Àìsáyà
44 “Wá fetí sílẹ̀, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi
Àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo yàn.+
5 Ẹnì kan máa sọ pé: “Ti Jèhófà ni mí.”+
Ẹlòmíì máa fi orúkọ Jékọ́bù pe ara rẹ̀,
Ẹlòmíì sì máa kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀ pé: “Ti Jèhófà.”
Á sì máa jẹ́ orúkọ Ísírẹ́lì.’
‘Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn.+
Kò sí Ọlọ́run kankan àfi èmi.+
Kó pè, kó sọ ọ́, kó sì fi ẹ̀rí hàn mí!+
Látìgbà tí mo ti gbé àwọn èèyàn àtijọ́ kalẹ̀,
Jẹ́ kí wọ́n sọ àwọn ohun tó ń bọ̀
Àti ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀.
Ṣebí mo ti sọ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ṣáájú, tí mo sì kéde rẹ̀?
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi.+
Ṣé Ọlọ́run kankan wà yàtọ̀ sí mi ni?
Rárá, kò sí Àpáta míì;+ mi ò mọ ìkankan.’”
9 Gbogbo àwọn tó ń ṣe ère gbígbẹ́ ò já mọ́ nǹkan kan,
Àwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí kò ní ṣàǹfààní rárá.+
Bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí wọn, wọn* ò rí nǹkan kan, wọn ò sì mọ nǹkan kan,+
Torí náà, ojú máa ti àwọn tó ṣe wọ́n.+
10 Ta ló máa ṣe ọlọ́run tàbí kó ṣe ère onírin*
Tí kò lè ṣàǹfààní rárá?+
11 Wò ó! Ojú máa ti gbogbo àwọn alájọṣe rẹ̀!+
Èèyàn lásán ni àwọn oníṣẹ́ ọnà.
Kí gbogbo wọn kóra jọ, kí wọ́n sì dúró.
Jìnnìjìnnì máa bò wọ́n, ojú sì máa tì wọ́n pa pọ̀.
12 Alágbẹ̀dẹ ń fi irinṣẹ́ rẹ̀* lu irin lórí ẹyin iná.
Ó ń fi àwọn òòlù ṣe é,
Ó ń fi apá rẹ̀ tó lágbára ṣe é.+
Ebi wá ń pa á, okun sì tán nínú rẹ̀;
Kò mu omi, ó sì ti rẹ̀ ẹ́.
13 Agbẹ́gi na okùn ìdíwọ̀n, ó fi ẹfun pupa sàmì sí i.
Ó fi ìfági fá a, ó sì fi kọ́ńpáàsì sàmì sí i.
14 Ẹnì kan wà tó jẹ́ pé iṣẹ́ rẹ̀ ni kó máa gé igi kédárì lulẹ̀.
Ó gbin igi lọ̀rẹ́ẹ̀lì, òjò sì mú kó dàgbà.
15 Ó wá di ohun tí èèyàn lè fi dáná.
Ó mú lára rẹ̀, ó sì fi yáná;
Ó dá iná, ó sì yan búrẹ́dì.
Àmọ́ ó tún ṣe ọlọ́run kan, ó sì ń sìn ín.
Ó fi ṣe ère gbígbẹ́, ó sì ń forí balẹ̀ fún un.+
16 Ó fi iná sun ìdajì rẹ̀;
Ìdajì yẹn ló fi yan ẹran tó ń jẹ, ó sì yó.
Ó tún yáná, ó wá sọ pé:
“Áà! Ara mi ti móoru bí mo ṣe ń wo iná yìí.”
17 Àmọ́ ó fi èyí tó ṣẹ́ kù ṣe ọlọ́run, ó fi ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ̀.
Ó ń forí balẹ̀ fún un, ó sì ń sìn ín,
Ó ń gbàdúrà sí i, ó sì ń sọ pé:
“Gbà mí, torí ìwọ ni ọlọ́run mi.”+
18 Wọn ò mọ nǹkan kan, wọn ò lóye nǹkan kan,+
Torí a ti lẹ ojú wọn pa, wọn ò sì lè ríran,
Ọkàn wọn ò sì ní ìjìnlẹ̀ òye.
19 Kò sí ẹni tó rò ó nínú ọkàn rẹ̀,
Tó ní ìmọ̀ tàbí òye, pé:
“Mo ti dáná sun ìdajì rẹ̀,
Ẹyin iná rẹ̀ ni mo fi yan búrẹ́dì, tí mo sì fi yan ẹran tí màá jẹ.
Ṣé ó wá yẹ kí n fi èyí tó kù ṣe ohun ìríra?+
Ṣé ó yẹ kí n máa sin ìtì igi* tí mo gé lára igi?”
20 Ó ń jẹ eérú.
Ọkàn rẹ̀ tí wọ́n ti tàn jẹ ti kó o ṣìnà.
Kò lè gba ara* rẹ̀, kì í sì í sọ pé:
“Ṣé irọ́ kọ́ ló wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí?”
21 “Rántí àwọn nǹkan yìí, ìwọ Jékọ́bù àti ìwọ Ísírẹ́lì,
Torí pé ìránṣẹ́ mi ni ọ́.
Èmi ni mo dá ọ, ìránṣẹ́ mi sì ni ọ́.+
Ìwọ Ísírẹ́lì, mi ò ní gbàgbé rẹ.+
22 Màá nu àwọn àṣìṣe rẹ kúrò bíi pé mo fi ìkùukùu* nù ún,+
Màá sì nu àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò bíi pé mo fi àwọsánmà tó ṣú bolẹ̀ nù ún.
Pa dà sọ́dọ̀ mi, torí màá tún ọ rà.+
23 Ẹ kígbe ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run,
Torí Jèhófà ti ṣe nǹkan kan!
Ẹ kígbe ìṣẹ́gun, ẹ̀yin ibi tó jìn ní ilẹ̀!
Ẹ kígbe ayọ̀, ẹ̀yin òkè,+
Ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín!
Torí Jèhófà ti tún Jékọ́bù rà,
Ó sì ń fi ẹwà rẹ̀ hàn lára Ísírẹ́lì.”+
“Èmi ni Jèhófà, ẹni tó dá ohun gbogbo.
Ta ló wà pẹ̀lú mi?
25 Màá mú kí iṣẹ́ àmì àwọn tó ń sọ̀rọ̀ asán* já sí pàbó,
Èmi sì ni Ẹni tó ń mú kí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ máa ṣe bí òpònú;+
Ẹni tó ń da nǹkan rú mọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n lójú,
Tó sì ń sọ ìmọ̀ wọn di ti òmùgọ̀;+
26 Ẹni tó ń mú kí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ,
Tó sì ń mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ délẹ̀délẹ̀;+
Ẹni tó ń sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé, ‘Wọ́n máa gbé inú rẹ̀’+
Àti nípa àwọn ìlú Júdà pé, ‘Wọ́n máa tún wọn kọ́,+
Màá sì mú kí àwọn ibi tó ti dahoro níbẹ̀ pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀’;+
27 Ẹni tó ń sọ fún ibú omi pé, ‘Gbẹ,
Màá sì mú kí gbogbo odò rẹ gbẹ táútáú’;+
28 Ẹni tó ń sọ nípa Kírúsì+ pé, ‘Òun ni olùṣọ́ àgùntàn mi,
Ó sì máa ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́ délẹ̀délẹ̀’;+
Ẹni tó ń sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé, ‘Wọ́n máa tún un kọ́’
Àti nípa tẹ́ńpìlì pé, ‘Wọ́n máa fi ìpìlẹ̀ rẹ lélẹ̀.’”+