Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ní ṣangiliti, ìyàtọ̀ ha wà láàárín àwọn èdè-ìsọ̀rọ̀ Bibeli náà “àwọn àgùtàn mìíràn” àti “ogunlọ́gọ̀ ńlá”?
Bẹ́ẹ̀ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kí ìlò ọ̀rọ̀ ká wa lára jù bí ó ti yẹ lọ tàbí kí a bínú bí ẹnì kan bá gbé àwọn èdè-ìsọ̀rọ̀ náà fún ara wọn.
Ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn Kristian mọ̀ àwọn apá àyọkà ọ̀rọ̀ náà níbi tí a ti rí àwọn èdè-ìsọ̀rọ̀ wọ̀nyí dáradára. Johannu 10:16 jẹ́ ọ̀kan. Níbẹ̀ ni Jesu ti sọ pé: “Emi . . . ní awọn àgùtàn mìíràn, tí kì í ṣe ti ọ̀wọ́ agbo yii; awọn wọnnì pẹlu ni mo gbọ́dọ̀ mú wá, wọn yoo sì fetísílẹ̀ sí ohùn mi, wọn yoo sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùtàn kan.” Ọ̀rọ̀ kejì, “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” fara hàn ní Ìṣípayá 7:9. A kà pé: “Lẹ́yìn nǹkan wọnyi mo rí, sì wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹni kankan kò lè kà, lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ ati níwájú Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa, wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà funfun; imọ̀ ọ̀pẹ sì ń bẹ ní ọwọ́ wọn.”
Ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ gbé Johannu 10:16 yẹ̀wò. Àwọn wo ni àwọn àgùtàn? Ó dára, ó yẹ kí a fi sọ́kàn pé gbogbo àwọn adúróṣinṣin ọmọlẹ́yìn Jesu ni a tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí àwọn àgùtàn. Ní Luku 12:32, ó pe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí yóò lọ sí ọ̀run ní “agbo kékeré.” Agbo kí ni? Ti àgùtàn. “Awọn àgùtàn” ti “agbo kékeré” náà yóò jẹ́ apákan Ìjọba ní ọ̀run. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn mìíràn wà, tí wọ́n ní ìrètí tí ó yàtọ̀, tí Jesu wò gẹ́gẹ́ bí àgùtàn.
A lè rí èyí ní Johannu orí 10. Lẹ́yìn sísọ̀rọ̀ nípa àwọn àgùtàn irú bí àwọn aposteli rẹ̀ tí òun yóò pè sí ìyè ní ọ̀run, Jesu fikún un ní ẹsẹ̀ 16 pé: “Emi . . . ní awọn àgùtàn mìíràn, tí kì í ṣe ti ọ̀wọ́ agbo yii; awọn wọnnì pẹlu ni mo gbọ́dọ̀ mú wá.” Tipẹ́tipẹ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti mọ̀ pé nínú ẹsẹ̀ yìí Jesu ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìrètí ìwàláàyè lórí ilẹ̀-ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣòtítọ́ ṣáájú àwọn àkókò Kristian, bí Abrahamu, Sara, Noa, ati Malaki, ní irú ìfojúsọ́nà bẹ́ẹ̀. Nítorí náà lọ́nà títọ́ a lè kà wọ́n mọ́ apákan “awọn àgùtàn mìíràn” ti Johannu 10:16. Nígbà Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún, irú àwọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ ṣáájú ìgbà Kristian bẹ́ẹ̀ ni a óò jí dìde tí wọn yóò sì kọ́ nípa Kristi Jesu wọ́n yóò sì tẹ́wọ́gbà á, ní dídi “awọn àgùtàn mìíràn” ti Olùṣọ́ Àgùtàn Àtàtà náà.
A mọ̀ pẹ̀lú pé níwọ̀n bí ìpè ẹgbẹ́ ti ọ̀run náà ti parí ní gbogbogbòò, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti di Kristian tòótọ́. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni a pè lọ́nà títọ́ ní “awọn àgùtàn mìíràn,” níwọ̀n bí wọ́n kì í ti í ṣe apákan “agbo kékeré” náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn àgùtàn mìíràn lónìí ń fojúsọ́nà láti máa wàláàyè nìṣó wọnú paradise orí ilẹ̀-ayé.
Nísinsìnyí, kí ni a lè sọ nípa ìdánimọ̀ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí a mẹ́nubà ní Ìṣípayá 7:9? Ó dára, wo ẹsẹ̀ 13 àti ìbéèrè náà, “Ta ni wọ́n níbo ni wọ́n sì ti wá?” A rí ìdáhùn náà ní Ìṣípayá 7:14: “Awọn wọnyi ni awọn tí wọ́n jáde wá lati inú ìpọ́njú ńlá naa.” Nítorí náà, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” jẹ́ àpapọ̀ àwọn tí wọ́n jáde wá, tàbí la ìpọ́njú ńlá náà já. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ̀ 17 ṣe sọ, a óò “fi wọ́n mọ̀nà lọ sí awọn ìsun omi ìyè” lórí ilẹ̀-ayé.
Bí ó ti wù kí ó rí, ó lè yéni nígbà náà pé, fún àwọn wọ̀nyí láti la ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀ náà já, wọ́n ti níláti fọ aṣọ wọn ṣáájú nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn náà, ní dídi olùjọsìn tòótọ́. Fún ìdí yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìṣípayá 7:9 ń ṣàpèjúwe àwọn ogunlọ́gọ̀ yìí lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá, a lè lo èdè-ìsọ̀rọ̀ náà “ogunlọ́gọ̀ ńlá” fún gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí ti ilẹ̀-ayé tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Jehofa nísinsìnyí, kété ṣáájú kí ìpọ́njú ńlá náà pẹ̀lú ìgbéjàkò tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣe fún ìsìn èké tó bẹ́ sílẹ̀.
Ní àkópọ̀, a lè rántí “awọn àgùtàn mìíràn” ní èdè-ìsọ̀rọ̀ gbígbòòrò, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun tí wọ́n ní ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀-ayé títíláé. Ó ní nínú ìṣọ̀wọ́ kéréje ti àwọn ẹni-bí-àgùtàn lónìí tí a ń kójọ gẹ́gẹ́ bí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” pẹ̀lú ìrètí wíwàláàyè la ìpọ́njú ńlá tí ó rọ̀dẹ̀dẹ̀ náà já. Ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn Kristian adúróṣinṣin tí wọ́n wà láàyè lónìí jẹ́ “àgùtàn mìíràn,” wọ́n sì jẹ́ apákan “ogunlọ́gọ̀ ńlá.”
Ó dára láti tún un sọ pé, bí ó ti dára tó láti ṣe kedere lórí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí, kò sí ìdí fún Kristian èyíkéyìí láti jẹ́ ẹni tí ìlò ọ̀rọ̀ ká lára ju bí ó ti yẹ lọ—èyí tí a lè pè ní ṣíṣe lámèyítọ́ lórí ọ̀rọ̀. Paulu kìlọ̀ nípa àwọn kan tí wọ́n “ń wú fùkẹ̀ pẹlu ìgbéraga” tí wọ́n sì ń lọ́wọ́ nínú “fífa ọ̀rọ̀.” (1 Timoteu 6:4) Bí àwa fúnra wa bá mọ àwọn ìyàtọ̀ kan láàárín àwọn èdè-ìsọ̀rọ̀, ìyẹn dára. Síbẹ̀, bóyá ní gbangba tàbí nínú lọ́hùn-ún, kò yẹ kí a jẹ́ olùṣelámèyítọ́ àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n lè má lo àwọn èdè-ìsọ̀rọ̀ Bibeli lọ́nà yíyẹ rẹ́gí.