ÀLÀYÉ ÌPARÍ ÌWÉ
1 JÈHÓFÀ
Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, orúkọ náà sì túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Jèhófà ni Ọlọ́run Olódùmarè, òun ló dá ohun gbogbo. Ó ní àgbára láti ṣe ohun tó bá pinnu láti ṣe.
Lédè Hébérù, álífábẹ́ẹ̀tì mẹ́rin ni wọ́n fi ń kọ orúkọ Ọlọ́run. Lédè Gẹ̀ẹ́sì, àwọn álífábẹ́ẹ̀tì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n máa ń lò ni YHWH tàbí JHVH. Nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n kọ lédè Hébérù, orúkọ Ọlọ́run fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà. Kárí ayé, àwọn èèyàn máa ń kọ orúkọ náà Jèhófà ní oríṣiríṣi ọ̀nà, wọ́n sì máa ń pè é lọ́nà tí wọ́n sábà máa ń pè é ní èdè wọn.
2 ỌLỌ́RUN LÓ “MÍ SÍ” BÍBÉLÌ
Ọlọ́run ló ni Bíbélì, àmọ́ àwọn èèyàn ni ó lò láti kọ ọ́. Ó dà bí ìgbà tí ọ̀gá iléeṣẹ́ kan sọ pé kí akọ̀wé òun bá òun kọ lẹ́tà kan, tó sì sọ ohun tó máa kọ fún un. Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti darí àwọn tó kọ Bíbélì kí wọ́n lè kọ èrò rẹ̀ sínú Bíbélì. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà darí wọn. Nígbà míì, ó jẹ́ kí wọ́n rí ìran tàbí kí wọ́n lá àlá, kí wọ́n sì kọ wọ́n sílẹ̀.
3 ÌLÀNÀ
Ìlànà jẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ṣàlàyé òtítọ́ tí kì í yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ìlànà tó sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́” kọ́ wa pé irú àwọn èèyàn tí a bá yàn lọ́rẹ̀ẹ́ lè pinnu bóyá ìwà wa máa dára tàbí ó máa burú. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ìlànà míì tó sọ pé “ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká” kọ́ wa pé kò sí ohun tí èèyàn ṣe tí kò ní jèrè rẹ̀.—Gálátíà 6:7.
4 ÀSỌTẸ́LẸ̀
Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ àlàyé nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tàbí kó jẹ́ àṣẹ, ó sì lè jẹ́ ìdájọ́. Ó tún lè jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ló ti ṣẹ.
5 ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ NÍPA MÈSÁYÀ
Jésù ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa Mèsáyà ṣẹ sí lára. Wo àpótí náà “Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà.”
▸ Orí 2, ìpínrọ̀ 17, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
6 OHUN TÍ JÈHÓFÀ NÍ LỌ́KÀN TÓ FI DÁ AYÉ
Jèhófà dá ayé láti jẹ́ Párádísè tí àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ á máa gbé. Ohun tó ní lọ́kàn kò tíì yí pa dà. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa mú ìwà ibi kúrò, á sì fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìyè àìnípẹ̀kun.
7 SÁTÁNÌ ÈṢÙ
Sátánì ni áńgẹ́lì tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Òun ló di Sátánì, ìyẹn “Alátakò,” nítorí pé ó ń bá Jèhófà jà. Òun ló tún ń jẹ́ Èṣù tó túmọ̀ sí “Abanijẹ́.” Ìdí tí wọ́n fi pè é ní orúkọ yìí ni pé ó ń purọ́ mọ́ Ọlọ́run, ó sì ń tan àwọn èèyàn jẹ.
8 ÁŃGẸ́LÌ
Tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà ti dá àwọn áńgẹ́lì kó tó dá ayé. Ó dá wọn láti máa gbé ọ̀run. Iye àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run ju ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù (100,000,000) lọ. (Dáníẹ́lì 7:10) Orúkọ wọn àti ìwà wọn yàtọ̀ síra, àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ pé kí àwọn èèyàn má ṣe jọ́sìn àwọn. Àwọn áńgẹ́lì tún wà ní ipò tó yàtọ̀ síra wọn, iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì gbé fún wọn. Lára àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ni pé kí wọ́n máa wà níwájú ìtẹ́ Jèhófà, àwọn míì máa ń jíṣẹ́, àwọn kan máa ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà láyé, wọ́n sì ń darí wọn, àwọn míì máa ń mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ, àwọn kan sì máa ń ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn. (Sáàmù 34:7; Ìfihàn 14:6; 22:8, 9) Lọ́jọ́ iwájú, wọ́n máa dara pọ̀ mọ́ Jésù láti ja ogun Amágẹ́dọ́nì.—Ìfihàn 16:14, 16; 19:14, 15.
9 Ẹ̀ṢẸ̀
Ẹ̀ṣẹ̀ ni ohunkóhun tí Jèhófà kò fẹ́ tàbí tí kò bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó lè jẹ́ ohun kan tá a fẹ́, ohun tá a rò tàbí tá a ṣe. Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, Ọlọ́run fún wa ní àwọn òfin àti àwọn ìlànà tó máa jẹ́ ká lè sá fún mímọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀, pípé ni Jèhófà dá ohun gbogbo, àmọ́ nígbà tí Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà, wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì di aláìpé. Wọ́n darúgbó, wọ́n sì kú. Àwa náà ń darúgbó, a sì ń kú nítorí pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù.
10 AMÁGẸ́DỌ́NÌ
Amágẹ́dọ́nì ni ogun tí Ọlọ́run máa fi pa ayé Sátánì run àti gbogbo èèyàn burúkú.
11 ÌJỌBA ỌLỌ́RUN
Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan tí Jèhófà gbé kalẹ̀ ní ọ̀run. Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba náà. Lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa lo Ìjọba yìí láti mú gbogbo ìwà ibi kúrò. Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso lé ayé lórí.
12 JÉSÙ KRISTI
Jésù ni Ọlọ́run dá kó tó dá àwọn nǹkan míì. Jèhófà rán Jésù wá sáyé láti wá kú nítorí gbogbo èèyàn. Lẹ́yìn tí wọ́n pa Jésù, Jèhófà jí i dìde. Ní báyìí, Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run tó ń ṣàkóso ní ọ̀run.
13 ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÀÁDỌ́RIN Ọ̀SẸ̀
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí Mèsáyà máa dé. Èyí sì jẹ́ ní ìparí àkókò kan tí Bíbélì pè ní ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin (69), ọ̀sẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sì parí ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni.
Báwo la ṣe mọ̀ pé ọdún 29 Sànmánì Kristẹni ni ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin (69) náà parí sí? Ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin (69) náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí Nehemáyà dé sí Jerúsálẹ́mù, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tún ìlú náà kọ́. (Dáníẹ́lì 9:25; Nehemáyà 2:1, 5-8) Tá a bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ọ̀sẹ̀,” ohun tó máa ń wá sí wa lọ́kàn ni ọjọ́ méje. Àmọ́, ọ̀sẹ̀ tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí mẹ́nu kàn kì í ṣe ọ̀sẹ̀ ọlọ́jọ́ méje ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀sẹ̀ tó ṣàpẹẹrẹ ọdún méje, èyí sì bá àsọtẹ́lẹ̀ kan mu tó sọ pé “ọjọ́ kan fún ọdún kan.” (Nọ́ńbà 14:34; Ìsíkíẹ́lì 4:6) Èyí túmọ̀ sí pé ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọdún méje, torí náà ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin (69) máa jẹ́ 483 ọdún [ìyẹn 69 x 7]. Tá a bá ka 483 ọdún láti ọdún 455 ṣáájú Sànmàní Kristẹni, ó máa gbé wa dé ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. Ọdún yẹn gan-an ni Jésù ṣe ìrìbọmi, tó sì di Mèsáyà!—Lúùkù 3:1, 2, 21, 22.
Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún mẹ́nu kan ọ̀sẹ̀ kan míì tó ṣàpẹẹrẹ ọdún méje míì. Ní àárín ọ̀sẹ̀ kan yẹn, ìyẹn ọdún 33 Sànmàní Kristẹni, wọ́n máa pa Mèsáyà àti pé láti ọdún 36 Sànmánì Kristẹni, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run máa dé gbogbo orílẹ̀-èdè, kò ní mọ sọ́dọ̀ àwọn Júù nìkan.—Dáníẹ́lì 9:24-27.
14 Ẹ̀KỌ́ ÈKÉ NI MẸ́TALỌ́KAN
Bíbélì kọ́ wa pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa àti pé Jésù ló dá kó tó dá àwọn nǹkan míì. (Kólósè 1:15, 16) Jésù kọ́ ni Ọlọ́run Olódùmarè. Kò sọ pé òun bá Ọlọ́run dọ́gba rí. Kódà, ó sọ pé: “Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28; 1 Kọ́ríńtì 15:28) Àmọ́, àwọn ẹ̀sìn kan ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, wọ́n sọ pé ẹni mẹ́ta ló para pọ̀ di Ọlọ́run kan, ìyẹn Baba, Ọmọ, àti ẹ̀mí mímọ́. Ọ̀rọ̀ náà “Mẹ́talọ́kan” kò sí nínú Bíbélì. Ẹ̀kọ́ èké ni.
Ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́. Ó jẹ́ agbára tí kò ṣeé fojú rí tí Ọlọ́run ń lò láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́. Ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ “kún fún ẹ̀mí mímọ́,” Jèhófà tún sọ pé: “Èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi sára onírúurú èèyàn.”—Ìṣe 2:1-4, 17.
15 ÀGBÉLÉBÙÚ
Kí nìdí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í lo àgbélébùú nínú ìjọsìn Ọlọ́run?
Ọjọ́ pẹ́ tí ẹ̀sìn èké ti ń lo àgbélébùú. Nígbà àtijọ́, àwọn kèfèrí máa ń lò ó tí wọ́n bá ń jọ́sìn ohun tí Ọlọ́run dá tàbí nínú ààtò ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà tí wọ́n ń fi ìbálòpọ̀ ṣe. Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún lẹ́yìn ikú Jésù ni àwọn Kristẹni kò fi lo àgbélébùú rárá nínú ìjọsìn wọn. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Kọnsitatáìnì Olú Ọba Róòmù sọ àgbélébùú di àmì ẹ̀sìn Kristẹni. Wọ́n ń lo àmì yìí láti mú kí ẹ̀sìn Kristẹni túbọ̀ gbajúmọ̀. Àmọ́, àgbélébùú ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Jésù Kristi. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Wọ́n ti máa ń lo àgbélébùú láàárín àwọn èèyàn tó gbé ayé ṣáájú Sànmánì Kristẹni àtàwọn èèyàn tó gbé ayé nígbà tí Sànmánì Kristẹni bẹ̀rẹ̀.”
Kì í ṣe orí àgbélébùú ni Jésù kú sí. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “àgbélébùú” ṣàpẹẹrẹ “òpó igi tó dúró ṣánṣán,” “igi gẹdú” tàbí “igi.” Bíbélì The Companion Bible ṣàlàyé pé: “Kò sí ẹ̀rí kankan nínú [Májẹ̀mú Tuntun] ti èdè Gíríìkì tó fi hàn pé igi méjì tí wọ́n fi dábùú ara wọn ni. Orí òpó igi tó dúró ṣánṣán ni Jésù kú sí.
Jèhófà kò fẹ́ ká lo àwọn ère tàbí àmì nínú ìjọsìn wa. Ẹ́kísódù 20:4, 5; 1 Kọ́ríńtì 10:14.
16 ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa ṣe Ìrántí Ikú rẹ̀. Wọ́n máa ń ṣe é ní Nísàn 14 lọ́dọọdún, ìyẹn sì bọ́ sí ọjọ́ kan náà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Níbi Ìrántí Ikú Jésù, wọ́n máa ń gbé búrẹ́dì àti wáìnì tó ṣàpẹẹrẹ ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù dé ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan. Àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run ló máa jẹ nínú búrẹ́dì, tí wọ́n á sì mu nínú wáìnì náà. Àwọn tó nírètí láti máa gbé ayé títí láé kò ní jẹ búrẹ́dì, wọn kò sì ní mu wáìnì náà. Àmọ́, wọ́n máa wà níbi Ìrántí Ikú Jésù náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.
17 ỌKÀN
Nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” ni wọ́n lò láti ṣàpẹẹrẹ (1) èèyàn, (2) ẹranko, tàbí (3) ẹ̀mí èèyàn tàbí ti ẹranko. Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé:
Èèyàn. “Ní àwọn ọjọ́ Nóà . . . a gba àwọn èèyàn díẹ̀ là nígbà ìkún omi, ìyẹn ọkàn mẹ́jọ.” (1 Pétérù 3:20) Ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” níbí ń tọ́ka sí àwọn èèyàn, ìyẹn Nóà àti ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àtàwọn ìyàwó wọn.
Ẹ̀ranko. “Ọlọ́run sì sọ pé: ‘Kí àwọn ohun alààyè [“ọkàn,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé] máa gbá yìn-ìn nínú omi, kí àwọn ẹ̀dá tó ń fò sì máa fò lójú ọ̀run.’ Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run wá sọ pé: ‘Kí ilẹ̀ mú àwọn ohun alààyè [“ọkàn,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé] jáde ní irú tiwọn, àwọn ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹran tó ń rákò àti àwọn ẹran inú igbó ní irú tiwọn.’ Ó sì rí bẹ́ẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:20, 24.
Ẹ̀mí èèyàn tàbí ti ẹranko. Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Gbogbo àwọn tó fẹ́ pa ọ́ [“àwọn tó ń wá ọkàn rẹ,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé] ti kú.” (Ẹ́kísódù 4:19) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ pé: “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà; olùṣọ́ àgùntàn àtàtà máa ń fi ẹ̀mí rẹ̀ [“ọkàn,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé] lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.”—Jòhánù 10:11.
Yàtọ̀ síyẹn, tí ẹnì kan bá ṣe ohun kan pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ìyẹn túmọ̀ sí pé ó ṣe é tinútinú dé ibi tí agbára rẹ̀ gbé e dé. (Mátíù 22:37; Diutarónómì 6:5) Ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” tún lè tọ́ka sí ohun tẹ́nì kan nífẹ̀ẹ́ sí tàbí ohun tó wu èèyàn. Wọ́n tún lè lo ọ̀rọ̀ náà òkú ọkàn fún ẹni tó ti kú.—Nọ́ńbà 6:6; Òwe 23:2; Àìsáyà 56:11; Hágáì 2:13.
18 Ẹ̀MÍ
Ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì tí wọ́n lò fún “ẹ̀mí” nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lè túmọ̀ sí oríṣiríṣi nǹkan. Síbẹ̀ ó tọ́ka sí ohun kan tí kò ṣeé fojú rí, bí afẹ́fẹ́, èémí èèyàn tàbí ti ẹranko. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “ẹ̀mí” tún lè tọ́ka sí àwọn ẹni ẹ̀mí tàbí kó tọ́ka sí ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́. Bíbélì kò kọ́ni pé ohun kan lára èèyàn máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tẹ́ni náà bá kú.—Ẹ́kísódù 35:21; Sáàmù 104:29; Mátíù 12:43; Lúùkù 11:13.
19 GẸ̀HẸ́NÀ
Àfonífojì kan tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ń pè ní Gẹ̀hẹ́nà, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń dáná sun àwọn ìdọ̀tí, tí wọ́n á sì jóná pátápátá. Kò sí ẹ̀rí kankan pé láyé ìgbà Jésù wọ́n máa ń sun àwọn èèyàn tàbí ẹranko láàyè ní àfonífojì yẹn tàbí pé wọ́n ń dá wọn lóró. Torí náà, Gẹ̀hẹ́nà kò ṣàpẹẹrẹ ibi àìrí kan, tí wọ́n ti ń sun àwọn tó ti kú tàbí tí wọ́n ń dá wọn lóró títí láé. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n jù sínú Gẹ̀hẹ́nà, ńṣe ló ń fi ṣàpẹẹrẹ ìparun pátápátá.—Mátíù 5:22; 10:28.
20 ÀDÚRÀ OLÚWA
Àdúrà yìí ni Jésù gbà nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà. A tún máa ń pè é ní àdúrà Baba Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run tàbí àdúrà àwòkọ́ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà pé:
““Kí orúkọ rẹ di mímọ́”
À ń gbàdúrà pé kí Jèhófà mú gbogbo irọ́ tí wọ́n ti pa mọ́ orúkọ rẹ̀ àti òun fúnra rẹ̀ kúrò. Èyí á mú kí gbogbo àwọn tó wà lọ́run àti láyé máa bu ọ̀wọ̀ àti ọlá fún orúkọ Ọlọ́run.
“Kí Ìjọba rẹ dé”
À ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run pa ayé burúkú Sátánì yìí run, kí ó ṣàkóso lé ayé lórí, kó sì sọ ayé di Párádísè.
“Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé”
À ń gbàdúrà pé kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé ṣẹ, kí àwọn èèyàn pípé tí wọ́n jẹ́ onígbọràn lè máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí nígbà tó dá èèyàn.
21 ÌRÀPADÀ
Jèhófà pèsè ìràpadà láti gba aráyé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ìràpadà yìí jẹ́ iye tá a nílò láti fi ra ẹ̀mí èèyàn pípé pa dà, èyí tí Ádámù ẹni àkọ́kọ́ sọ nù. Iye yìí náà lá tún nílò láti tún àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ṣe. Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé láti kú nítorí gbogbo ẹlẹ́ṣẹ̀. Ikú Jésù ló mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn láti wà láàyè títí láé, kí wọ́n sì di ẹni pípé.
22 KÍ NÌDÍ TÍ ỌDÚN 1914 FI ṢE PÀTÀKÌ GAN-AN?
Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì orí 4 kọ́ wa pé Ọlọ́run máa gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lọ́dún 1914.
Àsọtẹ́lẹ̀ náà: Jèhófà fi ìran kan han Ọba Nebukadinésárì láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa igi ńlá kan tí wọ́n gé lulẹ̀. Nínú ìran náà, wọ́n fi ọ̀já irin àti bàbà de kùkùté igi náà kó má bàa hù títí “ìgbà méje” máa fi pé. Lẹ́yìn náà, igi náà yóò tún pa dà hù.—Dáníẹ́lì 4:1, 10-16.
Ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ náà túmọ̀ sí: Igi náà ṣàpẹẹrẹ àkóso Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà fi lo àwọn ọba ní Jerúsálẹ́mù láti máa ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (1 Kíróníkà 29:23) Àmọ́, àwọn ọba yẹn di aláìṣòótọ́, àkóso wọn sì dópin. Wọ́n sì pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọdún yẹn ni “ìgbà méje” bẹ̀rẹ̀. (2 Àwọn Ọba 25:1, 8-10; Ìsíkíẹ́lì 21:25-27) Nígbà tí Jésù sọ pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀, títí àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè fi máa pé,” “ìgbà méje” yẹn ló ń tọ́ka sí. (Lúùkù 21:24) Torí náà, “ìgbà méje” náà kò parí nígbà tí Jésù wà láyé. Jèhófà ṣèlérí láti yan Ọba kan ní òpin “ìgbà méje” náà. Àkóso Jésù, tó jẹ́ Ọba tuntun náà máa mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé títí láé.—Lúùkù 1:30-33.
Bí “ìgbà méje” náà ṣe gùn tó: “Ìgbà méje” náà jẹ́ 2,520 ọdún. Tá a bá ka 2,520 ọdún láti ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó máa parí sí ọdún 1914. Ọdún yẹn gan-an ni Jèhófà sọ Jésù tó jẹ́ Mèsáyà di Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run.
Báwo la ṣe rí nọ́ńbà náà 2,520? Bíbélì sọ pé àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ jẹ́ 1,260 ọjọ́. (Ìfihàn 12:6, 14) Torí náà, “ìgbà méje” náà máa jẹ́ ìlọ́po méjì nọ́ńbà yẹn, ìyẹn 2,520 ọjọ́. Nítorí ìlànà àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé “ọjọ́ kan fún ọdún kan,” 2,520 ọjọ́ máa wá jẹ́ 2,520 ọdún.—Nọ́ńbà 14:34; Ìsíkíẹ́lì 4:6.
23 MÁÍKẸ́LÌ OLÚ ÁŃGẸ́LÌ
Ọ̀rọ̀ náà “olú áńgẹ́lì” túmọ̀ sí “olórí àwọn áńgẹ́lì.” Olú áńgẹ́lì kan ṣoṣo ni Bíbélì mẹ́nu kàn, orúkọ rẹ̀ sì ni Máíkẹ́lì.—Dáníẹ́lì 12:1; Júùdù 9.
Máíkẹ́lì ni Olórí àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ogun Ọlọ́run. Ìfihàn 12:7 sọ pé: “Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà . . . àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jà.” Ìwé Ìfihàn sọ pé Jésù ni Olórí àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run, torí náà, Máíkẹ́lì ni orúkọ míì tí Jésù ń jẹ́.—Ìfihàn 19:14-16.
24 ỌJỌ́ ÌKẸYÌN
Ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí àkókò kan tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó lágbára máa ṣẹlẹ̀ láyé kí Ìjọba Ọlọ́run tó pa ayé Sátánì yìí run. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, wọ́n tún lo àwọn gbólóhùn tó jọ ọ́, irú bí “ìparí ètò àwọn nǹkan” àti ìgbà “tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín,” àwọn ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ka sí ọjọ́ ìkẹyìn. (Mátíù 24:3, 27, 37) “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run lọ́dún 1914, ó sì máa parí nígbà tí ayé Sátánì yìí bá pa run ní Amágẹ́dọ́nì.—2 Tímótì 3:1; 2 Pétérù 3:3.
25 ÀJÍǸDE
Tí Ọlọ́run bá jí ẹnì kan tó ti kú dìde, ìyẹn là ń pè ní àjíǹde. Àjíǹde mẹ́sàn-án ni Bíbélì mẹ́nu kàn. Èlíjà, Èlíṣà, Jésù, Pétérù àti Pọ́ọ̀lù jí èèyàn dìde. Agbára Ọlọ́run nìkan ló mú kí wọ́n lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa jí “àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” dìde sí ayé. (Ìṣe 24:15) Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde sí ọ̀run. Èyí máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn tí Ọlọ́run yàn tàbí tó fi òróró yàn bá jíǹde sí ọ̀run láti máa bá Jésù gbé.—Jòhánù 5:28, 29; 11:25; Fílípì 3:11; Ìfihàn 20:5, 6.
26 Ẹ̀MÍ ÈṢÙ (ÌBẸ́MÌÍLÒ)
Bíbá ẹ̀mí èṣù lò tàbí ìbẹ́mìílò jẹ́ àṣà búburú tó dá lórí kéèyàn máa bá àwọn ẹ̀mí èṣù sọ̀rọ̀, bóyá ní tààràtà tàbí nípasẹ̀ ẹlòmíì, irú bíi babaláwo, woṣẹ́woṣẹ́ tàbí aríran. Ìdí táwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n gba ẹ̀kọ́ èké náà gbọ́ pé tẹ́nì kan bá kú, ẹ̀mí ẹni yẹn máa ń kúrò, á sì di ẹbọra alágbára. Àwọn ẹ̀mí èṣù tún máa ń mú kí àwọn èèyàn ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ara àṣà bíbá ẹ̀mí èṣù da nǹkan pọ̀ tún ni wíwo ìràwọ̀, wíwoṣẹ́, idán pípa, ṣíṣe àjẹ́, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, ẹgbẹ́ òkùnkùn àti lílo agbára abàmì. Ọ̀pọ̀ ìwé, ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé tí wọ́n fi ń wo ọjọ́ ọ̀la èèyàn, fíìmù, àwòrán tàbí orin máa ń mú kí ìbẹ́mìílò, idán pípa àti agbára abàmì dà bí ohun tí kò lè pani lára, tó sì ń gbádùn mọ́ni. Àwọn nǹkan míì tó tún lè mú kéèyàn bá àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù da nǹkan pọ̀ ni ọ̀pọ̀ àṣà ìsìnkú, irú bí ètùtù òkú, ayẹyẹ ìsìnkú, ayẹyẹ òkú ẹ̀gbẹ, ààtò ṣíṣe opó àti ṣíṣe àìsùn òkú. Àwọn èèyàn tiẹ̀ máa ń lo oògùn olóró nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gba agbára ẹ̀mí èṣù.—Gálátíà 5:20; Ìfihàn 21:8.
27 JÈHÓFÀ NI ỌBA ALÁṢẸ AYÉ ÀTỌ̀RUN
Jèhófà ni Ọlọ́run Olódùmarè, òun ló sì dá ayé àti ọ̀run. (Ìfihàn 15:3) Torí náà, òun ló ni ohun gbogbo, òun sì ni Ọba Aláṣẹ tó ń ṣàkóso gbogbo ohun tí ó dá. (Sáàmù 24:1; Àìsáyà 40:21-23; Ìfihàn 4:11) Ó ṣe òfin fún gbogbo ohun tó dá. Jèhófà ló tún ní àṣẹ láti yan àwọn míì láti jẹ́ alákòóso. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tá a sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu, a fi hàn pé à ń tì í lẹ́yìn pé òun ni Ọba Aláṣẹ.—1 Kíróníkà 29:11.
28 ÌṢẸ́YÚN
Ìṣẹ́yún ni kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ pa ọmọ inú oyún. Ó yàtọ̀ sí kí ọmọ ṣèèṣì kú nítorí jàǹbá kan tàbí nítorí pé ara aláboyún ṣiṣẹ́ gbòdì. Látìgbà tí obìnrin bá ti lóyún ọmọ kan, ọmọ náà ti di alààyè nìyẹn, kì í ṣe apá kan ara aláboyún náà.
29 GBÍGBA Ẹ̀JẸ̀ SÁRA
Ó jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n máa ń gbà tọ́jú ara, tí wọ́n máa ń fa odindi ẹ̀jẹ̀ síni lára tàbí kí wọ́n fa èyíkéyìí nínú apá mẹ́rin tí ẹ̀jẹ̀ pín sí síni lára látinú ara ẹlòmíì tàbí láti ibi tí wọ́n tọ́jú ẹ̀jẹ̀ sí. Apá mẹ́rin tí ẹ̀jẹ̀ pín sí ni omi inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ àti sẹ́ẹ̀lì tó ń mú ẹ̀jẹ̀ dì.
30 ÌBÁWÍ
Ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú Bíbélì láti fí túmọ̀ “ìbáwí” kì í kan ṣe ọ̀rọ̀ míì tá a lè pè ní ìyà. Tí wọ́n bá bá wa wí, wọ́n máa ń tọ́ wa sọ́nà, wọ́n máa ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì máa ń tún èrò wa ṣe. Jèhófà kì í búni, kì í sì í báni wí lọ́nà tó le koko. (Òwe 4:1, 2) Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jèhófà jẹ́ fún àwọn òbí. Ìbáwí tó bá fúnni máa ń gbéṣẹ́ débi pé ẹni náà á wá fẹ́ràn ìbáwí yẹn. (Òwe 12:1) Jèhófà fẹ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì máa ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ó máa ń tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n lè tún èrò wọn ṣe, kí wọ́n sì lè kọ́ bí èrò àti ìwà wọn ṣe lè bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Ara ìbáwí táwọn òbí ní láti fún àwọn ọmọ wọn ni pé kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n lóye ìdí tó fi yẹ kí wọ́n jẹ́ onígbọràn. Wọ́n tún ní láti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, láti nífẹ̀ẹ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti láti lóye àwọn ìlànà inú rẹ̀.
31 Ẹ̀MÍ ÈṢÙ
Wọ́n jẹ́ ẹ̀mí burúkú, wọ́n lágbára gan-an ju èèyàn lọ, a ò sì lè rí wọn. Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí jẹ́ áńgẹ́lì burúkú. Àìgbọràn tí wọ́n ṣe sí Ọlọ́run ni wọ́n fi di ọ̀tá rẹ̀, tí wọ́n sì di ẹ̀mí burúkú. (Jẹ́nẹ́sísì 6:2; Júùdù 6) Wọ́n dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ọ̀tẹ̀ tó ń ṣe sí Jèhófà.—Diutarónómì 32:17; Lúùkù 8:30; Ìṣe 16:16; Jémíìsì 2:19.