Ẹ̀KỌ́ 28
Fi Hàn Pé O Mọyì Ohun Tí Jèhófà àti Jésù Ṣe fún Ẹ
Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ tí ọ̀rẹ́ ẹ bá fún ẹ lẹ́bùn pàtàkì kan? Ó dájú pé inú ẹ máa dùn gan-an, wàá sì fẹ́ fi hàn pé o mọyì ẹ̀bùn náà. Jèhófà àti Jésù ló fún wa ní ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ. Ẹ̀bùn wo nìyẹn? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn náà?
1. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Ọlọ́run àti Kristi ṣe fún wa?
Bíbélì sọ pé “gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú [Jésù]” máa gbé ayé títí láé. (Jòhánù 3:16) Báwo lẹnì kan ṣe lè fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́? Ó kọjá pé kéèyàn kàn gba Jésù gbọ́. Ó tún yẹ ká jẹ́ káwọn ìpinnu wa àtàwọn ohun tá à ń ṣe fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́. (Jémíìsì 2:17) Tá a bá ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́, èyí á mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jésù àti Jèhófà Bàbá rẹ̀ máa lágbára sí i.—Ka Jòhánù 14:21.
2. Ohun pàtàkì wo la máa ń ṣe tó ń jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa?
Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ ọ̀nà míì táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè gbà fi hàn pé àwọn mọyì ẹbọ tó máa fi ara rẹ̀ rú. Ó ní kí wọ́n máa ṣe ohun pàtàkì kan tí Bíbélì pè ní “Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa,” èyí tá a tún ń pè ní Ìrántí Ikú Kristi. (1 Kọ́ríńtì 11:20) Jésù dá ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀ káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àti gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ lè máa rántí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. Nítorí ohun pàtàkì yìí, Jésù pa á láṣẹ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Tó o bá lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi, ìyẹn á fi hàn pé o mọyì ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí wa.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i kó o lè mọ àwọn nǹkan míì tó o lè ṣe tó máa fi hàn pé o mọyì ìfẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí wa. Jẹ́ ká wo bí Ìrántí Ikú Kristi ti ṣe pàtàkì tó.
3. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a moore?
Ká sọ pé ẹnì kan yọ ẹ́ nígbà tí omi fẹ́ gbé ẹ lọ. Ṣé wàá kàn gbàgbé ohun tí onítọ̀hún ṣe fún ẹ ni? Àbí wàá ṣe àwọn nǹkan tó máa fi hàn pé o mọyì oore ńlá tẹ́ni náà ṣe ẹ́?
Jèhófà ló mú ká wà láàyè. Ka 1 Jòhánù 4:8-10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tí ẹbọ tí Jésù fi ara rẹ̀ rú fi jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì?
Báwo ni ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa ṣe rí lára ẹ?
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa? Ka 2 Kọ́ríńtì 5:15 àti 1 Jòhánù 4:11; 5:3. Lẹ́yìn tó o bá ti ka ẹsẹ Bíbélì kọ̀ọ̀kan, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, báwo la ṣe lè fi hàn pé a moore?
4. Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù
Ọ̀nà míì tá a lè gbà fi hàn pé a moore ni pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ka 1 Pétérù 2:21, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe láti fi hàn pé ò ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí?
5. Máa lọ síbi Ìrántí Ikú Jésù
Kó o lè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, ka Lúùkù 22:14, 19, 20. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
Kí ni búrẹ́dì àti wáìnì ṣàpẹẹrẹ?—Wo ẹsẹ 19 àti 20.
Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣe ìrántí ikú òun, èyí tá a tún ń pè ní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ó ní kí wọ́n máa ṣe é lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ní àyájọ́ ọjọ́ tí wọ́n pa á. Torí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kóra jọ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́nà tó pàṣẹ pé ká máa gbà ṣe é. Kó o lè mọ bí ìpàdé náà ti ṣe pàtàkì tó, wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Àwọn nǹkan wo lo kíyè sí nínú fídíò yẹn nípa bá a ṣe ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi?
Búrẹ́dì àti wáìnì jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ. Búrẹ́dì ṣàpẹẹrẹ ara pípé tí Jésù fi rúbọ nítorí wa, wáìnì sì ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ Jésù
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Tó o bá ṣáà ti gba Jésù gbọ́, wàá rí ìgbàlà.”
Báwo lo ṣe máa lo Jòhánù 3:16 àti Jémíìsì 2:17 láti fi hàn pé àwọn nǹkan míì ṣì wà tó yẹ ká ṣe?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Tá a bá ń ṣohun tó fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Jésù, tá a sì ń lọ síbi ìrántí ikú rẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa.
Kí lo rí kọ́?
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Jésù?
Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún ẹ?
Kí nìdí tó fi pọn dandan kó o lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi?
ṢÈWÁDÌÍ
Kí ni ikú Kristi mú ká máa ṣe?
Ka ìwé yìí kó o lè túbọ̀ mọ ohun tí ìgbàgbọ́ jẹ́ àti bó o ṣe lè fi hàn pé o nígbàgbọ́.
“Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà” (Ilé Ìṣọ́, October 2016)
Nínú ìwé yìí, ka ìtàn ìgbésí ayé obìnrin kan tó sọ pé, “Mo Mọ́ Tónítóní, Mo sì Ń Gbádùn Ìgbésí Ayé Mi.” Wàá rí i pé ẹbọ tí Jésù fi ara rẹ̀ rú ṣe obìnrin náà láǹfààní.
“Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, August 1, 2011)
Ka ìwé yìí kó o lè rí ìdí tó fi jẹ́ pé àwọn díẹ̀ ló ń jẹ búrẹ́dì, tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi.