“Ẹ Máa Wádìí Ohun Tí Ẹ̀yin Fúnra Yín Jẹ́”
“Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 13:5.
1, 2. (a) Tí àwọn ohun tá a gbà gbọ́ kò bá dá wa lójú, àkóbá wo ló lè ṣe fún wa? (b) Kí lohun tó wáyé ní ọ̀rúndún kìíní nílùú Kọ́ríńtì tó ṣeé ṣe kó mú káwọn kan máa ṣiyèméjì nípa ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa tọ̀?
FOJÚ inú wò ó pé ọkùnrin kan ń gba ojú ọ̀nà kan lọ ní àgbègbè àrọko kan títí ó fi dé ìkóríta kan. Kò mọ èyí tó lọ síbi tó ń lọ nínú àwọn ọ̀nà tó jáde sí ìkóríta náà, ló bá béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń kọjá lọ, àmọ́ ọ̀rọ̀ wọn kò bára mu. Ọkùnrin náà ò mọ èyí tóun ì bá ṣe nítorí pé ọ̀nà tó yẹ kó gbà ò dá a lójú, ló bá di pé kò lè lọ mọ́. Àpèjúwe yìí jẹ́ ká mọ̀ pé a lè má mọ ohun tó yẹ ká ṣe táwọn ohun tá a gbà gbọ́ ò bá dá wa lójú. Tí ọ̀ràn bá sì wá lọ rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe ká má lè ṣèpinnu tó ṣe gúnmọ́, ọ̀nà tó yẹ ká tọ̀ sì lè má dá wa lójú mọ́.
2 Ohun kan wáyé ní ọ̀rúndún kìíní nílùú Kọ́ríńtì lórílẹ̀-èdè Gíríìsì tí ì bá ṣàkóbá fáwọn kan nínú ìjọ Kristẹni tó wà níbẹ̀. ‘Àwọn àpọ́sítélì adárarégèé’ ò fẹ́ gbà pé Pọ́ọ̀lù jẹ́ àpọ́sítélì, wọ́n sọ pé: “Àwọn lẹ́tà rẹ̀ wúwo, wọ́n sì lágbára, ṣùgbọ́n wíwàníhìn-ín òun alára jẹ́ aláìlera, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ní láárí.” (2 Kọ́ríńtì 10:7-12; 11:5, 6) Ó ṣeé ṣe kí irú ọ̀rọ̀ yẹn ti mú káwọn kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì máa ṣiyèméjì nípa ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa tọ̀.
3, 4. Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kọ́ríńtì?
3 Ìgbà tí Pọ́ọ̀lù lọ sílùú Kọ́ríńtì lọ́dún 50 Sànmánì Kristẹni ló dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀. Ó gbé ní Kọ́ríńtì fún “ọdún kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàárín wọn.” Àní, “ọ̀pọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì tí wọ́n . . . gbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbà gbọ́, a sì ń batisí wọn.” (Ìṣe 18:5-11) Ipò tẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù tí wọ́n ń gbé nílùú Kọ́ríńtì jẹ Pọ́ọ̀lù lógún gan-an ni. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará Kọ́ríńtì ti kọ lẹ́tà sí Pọ́ọ̀lù pé kó fún wọn nímọ̀ràn lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan. (1 Kọ́ríńtì 7:1) Pọ́ọ̀lù sì fún wọn nímọ̀ràn tó jíire.
4 Nínú ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sí wọn, ó sọ pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Ká ní àwọn arákùnrin tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ni, wọn ì bá má ti ṣiyèméjì nípa ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa tọ̀. Ìmọ̀ràn yẹn kan náà lè ṣe wá láǹfààní lónìí pẹ̀lú. Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀nà wo la lè gbà fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò? Báwo la ṣe lè dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́? Kí làwọn nǹkan tá a lè ṣe láti fi hàn pé à ń wádìí ohun tí àwa fúnra wa jẹ́?
“Ẹ Máa Dán Ara Yín Wò Bóyá Ẹ Wà Nínú Ìgbàgbọ́”
5, 6. Ìlànà wo la ní tá a lè máa fi dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́, kí sì nìdí tí ìlànà ọ̀hún fi bá a mu gẹ́ẹ́?
5 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ ìdánwò, ẹnì kan tàbí ohun kan gbọ́dọ̀ wà tá a máa dán wò, ìlànà kan sì gbọ́dọ̀ wà tá a máa tẹ̀ lé. Àmọ́, nínú ìdánwò tí Pọ́ọ̀lù ń sọ yìí, kì í ṣe ìgbàgbọ́ wa, ìyẹn àpapọ̀ àwọn ohun tá a gbà gbọ́, la fẹ́ dán wò. Àwa gan-an ni ìdánwò náà dá lé lórí. Ìlànà pípé sì wà tá a máa tẹ̀ lé láti fi dán ara wa wò. Àwọn ọ̀rọ̀ kan tí Dáfídì onísáàmù fi kọrin sọ pé: “Òfin Jèhófà pé, ó ń mú ọkàn padà wá. Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n. Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.” (Sáàmù 19:7, 8) Àwọn òfin Jèhófà tó pé, àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ̀ tó dúró ṣánṣán, àwọn ìránnilétí rẹ̀ tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, àtàwọn àṣẹ rẹ̀ tó mọ́ wà nínú Bíbélì. Nítorí náà, àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ni ìlànà tó bá a mu gẹ́ẹ́ tó yẹ ká tẹ̀ lé tá a bá fẹ́ dán ara wa wò.
6 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè dán ọkàn wa wò, ìyẹn irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Kí ló yẹ ká ṣe láti lè máa fi àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tó ń wọni lọ́kàn tó sì ń múni ronú jinlẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa? Onísáàmù náà sọ bá a ṣe lè ṣe é fún wa ní kedere. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí . . . inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, [tí] ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.” (Sáàmù 1:1, 2) Inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti lè rí “òfin Jèhófà.” Ó yẹ ká fẹ́ràn kíka Ọ̀rọ̀ Jèhófà. Àní, a ní láti ya àkókò sọ́tọ̀ tí a ó máa fi ohùn jẹ́jẹ́ kà á, tí a ó sì máa ṣàṣàrò nínú rẹ̀. Bá a sì ṣe ń ṣe èyí, a ní láti máa fi àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yẹ ara wa wò.
7. Kí ni olórí ọ̀nà tá a lè gbà dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́?
7 Olórí ọ̀nà tá a lè gbà dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́ ni pé ká máa ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà nínú rẹ̀, ká sì máa yẹ ìwà wa wò bóyá ó bá àwọn ohun tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mu. Ó sì dùn mọ́ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó lè jẹ́ ká túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
8. Báwo làwọn ìwé tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń tẹ̀ jáde ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́?
8 Jèhófà ti pèsè àwọn ẹ̀kọ́ àti ìtọ́ni nípasẹ̀ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń tẹ̀ jáde. (Mátíù 24:45) Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò” tó wà lápá ìparí ọ̀pọ̀ orí nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà.a Ẹ ò rí i pé àwọn ìbéèrè yìí fún wa ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti máa ṣe àṣàrò! Onírúurú ẹ̀kọ́ tí Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ń gbé jáde ń ràn wá lọ́wọ́ pẹ̀lú láti dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́. Nígbà tí arábìnrin kan ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àpilẹ̀kọ kan tó ṣàlàyé ìwé Òwe tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí nínú Ilé Ìṣọ́, ó ní: “Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà wúlò fún mi gan-an ni. Àwọn àpilẹ̀kọ náà jẹ́ kí n lè yẹ ara mi wò láti mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ìwà tí mò ń hù àti ìṣesí mi bá àwọn ìlànà òdodo Jèhófà mu.”
9, 10. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ń pèsè fún wa ká lè máa fi dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́?
9 A tún máa ń gba ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtọ́ni àti ọ̀rọ̀ ìyànjú láwọn ìpàdé ìjọ, ìpàdé àyíká àti ìpàdé àgbègbè. Àwọn ìpàdé wọ̀nyí wà lára àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Ọlọ́run ń pèsè fáwọn tí Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀. Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, . . . òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’” (Aísáyà 2:2, 3) Ìbùkún gbáà ló jẹ́ láti máa rí irú àwọn ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ gbà nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà.
10 Ohun mìíràn tá a tún lè máa fi dán ara wa wò ni ìmọ̀ràn táwọn tó tóótun nípa tẹ̀mí ń fúnni, irú bí àwọn alàgbà nínú ìjọ. Bíbélì sọ nípa wọn pé: “Ẹ̀yin ará, bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù, bí olúkúlùkù yín ti ń ṣọ́ ara rẹ̀ lójú méjèèjì, kí a má bàa dẹ ìwọ náà wò.” (Gálátíà 6:1) Inú wa mà dùn gan-an o pé Jèhófà pèsè irú nǹkan báyìí láti fi tọ́ wa sọ́nà!
11. Tá a bá fẹ́ dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́, kí ló yẹ ká ṣe?
11 Ẹ̀bùn àgbàyanu tó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá ni àwọn ìwé wa, àwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn ọkùnrin tá a yàn sípò jẹ́. Àmọ́ tá a bá fẹ́ dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́, a ní láti máa ṣe àyẹ̀wò ara wa. Nítorí náà, nígbà tá a bá ń ka àwọn ìwé wa tàbí tá à ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú látinú Ìwé Mímọ́, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ irú èèyàn tí ohun tí mò ń kà yìí tàbí ohun tí mò ń gbọ́ yìí ń sọ ni mí? Ṣé ohun tí mò ń ṣe nìyẹn? Ǹjẹ́ mò ń gbé ìgbé ayé mi lọ́nà tó bá àwọn ohun táwa Kristẹni gbà gbọ́ mu?’ Ohun tá a bá ṣe nípa àwọn ìsọfúnni tá à ń gbà nípasẹ̀ àwọn ohun tí Jèhófà pèsè wọ̀nyí ló máa sọ bóyá a jẹ́ ẹni tẹ̀mí lóòótọ́. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn ti ara kì í gba àwọn nǹkan ti ẹ̀mí Ọlọ́run, nítorí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni wọ́n jẹ́ lójú rẹ̀. . . . Àmọ́ ṣá o, ènìyàn ti ẹ̀mí ní tòótọ́ a máa wádìí ohun gbogbo wò.” (1 Kọ́ríńtì 2:14, 15) Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa fojú tẹ̀mí wo àwọn ohun tá à ń kà nínú àwọn ìwé ńlá wa, àwọn ìwé ìròyìn wa, àtàwọn ìwé mìíràn tí ètò Ọlọ́run ń tẹ̀ jáde àti ọ̀rọ̀ tá à ń gbọ́ nípàdé àti lẹ́nu àwọn alàgbà ká sì fi hàn pé a mọrírì wọn?
“Ẹ Máa Wádìí Ohun Tí Ẹ̀yin Fúnra Yín Jẹ́”
12. Kí ló yẹ ká ṣe láti fi hàn pé à ń wádìí ohun tí àwa fúnra wa jẹ́?
12 Láti lè wádìí ohun tí àwa fúnra wa jẹ́, olúkúlùkù wa ní láti ṣe àyẹ̀wò ara rẹ̀. A lè wà nínú òtítọ́, àmọ́ ṣé à ń fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá à ń kọ́ ṣèwà hù? Láti fi hàn pé à ń wádìí ohun tí àwa fúnra wa jẹ́, a ní láti máa ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé a dàgbà dénú nípa tẹ̀mí, a sì tún ní láti fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìpèsè tẹ̀mí.
13. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Hébérù 5:14 sọ, kí ló máa fi hàn pé a dàgbà dénú?
13 Kí ni ẹ̀rí tó ń fi hàn pé èèyàn dàgbà dénú nípa tẹ̀mí tó yẹ ká wò bóyá a ní? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a dàgbà dénú ni pé ká máa kọ́ agbára ìwòye wa. Bí àwọn tó ń sáré ìje ṣe ní láti fi eré sísá kọ́ra kí wọ́n tó lè mókè nínú eré sísá, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe ní láti kọ́ agbára ìwòye wa, ìyẹn ni pé ká máa lò ó láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò.
14, 15. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá gidigidi láti máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
14 Àmọ́ ṣá o, ká tó lè kọ́ agbára ìwòye wa, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ní ìmọ̀. Ìdí nìyí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa dá kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. Tí a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ nígbà gbogbo, pàápàá lórí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, agbára ìwòye wa á túbọ̀ mú hánhán. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni Ilé Ìṣọ́ ti máa ń gbé àwọn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ jáde. Kí la máa ń ṣe nígbà tá a bá rí àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀? Ǹjẹ́ a máa ń sá fún wọn nítorí pé “àwọn ohun kan tí ó nira láti lóye wà nínú wọn”? (2 Pétérù 3:16) Dípò tí a óò fi máa ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa sapá gidigidi láti lóye ohun tó wà nínú wọn.—Éfésù 3:18.
15 Tó bá wá ṣòro fún wa láti dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ńkọ́? Á dára ká gbìyànjú láti nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, ká sì jẹ́ kó mọ́ wa lára.b (1 Pétérù 2:2) Ìdí ni pé ká tó lè dàgbà dénú nípa tẹ̀mí, a ní láti máa jẹ oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí, ìyẹn àwọn ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, agbára ìwòye wa ò ní ju bó ṣe wà lọ. Àmọ́ o, kì í ṣe ká ní agbára ìwòye nìkan ló máa fi hàn pé a dàgbà dénú. A ní láti máa fi àwọn ohun tá à ń kọ́ nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa sílò nínú ohun gbogbo tá a bá ń ṣe lójoojúmọ́.
16, 17. Ìmọ̀ràn wo ni Jákọ́bù, ọmọ ẹ̀yìn Jésù, fúnni nípa bá a ṣe lè di “olùṣe ọ̀rọ̀ náà”?
16 A tún lè rí ẹ̀rí nípa ohun tí àwa fúnra wa jẹ́ nínú àwọn ohun tá à ń ṣe láti fi hàn pé a mọrírì òtítọ́, ìyẹn àwọn iṣẹ́ ìgbàgbọ́ wa. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn lo àpèjúwe kan tó ń múni ronú jinlẹ̀ láti ṣàlàyé bá a ṣe lè ṣe àyẹ̀wò ara wa, ó ní: “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan, ní fífi èrò èké tan ara yín jẹ. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò sì jẹ́ olùṣe, ẹni yìí dà bí ènìyàn tí ń wo ojú àdánidá rẹ̀ nínú dígí. Nítorí ó wo ara rẹ̀, ó sì lọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbàgbé irú ènìyàn tí òun jẹ́. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà, yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.”—Jákọ́bù 1:22-25.
17 Ohun tí Jákọ́bù ń sọ nínú ẹsẹ yẹn ni pé: ‘Fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàyẹ̀wò ara rẹ dáadáa bí ìgbà téèyàn ń wo dígí. Má ṣe dẹ́kun ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kó o sì máa fi àwọn ohun tó o kà nínú Bíbélì wo ibi tó bá yẹ kó o ti ṣàtúnṣe. Má sì ṣe gbàgbé ohun tó o rí. Ṣe àtúnṣe tó yẹ.’ Nígbà míì, ó lè má rọrùn láti ṣe àyẹ̀wò yìí.
18. Kí ló mú kó ṣòro láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jákọ́bù?
18 Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àṣẹ tí Jésù pa fún wa pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọkàn-àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” (Róòmù 10:10) Ká tó lè máa fi ẹnu wa polongo ní gbangba fún ìgbàlà, ó gba pé ká ṣe àwọn ìyípadà kan nígbèésí ayé wa. Àwọn kan wà láàárín wa tó jẹ́ pé kì í yá wọn lára láti lọ sóde ẹ̀rí. Fífi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti fífi iṣẹ́ náà ṣáájú nígbèésí ayé wa gba pé ká ṣe àwọn ìyípadà kan ká sì tún yááfì àwọn nǹkan kan. (Mátíù 6:33) Tá a bá sì ti wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ yìí, inú wa yóò máa dùn nítorí ìyìn tí iṣẹ́ náà ń mú bá Jèhófà. Nítorí náà, ǹjẹ́ à ń fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?
19. Kí lohun tó yẹ ká tún máa ṣe láti fi hàn pé a nígbàgbọ́?
19 Kí làwọn ohun tó yẹ ká tún máa ṣe láti fi ìgbàgbọ́ wa hàn? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn ohun tí ẹ kẹ́kọ̀ọ́, tí ẹ tẹ́wọ́ gbà, tí ẹ gbọ́, tí ẹ sì rí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi, ẹ máa fi ìwọ̀nyí ṣe ìwà hù; Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.” (Fílípì 4:9) À ń fi ohun tá a jẹ́ hàn nígbà tá a bá ń fi ohun tá a kọ́, ohun tá a gbà, ohun tá a gbọ́, àti ohun tá a rí ṣèwà hù. Ohun tó sì yẹ kí Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì jẹ́ ọmọlẹ́yìn máa ṣe nìyẹn. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”—Aísáyà 30:21.
20. Irú àwọn èèyàn wo ló ń ṣe ìjọ láǹfààní tó pọ̀?
20 Àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójú méjèèjì, tí wọ́n ń fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ nígbèésí ayé wọn, tí wọ́n sì ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn, ń ṣe ìjọ láǹfààní tó pọ̀. Wọ́n ń jẹ́ kí ìjọ tí wọ́n wà túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. Wọ́n wúlò gan-an ni, pàápàá nítorí bí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé tá a ní láti ràn lọ́wọ́ ṣe ń pọ̀ sí i. Tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó ní ká ‘máa dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́, ká sì máa wádìí ohun tí àwa fúnra wa jẹ́,’ àpẹẹrẹ tiwa náà máa ṣe àwọn ẹlòmíì láǹfààní.
Nífẹ̀ẹ́ sí Ṣíṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
21, 22. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?
21 Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ ọ́ lórin pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” (Sáàmù 40:8) Dáfídì nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kí nìdí? Ìdí ni pé òfin Jèhófà ń bẹ nínú ọkàn rẹ̀. Dáfídì ò ṣiyèméjì rárá nípa ọ̀nà tó yẹ kóun máa tọ̀.
22 Bí òfin Ọlọ́run bá wà ní ìhà inú wa, a ò ní máa ṣiyèméjì nípa ọ̀nà tó yẹ ká máa tọ̀. Àá nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa “tiraka tokuntokun” bá a ṣe ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.—Lúùkù 13:24.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.
b Tó o bá fẹ́ rí àwọn àbá tó wúlò nípa ọ̀nà téèyàn lè gbà kẹ́kọ̀ọ́, wo ojú ìwé 27 sí 32 nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo la ṣe lè dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́?
• Kí la ní láti ṣe tá a bá fẹ́ wádìí ohun tí àwa fúnra wa jẹ́?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a dàgbà dénú nípa tẹ̀mí?
• Báwo ni àwọn iṣẹ́ ìgbàgbọ́ wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ẹni tá a jẹ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ǹjẹ́ o mọ olórí ọ̀nà tó o lè gbà dán ara rẹ wò bóyá o wà nínú ìgbàgbọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Tá a bá ń lo agbára ìwòye wa, èyí á fi hàn pé a dàgbà dénú nípa tẹ̀mí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ọ̀nà tá a lè gbà fi ẹni tá a jẹ́ hàn ni pé ká má ṣe jẹ́ ‘olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe ọ̀rọ̀ náà’