ORÍ KEJÌ
Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá
1, 2. Kí nìdí tí Bíbélì fi jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run tó ń múnú ẹni dùn?
BÁWO ló ṣe máa rí lára rẹ tí ọ̀rẹ́ rẹ bá fún ẹ ní ẹ̀bùn kan tó yà ẹ́ lẹ́nu? Ó máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o tètè mọ ohun tó wà níbẹ̀, inú rẹ á dùn pé ọ̀rẹ́ rẹ fi ẹ́ sọ́kàn, wàá sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
2 Bíbélì jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá ò lè rí níbòmíì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún wa pé Ọlọ́run ló dá ọ̀run àti ayé, òun ló sì dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Ó fún wa láwọn ìlànà tó lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Nínú Bíbélì, a tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa mú kí ayé yìí di ibi ìtura. Ẹ̀bùn tó ń múnú ẹni dùn gan-an mà ni Bíbélì o!
3. Kí lo máa mọ̀ bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3 Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá rí i pé Ọlọ́run fẹ́ kó o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Bó o ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ máa sún mọ́ ọn.
4. Kí ló wú ẹ lórí nípa Bíbélì?
4 Wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì sí èdè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (2,600), wọ́n sì ti tẹ ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù rẹ̀ jáde. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn tó wà láyé ló lè ka Bíbélì ní èdè wọn. Ó ju mílíọ̀nù kan Bíbélì táwọn èèyàn ń rí gbà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ká sòótọ́, kò sí ìwé míì tó dà bíi Bíbélì.
5. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé “Ọlọ́run mí sí” Bíbélì?
5 ‘Ọlọ́run ló mí sí’ Bíbélì. (Ka 2 Tímótì 3:16.) Àmọ́ àwọn kan lè sọ pé, ‘Ṣebí àwọn èèyàn ló kọ Bíbélì, báwo ló ṣe wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?’ Bíbélì dáhùn pé: “Àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn [tàbí tọ́ wọn sọ́nà].” (2 Pétérù 1:21) Ńṣe ló dà bí ìgbà tí ọkùnrin oníṣòwò kan bá sọ fún akọ̀wé rẹ̀ pé kó kọ lẹ́tà. Ta ló ni lẹ́tà náà? Ọkùnrin oníṣòwò yẹn ni, kì í ṣe akọ̀wé rẹ̀. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run ló ni Bíbélì kì í ṣe àwọn ọkùnrin tó lò láti kọ ọ́. Ọlọ́run ló darí wọn láti kọ èrò rẹ̀ sílẹ̀. Torí náà, “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni Bíbélì jẹ́.—1 Tẹsalóníkà 2:13; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 2.
BÍBÉLÌ PÉ
6, 7. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì bára mu?
6 Ó ju ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) ọdún lọ tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Àkókò tó yàtọ̀ síra làwọn tó kọ ọ́ gbé ayé. Àwọn kan kàwé gan-an nínú wọn, àmọ́ àwọn míì ò kàwé púpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan nínú wọn jẹ́ dókítà. Àwọn míì jẹ́ àgbẹ̀, apẹja, olùṣọ́ àgùntàn, wòlíì, onídàájọ́, àti ọba. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó kọ ọ́ yàtọ̀ síra, síbẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ló bára mu. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú orí kan kò ta ko èyí tó wà nínú orí míì.a
7 Àwọn orí tó ṣáájú nínú Bíbélì sọ bí ìṣòro aráyé ṣe bẹ̀rẹ̀, àwọn orí tó kẹ́yìn sì sọ bí Ọlọ́run ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro yẹn, tí ayé á sì di Párádísè. Bíbélì sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí aráyé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó tún fi hàn pé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn máa ṣẹ.
8. Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bá Bíbélì mu.
8 Bíbélì kì í ṣe ìwé tí èèyàn fi ń kẹ́kọ̀ọ́ sáyẹ́ǹsì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìwé ọmọ ilé ẹ̀kọ́, síbẹ̀ òótọ́ ni ohun tó sọ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Bó ṣe yẹ kí ìwé tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run rí nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Léfítíkù, Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n ṣe lè dènà àrùn kó má bàa tàn kálẹ̀. Tipẹ́tipẹ́, kí àwọn èèyàn tó mọ bí kòkòrò àrùn ṣe ń fa àìsàn ni ọ̀rọ̀ yìí ti wà lákọsílẹ̀. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ayé kò dúró lórí ohunkóhun. (Jóòbù 26:7) Bákan náà, nígbà kan ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ayé rí pẹrẹsẹ, àmọ́ Bíbélì sọ pé ayé rí roboto.—Àìsáyà 40:22.
9. Kí la rí kọ́ látinú bí àwọn tó kọ Bíbélì ṣe jẹ́ olóòótọ́?
9 Gbogbo ìtàn inú Bíbélì pátá ló jẹ́ òótọ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìwé ìtàn ni kò ṣeé gbára lé torí pé wọ́n máa ń fi àwọn òótọ́ ọ̀rọ̀ kan pa mọ́. Bí àpẹẹrẹ, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí àwọn ọ̀tá ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè wọn. Àmọ́, àwọn tó kọ Bíbélì jẹ́ olóòótọ́, kódà wọ́n sọ bí àwọn ọ̀tá ṣe ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Wọ́n tún sọ nípa àwọn àṣìṣe tiwọn fúnra wọn. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Nọ́ńbà, Mósè sọ àṣìṣe ńlá kan tó ṣe àti bí Ọlọ́run ṣe bá a wí. (Nọ́ńbà 20:2-12) Bí àwọn tó kọ Bíbélì ṣe jẹ́ olóòótọ́ yìí fi hàn pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá. Èyí sì fi hàn pé a lè gbára lé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.
ÌWÉ KAN TÍ ÌMỌ̀RÀN RERE KÚN INÚ RẸ̀
10. Kí nìdí tí ìmọ̀ràn Bíbélì fi wúlò fún wa lóde òní?
10 ‘Ọlọ́run mí sí Bíbélì, ó sì wúlò fún kíkọ́ni, fún bíbáni wí àti fún mímú nǹkan tọ́.’ (2 Tímótì 3:16) Òótọ́ ni, àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì wúlò fún wa lóde òní. Jèhófà mọ bó ṣe dá wa, torí bẹ́ẹ̀, ó lóye bá a ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wa. Ó mọ̀ wá ju bí a ṣe mọ ara wa lọ, ó sì fẹ́ ká láyọ̀. Ó mọ ohun tó lè ṣe wá láǹfààní àti ohun tó lè kó bá wa.
11, 12. (a) Àwọn ìmọ̀ràn rere wo ni Jésù fún wa nínú Mátíù orí 5 sí 7? (b) Àwọn nǹkan míì wo la tún lè kọ́ látinú Bíbélì?
11 Nínú Mátíù orí 5 sí 7, a kà nípa àwọn ìmọ̀ràn rere tí Jésù fún wa nípa bá a ṣe lè láyọ̀, bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn, bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà àti bá a ṣe lè ní èrò tó tọ́ nípa owó. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn ló fún wa ní àwọn ìmọ̀ràn yìí, síbẹ̀ wọ́n ṣì wúlò títí dòní.
12 Nínú Bíbélì, Jèhófà tún kọ́ wa ní àwọn ìlànà tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìdílé aláyọ̀, láti fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ àti bá a ṣe lè gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Àwọn ìlànà Bíbélì tún lè ràn wá lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà, láìka irú ẹni tá a jẹ́ sí, ibi yòówù ká máa gbé tàbí àwọn ìṣòro tá a ní.—Ka Àìsáyà 48:17; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 3.
ÀSỌTẸ́LẸ̀ BÍBÉLÌ MÁA Ń ṢẸ
13. Kí ni Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ìlú Bábílónì?
13 Ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ti ṣẹ báyìí. Bí àpẹẹrẹ, Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa Bábílónì run. (Àìsáyà 13:19) Ó ṣàlàyé bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun ìlú náà gẹ́lẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilẹ̀kùn gìrìwò àti odò ńlá ló dáàbò bo ìlú náà, Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé odò náà máa gbẹ, àwọn ilẹ̀kùn ìlú náà á sì wà ní ṣíṣí sílẹ̀. Àwọn ọ̀tá máa gba ìlú náà láìjagun rárá. Àìsáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kírúsì ló máa ṣẹ́gun Bábílónì.—Ka Àìsáyà 44:27–45:2; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 4.
14, 15. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà ṣe ṣẹ?
14 Ọgọ́rùn-ún méjì (200) ọdún lẹ́yìn tí Àìsáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà, àwọn ọmọ ogun dé láti gbógun ti Bábílónì. Ta ló kó àwọn ọmọ ogun náà wá? Bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe sọ, Kírúsì, ọba Páṣíà ni. Ní báyìí, ọ̀nà ti wá ṣí sílẹ̀ fún àwọn apá tó kù nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà láti ṣẹ.
15 Ní òru ọjọ́ tí wọ́n gbógun tì wọ́n, àwọn ará Bábílónì ń ṣe àríyá kan. Ọkàn wọn balẹ̀ torí pé àwọn ògiri gìrìwò àti odò ńlá ló yí ìlú wọn ká. Àmọ́, Kírúsì àti àwọn ọmọ ogún rẹ dọ́gbọ́n darí omi náà gba ibòmíì kí omi náà lè fà. Omi náà fà débi tí àwọn ọmọ ogun Páṣíà fi lè gba inú rẹ̀ kọjá. Àmọ́, báwo ni ògiri gìrìwò náà ò ṣe ní ṣèdíwọ́ fáwọn ọmọ ogun náà láti wọ ìlú Bábílónì? Bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe sọ, àwọn ilẹ̀kùn wọn wà ní ṣíṣí sílẹ̀, èyí jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun yẹn gba ìjọba ìlú náà láìjagun rárá.
16. (a) Kí ni Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì lọ́jọ́ iwájú? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà ṣẹ?
16 Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá yá, ẹnì kankan ò ní gbé ìlú Bábílónì mọ́ láé. Ó kọ̀wé pé: “Ẹnikẹ́ni ò ní gbé inú rẹ̀ mọ́ láé, kò sì sẹ́ni tó máa gbé ibẹ̀ láti ìran dé ìran.” (Àìsáyà 13:20) Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lóòótọ́? Lóde òní, ìlú Bábílónì àtijọ́ wà ní nǹkan bí àádọ́ta (50) máìlì sí apá gúúsù ìlú Baghdad ní orílẹ̀-èdè Ìráàkì, ìlú náà sì ti di àwókù lásán. Kódà títí dòní, kò sẹ́nì kankan tó ń gbé ibẹ̀. Jèhófà fi “ìgbálẹ̀ ìparun” gbá Bábílónì.—Àìsáyà 14:22, 23.b
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé gbogbo àwọn ìlérí Ọlọ́run ló máa ṣẹ?
17 Ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ti ṣẹ, torí náà, ó yẹ ká gbà pé gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la ló máa ṣẹ. Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa sọ ayé dí Párádísè. (Ka Nọ́ńbà 23:19.) Bẹ́ẹ̀ ni, à ń retí “ìyè àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè parọ́, ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́.”—Títù 1:2.c
BÍBÉLÌ LÈ YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ PA DÀ
18. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”?
18 A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kò sí ìwé tó dà bíi Bíbélì. Àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò ta kora, tó bá sì ń sọ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tàbí ọ̀rọ̀ ìtàn, ò máa ń jóòótọ́ nígbà gbogbo. Ó fún wa ní ìmọ̀ràn rere, ó tún sọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ. Àmọ́, àwọn ohun tí Bíbélì ń ṣe tún jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára.” Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?—Ka Hébérù 4:12.
19, 20. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe lè jẹ́ kó o mọ irú ẹni tó o jẹ́? (b) Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì ẹ̀bùn tó o rí gbà, ìyẹn Bíbélì?
19 Bíbélì lè yí ìgbésí ayé rẹ pa dà. Ó lè jẹ́ kó o mọ irú ẹni tó o jẹ́. Ó máa fi ohun tó wà lọ́kàn rẹ hàn, á sì jẹ́ kó o mọ bó ṣe yẹ kó o máa ronú. Bí àpẹẹrẹ, a lè gbà pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ tá a bá fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lóòótọ́, ó yẹ ká máa ṣe ohun tí Bíbélì sọ.
20 Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá lóòótọ́. Ó fẹ́ kó o máa kà á, kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kó o sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ẹ̀bùn yìí, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Ní orí tó kàn, a máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa kókó yìí.
a Àwọn kan sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì kò bára mu, àmọ́ ìyẹn kì í ṣe òótọ́. Wo orí 7 ìwé náà The Bible—God’s Word or Man’s? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, o lè ka ojú ìwé 27 sí 29 nínú ìwé náà Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
c Ìparun Bábílónì wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ṣẹ, o lè rí ìsọfúnni lórí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi nínú Àlàyé Ìparí Ìwé 5.