kọ̀ọ̀kan, kò ní bá iye àwọn tó kú lọ́dún kọ̀ọ̀kan mu ní ti gidi, nítorí pé nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìdínlọ́gọ́ta [58,000,000] èèyàn ló bá ogun àgbáyé méjèèjì nìkan lọ. Àmọ́, tá a bá pàpà pín iye àwọn tó kú yìí sí iye ọdún tó wà nínú ọ̀rúndún ogún, a jẹ́ pé ogun ń pa nǹkan bí ẹgbẹ̀tàlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,500] èèyàn lójoojúmọ́, èyí tó fi hàn pé ọgọ́rùn-ún èèyàn ló ń kú ní wákàtí kọ̀ọ̀kan fún odidi àádọ́rùn-ún ọdún.” Ǹjẹ́ o lè finú ro ọ̀fọ̀ àti ẹ̀dùn ọkàn tí èyí ti kó bá ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tí wọ́n jẹ́ mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ àwọn tó bógun lọ?
Òótọ́ ni pé oúnjẹ tí aráyé ń pèsè pọ̀ gan-an, síbẹ̀ àìtó oúnjẹ wà lára àwọn ohun tó ń fi hàn pé ìkẹyìn ọjọ́ la wà yìí. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, oúnjẹ tí aráyé ń pèsè ti pọ̀ ju iye àwọn olùgbé ayé lọ. Síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ ibi làwọn èèyàn ò ti rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó torí pé àwọn púpọ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ nílẹ̀ tí wọ́n lè fi dáko tàbí kó jẹ́ pé wọn ò lówó tí wọ́n lè fi ra oúnjẹ. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, nǹkan bíi bílíọ̀nù kan ó lé igba mílíọ̀nù èèyàn ló jẹ́ pé gbogbo owó tí wọ́n ń rí ná lójúmọ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ má ju dọ́là kan (owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà) lọ. Nínú àwọn èèyàn wọ̀nyí sì rèé, nǹkan bí okòódínlẹ́gbẹ̀rin [780] mílíọ̀nù èèyàn ni ebi àpafẹ́ẹ̀ẹ́kú ń pa. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé lọ́dọọdún, àìjẹunrekánú ń ṣokùnfà ikú tó ń pa àwọn ọmọdé tí iye wọn ju mílíọ̀nù márùn-ún lọ.
Kí la lè sọ nípa ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀? Àjọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ilẹ̀ sọ pé láti ọdún 1990, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára láti ba ilé jẹ́ tó ń wáyé lọ́dọọdún jẹ́ mẹ́tàdínlógún ní ìpíndọ́gba. Bẹ́ẹ̀ ló sì jẹ́ pé, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára láti wó ilé palẹ̀ ń wáyé ní ìpíndọ́gba. Ìwé mìíràn sọ pé: “Ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni ìmìtìtì ilẹ̀ pa ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá.” Ọ̀kan lára ohun tó fa èyí ni pé látọdún 1914 sí ìsinsìnyí, ọ̀pọ̀ ìlú ńláńlá ló ti wà láwọn ibi tí ìmìtìtì ilẹ̀ ti ń wáyé.
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Burúkú Mìíràn
Jésù sọ pé: ‘Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ yóò wà láti ibì kan dé ibòmíràn.’ (Lúùkù 21:11) Lóde òní, ìtẹ̀síwájú ti wà lágbo ìmọ̀ ìṣègùn ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Síbẹ̀, àwọn àìsàn tó ti wà tipẹ́tipẹ́ àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú ṣì ń pọ́n ọmọ aráyé lójú. Ìwé kan tí Àjọ Tó Ń Mójú Tó Ọ̀rọ̀ Abẹ́lẹ̀ Nílẹ̀ Amẹ́ríkà tẹ̀ jáde sọ pé: “Látọdún 1973, ogún àìsàn táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, irú bí ikọ́ ẹ̀gbẹ, ibà àti kọ́lẹ́rà, ló tún ti rú yọ tó sì ń kọ lu àwọn èèyàn níbi tó pọ̀ gan-an. Gbogbo àwọn àìsàn wọ̀nyí ló sì ti lágbára gan-an débi pé wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ má gbóògùn mọ́. Bákan náà ló jẹ́ pé látọdún 1973, nǹkan bí ọgbọ̀n kòkòrò tó ń fa àìsàn, èyí tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ làwọn ògbógi ti mọ̀ báyìí. Lára ìwọ̀nyí ni àwọn kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì, àrùn Ebola, àrùn mẹ́dọ̀wú [hepatitis C], àti àrùn Nipah, kò sì sí ìwòsàn kankan fún àwọn àìsàn wọ̀nyí.” Ìròyìn kan tí Àjọ Alágbèélébùú Pupa tẹ̀ jáde ní June 28, 2000 sọ pé, lọ́dún 1999, iye àwọn tí àwọn àrùn tó ń gbèèràn pa fi ìlọ́po ọgọ́jọ [160] ju iye èèyàn tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí omíyalé, ìjì, àti irú àwọn ìjábá bẹ́ẹ̀ pa lọ.
Ohun mìíràn tó hàn gbangba tó jẹ́ ẹ̀rí pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí ni ‘ìwà àìlófin tí ń pọ̀ sí i.’ (Mátíù 24:12) Níbi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé lónìí, àwọn èèyàn ò lè ṣe kí wọ́n má ti ilẹ̀kùn ilé wọn, ńṣe lẹ̀rù sì máa ń bà wọ́n láti rìn nígboro bílẹ̀ bá ti ṣú. Àwọn nǹkan bíi bíba afẹ́fẹ́, omi àti ilẹ̀ jẹ́ tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ńkọ́, èyí tó jẹ́ pé àwọn tó ń ṣe ohun tí kò bófin mu ló ń dá ìṣòro wọ̀nyí sílẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà? Èyí náà jẹ́ ara ohun tó ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Ìwé Ìṣípayá sọ pé Ọlọ́run ti yan àkókò tí òun yóò run “àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:18.
Ìwà Táwọn Èèyàn Ń Hù Ní Ìkẹyìn Ọjọ́
Jọ̀wọ́ ṣí Bíbélì rẹ sí 2 Tímótì 3:1-5, kó o sì kà á. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ níbẹ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.” Ó wá sọ àwọn ìwà kan tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ ogún tí àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run yóò máa hù. Ǹjẹ́ o ti kíyè sí díẹ̀ nínú ìwà wọ̀nyí lára àwọn tí wọ́n ń gbé àdúgbò rẹ? Wo ohun táwọn kan sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa àwọn èèyàn òde ìwòyí.
“Olùfẹ́ ara wọn.” (2 Tímótì 3:2) “Lóde òní, tinú ara wọn [làwọn èèyàn] máa ń fẹ́ ṣe. [Wọ́n] máa ń sọ ara wọn di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, wọ́n sì máa ń fẹ́ káwọn èèyàn máa wárí fún wọn.”—Ìwé ìròyìn Financial Times, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
“Olùfẹ́ owó.” (2 Tímótì 3:2) “Láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ìgbéraga nítorí owó ò jẹ́ káwọn èèyàn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ mọ́. Tó ò bá ti lówó lọ́wọ́, ojú ẹni yẹpẹrẹ làwọn èèyàn yóò máa fi wò ọ́.”—Ìwé ìròyìn Jakarta Post, Indonesia.
“Aṣàìgbọràn sí òbí.” (2 Tímótì 3:2) ‘Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fáwọn òbí pé àwọn ọmọ wọn tí kò ju ọmọ ọdún mẹ́rin lọ ń pàṣẹ fún wọn bí ẹni pé ọba ni wọ́n, tí àwọn ọmọ wọn ọlọ́dún mẹ́jọ sì ń pariwo mọ́ wọn pé, “Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi jọ̀ọ́, ẹ̀yin ìkà yìí!”’—Ìwé ìròyìn American Educator, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
“Aláìdúróṣinṣin.” (2 Tímótì 3:2) “Láti [ogójì ọdún sẹ́yìn], àfàìmọ̀ ni ò ní jẹ́ pé bí ọ̀pọ̀ ọkùnrin ṣe ń já àwọn aya wọn àtàwọn ọmọ wọn jù sílẹ̀ ni ìṣòro tó ga jù lọ tó fi hàn pé àwọn èèyàn ò hùwà ọmọlúwàbí mọ́.”—Ìwé ìròyìn Wilson Quarterly, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
“Aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:3) “Ìwà ipá àárín ọkọ àti aya àtàwọn ọmọ wọ́pọ̀ gan-an níbi gbogbo káàkiri àgbáyé.”—Ìwé ìròyìn Journal of the American Medical Association, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
“Aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu.” (2 Tímótì 3:3) “Púpọ̀ lára ìròyìn tó máa ń wà níwájú ìwé ìròyìn ló ń jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn ò ní ìkóra-ẹni-níjàánu, wọn kì í hùwà ọmọlúwàbí, wọn kò sì láàánú ọmọnìkejì wọn àti ara wọn pàápàá. . . . Bí aráyé bá ń bá ìwà jàgídíjàgan lọ bí wọ́n ṣe ń bá a lọ yìí, ayé ò ní pẹ́ di ibi tí ìwà ọmọlúwàbí kò sí mọ́.”—Ìwé ìròyìn Bangkok Post, Thailand.
“Òǹrorò.” (2 Tímótì 3:3) “Kò síbi táwọn èèyàn ò ti máa ń bínú àbíjù, ìbínú tí kò nídìí. A máa ń rí i báwọn awakọ̀ ṣe máa ń fa ìbínú yọ lójú pópó, ó tún máa ń hàn nínú ìwà ìkà táwọn èèyàn ń hù síra wọn nínú ìdílé . . . ó sì tún máa ń hàn [nínú] ìwà ìkà tí kò nídìí táwọn ọ̀daràn máa ń hù. Ìgbàkigbà làwọn èèyàn lè hùwà ipá, ọ̀nàkọnà ló sì lè gbà ṣẹlẹ̀. Èyí ti jẹ́ kí ayé sú ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n máa ronú pé kò sí ààbò fún wọn.”—Ìwé ìròyìn Business Day, orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà.
“Olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:4) “Ohun táwọn kan ń jà fún ni pé kí wọ́n gba àwọn láyè láti máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tó bá wù wọ́n, bẹ́ẹ̀ kẹ̀ ohun tí ìlànà ẹ̀sìn Kristẹni ò fàyè gbà nìyẹn.”—Ìwé ìròyìn orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń jẹ́ Boundless.
“Àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” (2 Tímótì 3:5) “[Obìnrin kan tó jẹ́ aṣẹ́wó nígbà kan rí lórílẹ̀-èdè Netherlands] sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn ló pọ̀ jù lára àwọn tí ò fẹ́ kí ìjọba fọwọ́ sí i pé kí [iṣẹ́ aṣẹ́wó] di òwò tó bófin mu. Ó wá dánu dúró, ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì fi kún un pé nígbà tí òun ṣì ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó, àwọn òjíṣẹ́ [Ọlọ́run] wà lára àwọn tó máa ń wá sọ́dọ̀ òun déédéé. Tẹ̀ríntẹ̀rín ló fi sọ pé: ‘Àwọn aṣẹ́wó sábà máa ń sọ pé àwọn tó láwọn ń sin Ọlọ́run ni oníbàárà àwọn táwọn fẹ́ràn jù lọ.’”—Ìwé ìròyìn National Catholic Reporter, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú?
Lónìí, ńṣe ni wàhálà kún ayé fọ́fọ́ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ohun dáradára kan wà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó jẹ́ “àmì wíwàníhìn-ín [Kristi] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan.” Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:3, 14) Igba ó lé ọgbọ̀n [230] ilẹ̀ la ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn tí wọ́n wá “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” ló sì ń fìtara ṣiṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà. (Ìṣípayá 7:9) Kí ni àbájáde iṣẹ́ àṣekára wọn yìí? Òun ni pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n ti gbọ́ ìhìn rere nípa ohun tí Ìjọba náà jẹ́, àwọn ohun dáradára tó máa ṣe fún àwọn èèyàn àti ohun tí wọ́n lè ṣe kí ọwọ́ wọn lè tẹ́ àwọn ohun náà. Àní, ‘ìmọ̀ tòótọ́ ti di púpọ̀ yanturu ní àkókò òpin.’—Dáníẹ́lì 12:4.
Ó yẹ kó o ṣe ohun tó máa jẹ́ kó o lè ní ìmọ̀ yìí. Wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá ti wàásù ìhìn rere náà débi tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn. Jésù sọ pé: “Nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Matthew 24:14) Ìgbà yẹn ni àkókò yóò tó lójú Ọlọ́run láti fòpin sí gbogbo ìwà ibi lórí ilẹ̀ ayé. Ìwé Òwe 2:22 sọ pé: “Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.” Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀? Ńṣe ni Jésù yóò jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, níbi tí wọn ò ti ní lágbára láti tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́. (Ìṣípayá 20:1-3) Nígbà náà ‘àwọn adúróṣánṣán àtàwọn aláìlẹ́bi ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí’ ilẹ̀ ayé. Wọ́n á sì gbádùn àwọn ohun dáradára tí Ìjọba náà máa pèsè.—Òwe 2:21; Ìṣípayá 21:3-5.
Kí Lo Lè Ṣe?
Ó dájú pé àkókò tí Ọlọ́run máa pa ètò àwọn nǹkan Sátánì run ti kù sí dẹ̀dẹ̀. Àwọn tí ò bá kọbi ara sí àwọn ẹ̀rí tó wà pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí kò ní mọ̀gbà tí òpin máa dé bá wọn. (Mátíù 24:37-39; 1 Tẹsalóníkà 5:2) Abájọ tí Jésù fi sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nítorí yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé. Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn.”—Lúùkù 21:34-36.
Kìkì àwọn tó bá rí ojú rere Ọmọ ènìyàn, ìyẹn Jésù, ló lè máa retí pé àwọn yóò la òpin ètò àwọn nǹkan yìí já. Ó mà ṣe pàtàkì o pé ká lo àkókò tó ṣẹ́ kù yìí láti fi wá ojú rere Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi! Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Ọlọ́run, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Nígbà náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ kó o ṣe. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ yóò dùn láti ràn ọ́ lọwọ́ kó o lè lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì. A fi tìfẹ́tìfẹ́ ké sí ọ pé kó o kàn sí wọn tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
ÀWỌN ÀMÌ ỌJỌ́ ÌKẸYÌN
ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ BURÚKÚ:
▪ Ogun.—Mátíù 24:6, 7.
▪ Àìtó oúnjẹ.—Mátíù 24:7.
▪ Ìsẹ̀lẹ̀.—Mátíù 24:7.
▪ Àjàkálẹ̀ àrùn.—Lúùkù 21:11.
▪ Ìwà àìlófin tó ń peléke sí i.—Mátíù 24:12.
▪ Bíba ilẹ̀ ayé jẹ́.—Ìṣípayá 11:18.
ÀWỌN ÈÈYÀN:
▪ Olùfẹ́ ara wọn. —2 Tímótì 3:2.
▪ Olùfẹ́ owó.—2 Tímótì 3:2.
▪ Onírera.—2 Tímótì 3:2.
▪ Aṣàìgbọràn sí òbí. —2 Tímótì 3:2.
▪ Aláìlọ́pẹ́.—2 Tímótì 3:2.
▪ Aláìdúróṣinṣin. —2 Tímótì 3:2.
▪ Aláìní ìfẹ́ni àdánidá. —2 Tímótì 3:3.
▪ Aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu.—2 Tímótì 3:3.
▪ Òǹrorò.—2 Tímótì 3:3.
▪ Olùfẹ́ adùn.—2 Tímótì 3:4.
▪ Àwọn onísìn tí wọ́n ń ṣe àgàbàgebè.—2 Tímótì 3:5.
ÀWỌN OLÙJỌSÌN TÒÓTỌ́:
▪ Wọ́n ní ìmọ̀ yanturu. —Dáníẹ́lì 12:4.
▪ Wọ́n ń wàásù ìhìn rere jákèjádò ayé.—Mátíù 24:14.
[Credit Line]
UNITED NATIONS/Photo by F. GRIFFING