Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
12 Ní ti àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí,+ ẹ̀yin ará, mi ò fẹ́ kí ẹ ṣaláìmọ̀ nípa rẹ̀. 2 Ẹ mọ̀ pé nígbà tí ẹ ṣì jẹ́ èèyàn orílẹ̀-èdè,* wọ́n ń nípa lórí yín, wọ́n ń kó yín ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà tí kò lè sọ̀rọ̀,+ ẹ sì ń ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́. 3 Ní báyìí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé kò sí ẹni tó bá ń fi ẹ̀mí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ tó máa sọ pé: “Ẹni ègún ni Jésù!” kò sì sí ẹni tó lè sọ pé: “Jésù ni Olúwa!” àfi nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+
4 Oríṣiríṣi ẹ̀bùn ló wà, àmọ́ ẹ̀mí kan ló wà;+ 5 oríṣiríṣi iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló wà,+ síbẹ̀ Olúwa kan náà ló wà; 6 oríṣiríṣi iṣẹ́* ló wà, síbẹ̀ Ọlọ́run kan náà ló ń ṣe gbogbo iṣẹ́ náà nínú gbogbo èèyàn.+ 7 Àmọ́, à ń fi ẹ̀mí hàn nípasẹ̀ kálukú kí á lè ṣe àwọn míì láǹfààní.+ 8 A fún ẹnì kan ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n* nípasẹ̀ ẹ̀mí, a fún ẹlòmíì ní ọ̀rọ̀ ìmọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, 9 a fún òmíì ní ìgbàgbọ́+ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, a fún òmíì ní àwọn ẹ̀bùn ìwòsàn+ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, 10 síbẹ̀, a fún òmíì ní ẹ̀bùn láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ agbára,+ a fún òmíì ní ìsọtẹ́lẹ̀, a fún òmíì ní òye àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí,+ a fún òmíì ní ẹ̀bùn oríṣiríṣi èdè,*+ a sì fún òmíì ní ìtúmọ̀ àwọn èdè.+ 11 Àmọ́ gbogbo iṣẹ́ yìí ni ẹ̀mí kan náà yìí ń ṣe, ó ń pín ẹ̀bùn fún kálukú gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́.
12 Nítorí bí ara ṣe jẹ́ ọ̀kan àmọ́ tó ní ẹ̀yà púpọ̀, tí gbogbo ẹ̀yà ara yẹn sì jẹ́ ara kan+ bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Kristi. 13 Nítorí ipasẹ̀ ẹ̀mí kan ni a batisí gbogbo wa sínú ara kan, ì báà jẹ́ Júù tàbí Gíríìkì, ẹrú tàbí òmìnira, a sì mú kí gbogbo wa gba* ẹ̀mí kan.
14 Ní tòótọ́, kì í ṣe ẹ̀yà ara kan ṣoṣo ló dá di ara, ẹ̀yà ara púpọ̀ ni.+ 15 Tí ẹsẹ̀ bá sọ pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe apá kan ara,” ìyẹn ò sọ pé kì í ṣe apá kan ara. 16 Tí etí bá sì sọ pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” ìyẹn ò sọ pé kì í ṣe apá kan ara. 17 Tí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, ibo ni agbára ìgbọ́ràn máa wà? Tí gbogbo rẹ̀ bá jẹ́ ìgbọ́ràn, ibo ni agbára ìgbóòórùn máa wà? 18 Àmọ́ ní báyìí, Ọlọ́run ti to ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bí ó ṣe fẹ́ sínú ara.
19 Tí gbogbo wọn bá jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà, ibo ni ara máa wà? 20 Àmọ́ ní báyìí bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà ara púpọ̀, ara kan ṣoṣo ni wọ́n. 21 Ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Mi ò nílò rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni orí kò lè sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Mi ò nílò rẹ.” 22 Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀yà ara tó dà bíi pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára ṣe pàtàkì, 23 àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá ni à ń bọlá fún jù,+ nípa bẹ́ẹ̀ àwọn ẹ̀yà ara wa tí kò jọni lójú ni à ń yẹ́ sí jù lọ, 24 nígbà tó jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà ara wa tó fani mọ́ra kò nílò ohunkóhun. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ṣètò ara, ó fún àwọn ẹ̀yà ara tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára ní ọlá tó pọ̀ jù, 25 kó má bàa sí ìpínyà kankan nínú ara, àmọ́ kí àwọn ẹ̀yà ara lè máa ṣìkẹ́ ara wọn.+ 26 Tí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara tó kù á bá a jìyà;+ tí a bá sì ṣe ẹ̀yà ara kan lógo, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù á bá a yọ̀.+
27 Ní báyìí, ẹ̀yin jẹ́ ara Kristi,+ kálukú yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara.+ 28 Ọlọ́run ti yan ẹnì kọ̀ọ̀kan sínú ìjọ: èkíní, àwọn àpọ́sítélì;+ èkejì, àwọn wòlíì;+ ẹ̀kẹta, àwọn olùkọ́;+ lẹ́yìn náà, àwọn iṣẹ́ agbára;+ lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀bùn ìwòsàn;+ àwọn iṣẹ́ ìrànwọ́; àwọn agbára láti máa darí+ àti oríṣiríṣi èdè.*+ 29 Kì í ṣe gbogbo wọn ni àpọ́sítélì, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni wòlíì, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni olùkọ́, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára, àbí gbogbo wọn ni? 30 Kì í ṣe gbogbo wọn ló ní ẹ̀bùn ìwonisàn, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ló ń fi èdè fọ̀, àbí gbogbo wọn ni?+ Kì í ṣe gbogbo wọn ló jẹ́ olùtúmọ̀,* àbí gbogbo wọn ni?+ 31 Àmọ́ ẹ máa wá ẹ̀bùn tó tóbi jù.*+ Síbẹ̀, màá fi ọ̀nà tó ta yọ hàn yín.+