ORÍ 60
Ìran Ìyípadà Ológo
MÁTÍÙ 16:28–17:13 MÁÀKÙ 9:1-13 LÚÙKÙ 9:27-36
ÌRAN ÌYÍPADÀ OLÓGO
ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ GBỌ́ OHÙN ỌLỌ́RUN
Nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn ní Kesaríà ti Fílípì tó wà ní nǹkan bíi máìlì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sí Òkè Hámónì, ó sọ ohun kan tó ya àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́nu, ó ní: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tó dúró síbí yìí tí kò ní tọ́ ikú wò rárá títí wọ́n á fi kọ́kọ́ rí Ọmọ èèyàn tó ń bọ̀ nínú Ìjọba rẹ̀.”—Mátíù 16:28.
Ó dájú pé ọ̀rọ̀ náà ò ní yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dáadáa. Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìyẹn, Jésù mú mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ìyẹn Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù lọ sórí òkè kan tó ga gan-an. Ó ṣeé ṣe kí ilẹ̀ ti ṣú nígbà yẹn torí pé oorun ti ń kun àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Bí Jésù ṣe ń gbàdúrà, Ọlọ́run yí i pa dà níṣojú wọn. Àwọn àpọ́sítélì rí ojú ẹ̀ tó tàn yòò bí oòrùn, aṣọ ẹ̀ di funfun báláú, ó sì ń tàn yinrin.
Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n rí àwọn méjì kan tó jọ “Mósè àti Èlíjà.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa “lílọ rẹ̀, èyí tó máa tó mú ṣẹ ní Jerúsálẹ́mù.” (Lúùkù 9:30, 31) Ohun tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ ni lílọ náà túmọ̀ sí, ìyẹn bó ṣe máa kú tí Ọlọ́run sì máa jí i dìde. (Mátíù 16:21) Ìjíròrò yìí fi hàn pé ìmọ̀ràn tí Pétérù fún un ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, torí pé Jésù gbọ́dọ̀ kú.
Àwọn àpọ́sítélì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti wá jí báyìí, ohun tí wọ́n rí àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ yà wọ́n lẹ́nu gan-an. Ìran ni wọ́n ń rí, àmọ́ lójú Pétérù ṣe ló dà bíi pé ó ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ, lòun náà bá dá sí i, ó ní: “Rábì, ó dáa bí a ṣe wà níbí. Torí náà, jẹ́ ká pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.” (Máàkù 9:5) Bóyá torí kí ìran náà má bàa tètè parí ni Pétérù ṣe sọ pé òun fẹ́ pa àgọ́ síbẹ̀.
Bí Pétérù ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìkùukùu tó mọ́lẹ̀ yòò bò wọ́n, ohùn kan sì dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà. Ẹ fetí sí i.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohùn Ọlọ́run, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dojú bolẹ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Jésù wá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.” (Mátíù 17:5-7) Nígbà tí wọ́n máa gbójú sókè, Jésù nìkan ni wọ́n rí, wọn ò rí àwọn tó kù mọ́, ìran náà sì ti parí. Nígbà tí wọ́n ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ látorí òkè náà nídàájí, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ má sọ ìran náà fún ẹnikẹ́ni títí a fi máa jí Ọmọ èèyàn dìde.”—Mátíù 17:9.
Ìran táwọn àpọ́sítélì rí nípa Èlíjà mú kí wọ́n béèrè pé: “Kí ló wá dé tí àwọn akọ̀wé òfin fi ń sọ pé Èlíjà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá?” Jésù fèsì pé: “Èlíjà ti wá, wọn ò sì dá a mọ̀.” (Mátíù 17:10-12) Jòhánù Arinibọmi ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ torí pé iṣẹ́ tó ṣe jọ ti Èlíjà. Èlíjà ṣètò ọ̀nà sílẹ̀ fún Èlíṣà, Jòhánù sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún Kristi.
Ẹ wo bí ìran yẹn ṣe máa fún Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lókun! Ó jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn rí bí ògo Jésù ṣe máa pọ̀ tó nínú Ìjọba rẹ̀. Wọ́n rí “Ọmọ èèyàn tó ń bọ̀ nínú Ìjọba rẹ̀” bí Jésù ṣe ṣèlérí fún wọn tẹ́lẹ̀. (Mátíù 16:28) Nígbà tí wọ́n wà lórí òkè yẹn, wọ́n “fi ojú ara [wọn] rí ọlá ńlá rẹ̀.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Farisí fẹ́ kí Jésù fún àwọn ní àmì kó lè dá wọn lójú pé ọba tí Ọlọ́run yàn ni, kò fún wọn lámì kankan. Àmọ́, Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tó sún mọ́ ọn rí ìran ìyípadà ológo náà, ìyẹn sì mú kó dá wọn lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run máa ṣẹ. Ìyẹn ló mú kí Pétérù sọ nígbà tó yá pé: “A ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mú kó túbọ̀ dá wa lójú.”—2 Pétérù 1:16-19.