ORÍ 21
“Orúkọ Ìlú Náà Yóò Máa Jẹ́ Jèhófà Wà Níbẹ̀”
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ohun tí ìlú náà àti ọrẹ túmọ̀ sí
1, 2. (a) Apá wo ni wọ́n máa yà sọ́tọ̀ lákànṣe ní ilẹ̀ náà? (Wo àwòrán tó wà lára èèpo ìwé yìí.) (b) Ọ̀nà wo ni ìran yìí gbà fi àwọn tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀?
NÍNÚ ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí kẹ́yìn, ó rí apá kan ilẹ̀ náà tí wọ́n máa yà sọ́tọ̀ lákànṣe. Wọn ò ní pín ibẹ̀ fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì kankan, àmọ́ wọ́n máa yà á sọ́tọ̀, ó sì máa jẹ́ ọrẹ fún Jèhófà. Ìsíkíẹ́lì tún rí ìlú kan tó gbàfiyèsí tí orúkọ rẹ̀ sì ṣàrà ọ̀tọ̀. Ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí ló ṣe pàtàkì jù nínú ohun tó ń fi àwọn tó wà nígbèkùn náà lọ́kàn balẹ̀, ìyẹn sì ni pé: Jèhófà máa wà pẹ̀lú wọn tí wọ́n bá pa dà sí ìlù ìbílẹ̀ wọn tí wọ́n fẹ́ràn.
2 Ìsíkíẹ́lì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí ọrẹ náà ṣe rí. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó sọ, torí pé ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ ló ní fún àwa tá à ń ṣe ìjọsìn tòótọ́.
“Ilẹ̀ Mímọ́ Pẹ̀lú . . . Ìlú Náà”
3. Apá márùn-ún wo ni ilẹ̀ tí Jèhófà yà sọ́tọ̀ pín sí? Kí sì ni apá kọ̀ọ̀kan wà fún? (Wo àpótí náà, “Ilẹ̀ Tí Ẹ Ó Yà Sọ́tọ̀ Láti Fi Ṣe Ọrẹ.”)
3 Ilẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ (kìlómítà 13) láti àríwá sí gúúsù, ó sì tún jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn. Ilẹ̀ náà dọ́gba lẹ́gbẹ̀ẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, Bíbélì sì pè é ní “Gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n fi ṣe ọrẹ.” Wọ́n pín in sí ọ̀nà mẹ́ta ní ìbú. Ibi tó wà lápá òkè jẹ́ ti àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì ya ibi tó wà ní àárín sọ́tọ̀ fún tẹ́ńpìlì àtàwọn àlùfáà. Apá méjèèjì yẹn ló para pọ̀ jẹ́ “ilẹ̀ [tàbí ọrẹ] mímọ́.” Apá kékeré tó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ ìsàlẹ̀ tàbí “ibi tó ṣẹ́ kù,” jẹ́ ti “gbogbo ìlú.” Ó wà fún ìlú náà.—Ìsík. 48:15, 20.
4. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àkọsílẹ̀ nípa ọrẹ sí Jèhófà?
4 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àkọsílẹ̀ nípa ọrẹ sí Jèhófà? Bó ṣe jẹ́ pé ilẹ̀ tó jẹ́ ọrẹ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sọ́tọ̀, tí wọ́n sì wá pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà lẹ́yìn náà, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ibi tó jẹ́ ojúkò ìjọsìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà. (Ìsík. 45:1) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ làwọn tó wà nígbèkùn yìí kọ́ látinú bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ pínpín ilẹ̀ náà láti ibi tó ṣe pàtàkì jù. Ìjọsìn Jèhófà ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi sípò àkọ́kọ́ láyé wọn. Bákan náà lónìí, àwọn nǹkan tẹ̀mí, irú bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wíwá sáwọn ìpàdé Kristẹni àti kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù la kà sí pàtàkì jù. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe fi ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́, àá lè máa fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo lójoojúmọ́ ayé wa.
“Ìlú Náà Yóò Wà ní Àárín Rẹ̀”
5, 6. (a) Àwọn wo ni ìlú náà wà fún? (b) Kí ni ìlú náà kò jẹ́, kí sì nìdí?
5 Ka Ìsíkíẹ́lì 48:15. Kí ni “ìlú náà” àti ilẹ̀ tó yí i ká wà fún? (Ìsík. 48:16-18) Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì nínú ìran pé: Ìlú náà “yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.” (Ìsík. 45:6, 7) Torí náà, ìlú náà àti ilẹ̀ tó yí i ká kò sí lára “ilẹ̀ [tàbí ọrẹ] mímọ́” tí wọ́n máa “yà sọ́tọ̀ . . . fún Jèhófà.” (Ìsík. 48:9) Ẹ jẹ́ ká fi ìyàtọ̀ yìí sọ́kàn, ká wá jọ wo ohun tá a rí kọ́ lóde òní nínú ètò tí wọ́n ṣe nípa ìlú náà.
6 Ká tó lè mọ àwọn ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú ìlú náà, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ ohun tí ìlú náà kò jẹ́. Ìlú náà kì í ṣe ìlú Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ tí wọ́n tún kọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kò sí tẹ́ńpìlì nínú ìlú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran yẹn. Bákan náà, ìlú náà kì í ṣe ìlú èyíkéyìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì tá a mú pa dà bọ̀ sípò. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ìgbèkùn tó pa dà náà tàbí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ò fìgbà kankan kọ́ ìlú èyíkéyìí tó ní àwọn ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ìlú náà kì í ṣe ìlú tó wà ní ọ̀run. Kí nìdí? Torí pé orí ilẹ̀ “tó jẹ́ ti gbogbo èèyàn [tàbí tí kì í ṣe ilẹ̀ mímọ́]” ni wọ́n kọ́ ọ sí, ìyẹn sì yàtọ̀ sí ilé tí wọ́n kọ́ sórí ilẹ̀ tí wọ́n dìídì yà sọ́tọ̀ fún ìjọsìn mímọ́.—Ìsík. 42:20.
7. Kí ni ìlú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran náà? Kí ló ṣeé ṣe kí ìlú náà ṣàpẹẹrẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)
7 Kí wá ni ìlú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran náà? Ẹ má gbàgbé pé inú ìran tó ti rí ilẹ̀ náà ló ti rí ìlú yẹn. (Ìsík. 40:2; 45:1, 6) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ilẹ̀ tẹ̀mí ni ilẹ̀ náà, torí náà ìlú náà ní láti jẹ́ ìlú tẹ̀mí. Kí ló túmọ̀ sí tá a bá pe ibì kan ní “ìlú”? Ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí ibi tí àwọn èèyàn jọ ń gbé, tí wọ́n ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe nǹkan àti ètò tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Torí náà, ìlú tó wà létòlétò tí Ìsíkíẹ́lì rí, tí ààlà rẹ̀ dọ́gba ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ṣeé ṣe kó ṣàpẹẹrẹ ibùjókòó ìjọba kan tó wà létòlétò.
8. Ibo ni ìjọba yìí ń ṣàkóso lé lórí tàbí tó nasẹ̀ dé, kí sì nìdí?
8 Ibo ni ìjọba yìí ń ṣàkóso lé lórí tàbí tó nasẹ̀ dé? Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí fi hàn pé àwọn ohun tó ń wáyé ní ìlú náà ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ tẹ̀mí. Ìyẹn fi hàn pé, lóde òní, àárín àwọn èèyàn Ọlọ́run ni ìjọba náà ti ń ṣàkóso. Kí ló wá túmọ̀ sí nígbà tí wọ́n sọ pé ilẹ̀ náà jẹ́ ti gbogbo èèyàn tàbí pé kì í ṣe ilẹ̀ mímọ́? Ìyẹn rán wa létí pé kì í ṣe ìjọba tó wà ní ọ̀run ni ìlú náà ń tọ́ka sí, àmọ́ ó ń tọ́ka sí ètò ìjọba tó wà lórí ilẹ̀ ayé, èyí tí gbogbo àwọn tó wà nínú párádísè tẹ̀mí ń jàǹfààní rẹ̀.
9. (a) Àwọn wo ni alákòóso nínú ètò ìjọba orí ilẹ̀ ayé yẹn lóde òní? (b) Kí ni Jésù máa ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀?
9 Àwọn wo ni alákòóso nínú ètò ìjọba orí ilẹ̀ ayé yẹn? Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, ó pe ẹni tó ń múpò iwájú nínú ìjọba ìlú náà ní “ìjòyè.” (Ìsík. 45:7) Ìjòyè náà ń ṣe àbójútó àwọn èèyàn, àmọ́ kì í ṣe àlùfáà, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ọmọ Léfì. Ìjòyè yìí rán wa létí àwọn alábòójútó ìjọ Ọlọ́run lóde òní tí wọn kì í ṣe ẹni àmì òróró. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn yìí ń fìfẹ́ bójú tó agbo Ọlọ́run, wọ́n jẹ́ ara àwọn “àgùntàn mìíràn,” wọ́n sì ń fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ojúṣe wọn lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìjọba Kristi tó wà lọ́run. (Jòh. 10:16) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù máa yan àwọn alàgbà tàbí àwọn “olórí” tó kúnjú ìwọ̀n sípò “ní gbogbo ayé.” (Sm. 45:16) Ìjọba Ọlọ́run tó wà lọ́run máa darí wọn láti bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà.
“Jèhófà Wà Níbẹ̀”
10. Kí ni orúkọ ìlú náà? Kí nìyẹn mú kó dá wọn lójú?
10 Ka Ìsíkíẹ́lì 48:35. Orúkọ ìlú náà ni “Jèhófà Wà Níbẹ̀.” Orúkọ yìí mú kó dá wọn lójú pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú náà. Bí Jèhófà ṣe fi ìlú tó wà ní àárín gbùngbùn yìí han Ìsíkíẹ́lì, ó ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ fún àwọn tó wà nígbèkùn yẹn pé: ‘Màá tún wà pẹ̀lú yín lọ́tẹ̀ yìí!’ Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ gan-an!
11. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ nípa ìlú náà àti ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀?
11 Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ yìí? Orúkọ ìlú tá a mẹ́nu bà yìí fi dá àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lójú lóde òní pé Jèhófà wà pẹ̀lú àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé báyìí, kò sì ní fi wá sílẹ̀ nígbà kankan. Orúkọ tó nítumọ̀ yìí tún tẹnu mọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan: Kì í ṣe láti fún ẹnikẹ́ni lágbára ni ìlú náà ṣe wà, àmọ́ láti mú káwọn èèyàn máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà tó bọ́gbọ́n mu, tó sì fìfẹ́ hàn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ò fún àwọn tó ń ṣàkóso ìlú náà láṣẹ láti pín ilẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ náà, bó ṣe lè dà bíi pé ó tọ́ lójú àwa èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà retí pé kí àwọn alákòóso yẹn tẹ̀ lé ètò pínpín ilẹ̀ náà, tàbí àǹfààní tí òun fún àwọn ìránṣẹ́ òun, títí kan àwọn “aláìní.”—Òwe 19:17; Ìsík. 46:18; 48:29.
12. (a) Nǹkan pàtàkì míì wo ló tún wà ní ìlú náà? Kí nìyẹn fi hàn? (b) Ohun pàtàkì wo lèyí ń rán àwọn Kristẹni alábòójútó létí?
12 Nǹkan pàtàkì míì wo ló tún wà ní ìlú tá a pe orúkọ rẹ̀ ní “Jèhófà Wà Níbẹ̀”? Wọ́n sábà máa ń mọ odi yí àwọn ìlú àtijọ́ ká, ẹnubodè wọn kì í sì í pọ̀ rárá, àmọ́ ní ti ìlú tá à ń sọ yìí, ẹnubodè méjìlá (12) ló ní! (Ìsík. 48:30-34) Bí àwọn ẹnubodè ìlú náà ṣe pọ̀ dáadáa (ẹnubodè mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ògiri mẹ́rin tó yí ìlú náà ká) fi hàn pé àwọn alákòóso ìlú náà ṣeé sún mọ́, wọ́n sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ẹnubodè méjìlá (12) náà tún jẹ́ kó ṣe kedere pé ó wà fún gbogbo èèyàn, ìyẹn “gbogbo ilé Ísírẹ́lì.” (Ìsík. 45:6) Bí ìlú náà ṣe ní ẹnubodè tó pọ̀ fún àwọn èèyàn ń rán àwọn Kristẹni alábòójútó létí ohun pàtàkì kan. Jèhófà fẹ́ kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, tó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo àwọn tó ń gbé inú párádísè tẹ̀mí.
Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Ń “Wọlé Láti Jọ́sìn,” Wọ́n sì “Ń Ṣiṣẹ́ Nínú Ìlú Náà”
13. Kí ni Jèhófà sọ nípa oríṣiríṣi iṣẹ́ tí àwọn èèyàn á máa ṣe?
13 Ẹ jẹ́ ká pa dà sígbà ayé Ìsíkíẹ́lì, ká sì wo àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míì tó kọ sínú ìran tó gbòòrò tó sọ nípa pínpín ilẹ̀ náà. Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsìn. Àwọn àlùfáà, ìyẹn “àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́,” láá máa rúbọ, tí wọ́n á sì máa wá síwájú Jèhófà láti ṣiṣẹ́ fún un. Àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn “àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì,” ni wọ́n á “máa bójú tó ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ àti gbogbo nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe nínú rẹ̀.” (Ìsík. 44:14-16; 45:4, 5) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òṣìṣẹ́ á máa jára mọ́ṣẹ́ nítòsí ìlú náà. Àwọn wo làwọn òṣìṣẹ́ yìí?
14. Kí ni àwọn òṣìṣẹ́ tó wà ní tòsí ìlú náà rán wa létí rẹ̀?
14 Inú “gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì” ni àwọn òṣìṣẹ́ náà ti wá. Iṣẹ́ ìtìlẹ́yìn ni wọ́n ń ṣe. Ojúṣe wọn ni pé kí wọ́n dá oko tí wọ́n á fi máa pèsè oúnjẹ fún “àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ìlú náà.” (Ìsík. 48:18, 19) Ǹjẹ́ ètò yìí rán wa létí àǹfààní kan tá a ní lóde òní? Bẹ́ẹ̀ ni. Lóde òní gbogbo àwọn tó wà nínú párádísè tẹ̀mí ló láǹfààní láti máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin Kristi tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn àti àwọn tí Jèhófà yàn láti máa múpò iwájú lára àwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn.” (Ìfi. 7:9, 10) Ọ̀nà pàtàkì kan tá à ń gbà tì wọ́n lẹ́yìn ni bá a ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹrú olóòótọ́ náà tinútinú.
15, 16. (a) Kúlẹ̀kúlẹ̀ míì wo ló tún wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí? (b) Kí la láǹfààní láti máa ṣe tó jọ tinú ìran yẹn?
15 Kúlẹ̀kúlẹ̀ míì tún wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí tó lè kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan nípa iṣẹ́ ìsìn wa. Kí nìyẹn ná? Jèhófà sọ pé àwọn tó wà lára ẹ̀yà méjìlá (12) tí wọn kì í ṣe ọmọ Léfì máa wà lẹ́nu iṣẹ́ níbi méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì àti níbi ìjẹko ìlú náà. Kí ni wọ́n á máa ṣe láwọn ibẹ̀ yẹn? Gbogbo ẹ̀yà máa ń “wọlé láti jọ́sìn” nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì, wọ́n máa ń rúbọ sí Jèhófà níbẹ̀. (Ìsík. 46:9, 24) Àwọn tó wà nínú gbogbo ẹ̀yà máa ń dáko lórí ilẹ̀ náà láti ṣètìlẹ́yìn fún ìlú náà. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn òṣìṣẹ́ yìí?
16 Lóde òní, àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ èèyàn láǹfààní láti máa ṣe àwọn ohun tó jọ ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà “nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀” nípasẹ̀ ẹbọ ìyìn tí wọ́n ń rú. (Ìfi. 7:9-15) Ìyẹn bí wọ́n ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti bí wọ́n ṣe ń sọ ìgbàgbọ́ wọn jáde láwọn ìpàdé Kristẹni. Wọ́n gbà pé èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú ojúṣe àwọn ni pé káwọn máa sin Jèhófà ní tààràtà. (1 Kíró. 16:29) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣètìlẹ́yìn fún ètò Ọlọ́run ní onírúurú ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé àti àbójútó àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ẹ̀ka ọ́fíìsì àti lẹ́nu àwọn iṣẹ́ míì tí ètò Jèhófà ń ṣe. Àwọn míì ń fi owó wọn ṣètìlẹ́yìn fún àwọn iṣẹ́ náà. Ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń dáko lórí ilẹ̀ náà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, “fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 10:31) Wọ́n ń fìtara ṣe iṣẹ́ wọn, wọ́n sì ń ṣe é tayọ̀tayọ̀, torí wọ́n mọ̀ pé “inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.” (Héb. 13:16) Ṣé ìwọ náà kì í jẹ́ kí irú àwọn àǹfààní yìí bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́?
“À Ń Retí Ọ̀run Tuntun àti Ayé Tuntun”
17. (a) Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lọ́jọ́ iwájú? (b) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn wo ló máa jàǹfààní àkóso ibi tó dà bí ìlú náà?
17 Ǹjẹ́ a máa rí bí ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa ọrẹ ṣe máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lọ́jọ́ iwájú? Bẹ́ẹ̀ ni! Wo àpẹẹrẹ yìí: Ìsíkíẹ́lì rí i pé àárín ilẹ̀ náà ni ibi tí wọ́n pè ní “ilẹ̀ [tàbí ọrẹ] mímọ́” wà. (Ìsík. 48:10) Lọ́nà kan náà, ibi yòówù ká máa gbé ní ayé lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, Jèhófà á máa bá wa gbé. (Ìfi. 21:3) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn alákòóso tó ń bójú tó ibi tó dà bí ìlú náà, ìyẹn àwọn tá a máa yàn sípò ní ayé láti bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run, máa nasẹ̀ àbójútó wọn dé ibi gbogbo láyé ní ti pé wọ́n á máa fìfẹ́ darí gbogbo àwọn tó máa wà nínú “ayé tuntun,” ìyẹn àwùjọ àwọn èèyàn tuntun, wọ́n á sì máa tọ́ wọn sọ́nà.—2 Pét. 3:13.
18. (a) Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé àwọn alákòóso tó ń bójú tó ibi tó dà bí ìlú náà máa ṣàkóso lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́? (b) Kí ni orúkọ ìlú náà mú kó dá wa lójú?
18 Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé àwọn alákòóso tó ń bójú tó ibi tó dà bí ìlú náà á máa ṣàkóso lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́? Ìdí ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kó ṣe kedere pé ìlú tó ní ẹnubodè méjìlá (12) ní ayé yẹn ń rán wa létí Jerúsálẹ́mù Tuntun, ìlú tó ní ẹnubodè méjìlá (12) ní ọ̀run, ìyẹn Kristi àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jọ máa ṣàkóso. (Ìfi. 21:2, 12, 21-27) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ìpinnu tí àwọn alákòóso ìjọba náà bá ń ṣe láyé á máa bá ti Ìjọba Ọlọ́run mu ní ọ̀run, wọ́n á sì máa fara balẹ̀ tẹ̀ lé e. Àní sẹ́, orúkọ ìlú tí wọ́n pè ní “Jèhófà Wà Níbẹ̀” fi dá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lójú pé ìjọsìn mímọ́ á máa wà nìṣó, á sì máa gbèrú títí láé nínú Párádísè. Ẹ ò rí i pé ọjọ́ iwájú ológo ló ń dúró dè wá!