Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
12 Mo ní láti yangàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ṣàǹfààní, màá kọjá lọ sínú àwọn ìran tó ju ti ẹ̀dá lọ+ àti àwọn ìfihàn Olúwa.+ 2 Mo mọ ọkùnrin kan nínú Kristi, ẹni tí a gbà lọ sí ọ̀run kẹta lọ́dún mẹ́rìnlá (14) sẹ́yìn, bóyá nínú ara tàbí lóde ara, mi ò mọ̀, àmọ́ Ọlọ́run mọ̀. 3 Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, bóyá nínú ara tàbí láìsí ara, mi ò mọ̀; àmọ́ Ọlọ́run mọ̀, 4 ẹni tí a gbà lọ sínú párádísè, tí ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣeé sọ, tí kò sì bófin mu fún èèyàn láti sọ. 5 Màá fi irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ yangàn, àmọ́ mi ò ní fi ara mi yangàn, àfi àwọn àìlera mi. 6 Ká tiẹ̀ ní mo fẹ́ yangàn, mi ò ní jẹ́ aláìnírònú, torí òtítọ́ ni màá sọ. Àmọ́ mi ò ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má bàa gbóríyìn fún mi ju ohun tó rí tí mò ń ṣe tàbí ohun tó gbọ́ tí mò ń sọ, 7 lórí pé mo gba àwọn ìfihàn tó ṣàrà ọ̀tọ̀.
Kí n má bàa ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ, a fi ẹ̀gún kan sínú ara mi,+ áńgẹ́lì Sátánì, láti máa gbá mi ní àbàrá,* kí n má bàa ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ. 8 Ẹ̀ẹ̀mẹta ni mo bẹ Olúwa nípa èyí kó lè kúrò lára mi. 9 Àmọ́, ó sọ fún mi pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ, torí à ń sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.”+ Nítorí náà, ṣe ni màá kúkú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, tí màá sì máa fi àìlera mi yangàn, kí agbára Kristi lè máa wà lórí mi bí àgọ́. 10 Torí náà, mò ń láyọ̀ nínú àìlera, nínú ìwọ̀sí, ní àkókò àìní, nínú inúnibíni àti ìṣòro, nítorí Kristi. Torí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, ìgbà náà ni mo di alágbára.+
11 Mo ti di aláìnírònú. Ẹ̀yin lẹ sì sọ mí di bẹ́ẹ̀, torí ó yẹ kí ẹ ti dámọ̀ràn mi. Nítorí kò sí ohun kankan tó fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì yín adára-má-kù-síbìkan sàn jù mí lọ, ká tiẹ̀ ní mi ò já mọ́ nǹkan kan.+ 12 Ní tòótọ́, ẹ ti rí àwọn àmì tó fi hàn pé mo jẹ́ àpọ́sítélì nínú ọ̀pọ̀ ìfaradà,+ nínú àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* àti àwọn iṣẹ́ agbára.+ 13 Nítorí ọ̀nà wo ni àǹfààní tí ẹ ní gbà kéré sí ti àwọn ìjọ yòókù, yàtọ̀ sí pé èmi fúnra mi ò sọ ara mi di ẹrù sí yín lọ́rùn?+ Ẹ dárí jì mí tinútinú lórí àìtọ́ yìí.
14 Ẹ wò ó! Ìgbà kẹta nìyí tí mo ti ṣe tán láti wá sọ́dọ̀ yín, mi ò sì ní sọ ara mi di ẹrù sí yín lọ́rùn. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ni mò ń wá, kì í ṣe àwọn ohun ìní yín;+ torí a kò retí pé kí àwọn ọmọ+ máa to nǹkan jọ fún àwọn òbí wọn, àwọn òbí ni kó máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. 15 Ní tèmi, tayọ̀tayọ̀ ni màá ná gbogbo ohun tí mo ní, màá sì ná ara mi tán pátápátá fún yín.*+ Tó bá jẹ́ pé báyìí ni mo nífẹ̀ẹ́ yín tó, ṣé ó yẹ kí ìfẹ́ tí ẹ ní fún mi kéré sí tèmi? 16 Àmọ́ bó ti wù kó rí, mi ò sọ ara mi di ẹrù sí yín lọ́rùn.+ Síbẹ̀, ẹ̀ ń sọ pé, mo jẹ́ “ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́,” mo sì ń fi “ẹ̀tàn” mú yín. 17 Mi ò fi ìkankan nínú àwọn tí mo rán sí yín yàn yín jẹ, àbí mo ṣe bẹ́ẹ̀? 18 Mo rọ Títù pé kó wá sọ́dọ̀ yín, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀. Títù ò yàn yín jẹ rárá, àbí ó ṣe bẹ́ẹ̀?+ Irú ẹ̀mí kan náà la ní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ipa ọ̀nà kan náà la sì ń rìn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
19 Ṣé ohun tí ẹ̀ ń rò látìgbà yìí wá ni pé à ń gbèjà ara wa níwájú yín? Iwájú Ọlọ́run la ti ń sọ̀rọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi. Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, ká lè gbé yín ró la fi ń ṣe gbogbo ohun tí à ń ṣe. 20 Ẹ̀rù ń bà mí pé tí mo bá dé, mo lè má bá yín bí mo ṣe fẹ́, mo sì lè má rí bí ẹ ṣe rò, dípò bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ wàhálà, owú, ìbínú ńlá, awuyewuye, sísọ̀rọ̀ ẹni láìdáa, ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,* ìgbéraga àti rúdurùdu ni màá bá nílẹ̀. 21 Ó sì tún lè jẹ́ pé tí mo bá dé, Ọlọ́run mi á dójú tì mí níwájú yín, kó sì di pé màá ṣọ̀fọ̀ lórí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti dẹ́ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí wọn ò ronú pìwà dà kúrò nínú ìwà àìmọ́ àti ìṣekúṣe* pẹ̀lú ìwà àìnítìjú* tí wọ́n hù.