‘Ni Orukọ Ẹmi Mímọ́’
“Nitori naa ẹ lọ ki ẹ sì sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, ki ẹ maa bamtisi wọn ni orukọ . . . ẹmi mímọ́.”—MATIU 28:19, NW.
1. Ọrọ titun wo ni Johanu Arinibọmi lo ni isopọ pẹlu ẹmi mímọ́?
NI ỌDUN 29 ti Sanmani Tiwa, Johanu Arinibọmi jẹ́ agbékánkánṣiṣẹ́ ni Isirẹli ninu pipese ọna silẹ fun Mesaya naa, ati lakooko iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀, ó kéde ohun kan ti ó jẹ́ titun nipa ẹmi mímọ́. Nitootọ, awọn Juu ti mọ ohun ti Iwe Mímọ́ lede Heberu wi nipa ẹmi tẹlẹ. Bi o ti wu ki o ri, ẹnu ti lè yà wọn nigba ti Johanu wi pe: “Loootọ ni emi ń fi omi bamtisi yin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti . . . ń bọ lẹhin mi, . . . yoo fi ẹmi mímọ́ . . . bamtisi yin.” (Matiu 3:11) ‘Fifi ẹmi mímọ́ bamtisi’ jẹ́ ifihan titun kan.
2. Ọrọ titun wo ni Jesu nasẹ ti ó wémọ́ ẹmi mímọ́?
2 Ẹni naa ti ń bọ ni Jesu. Lakooko igbesi-aye rẹ̀ ori ilẹ-aye, Jesu kò fi ẹmi mímọ́ bamtisi ẹnikẹni, bi o tilẹ jẹ pe oun sọrọ nipa ẹmi naa ni ọpọlọpọ ìgbà. Ju bẹẹ lọ, lẹhin ajinde rẹ̀, ó tọka si ẹmi mímọ́ ni ọna titun miiran sibẹ. Ó sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Nitori naa ẹ lọ ki ẹ sì sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, ki ẹ maa bamtisi wọn ni orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin ati ti ẹmi mímọ́.” (Matiu 28:19, NW) Ọrọ naa “ni orukọ” tumọsi “ni mímọ̀dájú.” Bamtisimu inu omi ni mímọ Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ daju ni ó nilati yatọ sí fifi ẹmi mímọ́ bamtisi lẹẹkansii. Ó tun jẹ ifihan titun pẹlu ti o mu ẹmi mimọ lọwọ.
Fi Ẹmi Mímọ́ Bamtisi
3, 4. (a) Nigba wo ni fifi ẹmi mímọ́ bamtisi akọkọ wáyé? (b) Yatọ si bibamtisi wọn, bawo ni ẹmi mímọ́ ṣe ṣiṣẹ siha ọdọ awọn ọmọ-ẹhin Jesu ni Pẹntikọsi 33 C.E.?
3 Niti fifi ẹmi mímọ́ bamtisi, Jesu ṣeleri fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni kété ṣaaju igoke-re-ọrun rẹ̀: “A ó fi ẹmi mímọ́ bamtisi yin kii ṣe ni ọjọ pupọ lẹhin eyi.” (Iṣe 1:5, 8, NW) Laipẹ lẹhin naa ileri yẹn ni a muṣẹ. Ẹmi mímọ́ sọkalẹ sori 120 awọn ọmọ-ẹhin ti wọn pejọpọ ninu iyàrá oke ni Jerusalẹmu bí Jesu, lati ọrun wá, ti fi ẹmi mímọ́ ṣe bamtisi akọkọ. (Iṣe 2:1-4, 33) Pẹlu iyọrisi wo? Awọn ọmọ-ẹhin di apakan ara tẹmi Kristi. Gẹgẹ bi apọsiteli Pọọlu ti ṣalaye, “ninu ẹmi kan ni a ti bamtisi gbogbo [wọn] sinu ara kan.” (1 Kọrinti 12:13) Lakooko kan naa, a fi ẹmi bi wọn, a fami ororo yan wọn lati jẹ́ ọba ati alufaa ọjọ-ọla ni Ijọba Ọlọrun ti ọrun. (Efesu 1:13, 14; 2 Timoti 2:12; Iṣipaya 20:6) Ẹmi mímọ́ tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi èdídí ati àmì akọkọ ti ogún ọjọ-ọla ologo yẹn, ṣugbọn gbogbo rẹ̀ kọ́ niyẹn.—2 Kọrinti 1:21, 22.
4 Ni iwọnba ọdun diẹ ṣaaju, Jesu ti sọ fun Nikodemu pe: “Bikoṣepe a tun eniyan bí, oun kò lè ri ijọba Ọlọrun. . . . Bikoṣepe a fi omi ati ẹmi bi eniyan, oun kò lè wọ ijọba Ọlọrun.” (Johanu 3:3, 5) Nisinsinyi 120 eniyan ni a ti tún bí. Nipasẹ ẹmi mímọ́, a ti gbà wọn ṣọmọ gẹgẹ bi ọmọkunrin Ọlọrun, arakunrin Kristi. (Johanu 1:11-13; Roomu 8:14, 15) Gbogbo igbokegbodo ẹmi mímọ́ wọnyi tubọ jẹ́ agbayanu ni ọna ti wọn ju iṣẹ iyanu lọ. Ju bẹẹ lọ, laidabi awọn iṣẹ iyanu igbakanri, ẹmi mímọ́ kò dawọ duro lẹhin iku awọn apọsiteli ṣugbọn ó ti ń baa lọ lati jẹ́ agbékánkánṣiṣẹ́ ni ọna yii titi di ọjọ wa. Ó jẹ anfaani awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati ni awọn mẹmba ara Kristi ti a fẹmi bamtisi ti o kẹhin laaarin wọn, awọn wọnyi sì ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” lati pese ounjẹ tẹmi ni akoko titọ.—Matiu 24:45-47.
Bamtisi “ni Orukọ . . . Ẹmi Mímọ́”
5, 6. Bawo ni fifi ẹmi mímọ́ bamtisi akọkọ ṣe ṣamọna si bamtisimu ninu omi?
5 Ṣugbọn ki ni niti bamtisimu inu omi ni orukọ Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ ti a ṣeleri? Awọn ọmọ-ẹhin akọkọ wọnni ti a fi ẹmi bamtisi kò niriiri iru bamtisimu inu omi kan bẹẹ. Wọn ti gba bamtisimu inu omi ti Johanu ṣaaju, niwọn ìgbà ti iyẹn sì ti ṣetẹwọgba fun Jehofa ni akoko pato yẹn, a kò nilati tún wọn bamtisi mọ́. Ṣugbọn ni Pẹntikọsi 33 C.E., ogunlọgọ nla awọn ọkàn gba bamtisimu inu omi titun naa. Bawo ni eyi ṣe wáyé?
6 Fifi ẹmi mímọ́ bamtisi 120 ni ariwo ńlá kan ti ó fa awọn ogunlọgọ mọra ti bá rìn. Awọn wọnyi ni ẹnu yà lati gbọ ti awọn ọmọ-ẹhin ń fi èdè fọ̀, iyẹn ni pe, ní awọn èdè ajeji ti awọn ti ó wà nibẹ loye. Apọsiteli Peteru ṣalaye pe iṣẹ iyanu yii jẹ́ ẹ̀rí pe ẹmi Ọlọrun ni a ti tú jade nipasẹ Jesu, ẹni ti a ti ji dide lati inu oku ti ó sì jokoo nisinsinyi ni ọwọ ọtun Ọlọrun ni ọrun. Peteru fun awọn olugbọ rẹ̀ niṣiiri pe: “Ki gbogbo ile Isirẹli mọ̀ dajudaju pe Ọlọrun ti sọ ọ di Oluwa ati Kristi, Jesu yii ẹni ti ẹyin kànmọ́gi.” Oun lẹhin naa pari ọrọ nipa sisọ pe: “Ẹ ronupiwada, ẹ sì jẹ́ ki a bamtisi olukuluku yin ni orukọ Jesu Kristi fun idariji awọn ẹ̀ṣẹ̀ yin, ẹyin yoo si rí ẹbun ọ̀fẹ́ ẹmi mímọ́ gbà.” Nǹkan bi 3,000 ọkàn dahunpada.—Iṣe 2:36, 38, 41, NW.
7. Ni ọna wo ni 3,000 ti a bamtisi ni Pẹntikọsi 33 C.E. gbà ṣe bamtisi ni orukọ ti Baba, ti Ọmọkunrin, ati ti ẹmi mímọ́?
7 Njẹ a lè sọ pe awọn wọnyi ni a bamtisi ni orukọ (ni mímọ) Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ (dájú) bi? Bẹẹni. Bi o tilẹ jẹ pe Peteru kò sọ fun wọn lati bamtisi ni orukọ Baba, wọn mọ Jehofa daju gẹgẹ bi Oluwa Ọba-alaṣẹ tẹlẹ, niwọn bi wọn ti jẹ Juu nipa ti ara, mẹmba orilẹ-ede kan ti a yà sí mímọ́ fun un. Peteru kò sọ pe: ‘Ẹ bamtisi ni orukọ Ọmọkunrin.’ Nitori naa bamtisimu wọn duro fun mímọ Jesu daju gẹgẹ bi Oluwa ati Kristi wọn. Wọn jẹ́ ọmọ-ẹhin rẹ̀ nisinsinyi wọn sì gba pe idariji awọn ẹṣẹ wọn jẹ́ nipasẹ rẹ̀ lati isinsinyi lọ. Nikẹhin, bamtisimu naa jẹ́ ni mímọ ẹmi mímọ́ daju, a sì ṣe é ni idahunpada si ileri naa pe wọn yoo gba ẹmi naa gẹgẹ bi ẹbun ọ̀fẹ́ kan.
8. (a) Ni afikun si bamtisimu inu omi, bamtisimu miiran wo ni awọn Kristẹni ẹni ami ororo ti gbà? (b) Awọn wo yatọ si 144,000 ni wọn gba bamtisimu inu omi ni orukọ ẹmi mímọ́?
8 Awọn wọnni ti a fi omi bamtisi ni ọjọ Pẹntikọsi 33 C.E. ni a tun fi ẹmi bamtisi, ni jijẹ ẹni ti a fami ororo yan gẹgẹ bi ọba ati alufaa ọjọ-ọla ni Ijọba ti ọrun. Gẹgẹ bi iwe Iṣipaya ti wi, kiki 144,000 awọn wọnyi ni o wà. Nitori naa awọn wọnni ti a fi ẹmi bamtisi ti a ‘fi edidi di’ nikẹhin gẹgẹ bi ajumọ jogun Ijọba papọ jẹ́ 144,000. (Iṣipaya 7:4; 14:1) Bi o ti wu ki o ri, gbogbo awọn ọmọ-ẹhin titun—ohun yoowu ki ireti ọjọ-ọla wọn jẹ́—ni a bamtisi ninu omi ni orukọ Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́. (Matiu 28:19, 20) Nigba naa, ki ni, bamtisimu ni orukọ ẹmi mímọ́ tumọsi fun awọn Kristẹni, yala ti “agbo kekere” tabi ti “agutan miiran”? (Luuku 12:32; Johanu 10:16) Ṣaaju ki a tó dahun iyẹn, ẹ jẹ ki a ṣakiyesi awọn igbokegbodo diẹ ti ẹmi ni sanmani Kristẹni.
Awọn Eso Ti Ẹmi
9. Igbokegbodo ẹmi mímọ́ wo ni o ṣe pataki fun gbogbo awọn Kristẹni?
9 Igbokegbodo pataki ti ẹmi mímọ́ jẹ́ ní ríràn wa lọwọ lati mu awọn animọ Kristẹni dagba. Loootọ, nitori aipe awa kò lè yẹra fun dida ẹṣẹ. (Roomu 7:21-23) Ṣugbọn nigba ti a ba fi otitọ-inu ronupiwada, Jehofa ń dariji wa lori ipilẹ ẹbọ Kristi. (Matiu 12:31, 32; Roomu 7:24, 25; 1 Johanu 2:1, 2) Siwaju sii, Jehofa tun fẹ ki a jijakadi lodi si itẹsi wa lati dẹṣẹ, ẹmi mímọ́ yoo sì ràn wá lọ́wọ́ lati ṣe eyi. “Ẹ maa rìn nipa ti ẹmi,” ni Pọọlu wi, “ẹyin ki yoo sì mu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ.” (Galatia 5:16) Pọọlu ń baa lọ lati fihan pe ẹmi lè mu awọn animọ didara julọ jade ninu wa. Ó kọwe pe: “Eso ti ẹmi ni ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, inurere, iwarere-iṣeun, igbagbọ, iwapẹlẹ, ikora-ẹni-nijaanu.”—Galatia 5:22, 23, NW.
10. Bawo ni awọn eso ti ẹmi ṣe ń dagba ninu awọn Kristẹni?
10 Bawo ni ẹmi ṣe mu iru awọn eso bẹẹ ṣeeṣe ninu Kristẹni kan? Kò dédé ṣẹlẹ kiki nitori pe a jẹ́ Kristẹni oluṣeyasimimọ ati iribọmi. A nilati ṣiṣẹ síhà rẹ̀. Ṣugbọn bi a bá kẹgbẹ pẹlu awọn Kristẹni miiran ti wọn fi awọn animọ wọnyi han, bi a ba gbadura si Ọlọrun fun ẹmi rẹ̀ lati ran wa lọwọ lati mu awọn animọ kan dagba, bi a bá yẹra fun awọn ẹgbẹ́ buburu ti a sì kẹkọọ Bibeli fun imọran ati awọn apẹẹrẹ rere, nigba naa awọn eso ti ẹmi yoo dagba ninu wa.—Owe 13:20; 1 Kọrinti 15:33; Galatia 5:24-26; Heberu 10:24, 25.
A Yàn Wọ́n Nipasẹ Ẹmi Mímọ́
11. Ni ọna wo ni a gbà yan awọn alagba sipo nipasẹ ẹmi mímọ́?
11 Nigba ti Pọọlu ń ba awọn alagba Efesu sọrọ, ó sọ igbokegbodo ẹmi mímọ́ miiran di mímọ̀ nigba ti o wi pe: “Ẹ kiyesi ara yin ati si gbogbo agbo, laaarin eyi ti ẹmi mímọ́ ti yan yin ṣe alaboojuto, lati ṣe oluṣọ-agutan ijọ Ọlọrun, eyi ti o fi ẹjẹ Ọmọkunrin oun funraarẹ rà.” (Iṣe 20:28, NW) Bẹẹni, awọn alaboojuto ijọ, tabi alagba, ni a fi ẹmi mímọ́ yansipo. Ni ọna wo? Niti pe awọn alagba ti a yansipo gbọdọ dé oju ila awọn ohun àbéèrèfún ti a là lẹsẹẹsẹ sinu Bibeli ti a misi. (1 Timoti 3:1-13; Titu 1:5-9) Wọn lè mu awọn ohun àbéèrèfún wọnni dagba kiki pẹlu iranlọwọ ẹmi mímọ́. Siwaju sii, ẹgbẹ́ awọn alagba ti wọn damọran alagba titun kan yoo gbadura fun itọsọna ẹmi mímọ́ lati mọ yala ó dé oju ila awọn ohun àbéèrèfún tabi bẹẹkọ. Iyansipo naa gan-an ni a ṣe labẹ abojuto ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu ti a fami ororo yan.
Di Ẹni Ti A Tọ Sọna Nipasẹ Ẹmi
12. Bawo ni ẹmi ṣe le nipa lori wa nipasẹ Bibeli?
12 Awọn Kristẹni mọ daju pe awọn Iwe Mímọ́ ni a kọ labẹ idari ẹmi mímọ́. Fun idi yii, wọn walẹjin lọ sinu wọn fun ọgbọn ti a fi ẹmi mísí, gẹgẹ bi awọn ẹlẹ́rìí ṣaaju akoko Kristẹni ti ṣe. (Owe 2:1-9) Wọn kà wọn, ronu jinlẹ lé wọn lori, wọn sì jẹ́ ki wọn tọ́ igbesi-aye wọn sọna. (Saamu 1:1-3; 2 Timoti 3:16) A tipa bayii ran wọn lọwọ nipasẹ ẹmi lati ‘wadii awọn ohun ijinlẹ Ọlọrun.’ (1 Kọrinti 2:10, 13; 3:19) Titọ awọn iranṣẹ Ọlọrun sọna ni ọna yii jẹ́ igbokegbodo ẹmi Ọlọrun pataki fun akoko wa.
13, 14. Ki ni Jesu lo lati bojuto awọn iṣoro ninu ijọ, bawo ni ó sì ṣe ń ṣe bakan naa lonii?
13 Siwaju sii, ninu iwe Iṣipaya, Jesu ti a ji dide ranṣẹ si ijọ meje ni Aṣia Kekere. (Iṣipaya, ori 2 ati 3) Ninu wọn ó ṣipaya pe oun ti bẹ awọn ijọ naa wò oun sì moye ipo tẹmi wọn. O ri i pe, awọn diẹ ń fi apẹẹrẹ rere ti igbagbọ lelẹ. Ninu awọn miiran, awọn alagba yọọda fun ẹ̀ya isin, iwa palapala, ati kò-gbóná-kò-tutù lati sọ agbo dibajẹ. Yatọ si awọn ọkàn oluṣotitọ diẹ, ijọ ti o wà ni Sardis, ni o ti di oku nipa tẹmi. (Iṣipaya 3:1, 4) Bawo ni Jesu ṣe bojuto awọn iṣoro wọnyi? Pẹlu ẹmi mímọ́. Nigba ti o ń fun awọn ijọ meje naa ni imọran, ninu ọran kọọkan ihin-iṣẹ Jesu pari pẹlu ọrọ naa: “Ẹni ti o ba ni eti ki o gbọ ohun ti ẹmi ń sọ fun awọn ijọ.”—Iṣipaya 2:7, 11, 17, 29; 3:6, 13, 22.
14 Lonii, pẹlu, Jesu bẹ awọn ijọ wo. Nigba ti o sì woye awọn iṣoro, ó bojuto wọn sibẹ nipasẹ ẹmi mímọ́. Ẹmi lè ran wa lọwọ lati mọ ki a sì ṣẹpa awọn iṣoro taarata nipasẹ kika ti a ń ka Bibeli. Iranlọwọ tun lè wá nipasẹ iwe ikẹkọọ Bibeli ti a tẹ jade nipasẹ ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu ti a fami ororo yan. Ó sì lè wá lati ọdọ awọn alagba ti a fi ẹmi yansipo ninu ijọ. Ohun yoowu ki ọran naa jẹ́, yala imọran naa jẹ́ fun awọn ẹnikọọkan tabi fun ijọ lodindi, awa ha ń kọbiara si awọn ọrọ Jesu pe: “Ẹni ti o ba ni eti ki o gbọ ohun ti ẹmi ń sọ” bi?
Ẹmi ati Iṣẹ Iwaasu
15. Bawo ni ẹmi ṣe ṣiṣẹ siha ọdọ Jesu niti iṣẹ iwaasu?
15 Ni akoko kan nigba ti Jesu waasu ninu sinagọgu kan ni Nasarẹti, ó fi igbokegbodo miiran ti ẹmi han. Akọsilẹ naa sọ fun wa pe: “Ó sì ṣí akajọ iwe naa ó sì ri ibi ti a ti kọ ọ pe: ‘Ẹmi Jehofa ń bẹ lara mi, nitori ó ti fororo yan mi lati kéde ihinrere fun awọn òtòṣì, ó rán mi lati waasu itusilẹ fun awọn òǹdè ati ijerepada agbara iriran fun awọn afọju, lati tú awọn ti a nilára silẹ.’ Nigba naa ni ó bẹrẹ sii wi fun wọn pe: ‘Lonii ni iwe mímọ́ ti ẹ ṣẹṣẹ gbọ yii ni imuṣẹ.’” (Luuku 4:17, 18, 21, NW; Aisaya 61:1, 2) Bẹẹni, Jesu ni a fami ororo yan lati waasu ihinrere.
16. Ni ọrundun kìn-ín-ní, bawo ni ẹmi mímọ́ ṣe wémọ́ wiwaasu ihinrere lọna jijinlẹ?
16 Kété ṣaaju iku rẹ̀, Jesu sọ asọtẹlẹ igbetaasi iwaasu ńláǹlà kan tí awọn ọmọlẹhin rẹ̀ yoo ṣaṣepari. Ó sọ pe: “A kò lè ṣaima kọ́ waasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ede.” (Maaku 13:10) Awọn ọrọ wọnyi ni imuṣẹ akọkọ ni ọrundun kìn-ín-ní, ipa ti ẹmi mímọ́ sì kó yẹ fun afiyesi. Ẹmi mímọ́ ni o dari Filipi lati waasu fun ìwẹ̀fà ara Etiopia. Ẹmi mímọ́ dari Peteru si Kọniliu, ẹmi mímọ́ sì paṣẹ pe ki a rán Pọọlu ati Banaba jade gẹgẹ bi apọsiteli lati Antioku. Lẹhin naa, nigba ti Pọọlu fẹ lati waasu ni Eṣia ati Bitinia, ẹmi mímọ́ dí i lọwọ ní ọ̀nà kan. Ọlọrun fẹ ki iṣẹ ijẹrii naa kọja lọ si Europe.—Iṣe 8:29; 10:19; 13:2; 16:6, 7.
17. Lonii, bawo ni ẹmi mímọ́ ṣe wémọ́ iṣẹ iwaasu?
17 Lonii, ẹmi mímọ́ tun wémọ́ iṣẹ ijẹrii gidigidi. Ninu imuṣẹ Aisaya 61:1, 2, siwaju sii, ẹmi Jehofa ti yan awọn arakunrin Jesu lati waasu. Ni imuṣẹ ikẹhin ti Maaku 13:10, awọn ẹni ami ororo wọnyi, tí awọn ogunlọgọ nla ṣe iranlọwọ fun, ti waasu ihinrere naa ni gbogbo awọn “orilẹ-ede” niti gidi. (Iṣipaya 7:9, NW) Ẹmi sì ń ti gbogbo wọn lẹhin ninu eyi. Gẹgẹ bi o ti ri ni ọrundun kìn-ín-ní, ó ṣi ọna awọn ipinlẹ silẹ ó sì ṣatọna itẹsiwaju iṣẹ naa ni gbogbogboo. Ó fun awọn ẹnikọọkan lokun, ni ríràn wọn lọwọ lati ṣẹpa ibẹru ki wọn sì mu awọn oye ikọnilẹkọọ wọn dagba. Ju bẹẹ lọ, Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “A o sì mu yin lọ siwaju awọn baalẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹ̀rí si wọn ati si awọn Keferi. Nigba ti wọn ba sì fi yin lé wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan pe, bawo tabi ki ni ẹyin yoo wi. . . . Nitori pe kii ṣe ẹyin ni o ń sọ, ṣugbọn ẹmi Baba yin ni ń sọ ninu yin.”—Matiu 10:18-20.
18, 19. Ni ọna wo ni ẹmi gba darapọ mọ iyawo ninu kikesi awọn ọlọkantutu lati “gba omi ìyè naa lọfẹẹ”?
18 Ninu iwe Iṣipaya, Bibeli lẹẹkansii tẹnumọ ikopa ẹmi mímọ́ ninu iṣẹ iwaasu. Nibẹ ni apọsiteli Johanu ti rohin pe: “Ati ẹmi ati iyawo wi pe, Maa bọ. Ati ẹni ti o ń gbọ ki o wi pe, Maa bọ. Ati ẹni ti oungbẹ ń gbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba sì fẹ́, ki o gba omi ìyè naa lọfẹẹ.” (Iṣipaya 22:17) Iyawo, tí awọn tí ó ṣẹku ninu 144,000 ti wọn ṣì wà lori ilẹ-aye duro fun, ké si gbogbo eniyan lati gba omi ìyè lọfẹẹ. Ṣugbọn ṣakiyesi, ẹmi mímọ́ pẹlu wi pe “Maa bọ” Ni ọna wo?
19 Niti pe ihin-iṣẹ tí ẹgbẹ́ iyawo naa ń waasu—tí ogunlọgọ nla ti awọn agutan miiran ń tilẹhin—wá lati inu Bibeli, ti a kọ labẹ agbara idari ẹmi mímọ́ ni taarata. Ẹmi yẹn kan naa sì ti ṣí ọkan-aya ati ero inu ẹgbẹ́ iyawo silẹ lati loye Ọrọ onimiisi ki wọn sì ṣalaye rẹ̀ fun awọn miiran. Awọn wọnni ti a bamtisi gẹgẹ bi ọmọ-ẹhin titun ti Jesu Kristi ní idunnu lati gba ninu omi ìyè lọfẹẹ. Ó sì dun mọ wọn lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹmi ati iyawo ni sisọ pe “Maa bọ” fun awọn ẹlomiran sibẹ. Lonii, iye ti o ju million mẹrin lọ ń ṣajọpin pẹlu ẹmi ninu iṣẹ yii.
Gbigbe Ni Ibamu Pẹlu Bamtisimu Wa
20, 21. Bawo ni a ṣe lè gbé ni ibamu pẹlu bamtisimu wa ni orukọ ẹmi mímọ́, oju wo ni a sì nilati fi wo bamtisimu yii?
20 Bamtisimu ni orukọ ẹmi mímọ́ jẹ́ ikede itagbangba pe a mọ ẹmi mímọ́ daju a sì jẹwọ ipa ti o ń kó ninu awọn ète Jehofa. Ó tun wa tumọsi pe awa yoo fọwọsowọpọ pẹlu ẹmi, laiṣe ohunkohun lati di iṣiṣẹ rẹ̀ laaarin awọn eniyan Jehofa lọwọ. Nipa bayii, a mọ daju a sì fọwọsowọpọ pẹlu ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu. A fọwọsowọpọ pẹlu iṣeto alagba ninu ijọ. (Heberu 13:7, 17; 1 Peteru 5:1-4) A ń gbé nipa ọgbọn tẹmi, kii ṣe nipa ọgbọn ti ara, a sì yọnda fun ẹmi lati gbé animọ wa ró, ni titubọ sọ ọ di bii ti Kristi. (Roomu 13:14) A sì darapọ tọkantọkan pẹlu ẹmi ati iyawo ni wiwi pe “Maa bọ” fun araadọta-ọkẹ ti wọn ṣì lè dahunpada.
21 Ohun pataki wo ni o jẹ́ lati jẹ́ ẹni ti a bamtisi ‘ni orukọ ẹmi mímọ́’! Sibẹ, awọn ibukun wo ni o lè jẹ jade! Njẹ ki iye awọn wọnni ti a tipa bayii bamtisi maa baa lọ lati pọ sii. Njẹ ki gbogbo wa sì maa baa lọ lati gbe ni ibamu pẹlu itumọ bamtisimu yẹn, gẹgẹ bi a ti ń ṣẹrú fun Jehofa ti a sì n baa lọ lati maa “tàn yòò pẹlu ẹmi.”—Roomu 12:11, NW.
Ki Ni O Ranti Nipa Ẹmi Mímọ́?
◻ Ni ọna wo ni ẹmi mímọ́ gba jẹ́ agbékánkánṣiṣẹ́ ni Pẹntikọsi 33 C.E.?
◻ Bawo ni a ṣe lè mu awọn eso ẹmi jade?
◻ Ni ọna wo ni a gba yan awọn alagba sipo nipasẹ ẹmi mímọ́?
◻ Bawo ni Jesu ṣe bojuto awọn iṣoro ijọ nipasẹ ẹmi mimọ?
◻ Bawo ni ẹmi mímọ́ ṣe wémọ́ iṣẹ iwaasu lọna jijinlẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Bamtisimu ti Peteru waasu tun jẹ́ ni orukọ Baba ati ti ẹmi mímọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹmi wémọ́ wiwaasu ihinrere naa lọna jijinlẹ