Sísan Ohun Ti Kesari Padà fún Kesari
“Ẹ fi awọn ohun ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn.”—ROMU 13:7.
1, 2. (a) Gẹ́gẹ́ bí Jesu ṣe sọ, báwo ni àwọn Kristian ṣe lè mú kí ojúṣe wọn sí Ọlọrun wà déédéé pẹ̀lú ti Kesari? (b) Kí ni ohun tí ó jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lógún jù lọ?
GẸ́GẸ́ bí Jesu ti wí, àwọn ohun kan wà tí a jẹ Ọlọrun ní gbèsè rẹ̀, àwọn ohun kan sì wà tí a jẹ Kesari, tàbí Orílẹ̀-Èdè, ní gbèsè rẹ̀. Jesu wí pé: “Ẹ san awọn ohun ti Kesari padà fún Kesari, ṣugbọn awọn ohun ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ díẹ̀ wọ̀nyí, ó mú ìyàlẹ́nu bá àwọn ọ̀tá rẹ̀, ó sì ṣàkópọ̀ ṣókí nípa ìṣarasíhùwà tí ó wà déédéé tí a gbọ́dọ̀ ní nínú ipò ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọrun àti nínú ìbálò wa pẹ̀lú Orílẹ̀-Èdè. Abájọ tí ‘ẹnu bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn olùgbọ́ rẹ̀ sí i’!—Marku 12:17.
2 Àmọ́ ṣáá o, ohun tí ó jẹ àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lógún jù lọ ni pé, kí wọ́n san ohun ti Ọlọrun padà fún Ọlọrun. (Orin Dafidi 116:12-14) Ṣùgbọ́n, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò gbàgbé pé Jesu wí pé, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ohun kan fún Kesari. Ẹ̀rí ọkàn wọn tí a fi Bibeli kọ́ béèrè pé, kí wọ́n ronú tàdúràtàdúrà láti mọ bí wọn yóò ṣe san ohun tí Kesari bá béèrè padà tó. (Romu 13:7) Ní òde òní, ọ̀pọ̀ amòfin ti mọ̀ pé, agbára ìjọba ní ààlà, àti pé àwọn ènìyàn àti ìjọba níbi gbogbo wà lábẹ́ òfin àdánidá.
3, 4. Àwọn àlàyé fífani mọ́ra wo ni a ti ṣe nípa òfin àdánidá, òfin tí a ṣí payá, àti òfin ẹ̀dá ènìyàn?
3 Aposteli Paulu tọ́ka sí òfin àdánidá yìí nígbà tí ó kọ̀wé nípa àwọn ènìyàn ayé pé: “Nitori pé ohun tí a lè mọ̀ nipa Ọlọrun farahàn kedere láàárín wọn, nitori Ọlọrun mú kí ó farahàn kedere sí wọn. Nitori awọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere lati ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nitori a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ awọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé ati Jíjẹ́ Ọlọrun rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní àwíjàre.” Bí wọn yóò bá ṣiṣẹ́ lé e lórí, òfin àdánidá pàápàá yóò sún ẹ̀rí ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ wọ̀nyí ṣiṣẹ́. Nípa báyìí, Paulu sọ síwájú sí i pé: “Nitori nígbàkigbà tí awọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin bá ṣe awọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá, awọn ènìyàn wọnyi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn. Awọn gan-an ni awọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn-àyà wọn, nígbà tí ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí.”—Romu 1:19, 20; 2:14, 15.
4 Ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, gbajúgbajà amòfin ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, William Blackstone, kọ̀wé pé: “Láìsí àní àní, òfin ìṣẹ̀dá [òfin àdánidá], tí ó jẹ́ irọ̀ [tí ó ní ọjọ́ orí kan náà] pẹ̀lú aráyé, tí Ọlọrun fúnra rẹ̀ sì pa láṣẹ, ga lọ́lá ní ti ojúṣe ju òfin èyíkéyìí mìíràn lọ. Ó gbé gbogbo ayé dè, ní gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ní gbogbo ìgbà: kò sí òfin ẹ̀dá ènìyàn kankan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀, bí ó ba ta ko èyí.” Blackstone ń bá a nìṣó láti sọ nípa “òfin tí a ṣí payá,” gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú Bibeli, ó sì ṣàlàyé pé: “Lórí ìpìlẹ̀ méjì yìí, òfin ìṣẹ̀dá àti òfin ìṣípayá, ni gbogbo òfin ènìyàn sinmi lé; ìyẹn ni pé, a kò ní láti yọ̀ọ̀da fún òfin ẹ̀dá ènìyàn kankan láti ta ko àwọn wọ̀nyí.” Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jesu sọ nípa Ọlọrun àti Kesari, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Marku 12:17. Ní kedere, àwọn agbègbè kan wà tí Ọlọrun ti pààlà sí ohun tí Kesari lè béèrè lọ́wọ́ Kristian kan. Ìgbìmọ̀ Sanhẹdirin rìn gbéregbère dé agbègbè yẹn, nígbà tí wọ́n pàṣẹ fún àwọn aposteli láti dáwọ́ wíwàásù nípa Jesu dúró. Nítorí náà, àwọn aposteli tọ̀nà láti dáhùn padà pé: “Awa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:28, 29.
“Awọn Ohun ti Ọlọrun”
5, 6. (a) Lójú ìwòye ìbí Ìjọba náà ní ọdún 1914, kí ni àwọn Kristian túbọ̀ ní láti fi sọ́kàn dáradára? (b) Báwo ni Kristian kan ṣe ń fi hàn pé òjíṣẹ́ ni òun?
5 Ní pàtàkì láti ọdún 1914, nígbà tí Jehofa Ọlọrun, Olódùmarè, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso nípasẹ̀ Ìjọba Messia tí ó jẹ́ ti Kristi, ni àwọn Kristian ti ní láti rí i dájú pé àwọn kò fi ohun ti Ọlọrun fún Kesari. (Ìṣípayá 11:15, 17) Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, òfin Ọlọrun ń béèrè lọ́wọ́ àwọn Kristian nísinsìnyí láti ‘má ṣe jẹ́ apá kan ayé.’ (Johannu 17:16) Níwọ̀n bí wọ́n ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Ọlọrun, Olùfúnniníyè wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ fi hàn ní kedere pé àwọn kò jẹ́ ti ara wọn mọ́. (Orin Dafidi 100:2, 3) Gẹ́gẹ́ bí Paulu ti kọ̀wé, “awa jẹ́ ti Jehofa.” (Romu 14:8) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà tí Kristian kan bá ṣe batisí, a fi í joyè gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọrun, kí òun baà lè sọ bí Paulu ṣe sọ pé: “Ọlọrun . . . ti mú wa tóótun tẹ́rùntẹ́rùn nítòótọ́ lati jẹ́ òjíṣẹ́.”—2 Korinti 3:5, 6.
6 Aposteli Paulu tún kọ̀wé pé: “Emi ṣe iṣẹ́-òjíṣẹ́ mi lógo.” (Romu 11:13) Dájúdájú, ó yẹ kí àwa náà ṣe bẹ́ẹ̀. Yálà a ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àkókò kíkún tàbí a ń ṣe é lóòrèkóòrè, kí a fi í sọ́kàn pé Jehofa fúnra rẹ̀ ni ó yàn wá sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (2 Korinti 2:17) Níwọ̀n bí àwọn kan ti lè gbé ìbéèrè dìde sí ipò wa, gbogbo Kristian olùṣèyàsímímọ́, tí a ti batisí gbọ́dọ̀ wà ní sẹpẹ́ láti lè fi ẹ̀rí tí ó ṣe kedere, tí ó sì fẹsẹ̀ rinlẹ̀ hàn pé ní tòótọ́ ni àwọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ ìhìn rere náà. (1 Peteru 3:15) Ìwà rẹ̀ pẹ̀lú yẹ kí ó fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ hàn. Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọrun, Kristian kan ní láti ṣe alágbàwí ìwà rere, kí ó sì fi ṣèwàhù, kí ó di ìṣọ̀kan ìdílé mú, kí ó jẹ́ aláìlábòsí, kí ó sì bọ̀wọ̀ fún òfin àti àṣẹ. (Romu 12:17, 18; 1 Tessalonika 5:15) Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé Kristian kan ni, ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọrun àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tí Ọlọrun yàn fún un. Àṣẹ Kesari kò gbọdọ̀ mú kí ó pa àwọn wọ̀nyí tì. Ó hàn gbangba pé, a gbọ́dọ̀ kà wọ́n mọ́ “awọn ohun ti Ọlọrun.”
“Awọn Ohun ti Kesari”
7. Orúkọ rere wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní, ní ti sísan owó orí?
7 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ̀ pé àwọ́n ní láti “wà lábẹ́ awọn aláṣẹ onípò gíga,” àwọn olùṣàkóso ìjọba. (Romu 13:1) Nítorí náà, nígbà tí Kesari, Orílẹ̀-Èdè, bá béèrè ohun tí ó tọ́, ẹ̀rí ọkàn wọn tí a fi Bibeli kọ́ yóò yọ̀ọ̀da fún wọn láti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Kristian tòótọ́ wà lára àwọn tí a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn jù lọ ní ti owó orí sísan lórí ilẹ̀ ayé. Ní Germany, ìwé agbéròyìnjáde Münchner Merkur sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pé: “Àwọn ni wọ́n jẹ́ aláìlábòsí jù lọ ní ti owó orí sísan, àwọn ni ó sì ń tètè san owó orí wọn ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira náà.” Ní Itali, ìwé agbéròyìnjáde La Stampa sọ pé: “Àwọn [Ẹlẹ́rìí Jehofa] ni àwọn aráàlú tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin jù lọ tí ẹnikẹ́ni lè ní èrò rere sí: wọn kì í yẹ owó orí sílẹ̀ tàbí kí wọ́n wá ọ̀nà láti yẹ àwọn ofin tí kò bára dé sílẹ̀ fún àǹfààní ara wọn.” Àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ń ṣe èyí ‘ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn wọn.’—Romu 13:5, 6.
8. Owó orí nìkan ha ni ohun tí a jẹ Kesari ní gbèsè rẹ̀ bí?
8 A ha fi “awọn ohun ti Kesari” mọ sórí sísan owó orí bí? Ó tì o. Paulu to àwọn ohun mìíràn lẹ́sẹẹsẹ, irú bí ìbẹ̀rù àti ọlá. Nínú ìwé rẹ̀, Critical and Exegetical Hand-Book to the Gospel of Matthew, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Germany, Heinrich Meyer, kọ̀wé pé: “Nípa [àwọn ohun ti Kesari] . . . a kò ní láti rò pé wọ́n mọ sórí owó orí ìlú nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí Kesari lẹ́tọ̀ọ́ sí nítorí àkóso rẹ̀ tí ó tọ́.” Òpìtàn E. W. Barnes, nínú ìwé rẹ̀, The Rise of Christianity, sọ pé, Kristian kan yóò san owó orí tí ó bá jẹ, yóò sì “tẹ́wọ́ gba gbogbo ojúṣe Orílẹ̀-Èdè míràn lọ́nà kan náà, kìkì tí a kò bá ti pè é láti wá fún Kesari ní ohun tí ó jẹ́ ti Ọlọrun.”
9, 10. Ìlọ́tìkọ̀ wo ni Kristian kan lè ní nípa sísan ohun tí ó yẹ fún Kesari padà fún un, ṣùgbọ́n òkodoro òtítọ́ wo ni ó yẹ kí a fi sọ́kàn?
9 Kí ni Orílẹ̀-Èdè lè béèrè láìjẹ́ pé ó ra kaka lé àwọn ohun tí ó tọ́ sí Ọlọrun? Àwọn kan ti rò pé kìkì owó orí níkan ni àwọn lè san fún Kesari lọ́nà tí ó tọ́, kò tún sí ohun mìíràn tí àwọ́n lè fún un. Kì yóò tẹ́ wọn lọ́rùn láti fún Kesari ní ohunkóhun tí ó bá lè gba àkókò tí wọ́n lè lò fún àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọrun. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní láti ‘nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, gbogbo ọkàn wa, gbogbo èrò-inú wa, àti gbogbo okun wa,’ Jehofa ń retí pé kí a lo àkókò fún àwọn ohun mìíràn tí ó yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wa. (Marku 12:30; Filippi 3:3) Fún àpẹẹrẹ, a fún Kristian kan tí ó ti ṣègbéyàwó nímọ̀ràn láti ya àkókò sọ́tọ̀ fún títẹ́ ẹnì kejì rẹ̀ nínú ìgbéyàwó lọ́rùn. Irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ kò burú, ṣùgbọ́n aposteli Paulu sọ pé “ohun ti ayé” ni wọ́n, wọn kì í ṣe “awọn ohun ti Oluwa.”—1 Korinti 7:32-34; fi wé 1 Timoteu 5:8.
10 Síwájú sí i, Kristi pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti “san” owó orí “padà,” dájúdájú èyí sì ní lílo àkókò tí a ti yà sí mímọ́ fún Jehofa nínú—níwọ̀n bí a ti ya gbogbo ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún un lọ́nà yìí. Bí ìpíndọ́gba owó orí ní orílẹ̀-èdè kan bá jẹ́ ìpín 33 nínú ọgọ́rùn-ún nínú owó tí ń wọlé fúnni (ó pọ̀ jù báyìí lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan), èyí túmọ̀ sí pé lọ́dọọdún, òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ń san iye tí ó tó owó oṣù mẹ́rin nínú owó tí ń wọlé fún un sí Àpò Orílẹ̀-Èdè. Bí a bá sọ ọ́ lọ́nà míràn, nígbà tí yóò bá fi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ọba, òṣìṣẹ́ kan yóò ti lo nǹkan bí ọdún 15 láti fi wá owó orí tí “Kesari” ń béèrè. Tún gbé ọ̀ràn ètò ẹ̀kọ́ yẹ̀ wò pẹ̀lú. Ní ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè, òfin ń béèrè pé kí àwọn òbí jẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n lọ sí ilé ẹ̀kọ́ fún iye ọdún kan pàtó. Iye ọdún tí wọ́n yóò lò ní ilé ẹ̀kọ́ máa ń yàtọ̀ síra láti orílẹ̀-èdè kan sí èkejì. Ní àwọn ibi tí ó pọ̀ jù lọ, ó jẹ́ àkókò gígùn gan-an. Òtítọ́ ni pé, irú ètò ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń ṣàǹfààní, ṣùgbọ́n Kesari ni ó ń pinnu ìwọ̀n tí ọmọ kan gbọ́dọ̀ lò nínú ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà yìí, àwọn Kristian òbí sì ń fara mọ́ ìpinnu Kesari.
Iṣẹ́ Ológun Àpàpàǹdodo
11, 12. (a) Kí ni ohun tí Kesari ń béèrè fún ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀? (b) Ojú wo ni àwọn Kristian ìjímìjí fi wo iṣẹ́ ológun?
11 Ohun mìíràn tí Kesari ń béèrè fún ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ni iṣẹ́ ológun àpàpàǹdodo. Ní ọ̀rúndún ogún, ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè ti gbé ètò yìí kalẹ̀ ní àkókò ogun, àwọn kan sì ti gbé e kalẹ̀ ní àkókò tí nǹkan rọgbọ pẹ̀lú. Ní ilẹ̀ Faransé, fún ọ̀pọ̀ ọdún, ojúṣe yìí ni a ń pè ní owó orí àfẹ̀jẹ̀san, tí ó túmọ̀ sí pé gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin gbọ́dọ̀ múra tán láti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ fún Orílẹ̀-Èdè. Èyí ha jẹ́ ohun tí àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jehofa lè fi tọkàntọkàn ṣe bí? Ojú wo ni àwọn Kristian ọ̀rúndún kìíní fi wo ọ̀ràn yìí?
12 Bí àwọn Kristian ìjímìjí tilẹ̀ sakun láti jẹ́ aráàlú rere, ìgbàgbọ́ wọn kò yọ̀ọ̀da fún wọn láti gba ẹ̀mí ẹlòmíràn tàbí fi ẹ̀mí ara wọn rúbọ fún Orílẹ̀-Èdè. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Encyclopedia of Religion, sọ pé: “Àwọn bàbá ṣọ́ọ̀ṣì ìjímìjí, títí kan Tertullian àti Origen, tẹnu mọ́ ọn pé, a ká àwọn Kristian lọ́wọ́ kò láti gba ẹ̀mí ènìyàn, ìlànà kan tí kò yọ̀ọ̀da fún wọn láti lọ́wọ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Romu.” Nínú ìwé rẹ̀, The Early Church and the World, Ọ̀jọ̀gbọ́n C. J. Cadoux kọ̀wé pé: “Títí di ìgbà ìṣàkóso Marcus Aurelius ó kéré pin [láti ọdún 161 sí 180 Sànmánì Tiwa], kò sí Kristian kan tí ó di sójà lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀.”
13. Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù kò ṣe fi ojú tí àwọn Kristian ìjímìjí fi wo iṣẹ́ ológun wò ó?
13 Èé ṣe tí àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù kò fi ní irú ojú ìwòye yìí lónìí? Nítorí ìyípadà tegbò tigaga tí ó wáyé ní ọ̀rúndún kẹrin ni. Ìwé Kátólíìkì náà, A History of the Christian Councils, ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀ Kristian, . . . lábẹ́ àwọn ọba aláyélúwà tí wọ́n jẹ́ kèfèrí, ni ìsìn mú kí wọn lọ́ tìkọ̀ sí iṣẹ́ ológun, wọ̀n sì kọ̀ jálẹ̀ láti gbé ohun ìjà ogun, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ wọn yóò sá kúrò. Ìpàdé Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn [Arles, tí a ṣe ní ọdún 314 Sànmánì Tiwa], nígbà tí ó ń ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìyípadà tí Constantine mú wá, gbé ojúṣe náà kalẹ̀ pé àwọn Kristian gbọ́dọ̀ jagun, . . . nítorí pé Ṣọ́ọ̀ṣì náà wà ní àlàáfíà (in pace) lábẹ́ ọmọ aládé kan tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn Kristian.” Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí pípa ẹ̀kọ́ Jesu tì yìí, láti ìgbà yẹn títí di ìsinsìnyí, ẹgbẹ́ àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fún àwọn agbo wọn ní ìṣírí láti ṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn orílẹ̀-èdè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ti mú ìdúró wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn.
14, 15. (a) Lórí ìpìlẹ̀ wo ni àwọn Kristian ní àwọn ibì kan gbà ń béèrè fún ṣíṣàìfi iṣẹ́ ológun lọ̀ wọ́n? (b) Níbi tí a bá ti fi iṣẹ́ ológun lọ̀ wọ́n, àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ni ó lè ran Kristian kan lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tí ó tọ́ nínú ọ̀ràn iṣẹ́ ológun?
14 Ó ha pọndandan fún àwọn Kristian lónìí láti tẹ̀ sí ibi tí ayé tẹ̀ sí lórí ọ̀ràn yìí bí? Ó tì o. Bí Kristian kan tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́, tí ó sì ti ṣe batisí bá ń gbé ní orílẹ̀-èdè kan níbi tí a kì í ti í fi iṣẹ́ ológun lọ àwọn òjíṣẹ́ ìsìn, ó lè lo àǹfààní yìí, nítorí pé, ní ti gàsíkíá, òjíṣẹ́ ni. (2 Timoteu 4:5) Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè, títí kan United States àti Australia, kì í fi irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ àwọn òjíṣẹ́ ìsìn ní àkókò ogun. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tí ń ṣe iṣẹ́ ológun àpàpàǹdodo, nígbà tí nǹkan bá rọgbọ pẹ̀lú, a kì í fi iṣẹ́ ológun lọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, gẹ́gẹ́ bí àwọn òjíṣẹ́ ìsìn. Nípa báyìí, wọn lè máa tẹ̀ síwájú ní fífi iṣẹ́ ìsìn wọn fún gbogbo ènìyàn ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́.
15 Ṣùgbọ́n, bí Kristian náà bá ń gbé ni ilẹ̀ kan tí a ti ń fi iṣẹ́ ológun lọ àwọn òjíṣẹ́ ìsìn ńkọ́? Nígbà náà, òun yóò ní láti ṣe ìpinnu tí a gbé ka ẹ̀rí ọkàn tí a fi Bibeli kọ́. (Galatia 6:5) Bí ó ṣe ń ronú lórí ọlá àṣẹ Kesari, yóò gbé òun tí ó jẹ Jehofa ní gbèsè rẹ̀ yẹ̀ wò dáradára. (Orin Dafidi 36:9; 116:12-14; Ìṣe 17:28) Kristian náà yóò rántí pé àmì ìdánimọ̀ Kristian tòótọ́ ni ìfẹ́ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, àní àwọn tí ń gbé ní àwọn ilẹ̀ míràn tàbí àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà ìran mìíràn pàápàá. (Johannu 13:34, 35; 1 Peteru 2:17) Síwájú sí i, òun kì yóò gbàgbé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tí a rí nínú àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ bí Isaiah 2:2-4; Matteu 26:52; Romu 12:18; 14:19; 2 Korinti 10:4; àti Heberu 12:14.
Iṣẹ́ Àṣesìnlú
16. Ní àwọn ilẹ̀ kan, iṣẹ́ tí kì í ṣe ti ológun wo ni Kesari ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tí kò bá gba iṣẹ́ ológun?
16 Ṣùgbọ́n, àwọn ilẹ̀ kan wà tí Orílẹ̀-Èdè ti ń fi iṣẹ́ ológun lọ àwọn òjíṣẹ́ ìsìn, síbẹ̀síbẹ̀ tí ó gbà pé àwọn kan lè kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ológun. Ọ̀pọ̀ ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ ń pèsè ọ̀nà fún irú àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ń darí bẹ́ẹ̀, kí a má ṣe fipá mú wọn wọnú iṣẹ́ ológun. Ní àwọn ibì kan, iṣẹ́ àṣesìnlú tí a béèrè fún, irú bí iṣẹ́ tí ó wúlò láwùjọ, ni a kà sí iṣẹ́ tí kì í ṣe ti ológun, tí a ń ṣe sin orílẹ̀-èdè. Kristian kan tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ ha lè tẹ́wọ́ gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ bí? Níhìn-ín pẹ̀lú, Kristian olùṣèyàsímímọ́, tí a ti batisí yóò ni láti ṣe ìpinnu ti ara rẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀rí ọkàn tí a fi Bibeli kọ́.
17. Àpẹẹrẹ ìṣáájú ha wà nínú Bibeli fún iṣẹ́ àṣesìnlú, tí kì í ṣe ti ológun bí?
17 Ó dà bíi pé a ṣe iṣẹ́ àpàpàǹdodo ní àkókò tí a kọ Bibeli. Ìwé ìtàn kan sọ pé: “Ní àfikún sí owó orí àti àwọn ẹ̀tọ́ tí a ń gbà lọ́wọ́ àwọn olùgbé Judea, iṣẹ́ àṣesìnlú tún ń bẹ [iṣẹ́ ọ̀fẹ́ tí àwọn aláṣẹ ìlú ń múni ṣe]. Ètò láéláé kan ni èyí jẹ́ ní Ìlà Oòrùn, èyí tí àwọn aláṣẹ Helleni àti Romu ṣì ń ṣe síbẹ̀. . . . Májẹ̀mú Tuntun, pẹ̀lú, fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ iṣẹ́ àṣesìnlú ní Judea, ní fífi bí ó ṣe tàn kálẹ̀ tó nígbà náà lọ́hùn-ún hàn. Ní ìbámu pẹ̀lú àṣà yìí, àwọn sójà fipá mú Simoni ará Kirene láti gbé àgbélébùú Jesu [igi oró] (Matteu 5:41; 27:32; Marku 15:21; Luku 23:26).”
18. Irú iṣẹ́ àwùjọ, tí kì í ṣe ti ológun, tí kì í sì í ṣe ti ìsìn wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa máa ń kọ́wọ́ tì lẹ́yìn nígbà gbogbo?
18 Lọ́nà tí ó jọra, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan lónìí, Orílẹ̀-Èdè tàbí àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ béèrè pé kí àwọn aráàlú lọ́wọ́ nínú onírúurú iṣẹ́ àwùjọ. Nígbà míràn, èyí lè jẹ́ fún iṣẹ́ kan pàtó, irú bíi gbígbẹ́ kànga tàbí líla ojú ọ̀nà; nígbà míràn ó lè jẹ́ èyí tí a ń ṣe déédéé, irú bíi títún ojú ọ̀nà, ilé ẹ̀kọ́, tàbí ilé ìwòsàn ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Níbi tí irú iṣẹ́ àṣesìnlú bẹ́ẹ̀ bá ti jẹ́ fún ire àwùjọ, tí kò sì ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn èké, tàbí tí kò ta ko ẹ̀rí ọkàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àwọn ọ̀nà kan, wọ́n máa ń fìgbà gbogbo fara mọ́ ọn. (1 Peteru 2:13-15) Èyí ti fìgbà gbogbo yọrí sí ìjẹ́rìí tí ó jíire, nígbà míràn ó sì ti pa àwọn tí ń fẹ̀sùn èké kan àwọn Ẹlẹ́rìí pé wọ́n jẹ́ aṣòdì sí ìjọba lẹ́nu mọ́.—Fi wé Matteu 10:18.
19. Báwo ni Kristian kan ṣe lè yanjú ọ̀ràn náà, bí Kesari bá ní kí ó ṣe iṣẹ́ tí kì í ṣe ti ológun, tí ó jẹ́ àṣesin orílẹ̀-èdè fún sáà kan?
19 Ṣùgbọ́n, bí Orílẹ̀-Èdè kan bá béèrè pé kí Kristian kan ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú tí ó jẹ́ apá kan ṣíṣiṣẹ́ sin orílẹ̀-èdè lábẹ́ ìjọba alágbádá ńkọ́? Níhìn-ín pẹ̀lú, àwọn Kristian gbọ́dọ̀ gbé ìpinnu tí wọ́n bá ṣe ka ẹ̀rí ọkàn tí a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. “Gbogbo wa ni yoo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọrun.” (Romu 14:10) Àwọn Kristian tí wọ́n dojú kọ ohun tí Kesari béèrè fún ní láti gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà, kí wọ́n sì ṣàṣàrò lé e lórí.a Ó tún lè bọ́gbọ́n mu láti jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú àwọn Kristian tí wọ́n dàgbà dénú nínú ìjọ. Lẹ́yìn èyí, a gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu ara ẹni.—Owe 2:1-5; Filippi 4:5.
20. Àwọn ìbéèrè àti ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ni ó lè ran Kristian kan lọ́wọ́ láti ronú lórí ọ̀ràn iṣẹ́ àṣesìnlú, tí ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè ẹni, tí kì í sì í ṣe ti ológun?
20 Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, àwọn Kristian yóò gbé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìlànà Bibeli yẹ̀ wò. Paulu wí pé, a gbọ́dọ̀ ‘jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba-àkóso ati awọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso, kí a gbara dì fún iṣẹ́ rere gbogbo, kí a jẹ́ afòyebánilò, kí a máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sójú táyé sí ènìyàn gbogbo.’ (Titu 3:1, 2) Lọ́wọ́ kan náà, yóò dára kí àwọn Kristian gbé iṣẹ́ àṣesìnlú tí a wéwèé náà yẹ̀ wò. Bí wọ́n bá tẹ́wọ́ gbà á, wọn yóò ha lè di àìdásí tọ̀tún tòsì Kristian wọn mú bí? (Mika 4:3, 5; Johannu 17:16) Yóò ha mú kí wọn lọ́wọ́ nínú àwọn ìsìn èké kan bí? (Ìṣípayá 18:4, 20, 21) Ṣíṣe é yóò ha dí wọn lọ́wọ́ láti bójú tó ẹrù iṣẹ́ Kristian wọn tàbí yóò ha pààlà tí kò bọ́gbọ́n mu sí bí wọn yóò ṣe bójú tó o bí? (Matteu 24:14; Heberu 10:24, 25) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, wọn yóò ha lè máa bá a nìṣó láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, bóyá kí wọ́n tilẹ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ tí a béèrè fún náà bí?—Heberu 6:11, 12.
21. Ohun yòówù kí ìpinnu rẹ̀ jẹ́, ojú wo ni ìjọ ní láti fi wo arákùnrin kan tí ó ń yanjú ọ̀ràn iṣẹ́ àṣesìnlú, tí ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè ẹni, tí kì í sì í ṣe ti ológun?
21 Bí àwọn ìdáhùn aláìlábòsí tí Kristian kan ní sí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ bá sún un láti parí èrò sí pé, iṣẹ́ àṣesìnlú, tí ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè ẹni jẹ́ “iṣẹ́ rere” tí òún lè ṣe ní ṣíṣègbọràn sí àwọn aláṣẹ ńkọ́? Ìpinnu tirẹ̀ nìyẹn níwájú Jehofa. Àwọn alàgbà tí a yàn sípò àti àwọn mìíràn ní láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn arákùnrin náà délẹ̀délẹ̀, kí wọ́n sì máa wò ó gẹ́gẹ́ bíi Kristian tí ó ní ìdúró rere. Ṣùgbọ́n, bí Kristian kan bá rí i pé òun kò lè ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú yìí, a tún ní lati bọ̀wọ̀ fún ipò rẹ̀. Òun pẹ̀lú ní ìdúró rere, ó sì ní láti rí ìtìlẹyìn onífẹ̀ẹ́ gbà.—1 Korinti 10:29; 2 Korinti 1:24; 1 Peteru 3:16.
22. Ipò yòówù tí a lè dojú kọ, kí ni a óò máa bá a nìṣó láti ṣe?
22 Gẹ́gẹ́ bí i Kristian, a kò ní láti dẹ́kun fífi “fún ẹni tí ó béèrè fún ọlá, irúfẹ́ ọlá bẹ́ẹ̀.” (Romu 13:7) A óò bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rere, a óò sì máa wá ọ̀nà láti jẹ́ aráàlú tí ó lẹ́mìí àlàáfíà, tí ó sì ń pa òfin mọ́. (Orin Dafidi 34:14) A tún lè gbàdúrà “nipa awọn ọba ati gbogbo awọn wọnnì tí wọn wà ní ibi ipò gíga” nígbà tí a bá pe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí láti ṣe ìpinnu tí ó kan ìgbésí ayé Kristian àti iṣẹ́ wa. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí sísan àwọn ohun ti Kesari padà fún Kesari, a retí pé “a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí-ayé píparọ́rọ́ ati dídákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹlu ìfọkànsin Ọlọrun kíkún ati ìwà àgbà.” (1 Timoteu 2:1, 2) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a óò máa bá a nìṣó láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé, a óò sì máa fi tọkàntọkàn san ohun ti Ọlọrun padà fún Ọlọrun.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé-Ìṣọ́nà, May 15, 1964, ojú ìwé 308, ìpínrọ̀ 21 (Gẹ̀ẹ́sì).
Ìwọ́ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Láti mú kí ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Kesari àti Jehofa wà déédéé, kí ni ohun tí ó jẹ Kristian lógún jù lọ?
◻ Kí ni a jẹ Jehofa ní gbèsè rẹ̀, tí a kò sì lè fún Kesari láé?
◻ Kí ni àwọn nǹkan tí a lè fún Kesari padà lọ́nà tí ó tọ́?
◻ Àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ wo ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tí ó tọ́ nínú ọ̀ràn iṣẹ́ ológun àpàpàǹdodo?
◻ Kí ni àwọn nǹkan tí a lè fi sọ́kàn bí a bá pè wá fún iṣẹ́ àṣesìnlú, tí ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè ẹni, tí kì í sì í ṣe ti ológun?
◻ Ní ti Jehofa àti Kesari, kí ni a óò máa bá a nìṣó láti ṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn aposteli sọ fún ìgbìmọ̀ Sanhẹdirin pé: “Awa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn”