Orí 8
Agbára Ìmúbọ̀sípò—Jèhófà “Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”
1, 2. Àwọn àdánù wo ló máa ń bá ìran ènìyàn lóde òní, ipa wo lèyí sì máa ń ní lórí wa?
ỌMỌ kékeré kan ò rí ohun ìṣeré rẹ̀ tó fẹ́ràn gan-an mọ́ ló bá bù sẹ́kún. Àsunwà ló ń sun ẹkún tá à ń wí yìí. Ó mà ṣe o! Àmọ́, ǹjẹ́ o tíì rí bí inú ọmọdé kan ṣe máa ń dùn tó nígbà tí òbí rẹ̀ bá bá a rí nǹkan rẹ̀ tó sọ nù tàbí nígbà tí ó bá bá a tún un ṣe tó sì wá fi lé e lọ́wọ́? Lójú òbí yẹn, nǹkan kékeré ni wíwá ohun ìṣeré yẹn rí tàbí títún un ṣe jẹ́. Ṣùgbọ́n ní ti ọmọ, ńṣe ni inú rẹ̀ dùn, ó sì jọ ọ́ lójú. Nítorí ohun tó rò pé òun ò ní rí mọ́ títí láé ti tún padà sí i lọ́wọ́!
2 Jèhófà, Baba tó ju baba lọ, lágbára láti fi ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé lè máa rò pé ọwọ́ àwọn ò lè tẹ̀ mọ́ láéláé lé wọn lọ́wọ́ padà. Àmọ́ ohun ìṣeré ọmọdé kọ́ là ń wí yìí o. Nínú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” tí à ń gbé yìí, àdánù tó ń bá wa burú gan-an jù bẹ́ẹ̀ lọ. (2 Tímótì 3:1-5) Inú ewu ni ọ̀pọ̀ jù lọ ohun tó ń jẹ àwọn èèyàn lógún jù lọ máa ń wà ṣáá, àwọn bí ibùgbé, ohun ìní, iṣẹ́ ẹni àti ìlera ẹni pàápàá. Ọkàn wa tún lè dà rú tí a bá ronú nípa bí àwọn èèyàn ṣe ń ba àyíká wa jẹ́ tí ìyẹn sì ń fa àkúrun onírúurú ẹ̀dá inú ayé. Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ò kàn tiẹ̀ tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀dùn ọkàn tí ikú ẹni tá a fẹ́ràn máa ń kó báni. Ìrora àdánù yẹn àti ìrora ti pé ikú ọ̀hún ò ṣe é dá dúró máa ń pọ̀ jọjọ.—2 Sámúẹ́lì 18:33.
3. Ohun ìtùnú wo ni Ìṣe 3:21 mẹ́nu kàn pé ó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ọ̀nà wo ni Jèhófà yóò sì gbà mú un ṣẹ?
3 Nítorí náà, ó jẹ́ ohun ìtùnú gbáà fún wa láti kọ́ nípa bí Jèhófà ṣe lágbára láti mú nǹkan bọ̀ sípò! Níwájú, a óò rí i kọ́ pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nǹkan ni Ọlọ́run lágbára láti mú bọ̀ sípò fáwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé àti pé yóò sì ṣe nǹkan wọ̀nyẹn. Bíbélì pàápàá fi hàn pé Jèhófà pète “ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo.” (Ìṣe 3:21) Ohun tí Jèhófà yóò lò láti fi ṣe é ni Ìjọba Mèsáyà, tí Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ yóò ṣàkóso. Ẹ̀rí fi hàn pé Ìjọba yìí bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ní ọ̀run lọ́dún 1914.a (Mátíù 24:3-14) Kí ni yóò mú bọ̀ sípò? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn mélòó kan yẹ̀ wò lára iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò ńláǹlà tí Jèhófà ti ṣe àti èyí tí yóò ṣe. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí a ti ń rí ọ̀kan nínú rẹ̀, a sì ń mọ̀ ọ́n lára. Àwọn mìíràn yóò wáyé lọ́nà tó ga lọ́lá lọ́jọ́ iwájú.
Ìmúbọ̀sípò Ìsìn Mímọ́
4, 5. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ìrètí wo sì ni Jèhófà fún wọn?
4 Ohun kan tí Jèhófà ti mú bọ̀ sípò báyìí ni ìsìn mímọ́. Láti lóye ohun tí èyí túmọ̀ sí, ẹ jẹ́ ká ṣe àyẹ̀wò ṣókí nípa ìtàn ìjọba Júdà. Àyẹ̀wò yìí yóò jẹ́ ká ní ìjìnlẹ̀ òye, tó mórí yá gágá, nípa bí Jèhófà ṣe ti ń lo agbára rẹ̀ láti mú àwọn nǹkan bọ̀ sípò.—Róòmù 15:4.
5 Fojú inú wo bí nǹkan ṣe rí lára àwọn Júù olóòótọ́ nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìlú wọn àtàtà pa run, wọ́n sì wó odi rẹ̀ palẹ̀. Èyí tó burú jù ni pé, tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì tó jẹ́ ojúkò kan ṣoṣo tí gbogbo ayé ti lè máa ṣe ìjọsìn mímọ́ fún Jèhófà di òkìtì àwókù. (Sáàmù 79:1) Àwọn tó la ìparun yẹn já dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì, wọ́n fi ìlú ìbílẹ̀ wọn sílẹ̀ láhoro, níbi táwọn ẹranko ìgbẹ́ yóò ti máa jẹ̀. (Jeremáyà 9:11) Lójú ọmọ aráyé, ìlú wọn ò lè gbérí mọ́ láéláé. (Sáàmù 137:1) Ṣùgbọ́n Jèhófà tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìparun yìí tipẹ́tipẹ́ fún wọn nírètí pé àkókò ìmúbọ̀sípò ń bọ̀.
6-8. (a) Kí ni kókó tó wọ́pọ̀ gan-an nínú ìwé tí àwọn wòlíì Hébérù kọ, báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì ṣe ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́? (b) Lóde òní, ọ̀nà wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run gbà rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò?
6 Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ ìmúbọ̀sípò jẹ́ kókó tó wọ́pọ̀ gan-an nínú ìwé tí àwọn wòlíì Hébérù kọ.b Jèhófà tipasẹ̀ wọn ṣèlérí pé a óò mú ilẹ̀ wọn bọ̀ sípò, tí àwọn èèyàn yóò tún padà máa gbé ibẹ̀, tí yóò sì jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá táwọn ẹranko ẹhànnà àtàwọn ọ̀tá ò ní dojú ìjà kọ wọ́n mọ́. Ó ṣàpèjúwe ilẹ̀ wọn tó máa padà bọ̀ sípò pé Párádísè ni yóò jẹ́ ní tòótọ́! (Aísáyà 65:25; Ìsíkíẹ́lì 34:25; 36:35) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìjọsìn tòótọ́ yóò fìdí múlẹ̀, a ó sì tún tẹ́ńpìlì kọ́. (Míkà 4:1-5) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn nírètí, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da ìgbèkùn wọn fún àádọ́rin ọdún ní Bábílónì.
7 Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àkókò ìmúbọ̀sípò ọ̀hún wọlé dé. Bí àwọn Júù ṣe gba ìdáǹdè kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì, wọ́n padà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n lọ tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́ níbẹ̀. (Ẹ́sírà 1:1, 2) Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n rọ̀ mọ́ ìsìn tòótọ́, Jèhófà bù kún wọn, ó mú kí ilẹ̀ wọn lọ́ràá kí ó sì máa sèso jìngbìnnì. Ó dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹranko ẹhànnà tó ti gba gbogbo ilẹ̀ náà kan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Inú wọn á mà dùn o, fún bí Jèhófà ṣe lo agbára rẹ̀ láti mú àwọn nǹkan bọ̀ sípò fún wọn! Ṣùgbọ́n ìmúṣẹ àkọ́kọ́ lásán, tó kàn mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò ṣẹ níwọ̀nba, làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn jẹ́. Ìmúṣẹ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ yóò ṣì wáyé “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ìyẹn ìgbà tiwa yìí, nígbà tí Ajogún Dáfídì Ọba tí a ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́ yóò gorí ìtẹ́.—Aísáyà 2:2-4; 9:6, 7.
8 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù gorí ìtẹ́ Ìjọba ọ̀run lọ́dún 1914, tó fi bẹ̀rẹ̀ sí bójú tó àwọn nǹkan tẹ̀mí tí àwọn olóòótọ́ èèyàn Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé nílò. Bí Kírúsì ajagunṣẹ́gun, ará ilẹ̀ Páṣíà, ṣe dá àwọn àṣẹ́kù àwọn Júù nídè kúrò ní Bábílónì lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, bẹ́ẹ̀ ni Jésù ṣe dá àṣẹ́kù àwọn Júù nípa tẹ̀mí tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nídè kúrò nínú Bábílónì òde òní, ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (Róòmù 2:29; Ìṣípayá 18:1-5) Láti ọdún 1919 síwájú ni a tí mú ìsìn mímọ́ padà bọ̀ sí ipò tó yẹ kó wà nínú ìgbésí ayé àwọn ojúlówó Kristẹni. (Málákì 3:1-5) Látìgbà yẹn wá làwọn èèyàn Jèhófà ti ń sìn ín nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí, ìyẹn ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ṣíṣe ìsìn mímọ́. Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì fún wa lóde òní?
Ìmúbọ̀sípò Nípa Tẹ̀mí—Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì
9. Lẹ́yìn ìgbà ayé àwọn àpọ́sítélì, kí ni àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe sí ìjọsìn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kí ni Jèhófà wá ṣe láyé ìgbà tiwa?
9 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí ìtàn sọ nípa rẹ̀ ná. Àwọn Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní lọ́hùn-ún rí ọ̀pọ̀ ìbùkún nípa tẹ̀mí gbà. Ṣùgbọ́n Jésù àtàwọn àpọ́sítélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn yóò sọ ìsìn tòótọ́ dìbàjẹ́ tí yóò sì dàwátì. (Mátíù 13:24-30; Ìṣe 20:29, 30) Lóòótọ́, ẹ̀yìn ìgbà ayé àwọn àpọ́sítélì làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì gbòde. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn gbàbọ̀dè nípa títẹ́wọ́gba ẹ̀kọ́ àti ìṣe àwọn abọ̀rìṣà. Wọ́n mú kí títọ Ọlọ́run lọ di ẹtì, nítorí àlàyé tí wọ́n ń ṣe nípa Ọlọ́run ni pé ó jẹ́ Mẹ́talọ́kan téèyàn ò lè lóye. Wọ́n wá ń kọ́ àwọn èèyàn pé Màríà àti onírúurú “àwọn ẹni mímọ́” ni kí wọ́n máa gbàdúrà sí dípò Jèhófà. Wàyí o, lẹ́yìn tí wọ́n ti wá fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sọ ìsìn dìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ni Jèhófà ṣe? Ó dá sí ọ̀rọ̀ náà! Ó mú ìsìn mímọ́ bọ̀ sípò nínú ayé òde òní, ayé tí ẹ̀sìn èké kún fọ́fọ́, tí ìwà àìṣèfẹ́-Ọlọ́run ti gbòde kan! Láìsọ àsọdùn, a lè sọ pé ìmúbọ̀sípò yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ lóde òní.
10, 11. (a) Nǹkan méjì wo ni Párádísè tẹ̀mí jẹ mọ́, báwo ló sì ṣe kàn ọ́? (b) Irú àwọn èèyàn wo ni Jèhófà ń kó jọ pọ̀ sínú Párádísè tẹ̀mí, kí ni wọn yóò láǹfààní láti rí?
10 Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní ń gbádùn Párádísè nípa tẹ̀mí. Kí ni Párádísè yìí jẹ mọ́? Nǹkan méjì ló jẹ mọ́ ní pàtàkì. Lákọ̀ọ́kọ́, ó jẹ mọ́ ìsìn mímọ́ ti Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà. Ọlọ́run ti fi ọ̀nà ìjọsìn tí kò ní irọ́ àti èrú nínú jíǹkí wa. Ó ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa. Èyí tó mú ká lè mọ̀ nípa Bàbá wa ọ̀run, ká lè tẹ́ ẹ lọ́rùn, ká sì sún mọ́ ọn. (Jòhánù 4:24) Àwọn èèyàn ni nǹkan kejì tí Párádísè tẹ̀mí jẹ mọ́. Bí Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jèhófà ti kọ́ àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ní àwọn ọ̀nà àlàáfíà “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” Ó mú ogun kúrò pátápátá láàárín wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ aláìpé, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀. Ó ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tó ń mú ká ní àwọn ànímọ́ pàtàkì, ti ìsapá wa lẹ́yìn. (Éfésù 4:22-24; Gálátíà 5:22, 23) Bí o bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run, a jẹ́ pé o ti di apá kan Párádísè tẹ̀mí ní ti gidi nìyẹn.
11 Irú àwọn èèyàn tí Jèhófà ń fẹ́ ló ń kó jọ pọ̀ sínú Párádísè tẹ̀mí yìí, ìyẹn àwọn èèyàn tó fẹ́ràn rẹ̀, tó fẹ́ràn àlàáfíà, tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni yóò láǹfààní láti rí ìmúbọ̀sípò tó tiẹ̀ tún kàmàmà jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìyẹn ìmúbọ̀sípò ìran ènìyàn àti gbogbo ilẹ̀ ayé.
“Wò Ó! Mo Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”
12, 13. (a) Kí nìdí tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò nípa tẹ̀mí yóò tún fi ṣẹ lọ́nà mìíràn? (b) Kí ló jẹ́ ète Jèhófà nípa ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ ní Édẹ́nì, kí sì nìdí tí èyí fi fún wa nírètí nípa ọjọ́ ọ̀la?
12 Púpọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò ló jọ pé ìmúṣẹ rẹ̀ ju kìkì ìmúbọ̀sípò nípa tẹ̀mí lọ. Bí àpẹẹrẹ, Aísáyà kọ̀wé nípa ìgbà kan tí àwọn aláìsàn, arọ, afọ́jú àti adití yóò gba ìwòsàn, tí a óò sì gbé ikú pàápàá mì títí láé. (Aísáyà 25:8; 35:1-7) Irú ìlérí yẹn kò ṣẹ nípa ti ara ní Ísírẹ́lì àtijọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí nípa tẹ̀mí lóde òní, ìdí tó dájú wà fún wa láti gbà gbọ́ pé yóò ṣì ṣẹ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa ti ara lọ́jọ́ iwájú. Báwo ni a ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
13 Jèhófà sọ ète rẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé ní kedere ní Édẹ́nì àtijọ́: Ńṣe ló ń fẹ́ kí ìran ènìyàn tó ṣọ̀kan, tó jẹ́ aláyọ̀, tó sì ní ìlera pípé máa gbébẹ̀. Ó ń fẹ́ kí tọkùnrin tobìnrin máa bójú tó ilẹ̀ ayé àti gbogbo ẹ̀dá inú rẹ̀, kí wọ́n sì sọ gbogbo ilé ayé di Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Èyí yàtọ̀ pátápátá sí bí àwọn nǹkan ṣe wá rí nísinsìnyí. Àmọ́ ṣá, kí ó dá wa lójú pé kò sóhun tó lè dènà ète Jèhófà láé. (Aísáyà 55:10, 11) Jésù tó jẹ́ Mèsáyà tí Jèhófà fi jọba ni yóò mú Párádísè tó kárí ayé yìí wá.—Lúùkù 23:43.
14, 15. (a) Báwo ni Jèhófà yóò ṣe “sọ ohun gbogbo di tuntun”? (b) Báwo ni ìgbésí ayé yóò ṣe rí nínú Párádísè, kí lohun tó sì wù ọ́ jù níbẹ̀?
14 Kàn tiẹ̀ wò ó bó ṣe máa dára tó ká ní gbogbo ayé di Párádísè! Jèhófà sọ nípa àkókò yẹn pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” (Ìṣípayá 21:5) Wo ohun tí ìyẹn yóò túmọ̀ sí ná. Nígbà tí Jèhófà bá ti lo agbára rẹ̀ láti fi pa ètò búburú yìí run, yóò ṣẹ́ ku “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” Èyí tó túmọ̀ sí pé ìjọba tuntun kan yóò máa ṣàkóso lórí àwùjọ èèyàn tuntun lórí ilẹ̀ ayé, tí yóò kún fún kìkì àwọn tó fẹ́ràn Jèhófà tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (2 Pétérù 3:13) A óò sọ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ dẹni tí kò rí nǹkan kan ṣe mọ́. (Ìṣípayá 20:3) Lẹ́yìn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, aráyé á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀dá burúkú, oníwàkiwà, asọnidìbàjẹ́ wọ̀nyẹn. Áà, ìtura ìgbà náà á mà ga o!
15 Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a ó lè bójú tó ilé ayé ẹlẹ́wà yìí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa ṣe láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ilẹ̀ ayé kúkú lágbára láti fúnra rẹ̀ múra bọ̀ sípò. Àwọn adágún omi àti odò tá a ti sọ dìbàjẹ́ lé sọ ara wọn di mímọ́ nigín padà bí a bá dáwọ́ ohun tó ń kó èérí bá a dúró; ojú ilẹ̀ tí ogun ti sọ dìbàjẹ́ lè tún ara rẹ̀ ṣe padà bí ogun bá dáwọ́ dúró. Yóò mà dùn mọ́ni gan-an o láti ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ohun àdáyébá inú ayé láti yí ayé padà di ọgbà ẹlẹ́wà, àní ọgbà Édẹ́nì tó kárí ayé, tó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ìṣẹ̀dá! Dípò pípa táwọn èèyàn ń pa onírúurú ẹranko àti ewéko ayé run dà nù, ńṣe la óò máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ìṣẹ̀dá inú ayé. Kódà kò ní sídìí fún àwọn ọmọdé láti máa bẹ̀rù ẹranko ẹhànnà mọ́.—Aísáyà 9:6, 7; 11:1-9.
16. Ìmúbọ̀sípò wo ni yóò kan olúkúlùkù olóòótọ́ èèyàn nínú Párádísè?
16 Olúkúlùkù wa yóò ní ìmúbọ̀sípò tirẹ̀ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, ìmúláradá yóò wà fún àwọn olùlàájá kárí ayé. Jésù yóò lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti fi la ojú àwọn afọ́jú, láti fi ṣí etí àwọn adití, láti mú arọ àti aláìsàn lára dá gẹ́lẹ́ bí ó ti ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 15:30) Ara àwọn arúgbó yóò tún padà le koko tòun ti okun ìgbà èwe. (Jóòbù 33:25) Ara tó hun jọ á padà máa jà yọ̀yọ̀, ọwọ́ àtẹsẹ̀ tó ti ká kò yóò nà padà, ara á sì padà le pọ́n-ún pọ́n-ún. Gbogbo ọmọ aráyé olóòótọ́ ni yóò hàn sí pé ipa ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti ń tán lọ lára wọn. Ẹnu wa ò ní gbọpẹ́, ètè wa ò ní gba ìyìn sí Jèhófà Ọlọ́run fún lílò tó lo àgbàyanu agbára ìmúbọ̀sípò rẹ̀! Ẹ jẹ́ ká wá pàfiyèsí sí apá kan tó dùn mọ́ni lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nínú àkókò ìmúbọ̀sípò yìí.
Mímú Òkú Sọjí
17, 18. (a) Kí nìdí tí Jésù fi bá àwọn Sadusí wí? (b) Kí lohun tó mú kí Èlíjà ké pe Jèhófà pé kí ó jí ọmọ kan dìde?
17 Ní ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn aṣáájú ìsìn kan tí à ń pè ní Sadusí kò gbà pé àjíǹde wà. Jésù fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bá wọn wí, ó ní: “Ẹ ṣàṣìṣe, nítorí ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tàbí agbára Ọlọ́run.” (Mátíù 22:29) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Jèhófà ní agbára láti jí òkú dìde. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
18 Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Èlíjà ná. Opó kan gbé ọmọ rẹ̀ tó ti sọra nù dání. Ọmọ náà ti kú. Kàyéfì lọ̀rọ̀ náà ní láti jẹ́ fún wòlíì Èlíjà tó ti dé sí opó yìí lọ́dọ̀ látìgbà díẹ̀ sẹ́yìn. Ṣáájú ìgbà tí à ń wí yìí, Èlíjà ti kọ́kọ́ gba ẹ̀mí ọmọ yìí là tí ò jẹ́ kí ebi lù ú pa. Ó ṣeé ṣe kí Èlíjà àti ọmọ kékeré yìí tiẹ̀ ti wá mojú ara wọn dáadáa. Láìsí àní-àní, ikú ọmọ náà dun ìyá rẹ̀ gidigidi. Ọmọ yìí nìkan ni obìnrin yìí fi ń rántí ọkọ rẹ̀ tó ti kú. Bóyá obìnrin náà tiẹ̀ ń rò ó tẹ́lẹ̀ pé ọmọ yìí ni yóò tọ́jú òun lọ́jọ́ ogbó. Ọkàn opó yìí dà rú, ó sì ń bẹ̀rù pé àfàìmọ̀ ni ò fi ní jẹ́ pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tóun ti ṣẹ̀ sẹ́yìn lòun ń jẹ. Ara Èlíjà ò gbà á, kò fẹ́ kí ìrònú ìyẹn tún kún àjálù tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Ló bá rọra gbé òkú ọmọ yìí láyà ìyá rẹ̀, ó gbé e lọ sí yàrá tiẹ̀, ó sì ké pe Jèhófà Ọlọ́run pé kí ó mú kí ọkàn, tàbí ẹ̀mí ọmọ náà padà sínú rẹ̀.—1 Àwọn Ọba 17:8-21.
19, 20. (a) Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun nígbàgbọ́ pé Jèhófà lágbára láti mú nǹkan bọ̀ sípò, kí ló sì jẹ́ kó ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe san èrè fún Èlíjà nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀?
19 Kì í ṣe Èlíjà ló kọ́kọ́ máa nígbàgbọ́ nínú àjíǹde. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni Ábúráhámù ti gbà gbọ́ pé Jèhófà ní agbára láti múni bọ̀ sípò, ó sì nídìí tó ṣe gúnmọ́ tó fi gbà bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún tí Sárà jẹ́ àádọ́rùn-ún ọdún, Jèhófà mú ẹ̀ya ara ìbímọ wọn sọjí, ó sì mú kí Sára bí ọmọkùnrin kan lọ́nà ìyanu. (Jẹ́nẹ́sísì 17:17; 21:2, 3) Nígbà tó yá, tí ọmọ náà ti dàgbà, Jèhófà ní kí Ábúráhámù fi ọmọ rẹ̀ yìí rúbọ. Ábúráhámù lo ìgbàgbọ́, ó gbà pé Jèhófà lè mú Ísákì ọmọ òun olùfẹ́ sọjí padà. (Hébérù 11:17-19) Ó lè jẹ́ ìgbàgbọ́ alágbára yẹn ló jẹ́ kí Ábúráhámù mú un dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú ní kété ṣáájú kó tó gorí òkè láti fi ọmọ rẹ̀ rúbọ, pé òun àti Ísákì ń padà bọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 22:5.
20 Àmọ́ ṣá o, Jèhófà dá ẹ̀mí Ísákì sí, ìyẹn ni kò fi sídìí láti máa wá jí i dídè nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ṣùgbọ́n nígbà ti Èlíjà, ńṣe ni ọmọ opó yẹn kú ní tiẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé fúngbà díẹ̀ ni. Jèhófà jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wòlíì yìí lérè, ó jí ọmọ náà dìde! Èlíjà wá fa ọmọ náà lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì sọ ọ̀rọ̀ mánigbàgbé yìí, pé: “Wò ó, ọmọkùnrin rẹ yè”!—1 Àwọn Ọba 17:22-24.
21, 22. (a) Kí ni ète àwọn àjíǹde tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́? (b) Nínú Párádísè, báwo ni àwọn tá a jí dìde yóò ṣe pọ̀ tó, ta ni yóò sì jí wọn dìde?
21 Ìyẹn ló wá jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tó máa hàn nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì pé Jèhófà lo agbára rẹ̀ láti mú ẹ̀mí èèyàn bọ̀ sípò. Lẹ́yìn náà, Jèhófà tún fún Èlíṣà, Jésù, Pọ́ọ̀lù àti Pétérù lágbára láti jí òkú dìde. Lóòótọ́, àwọn tá a jí dìde tún padà kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn o. Síbẹ̀síbẹ̀, irú àkọsílẹ̀ Bíbélì bẹ́ẹ̀ fún wa ní àpẹẹrẹ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
22 Nínú Párádísè, Jésù yóò ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí í ṣe “àjíǹde àti ìyè.” (Jòhánù 11:25) Yóò jí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn dìde, yóò sì fún wọn láǹfààní láti máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 5:28, 29) Áà, ọjọ́ lọjọ́ náà tí tẹbí tọ̀rẹ́ tí ikú ti yà nípa láti ọjọ́ pípẹ́ yóò tún fojú kanra! Fojú inú wo bí wọn yóò ṣe sáré dì mọ́ra gbàgì pẹ̀lú ayọ̀ ńláǹlà! Gbogbo ènìyàn yóò wá máa yin Jèhófà lógo fún lílò tó lo agbára rẹ̀ láti mú àwọn nǹkan bọ̀ sípò.
23. Kí ni ọ̀nà gíga jù lọ tí Jèhófà gbà fi agbára rẹ̀ hàn, báwo lèyí sì ṣe mú kí ìrètí wa ọjọ́ ọ̀la dájú hán-ún hán-ún?
23 Jèhófà ti fúnni ní ẹ̀rí tó dájú hán-ún hán-ún pé ìrètí yẹn kò lè yẹ̀. Jèhófà fi agbára rẹ̀ hàn lọ́nà gíga jù lọ ní ti pé ó jí Jésù Ọmọ rẹ̀ dìde sípò ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ńlá, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹni tí ipò rẹ̀ tẹ̀ lé ti Jèhófà. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ni Jésù fara hàn nígbà tó jíǹde. (1 Kọ́ríńtì 15:5, 6) Béèyàn bá tiẹ̀ jẹ́ oníyèmejì ẹ̀dá pàápàá, ó yẹ kí ẹ̀rí yìí mú kó gbà pé òótọ́ ni ìrètí yìí. Jèhófà lágbára láti mú ẹ̀mí ẹni padà bọ̀ sípò.
24. Kí nìdí tí a fi lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò jí àwọn òkú dìde, kí ló sì yẹ kó máa wà lọ́kàn olúkúlùkù wa pé a fẹ́ ṣe?
24 Kì í ṣe pé Jèhófà lágbára láti jí òkú dìde nìkan ni, àní ó tiẹ̀ ń fẹ́ láti jí wọn dìde. Ọlọ́run mí sí Jóòbù láti sọ ọ́ pé Jèhófà tiẹ̀ máa ń ṣe àfẹ́rí bí yóò ṣe jí àwọn òkú dìde. (Jóòbù 14:15) Ǹjẹ́ ọkàn rẹ kò fà mọ́ Ọlọ́run wa tó ń hára gàgà láti lo agbára ìmúbọ̀sípò rẹ̀ lọ́nà onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀? Àmọ́ ṣá o, rántí pé apá kan nínú iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò ńláǹlà tí Jèhófà yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú ni àjíǹde jẹ́. Bí o ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ ọn tímọ́tímọ́, jẹ́ kó máa wà lọ́kàn rẹ̀ nígbà gbogbo pé wàá fẹ́ wà níbẹ̀ láti rí bí Jèhófà yóò ṣe máa “sọ ohun gbogbo di tuntun.”—Ìṣípayá 21:5.
a “Àkókò ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo” bẹ̀rẹ̀ nígbà tí a gbé Ìjọba Mèsáyà kalẹ̀ tí ajogún Dáfídì Ọba sì gorí ìtẹ́ rẹ̀. Ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ni pé ajogún rẹ̀ kan yóò máa ṣàkóso títí ayérayé. (Sáàmù 89:35-37) Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, kò sí ọmọ èèyàn kankan tó jẹ́ irú ọmọ Dáfídì tó ń ṣàkóso lórí ìtẹ́ Ọlọ́run. Jésù, tá a bí lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ajogún Dáfídì, ló wá di Ọba tá a ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́ náà nígbà tó jọba ní ọ̀run.
b Bí àpẹẹrẹ, gbogbo àwọn èèyàn tó tẹ̀ lé e yìí pátá ló sọ̀rọ̀ lórí kókó yẹn: Mósè, Aísáyà, Jeremáyà, Ìsíkíẹ́lì, Hóséà, Jóẹ́lì, Ámósì, Ọbadáyà, Míkà àti Sefanáyà.