Ní Inú Dídùn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
ALÁYỌ̀ ni ènìyàn tí “inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà.” Irú ẹni bẹ́ẹ̀ a máa fi “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “tọ̀sán-tòru.” (Sm. 1:1, 2) Ǹjẹ́ o máa ń ní irú inú dídùn bẹ́ẹ̀? Báwo ni o ṣe lè mú kí ìdùnnú tí ò ń rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pọ̀ sí i?
Fetí Sílẹ̀ bí Jèhófà Ṣe Ń Sọ̀rọ̀
Má kàn máa ka ọ̀rọ̀ lọ gbuurugbu. Fojú inú wo ipò àwọn nǹkan tó ò ń kà nípa rẹ̀. Máa fi etí inú gbọ́ ohùn àwọn èèyàn tí ò ń kà nípa wọn. Bí o ṣe ń ka àwọn orí tó wà lápá ìbẹ̀rẹ̀ Bíbélì, gbọ́ ohùn Jèhófà fúnra rẹ̀ bí ó ṣe ń sọ àwọn ohun tó ṣe lẹ́sẹẹsẹ láti mú kí ayé ṣeé gbé fún èèyàn. Gbọ́ bí ó ṣe ń sọ fún Ọmọ rẹ̀, Àgbà Òṣìṣẹ́, pé àsìkò ti tó láti dá àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́. Sì fojú inú wo ìran yìí: Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀, Ọlọ́run ṣèdájọ́ wọn, lẹ́yìn náà, ó wá lé wọn jáde kúrò nínú Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì, orí 1 sí 3) Nígbà tí o bá ń kà á pé ohùn kan wá láti ọ̀run tó sọ pé Jésù Kristi ni Ọmọ Ọlọ́run, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, tí Ọlọ́run rán láti wá fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ọmọ aráyé, jẹ́ kí ó dà bí ẹni pé o ń gbọ́ ohùn ọlọ́lá ńlá yẹn. (Mát. 3:16, 17) Gbìyànjú láti fojú inú wo ìṣarasíhùwà àpọ́sítélì Jòhánù nígbà tó gbọ́ tí Jèhófà kéde pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” (Ìṣí. 21:5) Ní tòdodo, kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà báyìí jẹ́ ohun tó ń dùn mọ́ni jọjọ!
Máa ka àkọsílẹ̀ onímìísí nìṣó, ìwọ yóò sì wá mọ̀ pé Ẹni ọlọ́lá ńlá tí ó sì jẹ́ àgbàyanu gidigidi ni Jèhófà. Ọkàn rẹ yóò wá fà mọ́ Ẹni tó fẹ́ràn wa yìí gidigidi, tó ń fi àánú bá wa lò, tó ń ràn wá lọ́wọ́ bí a bá ń fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣakitiyan láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, tó sì ń fọ̀nà bí a ṣe lè ṣe àṣeyọrí hàn wá nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe.—Jóṣ. 1:8; Sm. 8:1; Aísá. 41:10.
Bí o ṣe ń lo àkókò sí i tó láti ka Bíbélì, bẹ́ẹ̀ náà lo ṣe máa ní ìtẹ́lọ́rùn tó, nítorí pé ìmọ̀ rẹ nípa ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí o ṣe yóò máa túbọ̀ pọ̀ sí i ni. Àmọ́, ìdùnnú rẹ yóò ju ìyẹn lọ ṣá o. Nígbà tí ìwé tí ò ń kà bá ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ bí o ṣe lè fi ọgbọ́n yanjú ìṣòro, èrò tìrẹ náà yóò dà bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ àgbàyanu. Ìdí nìyẹn tí ọkàn mi fi pa wọ́n mọ́.” (Sm. 119:129) Ìwọ pẹ̀lú yóò yọ̀, bí o ṣe ń lóye àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tọ́ ìrònú àti ìfẹ́ ọkàn rẹ sípa ti Ọlọ́run.—Aísá. 55:8, 9.
Bíbélì ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà nípa ìwà híhù, èyí tó ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ìpalára tó sì ń fọ̀nà tí ó tọ́ hàn wá. Bí a ṣe ń kà á, yóò máa hàn sí wa pé Jèhófà jẹ́ Baba tó mọ àwọn ìṣòro tí yóò jẹ yọ tí a bá fàyè gba àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara aláìpé. Kò fẹ́ ká kàgbákò rárá, èyí tó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀ bí a bá ré ìlànà ìwà híhù rẹ̀ gíga kọjá. Ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún, ó sì ń fẹ́ ká gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ. Kíkà tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ ká túbọ̀ mọyì rẹ̀ pé ìbùkún ńláǹlà ló jẹ́ fún wa pé òun ni Ọlọ́run àti Baba wa ọ̀run.
Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́
Onísáàmù sọ nípa ẹni tó ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ pé: “Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” (Sm. 1:3) Dájúdájú, láìka àìpé wa sí, láìka ti pé à ń gbé inú ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì sí, láìsì ka àwọn ìsapá tí Èṣù ń ṣe láti pa wá jẹ sí, kíkà tí a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé tí a sì ń fi ohun tó wà nínú rẹ̀ sílò yóò jẹ́ kí a lè kẹ́sẹ járí nínú gbogbo ohun tó bá wé mọ́ àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà.
Níwọ̀n bí ayé ògbólógbòó yìí ti ń gbógun tì wá, gbígbà tí a bá ń gba èrò Ẹlẹ́dàá sínú lójoojúmọ́, ì báà jẹ́ fún ìwọ̀nba ìṣẹ́jú mélòó kan péré, yóò fún wa lókun. Àwọn kan tó dèrò ẹ̀wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn kò rí kà ju àwọn ẹsẹ Bíbélì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn lọ. Ìwọ̀nyẹn ni wọ́n gé, tí wọ́n há sórí, tí wọ́n sì ṣàṣàrò lé lórí. Jèhófà sì bù kún ìsapá wọn nítorí pé wọ́n ṣe ohun tí wọ́n lè ṣe lábẹ́ ipò ti wọ́n wà láti lè gba ìmọ̀ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú. (Mát. 5:3) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, èyí tó pọ̀ jú nínú wa tún ní òmìnira ju ìyẹn lọ dáadáa. Kí á má ṣe ronú pé tí a bá kàn ti sáré ka ẹsẹ Bíbélì kan ṣoṣo lẹ́ẹ̀kan lóòjọ́, ìyẹn á ṣe ohun ìyanu kan ṣáá. Àmọ́ ṣá o, a ó jàǹfààní bí a bá tún ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa ṣe, kí á fi lè rí àyè máa ka ìpín kan nínú Bíbélì lójoojúmọ́, kí á ronú lé e lórí, kí a sì fi í sílò ní ìgbésí ayé wa.
Ká sòótọ́ o, ètò tí a ṣe dáadáa pàápàá ṣì lè forí gbárí pẹ̀lú àwọn nǹkan mìíràn. Bí ìyẹn bá sì ti ṣẹlẹ̀, ńṣe ló yẹ ká jẹ́ kí ohun tó ṣe pàtàkì gba ipò iwájú. Bí àpẹẹrẹ, kì í sábà wáyé pé ká dìídì máà mu omi fún odindi ọjọ́ kan tàbí méjì. Nípa bẹ́ẹ̀, bó ṣe wù kí ìgbésí ayé wa rí lójoojúmọ́, a ní láti wá àyè láti fi omi òtítọ́ tu ara wa lára.—Ìṣe 17:11.
Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Látòkèdélẹ̀
Ǹjẹ́ ìwọ fúnra rẹ tíì ka Bíbélì tán láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin? Òkè ìṣòro ńlá gbáà ló jẹ́ lójú àwọn kan láti bẹ̀rẹ̀ Bíbélì kíkà láti Jẹ́nẹ́sísì títí lọ dé Ìṣípayá. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ni púpọ̀ àwọn tó fẹ́ ka gbogbo Bíbélì ti kọ́kọ́ máa ń bẹ̀rẹ̀. Kí nìdí? Ó lè jẹ́ nítorí pé wọ́n tètè máa ń rí ohun tó kàn wọ́n nínú ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé wọ̀nyẹn tó dá lórí àpẹẹrẹ Jésù ẹni tí wọ́n ń sapá láti tẹ̀ lé. Tàbí nítorí pé wọ́n á tètè ka Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tán, èyí tó kàn fi díẹ̀ ju ìdámẹ́rin Bíbélì lọ. Bí wọ́n bá sì ti ka ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n yẹn tán, wọ́n á wá yíjú sí ìwé mọ́kàndínlógójì tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí kà wọ́n lákàgbádùn. Nígbà tí wọ́n bá fi máa parí kíka Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tán, àṣà kíka Bíbélì déédéé á ti mọ́ wọn lára, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ máa bá a lọ, títí tí wọ́n á fi ka Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì lẹ́ẹ̀kejì, tí wọn ò sì ní dáwọ́ dúró mọ́. Ńṣe ni kí ìwọ náà sọ kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ dàṣà títí láé.
Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà nínú ìdílé rẹ tàbí nínú ìjọ rẹ tí kò lè kàwé bí? Oò ṣe yọ̀ǹda ara rẹ láti máa ka Bíbélì sí i létí déédéé? Wàá jàǹfààní, òun náà á sì rí èrè níbẹ̀ bó bá ṣe ń ṣàṣàrò lórí ohun tó gbọ́, tó sì ń fi í sílò ní ìgbésí ayé rẹ̀.—Ìṣí. 1:3.
Bí àkókò ti ń lọ, o lè wá dáwọ́ lé àwọn àfikún ìwádìí lórí Bíbélì tí ò ń kà. Àwọn kan nínú rẹ̀ lè mú kí o túbọ̀ wá mọyì bí onírúurú ẹ̀ka inú Bíbélì ṣe wé mọ́ ara wọn. Bí Bíbélì rẹ bá sì ní àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, wọ́n lè tọ́ka rẹ sí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni nípa ìtàn àwọn ohun tó fa ìṣẹ̀lẹ̀ tí ò ń kà, kí wọ́n sì tún tọ́ka rẹ sí àwọn àkọsílẹ̀ mìíràn tó jọ ọ́. Wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ipò àwọn nǹkan tó mú kí wọ́n kọ onírúurú orin ìyìn inú Bíbélì, àti àwọn ìwé tí àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi kọ. Ìwé Insight on the Scriptures pèsè ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni nípa àwọn èèyàn, àwọn ibi, àti àwọn ànímọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn. Àwọn àwòrán atọ́ka ń pe àfiyèsí sí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó jẹ́ ká mọ àwọn ọba àti wòlíì tó jọ gbé ayé lásìkò kan náà, ó sì sọ àwọn ọdún tó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì ti wáyé.
Bí o ṣe ń ṣàṣàrò lórí ohun tí ò ń kọ́, wàá lóye àwọn ìdí tí àwọn nǹkan kan fi wáyé lọ́nà tó gbà wáyé láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Wàá sì mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe àwọn ohun tó ṣe sí àwọn èèyàn rẹ̀. Ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń wo ohun tí àwọn ìjọba, àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè àtàwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣe yóò ṣe kedere sí ọ. Èyí yóò fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye púpọ̀ sí i nípa èrò inú Ọlọ́run.
Ìtàn Bíbélì á túbọ̀ wù ọ́ nígbà tó o bá ń fojú inú wo àgbègbè tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ti ṣẹlẹ̀. Àwọn àwòrán ilẹ̀ tí ìtàn Bíbélì mẹ́nu kàn fi bí ojú ilẹ̀ wọ̀nyẹn ṣe rí hàn, àti bí wọ́n ṣe jìnnà síra tó. Bí àpẹẹrẹ, ibo ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ibi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti sọdá Òkun Pupa? Báwo ni Ilẹ̀ Ìlérí ṣe fẹ̀ tó? Ibo ni Jésù rìn dé nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? Kí ni àwọn ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fojú rí nígbà àwọn ìrìn àjò míṣọ́nnárì tó rìn? Àwọn àwòrán ilẹ̀ àti àlàyé bí ojú ilẹ̀ ṣe rí, pèsè àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí yóò mú kí ohun tí ò ń kà dà bíi pé ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Ibo lo ti lè rí àwọn àwòrán ilẹ̀ tí ìtàn Bíbélì mẹ́nu kàn? Àwọn kan wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Nǹkan bí àádọ́rin àwòrán ilẹ̀ wà nínú ìwé Insight méjèèjì, atọ́ka àwòrán ilẹ̀ sì tún wà ní ìparí apá kìíní ìwé yẹn. Lo ìwé Watch Tower Publications Index láti fi ṣàwárí àwọn àwòrán ilẹ̀ yòókù. Bí o kò bá ní àwọn ìwé wọ̀nyí, lo àwọn àwòrán ilẹ̀ tí à ń tẹ̀ jáde nínú Ilé Ìṣọ́, wọ́n á ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá ń ka Bíbélì.
Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, Dáfídì Ọba yin Jèhófà pé: “Àwọn ìrònú rẹ mà ṣe iyebíye o! Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn pátápátá mà pọ̀ o!” (Sm. 139:17) Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yin Jèhófà nítorí pé Ó “ti tàn sí ọkàn-àyà wa láti fi ìmọ̀ ológo nípa Ọlọ́run tànmọ́lẹ̀ sí i nípasẹ̀ ojú Kristi.” (2 Kọ́r. 4:6) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ló wà láàárín ìgbà ayé Dáfídì sí ìgbà ti Pọ́ọ̀lù; síbẹ̀, àwọn méjèèjì ní inú dídùn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìwọ pẹ̀lú lè ní inú dídùn sí i bó o bá wá àyè láti ka gbogbo ohun tí Jèhófà ti pèsè fún ọ ní ojú ewé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó mí sí.